Ǹjẹ́ O Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run Kan Tí Kò Ṣeé Fojú Rí?
Ǹjẹ́ O Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run Kan Tí Kò Ṣeé Fojú Rí?
O lè béèrè pé, ‘báwo ni mo ṣe lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ẹnì kan tí n kò lè rí?’ Ìyẹn lè jọ ìbéèrè kan tó ṣe pàtàkì. Àmọ́ gbé èyí yẹ̀ wò ná:
ṢÉ DANDAN ni ká fojú kan ẹnì kan kí àjọṣe onífẹ̀ẹ́ tó wà pẹ́ títí tó lè wáyé pẹ̀lú onítọ̀hún ni? Ǹjẹ́ àwọn ohun kan tí kò ṣeé fojú rí kò ṣe pàtàkì, àní ju èyí tí ojú tilẹ̀ lè rí lọ? Wọ́n mà ṣe pàtàkì o! Ìdí rèé tí àwọn kan fi lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ kíkọ lẹ́tà síra wọn déédéé—tí àwọn lẹ́tà wọn máa ń sọ òdodo ọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, ohun tí wọ́n kórìíra, góńgó wọn, ìlànà tí wọ́n dì mú, àwàdà ṣíṣe, àtàwọn ìwà àbínibí tàbí ìfẹ́ ọkàn wọn mìíràn.
Àwọn afọ́jú pẹ̀lú ti jẹ́ kó hàn pé, kò pọn dandan láti ríran kí á tó lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ẹlòmíràn. Ìwọ wo àpẹẹrẹ ti Edward àti Gwen, tọkọtaya kan tó jẹ́ afọ́jú. a Ilé ẹ̀kọ́ tó wà fún àwọn afọ́jú ni Edward ti pàdé Gwen, níbi tó ti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ àgbà bí i tirẹ̀. Ó fẹ́ràn àwọn ànímọ́ Gwen gan-an, pàápàá jù lọ bó ṣe máa ń sọ̀rọ̀ tó sì máa ń hùwà láìṣàbòsí, àti bí kì í ṣeé fi iṣẹ́ ṣeré rárá. Ẹ̀wẹ̀, Gwen náà fà mọ́ Edward, nítorí, gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ ọ́, “ó ní gbogbo ànímọ́ tí wọ́n fi kọ́ mi láti kékeré pé ó ṣe pàtàkì.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wọn sọ́nà, ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, wọ́n di tọkọtaya.
Edward sọ pé, “nígbà tí ẹ bá jọ wà pa pọ̀, pé èèyàn jẹ́ afọ́jú kò ní kí èèyàn máà ní àjọṣe pẹ̀lú ẹlòmíràn. Ẹ lè má lè rí ara yín, àmọ́ kò ṣòro láti mọ ìmọ̀lára yín.” Ní báyìí o, lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta, wọ́n ṣì nífẹ̀ẹ́ ara wọn gidigidi. Wọ́n ṣàlàyé pé ó kéré tán, ohun mẹ́rin ló jẹ́ kí àjọṣepọ̀ wọn tó lárinrin yìí ṣeé ṣe: (1) ṣíṣàkíyèsí àwọn ànímọ́ tí ẹnì kejì ní, (2) ríronú nípa àwọn ànímọ́ náà àti jíjẹ́ kí wọ́n fà ọ́ mọ́ra, (3) jíjẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó jíire máa wà, àti (4) ṣíṣe àwọn nǹkan pa pọ̀.
Àwọn kókó mẹ́rin wọ̀nyí ṣe pàtàkì nínú àjọṣe èyíkéyìí tó bá dára, ì báà jẹ́ láàárín ọ̀rẹ́, alábàáṣègbéyàwó, tàbí ní pàtàkì jù, láàárín ènìyàn àti Ọlọ́run. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a ó rí i bí fífi àwọn kókó wọ̀nyí sílò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè rí i. b
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ náà padà.
b Láìdàbí àjọṣe tó máa ń wà láàárín àwọn ènìyàn, àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ èyí táa gbé karí ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run wà. (Hébérù 11:6) Fún ìjíròrò kíkún nípa mímú ìgbàgbọ́ lílágbára dàgbà nínú Ọlọ́run, jọ̀wọ́ wo ìwé Is There a Creator Who Cares About You?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.