Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ìwà Rere Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Ló Dára Jù Lọ?

Ṣé Ìwà Rere Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Ló Dára Jù Lọ?

Ṣé Ìwà Rere Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Ló Dára Jù Lọ?

“ÀWÙJỌ ẹ̀dá nílò ojúlówó àwọn ìlànà pàtàkì tí a tò lẹ́sẹẹsẹ tí yóò fún àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ní ààbò àti ìdarí.” Ohun tí òǹkọ̀wé ará Jámánì kan tó nírìírí, tó sì tún jẹ́ oníròyìn lórí tẹlifíṣọ̀n, sọ nìyẹn. Ìyẹn sì mọ́gbọ́n dání lóòótọ́. Kí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tó lè fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ó sì ní láárí, àwọn èèyàn ibẹ̀ gbọ́dọ̀ ní ìpìlẹ̀ tó ṣe gúnmọ́ tó jẹ́ ti ìlànà tí gbogbo gbòò tẹ́wọ́ gbà tó fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́ àti sáàárín ohun tó dára àti èyí tó burú. Ìbéèrè náà ni pé: Àwọn ìlànà wo ló dára jù lọ fún àwùjọ àtàwọn ẹ̀dá inú rẹ̀?

Tó bá jẹ́ pé àwọn ìlànà ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni la tẹ́wọ́ gbà, ó yẹ kí wọ́n ran olúkúlùkù lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé tó wà déédéé, tó sì jẹ́ aláyọ̀. Ìyẹn yóò jẹ́ kí àwùjọ àwọn ènìyàn tó ń pa àwọn ìlànà wọ̀nyẹn mọ́ túbọ̀ láyọ̀ sí i, kí wọ́n sì túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ sí i. Ṣé bọ́ràn ṣe rí nìyẹn? Ẹ jẹ́ kí a gbé ohun ti Bíbélì ní í sọ yẹ̀ wò lórí àwọn ọ̀ràn méjì tó ṣe pàtàkì: àwọn ni ìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó àti àìṣàbòsí nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́.

Fà Mọ́ Ẹnì Kejì Rẹ Nínú Ìgbéyàwó

Ẹlẹ́dàá wa dá Ádámù, lẹ́yìn náà ó dá Éfà láti jẹ́ ẹnì kejì rẹ̀. Ìsopọ̀ wọn ni ìgbéyàwó àkọ́kọ́ nínú ìtàn, ó sì yẹ kó jẹ́ àjọṣe tó wà pẹ́ títí. Ọlọ́run sọ pé: “Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀.” Ní nǹkan bí ẹgbàajì [4,000] ọdún lẹ́yìn náà, Jésù Kristi tún ìlànà ìgbéyàwó yìí sọ fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Síwájú sí i, ó ka ìbálòpọ̀ lẹ́yìn òde ìgbéyàwó léèwọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; 2:24; Mátíù 5:27-30; 19:5.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Bíbélì sọ, àṣírí ìgbéyàwó aláyọ̀ ni ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ láàárín tọkọtaya. Ọkọ, tó jẹ́ olórí ìdílé, gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan hàn nípa wíwá ire aya rẹ̀. Ó ní láti máa bá a gbé “ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀” kò sì gbọ́dọ̀ “bínú” sí i “lọ́nà kíkorò.” Aya náà sì gbọ́dọ̀ ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” fún ọkọ rẹ̀. Bí gbogbo tọkọtaya bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ jù lọ lára ìṣòro tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó la ó yẹra fún tàbí ká borí wọn. Ọkọ yóò máa fẹ́ láti fà mọ́ aya rẹ̀, aya náà yóò sì fà mọ́ ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú.—1 Pétérù 3:1-7; Kólósè 3:18, 19; Éfésù 5:22-33.

Ǹjẹ́ ìlànà Bíbélì pé kí tọkọtaya máa fi òtítọ́ ọkàn fà mọ́ ara wọn ń mú kí ìgbéyàwó jẹ́ aláyọ̀? Tóò, ronú nípa àbájáde ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Jámánì. Wọ́n ní káwọn èèyàn sọ àwọn kókó tó lè mú kí ìgbéyàwó yọrí sí rere. Kókó táwọn èèyàn mẹ́nu kan jù lọ ni ìṣòtítọ́ látọ̀dọ̀ tọ̀túntòsì. Àbí ìwọ ò gbà pé inú àwọn tó ti ṣègbéyàwó máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá mọ̀ pé ẹnì kejì àwọn jẹ́ olóòótọ́?

Bí Ìṣòro Bá Dìde Ńkọ́?

Bí gbọ́nmisi-omi-ò-to bá wà láàárín tọkọtaya ńkọ́? Bí ìfẹ́ wọn bá ṣá ńkọ́? Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kò yẹ kí wọ́n fòpin sí ìgbéyàwó náà? Àbí ìmọ̀ràn Bíbélì pé ká fi ìṣòtítọ́ fà mọ́ ẹni kejì ẹni nínú ìgbéyàwó ṣì ṣeé mú lò ni?

Àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì mọ̀ pé gbogbo tọkọtaya ló máa níṣòro nítorí àìpé ẹ̀dá. (1 Kọ́ríńtì 7:28) Síbẹ̀, àwọn tọkọtaya tí wọ́n pa ìlànà ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni mọ́ máa ń gbìyànjú láti dárí ji ara wọn àti láti jùmọ̀ yanjú àwọn ìṣòro wọn. Àmọ́ ṣá o, àwọn ipò kan máa ń dìde—bíi panṣágà tàbí ìlunibolẹ̀—tí ó lè mú kí Kristẹni kan ronú nípa pípínyà tàbí ìkọ̀sílẹ̀. (Mátíù 5:32; 19:9) Ṣùgbọ́n kéèyàn kánjú fòpin sí ìgbéyàwó rẹ̀ láìsí ìdí kán tó ṣe gúnmọ́ tàbí kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ kóun lè rọ́nà fẹ́ ẹlòmíràn ń fi ẹ̀mí onímọtara-ẹni-nìkan tí kò bìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn hàn. Ó dájú pé kì í jẹ́ kí ìgbésí ayé ẹni wà déédéé, kì í sì í jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Ẹ jẹ́ kí a wo àpẹẹrẹ kan.

Peter rí i pé ìgbéyàwó òun kò gbámúṣé bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. a Bó ṣe fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nìyẹn, tó kó lọ sọ́dọ̀ Monika, tóun náà ti fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Láàárín oṣù díẹ̀, Peter jẹ́wọ́ pé gbígbé tí òun ń bá Monika gbé “kò rọrùn bóun ṣe rò pé ó máa rí.” Kí nìdí rẹ̀? Ńṣe ni àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó ẹ̀dá ènìyàn hàn kedere nínú àjọṣe rẹ̀ tuntun yìí bó ṣe rí nínú ti tẹ́lẹ̀. Èyí tó wá tún burú jù lọ ni pé ìpinnu onímọtara-ẹni-nìkan tó kánjú ṣe náà tún kó o sínú ìṣòro ìṣúnná owó tó burú jáì. Láfikún sí i, ìdààmú ọkàn bá àwọn ọmọ Monika nítorí ìyípadà ńláǹlà tó dé bá ìdílé wọn.

Gẹ́gẹ́ bí ìrírí yìí ti fi hàn, nígbà tí ìṣòro bá ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó kan, sísá kúrò nínú rẹ̀ kì í sábà jẹ́ ojútùú sí ìṣòro náà. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, bí yánpọnyánrin tilẹ̀ bẹ́ sílẹ̀, gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà ìwà rere tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fi kọ́ni lè máà jẹ́ kí ìgbéyàwó náà fọ́, kó sì wá di èyí tí mìmì kan ò lè mì. Bí ọ̀ràn Thomas àti Doris ṣe rí nìyẹn.

Thomas àti Doris ti gbéra wọn níyàwó fún ohun tó lé lọ́gbọ̀n ọdún kó tó di pé Thomas bẹ̀rẹ̀ sí mutí àmuyíràá. Bí ìbànújẹ́ ṣe dorí Doris kodò nìyẹn, àwọn méjèèjì sì pinnu láti kọ ara wọn. Doris wá fi ọ̀rọ̀ náà lọ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí Ẹlẹ́rìí náà ṣe fi ohun tí Bíbélì sọ nípa ìgbéyàwó han Doris nìyẹn, tó sì gbà á níyànjú pé kó má kánjú láti fi í sílẹ̀ ṣùgbọ́n kí òun àti ọkọ rẹ̀ kọ́kọ́ gbìyànjú láti wá ojútùú sí ìṣòro náà. Ohun tí Doris ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Láàárín oṣù díẹ̀, wọ́n gbàgbé ọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀sílẹ̀. Thomas àti Doris bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ìṣòro wọn pa pọ̀. Ìmọ̀ràn Bíbélì tí wọ́n tẹ̀ lé fún ìgbéyàwó wọn lókun, ó sì fún wọn ní àyè láti yanjú àwọn ìṣòro wọn.

Àìṣàbòsí Nínú Ohun Gbogbo

Fífi ìṣòtítọ́ fà mọ́ ọkọ tàbí aya ẹni ń gba ìfaradà ńlá àti kéèyàn ṣe tán láti pa ìlànà mọ́. Irú àwọn ànímọ́ kan náà yìí la nílò láti máa wà gẹ́gẹ́ bí aláìlábòsí nínú ayé alábòsí yìí. Ohun tí Bíbélì ní í sọ nípa àìlábòsí lọ bí ilẹ̀ bí ẹní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Jùdíà pé: “A . . . dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Kí nìyẹn túmọ̀ sí?

Aláìlábòsí ènìyàn máa ń ṣòótọ́, kì í sì í ṣèrú. Ó máa ń bá àwọn ẹlòmíràn lò lọ́nà tó dára—kì í ṣe onímàgòmágó, ó lọ́wọ̀, kì í tanni jẹ tàbí kó ṣini lọ́nà. Láfikún sí i, aláìlábòsí ènìyàn ni ẹni tó ní ìwà títọ́, tí kì í yan èèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ. Àwọn aláìlábòsí ènìyàn máa ń fi kún ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbọ́kànlé tó máa ń jẹ́ kéèyàn lẹ́mìí tó dára, tó sì ń jẹ́ kí àjọṣepọ̀ tó dára wà láàárín ẹ̀dá ènìyàn.

Ǹjẹ́ àwọn aláìlábòsí èèyàn tiẹ̀ láyọ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ìdí wà fún wọn láti láyọ̀. Láìka bí ìwà ìbàjẹ́ àti awúrúju ṣe pọ̀ tó sí—tàbí bóyá nítorí bó ṣe rí bẹ́ẹ̀—àwọn ẹlòmíràn sábà máa ń kan sáárá sáwọn aláìlábòsí èèyàn. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn ọ̀dọ́, àìlábòsí jẹ́ ìwà funfun tí ìpín àádọ́rin nínú àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò gbé lárugẹ. Síwájú sí i, láìka bí a ṣe dàgbà sí, àìlábòsí ni ohun kìíní táa máa ń fẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn táa kà sí ọ̀rẹ́.

Àtìgbà tí Christine ti wà lọ́mọ ọdún méjìlá ni wọ́n ti kọ́ ọ lólè jíjà. Bí ọdún ti ń gorí ọdún ló túbọ̀ ń di ògbóǹkangí jáwójáwó. Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn ọjọ́ kan wà tí mo máa ń mú owó tí ó tó ẹgbọ̀kànlá [2,200] dọ́là wálé.” Àmọ́ wọ́n mú Christine láwọn ìgbà bíi mélòó kan, ó sì máa ń bẹ̀rù nígbà gbogbo kí wọ́n má ju òun sẹ́wọ̀n. Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa àìlábòsí fún un, àwọn ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni fa Christine mọ́ra. Ó kẹ́kọ̀ọ́ láti ṣègbọràn sí ìṣílétí náà pé: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́.”—Éfésù 4:28.

Christine ti fi olè jíjà sílẹ̀ kó tó di pé ó ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ń sakun nígbà yẹn láti jẹ́ aláìlábòsí nínú ohun gbogbo, níwọ̀n bí àwọn Ẹlẹ́rìí ò ti fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ nípa àìlábòsí àti àwọn ànímọ́ Kristẹni mìíràn. Ìwé ìròyìn náà, Lausitzer Rundschau, ròyìn pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ nípa ìwà rere bí àìlábòsí, ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, àti ìfẹ́ aládùúgbò jẹ́ ohun tí wọ́n gbé lárugẹ gan-an nínú ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí.” Kí wá ni èrò Christine nípa ìgbésí ayé rẹ̀ tó yí padà? Ó ní: “Inú mi dùn gan-an nísinsìnyí tí mi o jalè mọ́. Mo ri pé mo ti di ẹnì kan tí a bọ̀wọ̀ fún láwùjọ.”

Gbogbo Àwùjọ Ló Ń Jàǹfààní

Kì í ṣe pé àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ẹnì kejì wọn nínú ìgbéyàwó, tí wọ́n sì tún jẹ́ aláìlábòsí ń láyọ̀ ju àwọn tó kù lọ nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún ń ṣàǹfààní fún àwùjọ lápapọ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ tí kì í rẹ́ni jẹ làwọn agbanisíṣẹ́ máa ń fẹ́. Gbogbo wa la fẹ́ ká ní àwọn aládùúgbò tó ṣeé gbíyè lé, a sì máa ń fẹ́ láti rajà láwọn ilé ìtajà tó jẹ́ ti àwọn oníṣòwò tí ọwọ́ wọ́n mọ́. Àbí a kì í bọ̀wọ̀ fáwọn òṣèlú, àwọn ọlọ́pàá, àtàwọn adájọ́ tí wọ́n kórìíra ìwà ìbàjẹ́? Àwùjọ máa ń jàǹfààní gan-an nígbà táwọn tó wà níbẹ̀ bá ka àìṣàbòsí sí ara ojúṣe wọn, tí kì í ṣe ohun tí wọ́n kàn ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ráyè láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Síwájú sí i, àwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn ni ìpìlẹ̀ ìdílé tó dúró sán-ún. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ló sì máa fara mọ́ ohun tí òṣèlú ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù kan sọ pé: “Títí di oní olónìí ni ìdílé [tó jẹ́ ohun àbáláyé] ṣì jẹ́ ibi ààbò tó ṣe pàtàkì jù lọ fún ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ète ẹ̀dá ènìyàn.” Inú ìdílé tó lẹ́mìí àlàáfíà ni tọmọdé tàgbà ti máa ń láǹfààní láti fọkàn balẹ̀ pé kò séwu. Nípa bẹ́ẹ̀ àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ nínú ìgbéyàwó máa ń ṣèrànwọ́ láti gbé àwùjọ tó dára ró.

Ronú nípa bí olúkúlùkù yóò ṣe gbádùn tó tí kò bá sí ọkọ tàbí aya táa pa tì, tí kò sí kóòtù ìkọ̀sílẹ̀ mọ́, tàbí ọ̀ràn nípa ọ̀dọ̀ ta lọmọ yóò máa gbé nínú àwọn méjèèjì. Tí kò bá tún wá sí àwọn jáwójáwó, àwọn tó ń jalè nílé ìtajà, àwọn tó ń kówó jẹ, àwọn òṣìṣẹ́ tí ìwà ìbàjẹ́ ti wọ̀ lẹ́wù, tàbí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ń ṣèrú mọ́ ńkọ́? Ǹjẹ́ ìyẹn kò dún bí àlá lásán? Kò dún bẹ́ẹ̀ létí àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ sí Bíbélì àti sí ohun tó sọ nípa ọjọ́ ọ̀la wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé Ìjọba Mèsáyà ti Jèhófà yóò bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso lórí gbogbo àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn orí ilẹ̀ ayé láìpẹ́. Lábẹ́ Ìjọba yẹn, gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ la óò kọ́ bí a ṣe ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni. Ní àkókò yẹn, “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.

Ìwà Rere Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Ló Dára Jù Lọ

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tó ti yẹ Ìwé Mímọ́ wò dáadáa ló ti wá mọyì rẹ̀ pé orí ọgbọ́n Ọlọ́run tó ju èrò ènìyàn lọ fíìfíì la gbé ìmọ̀ràn inú Bíbélì kà. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ka Bíbélì sí ohun tó ṣeé gbíyè lé, tó sì ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé òde òní. Wọ́n mọ̀ pé fún àǹfààní àwọn ló jẹ́ bí àwọn bá fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò.

Látàrí ìyẹn, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fọkàn sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n mú kí ìgbésí ayé tiwọn fúnra wọn túbọ̀ sunwọ̀n sí i, wọ́n sì tún ń ṣe àwọn tó yí wọn ká láǹfààní. Wọ́n sì tún ní ìgbẹ́kẹ̀lé tó jinlẹ̀ nínú “ìyè . . . tí ń bọ̀,” nígbà tí ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni yóò di èyí tí gbogbo ènìyàn ń tẹ̀ lé.—1 Tímótì 4:8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí padà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Bí nǹkan kò bá ṣẹnuure fún tọkọtaya mọ́, gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tí Bíbélì fi kọ́ni lè máà jẹ́ kí ìgbéyàwó náà fọ́ àti pé yóò mú un wá sí ibi tí mìmì kan ò ti lè mì í

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Láìka bí ìwà ìbàjẹ́ ṣe gbòde kan sí—tàbí bóyá nítorí bó ṣe rí bẹ́ẹ̀—àwọn ẹlòmíràn sábà máa ń kan sáárá sáwọn aláìlábòsí èèyàn