Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó Yẹ Kí O Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ẹ̀sìn Mìíràn?

Ṣé Ó Yẹ Kí O Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ẹ̀sìn Mìíràn?

Ṣé Ó Yẹ Kí O Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ẹ̀sìn Mìíràn?

“MIGUEL tó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí ní Gúúsù Amẹ́ríkà sọ pé: “Mo ti ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni fún nǹkan bí ọdún kan, mo sì máa ń gbádùn bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí fetí sí àwọn ètò ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe lórí rédíò, mo sì ń wo àwọn ẹlẹ́sìn tó ń wàásù lórí tẹlifíṣọ̀n. Mo rò pé àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọ̀nyẹn lè ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ̀ nípa àwọn tó wà nínú àwọn ẹ̀sìn mìíràn. Mo wá rí i pé àwọn ẹ̀kọ́ wọn ò tiẹ̀ bá Bíbélì mu rárá, àmọ́ mo fẹ́ mọ fìn-ín ìdí kókò.”

Ní orílẹ̀-èdè kan náà yẹn ni Jorge ti ń fìtara kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa ìjọsìn tòótọ́. Àmọ́, ní àkókò kan, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́tí sí àwọn ètò ẹ̀sìn orí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n. Ó máa ń sọ pé: “Ó yẹ kóo mọ ohun táwọn ẹlòmíràn ń rò.” Nígbà tí wọ́n bá sì bi í nípa ewu tó lè tẹ̀yìn irú gbígbọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké bẹ́ẹ̀ jáde, yóò dáhùn pé: “Kò sóhun tó lè jin ìgbàgbọ́ ẹni tó bá mọ òtítọ́ Bíbélì lẹ́sẹ̀.” Àwọn ìrírí wọ̀nyí wá gbé ìbéèrè pàtàkì kan dìde pé, ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti fetí sí ohun tí àwọn ẹlòmíràn gbà gbọ́?

Mímọ Ẹ̀sìn Kristẹni Tòótọ́

Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni tó ń dìde lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan sọ ìjọsìn tòótọ́ di eléèérí. Níwọ̀n bí Jésù ti mọ̀ pé èyí máa ṣẹlẹ̀, ó sọ ọ̀nà kan táa lè gbà fìyàtọ̀ sáàárín àwọn ayédèrú ẹ̀sìn Kristẹni àti ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, ó kìlọ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tí ń wá sọ́dọ̀ yín nínú aṣọ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n jẹ́ ọ̀yánnú ìkookò.” Ó wá fi kún un pé: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀.” (Mátíù 7:15-23) Àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Jésù máa ń fi àwọn ohun tó kọ́ wọn sílò, ó sì rọrùn láti fi èso rere tí wọ́n ń mú jáde dá wọn mọ̀. Gẹ́gẹ́ bí Jésù alára ti ṣe, wọ́n máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn láti ṣàlàyé Ìjọba Ọlọ́run láti inú Ìwé Mímọ́. Nítorí pé wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, wọn kì í lọ́wọ́ nínú ìṣèlú ayé àti àríyànjiyàn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Wọ́n tẹ́wọ́ gba Bíbélì pé ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún un pé ó jẹ́ òtítọ́. Wọ́n ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀. Níwọ̀n bí wọ́n sì ti ń tiraka láti máa fi ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi ń kọ́ni hàn, wọn kì í lọ́wọ́ nínú ogun. Dípò ìyẹn, ńṣe ni wọ́n ń bára wọn lò bí ọmọ ìyá.—Lúùkù 4:43; 10:1-9; Jòhánù 13:34, 35; 17:16, 17, 26.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ó ṣeé ṣe láti “rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” (Málákì 3:18) Àwọn olùjọsìn tòótọ́ òde òní wà ní ìṣọ̀kan lérò àti níṣe bíi tàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. (Éfésù 4:4-6) Tóo bá ti lè mọ irú ẹgbẹ́ ojúlówó Kristẹni bẹ́ẹ̀, kí ló dé tí o tún fi ní láti máa ṣe ojú-mìí-tó tàbí tí wàá tún fi máa wá fìn-ín ìdí kókò ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn?

Ṣọ́ra fún Àwọn Olùkọ́ Èké

Bíbélì fi hàn pé lẹ́yìn téèyàn bá ti mọ òtítọ́ Bíbélì tán pàápàá, ewu wà pé àwọn ẹ̀kọ́ èké ṣì lè sọni dìbàjẹ́ nípa tẹ̀mí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.” (Kólósè 2:8) Bọ́ràn ṣe rí gan-an ni àyọkà yìí mà gbé jáde o! Bí ìgbà tí àwọn ẹranko bá fẹ́ gbé ọ lọ kí wọ́n sì pa ọ́ jẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn olùkọ́ èké ṣe lè jẹ́ ewu ní ti gidi.

Lóòótọ́, Pọ́ọ̀lù kíyè sí ohun táwọn ẹlòmíràn gbà gbọ́. Ìgbà kan wà tó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò rẹ̀ nípa sísọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Áténì, mo ṣàkíyèsí pé nínú ohun gbogbo, ó jọ pé ẹ kún fún ìbẹ̀rù àwọn ọlọ́run àjúbàfún ju àwọn mìíràn lọ. Fún àpẹẹrẹ, bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo sì ń fẹ̀sọ̀ kíyè sí àwọn ohun tí ẹ ń júbà fún, mo tún rí pẹpẹ kan, lórí èyí tí a kọ àkọlé náà ‘Sí Ọlọ́run Àìmọ̀.’” (Ìṣe 17:22, 23) Àmọ́ ṣá o, kì í wá ṣe pé Pọ́ọ̀lù ń fi ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Gíríìkì bọ́ èrò inú ara rẹ̀ déédéé.

Ohun kan ni kéèyàn mọ̀ nípa orírun àti ìgbàgbọ́ àwọn ẹ̀sìn èké, àmọ́ ohun mìíràn pátápátá ni kéèyàn máa fi wọ́n bọ́ ara rẹ. a Jèhófà ti yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti pèsè ẹ̀kọ́ táa gbé karí Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Mátíù 4:4; 24:45) Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ kọ̀wé pé: “Ẹ kò lè máa ṣalábàápín ‘tábìlì Jèhófà’ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù. Àbí ‘àwa ha ń ru Jèhófà lọ́kàn sókè sí owú ni bí’?”—1 Kọ́ríńtì 10:20-22.

Àwọn kan lára àwọn olùkọ́ èké ti lè fìgbà kan rí jẹ́ Kristẹni tòótọ́, àmọ́ tó kàn di àkókò kan tí wọ́n fi òtítọ́ sílẹ̀ lọ sínú ìṣìnà. (Júúdà 4, 11) Kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu. Lẹ́yìn tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tó jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ó wá sọ nípa “ẹrú búburú,” ìyẹn ẹgbẹ́ tó ń ṣàròyé pé, “ọ̀gá mi ń pẹ́,” tó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. (Mátíù 24:48, 49) Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn wọ̀nyí àtàwọn ọmọlẹ́yìn wọn kì í ní ẹ̀kọ́ tó yè kooro ti ara wọn; ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ni pé káwọn sáà máa ba ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn jẹ́. Tìtorí tiwọn ni àpọ́sítélì Jòhánù ṣe kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín, tí kò sì mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé yín láé tàbí kí ẹ kí i.”—2 Jòhánù 10; 2 Kọ́ríńtì 11:3, 4, 13-15.

Ì bá dára káwọn aláìlábòsí ènìyàn tí wọ́n ń wá òtítọ́ kiri fara balẹ̀ gbé ohun tí wọ́n ń gbọ́ látọ̀dọ̀ onírúurú ẹ̀sìn yẹ̀ wò. Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò bù kún àwọn aláìlábòsí-ọkàn tí wọ́n ń wá òtítọ́ kiri. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n Ọlọ́run pé: “Bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò . . . rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” (Òwe 2:4, 5) Lẹ́yìn táwọn Kristẹni tòótọ́ bá ti rí ìmọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Bíbélì àti ìjọ Kristẹni, tí wọ́n sì ti rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn tí ìmọ̀ yẹn ń tọ́ sọ́nà, wọn kì í tún tẹ́tí sí àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn èké mọ́.—2 Tímótì 3:14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé Mankind’s Search for God, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde, fún wa ní ìsọfúnni tó ṣe kókó nípa bí ọ̀pọ̀ lára ẹ̀sìn tó wà láyé ṣe bẹ̀rẹ̀ àti irú ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni.