Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà Rere Ti Ń Dín Kù

Ìwà Rere Ti Ń Dín Kù

Ìwà Rere Ti Ń Dín Kù

“IRÚ nǹkan báyẹn kì í ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀,” ohun tí Helmut Schmidt, tó jẹ́ alábòójútó ètò abẹ́lé ní ilẹ̀ Jámánì tẹ́lẹ̀, sọ nìyẹn. Ó ń kédàárò nípa ìwà àìṣòótọ́ tó burú jáì tí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ń hù tó sì jẹ́ pé òun ni wọ́n fi ń ṣe àkọlé ìwé ìròyìn lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí. Ó sọ pé: “Ìwọra ti mú kí ìwà rere sọnù pátápátá.”

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa gbà pé òótọ́ lohun tó sọ yìí. Ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí gbogbo gbòò ti tẹ́wọ́ gbà látọjọ́ pípẹ́ pé ó jẹ́ atọ́nà láti mọ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ ti di èyí tí wọ́n fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Bọ́ràn ṣe rí gan-an nìyí, kódà láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti pe ara wọn ní ẹlẹ́sìn Kristẹni pàápàá.

Ǹjẹ́ Ìwà Rere Tí Bíbélì Fi Kọni Ṣe Pàtàkì?

Ìwà rere tí a gbé karí ẹ̀kọ́ Bíbélì ní àìlábòsí àti ìwà títọ́ nínú. Síbẹ̀ awúrúju, ìwà ìbàjẹ́, àti èrú ń gbòde kan ni. Ìwé ìròyìn The Times ti London ròyìn pé àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan “ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n gba ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ márùn-ún pọ́n-ùn [owó ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì] lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo kí wọ́n lè dá àwọn oògùn líle táwọn ọlọ́pàá gba padà fáwọn ọ̀daràn tàbí kí wọ́n lè bo àṣírí àwọn ògbóǹkangí ẹlẹ́gírí.” Wọ́n tún sọ pé èrú táwọn abánigbófò ń ṣe ti di àṣà tó gbòde ní Ọsirélíà. Ní Jámánì ó ya àwùjọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lẹ́nu nígbà táwọn olùwádìí rídìí “ọ̀kan lára èrú tó burú jù lọ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ní ilẹ́ Jámánì” lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan, “tó ta yọ láàárín àwọn onímọ̀ nípa apilẹ̀ àbùdá” ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó purọ́ tàbí pé ó hùmọ̀ àwọn ìsọfúnni kan lọ́nà tó bùáyà.

Ìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó, èyí tó yẹ kó jẹ́ àjọṣe tí kì í lópin, tún wà lára ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni. Àmọ́ iye àwọn tọkọtaya tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ló ń parí rẹ̀ sí kóòtù ìkọ̀sílẹ̀. Ìwé ìròyìn Kátólíìkì náà, Christ in der Gegenwart (Kristẹni Ti Lọ́wọ́lọ́wọ́), sọ pé, “kódà ní Switzerland tó jẹ́ ‘arọ̀mọ́pìlẹ̀’ pàápàá, ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ló ń forí ṣánpọ́n.” Ní Netherlands, ìpín mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nínú gbogbo ìgbéyàwó ló ń parí sí ìkọ̀sílẹ̀. Obìnrin kan tó kíyè sí bí àwọn nǹkan ṣe ń yí padà láwùjọ ní ilẹ̀ Jámánì láti àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn kọ̀wé nípa bó ṣe ká a lára pé: “Wọ́n ti wá ka ìgbéyàwó sí àṣà àtijọ́ tí kò bóde mu mọ́. Ẹnì kan ṣoṣo kọ́ làwọn èèyàn ń fẹ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn mọ́.”

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ka ìlànà ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni sí èyí tó ṣeé gbíyè lé, tó sì ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé òde òní. Tọkọtaya kan tó ń gbé ní ààlà ilẹ̀ Switzerland àti Jámánì rí i pé kíkẹ́kọ̀ọ́ láti fi ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni sílò ń jẹ́ káwọn túbọ̀ láyọ̀ sí i. Lójú tiwọn, “ìlànà kan ṣoṣo ló wà fún gbogbo apá ìgbésí ayé. Ìlànà náà ni Bíbélì.”

Kí lèrò tìẹ? Ṣé Bíbélì lè fúnni nílànà tó ní láárí? Ǹjẹ́ ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni ṣeé mú lò lóde òní?