Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àlàáfíà Ayé—Lọ́nà Wo?

Àlàáfíà Ayé—Lọ́nà Wo?

Àlàáfíà Ayé—Lọ́nà Wo?

ṢÉ ÀLÀÁFÍÀ ayé ti sún mọ́lé? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fìgbà kan rò bẹ́ẹ̀, àmọ́ wọ́n ti wá ń ṣiyè méjì báyìí. Ní ìbámu pẹ̀lú ìròyìn kan tó jíròrò àwọn ìpèníjà ọjọ́ iwájú, èyí tí wọ́n tẹ̀ sínú ìwé ìròyìn Daily Mail & Guardian ti Gúúsù Áfíríkà, “àwítẹ́lẹ̀ nípa ètò tuntun kan kárí ayé tí wọ́n wí ní ọdún mẹ́wàá péré sẹ́yìn ti wá dà bí ohun kan tí kò ṣeé fọkàn sí mọ́.”

Àwọn òǹkọ̀wé náà rántí ẹ̀mí táwọn èèyàn ní láwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn pé nǹkan yóò dára. Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ parí nígbà yẹn ni, kò sì sí gbọ́nmisi-omi-ò-to láàárín àwọn alágbára ayé mọ́. Ipò nǹkan dà bí ẹni pé ìbẹ̀rẹ̀ sànmánì tuntun ni, ọ̀pọ̀ sì retí pé ìran ènìyàn yóò wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí ojútùú tó jẹ́ ojúlówó sí ogun tí wọ́n ń gbé ti ipò òṣì, àìsàn, àti àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ àyíká. Ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn àwítẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn ti wá di àlá tí kò lè ṣẹ báyìí. Rògbòdìyàn ti bẹ́ sílẹ̀ láwọn àgbègbè tó jẹ́ pé agbára káká la fi mọ̀ nípa wọn; ipò òṣì sì túbọ̀ ń gogò sí i ní ayé. Orílẹ̀-èdè tuntun méjì tún ti dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè alágbára átọ́míìkì. Orúkọ Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti bàjẹ́ nítorí àìtóótun rẹ̀ láti yanjú yánpọnyánrin tó ń lọ láàárín aráyé. Ẹ̀mí táwọn èèyàn ní pé nǹkan yóò dára ti wá di ẹ̀mí pé nǹkan yóò burú jáì.”

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé bó ti wu kí ìsapá ẹ̀dá ènìyàn wúni lórí tó, kò lè kẹ́sẹ járí láé. Kí nìdí? Nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ ọ́, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Kò sí bí ayé ṣe lè wà ní ipò Párádísè tí Ọlọ́run dá a sí, tó bá ṣì wà lábẹ́ ìdarí Sátánì.

Láàárín àkókò kan náà, ìdí ṣì wà láti ní ẹ̀mí pé nǹkan-yóò-dára. Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí láti mú àlàáfíà ayé wá, kì í ṣe nípa gbígbárùkù ti ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí o, àmọ́ nípa mímú “ilẹ̀ ayé tuntun” nínú èyí tí “òdodo yóò . . . máa gbé” wá. (2 Pétérù 3:13) Bẹ́ẹ̀ ni o, nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run, àgbáyé wa yóò yí padà di ilé alálàáfíà àti ayọ̀ níbi tí ìgbésí ayé àti iṣẹ́ yóò tí máa múnú gbogbo aráyé onígbọràn dùn ní gbogbo ìgbà. Síwájú sí i, Ọlọ́run ṣèlérí láti “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” A kò gbé àwọn ìlérí wọ̀nyí karí àwítẹ́lẹ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ táwọn èèyàn ń ṣe. Dípò ìyẹn, orí Ọ̀rọ̀ tó dájú hán-ún hán-ún tó wá látẹnu Ẹlẹ́dàá, tí kò lè purọ́, la gbé e kà.— Ìṣípayá 21:4; Títù 1:2.