Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjọba Ọlọ́run—Ìṣàkóso Tuntun Fún Ilẹ̀ Ayé

Ìjọba Ọlọ́run—Ìṣàkóso Tuntun Fún Ilẹ̀ Ayé

Ìjọba Ọlọ́run—Ìṣàkóso Tuntun Fún Ilẹ̀ Ayé

“Ìjọba náà . . . yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—DÁNÍẸ́LÌ 2:44.

1. Ìgbọ́kànlé wo la lè ní nínú Bíbélì?

 BÍBÉLÌ jẹ́ ohun tí Ọlọ́run ṣí payá fún ènìyàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (1 Tẹsalóníkà 2:13) Bíbélì kún fún àwọn ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run; àwọn ìsọfúnni nípa àkópọ̀ ìwà rẹ̀, àwọn ète rẹ̀, àti àwọn ohun tí ó béèrè lọ́wọ́ wa. Ó ní ìmọ̀ràn tó dára jù lọ lórí ìgbésí ayé ìdílé àti ìwà wa ojoojúmọ́. Ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n nímùúṣẹ láyé ìgbàanì, àwọn tó ń nímùúṣẹ nísinsìnyí, àti àwọn tí yóò nímùúṣẹ lọ́jọ́ iwájú. Dájúdájú, “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.

2. Báwo ni Jésù ṣe tẹnu mọ́ àkòrí Bíbélì?

2 Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Bíbélì ni àkòrí rẹ̀, ìyẹn ni: ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run (ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣàkóso) nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run. Ìyẹn ni Jésù fi ṣe ipò kìíní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. “Jésù bẹ̀rẹ̀ wíwàásù, ó sì ń wí pé: ‘Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mátíù 4:17) Ó fi ipò tó yẹ kó wà nínú ìgbésí ayé wa hàn nípa rírọ̀ wá pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” (Mátíù 6:33) Ó tún fi bó ti ṣe pàtàkì tó hàn nípa kíkọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn láti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10.

Ìjọba Tuntun Lórí Ilẹ̀ Ayé

3. Èé ṣe tí ìjọba Ọlọ́run fi jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì fún wa báyìí?

3 Èé ṣe tí Ìjọba Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì fún ẹ̀dá ènìyàn tó bẹ́ẹ̀? Nítorí pé láìpẹ́ yóò ṣe nǹkan kan tí yóò yí ìṣàkóso ayé yìí padà títí láé ni. Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì orí kejì, ẹsẹ ogójì ó lé mẹ́rin sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [tí wọ́n ń ṣàkóso lórí ayé báyìí], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ [ìjọba kan ní ọ̀run] èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn [àwọn ìjọba ayé], òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Nígbà tí Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run bá ń ṣàkóso lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, kò tún ní sí pé èèyàn ń darí ayé yìí mọ́. Ìṣàkóso èèyàn tó pínyà, tí kò sì tẹ́ni lọ́rùn yóò di ohun tó kọjá lọ títí láé.

4, 5. (a) Èé ṣe tí Jésù fi jẹ́ ẹni tí ó tóótun jù lọ láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà? (b) Iṣẹ́ wo ni Jésù yóò gbà láìpẹ́?

4 Olórí Alákòóso nínú Ìjọba ọ̀run, tó wà lábẹ́ ìdarí Jèhófà ní tààràtà ni ẹni tí ó tóótun jù lọ náà—Kristi Jésù. Kó tó di pé ó wá sórí ilẹ̀ ayé, ó ti wà ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́” fún Ọlọ́run ní ti pé òun ni ẹni àkọ́kọ́ nínú gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọ́run. (Òwe 8:22-31) “Òun ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí, àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá; nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Kólósè 1:15, 16) Nígbà tí Ọlọ́run sì rán Jésù wá sórí ilẹ̀ ayé, ó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà. Ó fara da àdánwò tó burú jù lọ láyé, ó sì kú gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí Baba rẹ̀.—Jòhánù 4:34; 15:10.

5 Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, títí dé ojú ikú pàápàá, ó gba èrè. Ọlọ́run jí i dìde sí ọ̀run, ó sì fún un ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ Ọba Ìjọba ọ̀run. (Ìṣe 2:32-36) Gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba náà, Kristi Jésù yóò gba iṣẹ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti darí ẹgbàágbèje àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára nínú mímú ìṣàkóso ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé àti fífọ gbogbo ìwà ibi mọ́ kúrò nínú àgbáyé wa yìí. (Òwe 2:21, 22; 2 Tẹsalóníkà 1:6-9; Ìṣípayá 19:11-21; 20:1-3) Lẹ́yìn náà ni Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run lábẹ́ Kristi yóò jẹ́ ìjọba tuntun tí yóò máa ṣàkóso, ìyẹn ìjọba kan ṣoṣo lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 11:15.

6. Irú ìṣàkóso wo ni a lè retí látọ̀dọ̀ Ọba Ìjọba náà?

6 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa Alákòóso tuntun lórí ayé náà pé: “A sì fún un ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.” (Dáníẹ́lì 7:14) Nítorí pé Jésù yóò fara wé ìfẹ́ Ọlọ́run, àlàáfíà àti ayọ̀ tó máa wà lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ yóò ga lọ́lá. (Mátíù 5:5; Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 4:7-10) “Ní ti bíbí sí i ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà kì yóò lópin, . . . láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo àti pẹ̀lú òdodo.” (Aísáyà 9:7, Revised Standard Version) Ìbùkún ńláǹlà ni yóò mà jẹ́ o láti ní Alákòóso tó ń fi ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, àti òdodo ṣàkóso! Abájọ tí Pétérù kejì orí kẹta, ẹsẹ ìkẹtàlá fi sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀run tuntun [Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run] àti ilẹ̀ ayé tuntun [àwùjọ tuntun lórí ilẹ̀ ayé] wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”

7. Báwo ni Mátíù 24:14 ṣe ń nímùúṣẹ lóde òní?

7 Dájúdájú, Ìjọba Ọlọ́run ni ìròyìn tó dára jù lọ fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ohun tó tọ́. Gẹ́gẹ́ bí ara àmì pé a ti ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò búburú yìí ni Jésù fi sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (2 Tímótì 3:1-5; Mátíù 24:14) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti ń nímùúṣẹ báyìí, bí àwọn bíi mílíọ̀nù mẹ́fà Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ilẹ̀ ti ń ya ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí sọ́tọ̀ lọ́dọọdún láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ibi ìjọsìn wọn tí nǹkan bí ẹgbàá márùnlélógójì [90,000] ìjọ jákèjádò ayé ń lò la ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ibẹ̀ làwọn èèyàn ti wá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjọba tuntun tó ń bọ̀.

Àwọn Alájùmọ̀ṣàkóso

8, 9. (a) Ibo làwọn tí yóò bá Kristi ṣàkóso ti wá? (b) Ìgbọ́kànlé wo la lè ní nínú ìṣàkóso Ọba náà àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀?

8 Àwọn tí yóò bá Kristi Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run yóò wà. Ìṣípayá orí kẹrìnlá, ẹsẹ ìkíní sí ìkẹrin sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn ní a ó “rà lára aráyé” tí a ó sì jí wọn dìde sí iye ti ọ̀run. Tọkùnrin tobìnrin ló wà nínú wọn, àwọn tó jẹ́ pé dípò kí a máa ṣe ìránṣẹ́ fún wọn, ńṣe ni wọ́n ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ìránṣẹ́ fún Ọlọ́run àti fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn. “Wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” (Ìṣípayá 20:6) Iye wọ́n kéré gan-an ju ti àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” tí yóò la òpin ètò ìsinsìnyí já. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀” fún Ọlọ́run “tọ̀sán-tòru,” àmọ́, wọn kò ní ìpè ti ọ̀run. (Ìṣípayá 7:9, 15) Wọ́n jẹ́ ìpìlẹ̀ ayé tuntun náà gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run.—Sáàmù 37:29; Jòhánù 10:16.

9 Ní yíyan àwọn tí yóò bá Kristi ṣàkóso ní ọ̀run, Jèhófà yan àwọn olóòótọ́ ènìyàn tí wọ́n ti nírìírí ìgbésí ayé àti gbogbo ìṣòro inú rẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun kan tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tí kò tíì ṣẹlẹ̀ sáwọn ọba àti àlùfáà wọ̀nyí rí. Nípa bẹ́ẹ̀, gbígbé tí wọ́n ti gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò mú kó rọrùn fún wọn láti ṣàkóso lórí ẹ̀dá ènìyàn. Kódà Jésù alára “kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀.” (Hébérù 5:8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ pé: “Àwa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni tí kò lè báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa, bí kò ṣe ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.” (Hébérù 4:15) Ìtùnú ńlá mà lèyí o, láti mọ̀ pé nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run, àwọn ọba àti àlùfáà tó nífẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ń báni kẹ́dùn ní yóò ṣàkóso àwọn ènìyàn!

Ǹjẹ́ Ìjọba Náà Tiẹ̀ Wà Nínú Ète Ọlọ́run?

10. Èé ṣe tí Ìjọba ọ̀run náà kò fi sí lára ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀?

10 Ṣé Ìjọba ọ̀run náà wà lára ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ nígbà tó dá Ádámù àti Éfà? Nínú àkọsílẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, kò síbi táa ti mẹ́nu kan Ìjọba tí yóò ṣàkóso aráyé. Jèhófà fúnra rẹ̀ ni Alákòóso wọn, níwọ̀n bí wọ́n bá ti ń ṣègbọràn sí i, wọn ò nílò ìṣàkóso mìíràn. Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní fi hàn pé Jèhófà bá Ádámù àti Éfà lò, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ipasẹ̀ àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ ti ọ̀run ló fi ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà lo àwọn gbólóhùn bí, “Ọlọ́run sì wí fún wọn” àti “Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí” fún wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28, 29; Jòhánù 1:1.

11. Ìbẹ̀rẹ̀ pípé wo ni ìran ènìyàn ní?

11 Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Gbogbo nǹkan tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì ló pé pérépéré. Inú Párádísè ni Ádámù àti Éfà gbé. Wọ́n ní èrò inú pípé àti ara pípé. Wọ́n lè bá Olùṣẹ̀dá wọn sọ̀rọ̀, òun náà sì lè bá wọn sọ̀rọ̀. Ká ní wọ́n sì dúró bí olóòótọ́ ni, wọn ì bá bí àwọn ọmọ pípé. À bá má tiẹ̀ nílò ìjọba tuntun ti ọ̀run rárá.

12, 13. Bí ìran ènìyàn pípé ṣe ń pọ̀ sí i, èé ṣé tí ì bá ṣì fi ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti máa bá wọn sọ̀rọ̀?

12 Bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe wá ń pọ̀ sí i, báwo ni Ọlọ́run ì bá ṣe máa bá gbogbo wọn sọ̀rọ̀? Ronú nípa àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run. Wọ́n wà pa pọ̀ ní àgbájọ àgbájọ tí à ń pé ní ìṣùpọ̀ ìràwọ̀. Àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kan wà tí wọ́n ní bílíọ̀nù kan ìràwọ̀ nínú. Àwọn mìíràn ní nǹkan bíi tírílíọ̀nù nínú. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sì fojú bù ú pé nǹkan bí ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ló wà nínú àgbáálá ayé tí ó ṣeé fojú rí! Síbẹ̀, Ẹlẹ́dàá náà sọ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.”—Aísáyà 40:26.

13 Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti mọ gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lókè ọ̀run wọ̀nyí, ó dájú pé kò ní ṣòro fún ún láti mọ ènìyàn tí wọ́n kéré níye gan-an. Kódà nísinsìnyí pàápàá, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ló ń gbàdúrà sí i lójoojúmọ́. Ojú ẹsẹ̀ sì ni àwọn àdúrà wọ̀nyẹn máa ń dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, bíbá gbogbo ẹ̀dá ènìyàn pípé sọ̀rọ̀ kò ní ṣòro fún un rárá ni. Ì bá máà nílò Ìjọba ọ̀run kankan kó tó lè darí wọ́n. Àgbàyanu ètò mà lèyí o—kéèyàn ní Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Alákòóso, kí ó lè lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní tààràtà, kó nírètí pé òun ò ní kú láé, kó sì máa gbé títí lọ fáàbàdà nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé!

“Kì Í Ṣe Ti Ènìyàn”

14. Èé ṣe táwọn èèyàn yóò fi máa nílò ìṣàkóso Jèhófà títí lọ?

14 Àmọ́ ṣá o, àwọn èèyàn, kódà kí wọ́n jẹ́ ẹni pípé pàápàá, yóò máa nílò ìṣàkóso Jèhófà títí lọ ni. Nítorí kí ni? Nítorí pé Jèhófà kò dá wọn pẹ̀lú làákàyè tí wọn ó fi kẹ́sẹ járí fúnra wọn láìsí lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. Túláàsì nìyẹn jẹ́ fún ìran ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wòlíì Jeremáyà ṣe jẹ́wọ́ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀. Tọ́ mi sọ́nà, Jèhófà.” (Jeremáyà 10:23, 24) Ìwà òmùgọ̀ gbáà ni yóò jẹ́ fún àwọn èèyàn láti ronú pé àwọn lè káwọ́ àwùjọ láìsí pé Jèhófà ń ṣàkóso wọn. Yóò lòdì pátápátá sí bí a ṣe dá wọn. Kò sọ́gbọ́n táa lè dá tí gbígba òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà ò fi ní yọrí sí ìmọtara-ẹni-nìkan, ìkórìíra, ìwà òǹrorò, ìwà ipá, ogun, àti ikú. ‘Ńṣe ni ènìyàn yóò máa jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.’—Oníwàásù 8:9.

15. Kí ni àbájáde ohun búburú tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ yàn?

15 Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ pinnu pé wọn ò fẹ́ kí Ọlọ́run jẹ́ Alákòóso wọn, wọ́n sì yàn láti máa ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́. Àbájáde rẹ̀ ni pé, Ọlọ́run kò gbà pé kí wọ́n máa wà ní ìjẹ́pípé nìṣó. Wọ́n wá dà bí ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ kan táa fa okùn rẹ̀ yọ kúrò níbi tó ti ń gba agbára iná. Nípa bẹ́ẹ̀, bí àkókò ti ń lọ, agbára wọn wá ń dín kù, wọ́n sì dákẹ́ wẹ́lo—nínú ikú. Wọ́n wá dà bíi bátànì kan tó lábùkù, ipò yẹn sì ni gbogbo ohun tí wọ́n lè tàtaré rẹ̀ sọ́dọ̀ àtọmọdọ́mọ wọn. (Róòmù 5:12) “Àpáta náà [Jèhófà], pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. . . . Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun níhà ọ̀dọ̀ àwọn fúnra wọn; wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀, àbùkù náà jẹ́ tiwọn.” (Diutarónómì 32:4, 5) Lóòótọ́, ẹ̀dá ẹ̀mí ọlọ̀tẹ̀ tó di Sátánì ló nípa lórí Ádámù àti Éfà, àmọ́, èrò inú pípé ni wọ́n ní, ó sì yẹ kí wọ́n kọ ìmọ̀ràn burúkú rẹ̀ sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-19; Jákọ́bù 4:7.

16. Báwo ni ìtàn ṣe jẹ́rìí sí ohun tó jẹ́ ìyọrísí gbígba òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run?

16 Ìtàn jẹ́rìí tó pọ̀ rẹpẹtẹ sí ohun tó jẹ́ ìyọrísí gbígba òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún làwọn èèyàn ti ń gbìyànjú onírúurú ìjọba, wọ́n tún gbìyànjú gbogbo ètò ọrọ̀ ajé àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Síbẹ̀, ńṣe ni ìwà ibi túbọ̀ ń “tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.” (2 Tímótì 3:13) Ọ̀rúndún ogún fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí. Ó kún fún ìkórìíra, ìwà ipá, ogun, ebi, ipò òṣì, àti ìjìyà tó burú jù ti ìgbàkígbà rí nínú ìtàn. Kò sí bí ìmọ̀ ìṣègùn ṣe lè tẹ̀ síwájú tó, ní ọjọ́ kan ṣáá, olúkúlùkù yóò kú. (Oníwàásù 9:5, 10) Nítorí pé àwọn èèyàn gbìyànjú láti darí ìṣísẹ̀ ara wọn, wọ́n ti yọ̀ǹda ara wọn láti di ìjẹ fún Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀ débi pé Bíbélì ní láti pe Sátánì ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.”—2 Kọ́ríńtì 4:4.

Ẹ̀bùn Òmìnira Láti Ṣe Ohun Tó Wuni

17. Báwo ló ṣe yẹ kéèyàn lo ẹ̀bùn òmìnira tí Ọlọ́run fún un láti ṣe ohun tó wù ú?

17 Èé ṣe tí Jèhófà fi fàyè gba àwọn ènìyàn láti máa ṣe ohun tó wù wọ́n? Nítorí pé ó dá wọn pẹ̀lú ẹ̀bùn òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọn, ìyẹn ni agbára láti yan ohun tó wù wọ́n. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá . . . wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” (2 Kọ́ríńtì 3:17) Kò sẹ́ni tó fẹ́ dà bíi róbọ́ọ̀tì, táá fẹ́ kí ẹlòmíì máa pinnu fóun, ohun tóun máa sọ àti ohun tóun máa ṣe ní ìṣẹ́jú dé ìṣẹ́jú nínú ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn lo ẹ̀bùn òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n yẹn lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, kí wọ́n rí ọgbọ́n tó wà nínú ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti bíbá a nìṣó ní jíjẹ́ ọmọ abẹ́ rẹ̀. (Gálátíà 5:13) Nítorí náà, òmìnira wọn gbọ́dọ̀ ní ààlà, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yánpọnyánrin ló máa dá sílẹ̀. Kò gbọ́dọ̀ kọjá ààlà àwọn òfin onínúure tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀.

18. Kí ni Ọlọ́run ti fi hàn nípa jíjẹ́ káwọn èèyàn yan ohun tó wù wọ́n?

18 Nípa jíjẹ́ káwọn èèyàn máa dá tinú wọn ṣe, Ọlọ́run ti fi hàn láìkù síbì kan pé a nílò ìṣàkóso òun. Ọ̀nà ìṣàkóso rẹ̀, ìyẹn ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀, nìkan ṣoṣo ni ọ̀nà tí ó tọ́. Ó ń yọrí sí ayọ̀, ìtẹ́lọ́rùn, àti aásìkí tí kò láfiwé. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé Jèhófà dá èrò inú wa àti ara wa láti ṣiṣẹ́ lọ́nà tó dára jù lọ nígbà táa bá rìn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin rẹ̀. “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísáyà 48:17) Yíyan ohun tó wù wá láìkọjá ààlà àwọn òfin Ọlọ́run kò lè jẹ́ ẹrù ìnira ṣùgbọ́n yóò yọrí sí níní onírúurú oúnjẹ aládùn, ilé tó dára, iṣẹ́ ọnà tó dára àti orin tó ń múnú ẹni dùn. Ká ní wọ́n lo òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n lọ́nà rere ni, ì bá ti jẹ́ kí wọ́n gbé ìgbésí ayé fífani mọ́ra, tó jẹ́ àgbàyanu nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

19. Ètò wo ni Ọlọ́run lò láti mú àwọn ènìyàn padà bá òun rẹ̀?

19 Àmọ́, nítorí pé wọ́n yan ohun tí kò dáa, àwọn èèyàn sọ ara wọn di àjèjì sí Jèhófà, wọ́n di aláìpé, wọ́n ń darúgbó, wọ́n sì ń kú. Nítorí náà, a ní láti rà wọ́n padà kúrò nínú ipò ìbànújẹ́ yẹn, kí a sì mú kí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run lọ́nà yíyẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀. Ètò tí Ọlọ́run yàn láti fi ṣe èyí ni Ìjọba náà, Olùtúnniràpadà náà sì ni Jésù Kristi. (Jòhánù 3:16) Nípasẹ̀ ìṣètò yìí, àwọn tó ronú pìwà dà látọkànwá—bíi ti ọmọ onínàákúnàá inú àpèjúwe Jésù—la óò mú padà bá Ọlọ́run rẹ́, tí òun náà yóò sì gbà wọ́n padà bí ọmọ rẹ̀.—Lúùkù 15:11-24; Róòmù 8:21; 2 Kọ́ríńtì 6:18.

20. Báwo ni Ìjọba náà yóò ṣe mú ète Ọlọ́run ṣẹ?

20 Láìkùnà, ìfẹ́ Jèhófà yóò di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 14:24, 27; 55:11) Nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ lábẹ́ Kristi, Ọlọ́run yóò dá ẹ̀tọ́ tó ní láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ wa láre ní kíkún. Ìjọba náà yóò fòpin sí ìṣàkóso ènìyàn àti ti àwọn ẹ̀mí èṣù lórí ilẹ̀ ayé yìí, òun nìkan ṣoṣo ni yóò sì ṣàkóso láti ọ̀run fún ẹgbẹ̀rún ọdún. (Róòmù 16:20; Ìṣípayá 20:1-6) Àmọ́ o, báwo la ó ṣe mọ̀ pé ọ̀nà tí Jèhófà gba ń ṣàkóso ló dára jù lọ ní àkókò yẹn? Àti pé ipa wo ni Ìjọba náà yóò kó lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún náà? Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò.

Àwọn Kókó fún Àtúnyẹ̀wò

• Kí ni àkòrí Bíbélì?

• Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ alákòóso ilẹ̀ ayé tuntun?

• Èé ṣe tí ìṣàkóso ènìyàn láìjẹ́ pé Ọlọ́run dá sí i kò fi lè ṣàṣeyọrí láé?

• Báwo la ṣe gbọ́dọ̀ lo òmìnira ṣísṣe ohun tó wuni?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ẹ̀kọ́ Jésù tẹnu mọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run nípasẹ̀ Ìjọba náà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Gbogbo ilẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fi Ìjọba náà ṣe olórí ẹ̀kọ́ wọn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ìtàn jẹ́rìí sí àwọn àbájáde búburú tó jẹ́ ìyọrísí òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run

[Àwọn Credit Line]

Sójà WWI: Fọ́tò U.S. National Archives; àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́: Oświęcim Museum; ọmọ: FỌ́TÒ UN 186156/J. Isaac