Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Kan Sáárá Sí Ìgbàgbọ́ kan Tí Kì Í Yẹ̀”!

“Ẹ Kan Sáárá Sí Ìgbàgbọ́ kan Tí Kì Í Yẹ̀”!

Ìtàn Ìgbésí Ayé

“Ẹ Kan Sáárá Sí Ìgbàgbọ́ kan Tí Kì Í Yẹ̀”!

GẸ́GẸ́ BÍ HERBERT MÜLLER TI SỌ Ọ́

Kò ju oṣù mélòó kan lọ lẹ́yìn tí Hitler gbógun ti Netherlands tí wọ́n fi fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò pẹ́ kò jìnnà, orúkọ mi ti fara hàn lára àwọn tí ìjọba Násì ń wá kiri jù lọ, bí ẹní dọdẹ ẹranko ni wọ́n sì ṣe ń dọdẹ mi kiri.

ÌGBÀ kan wà tí sísá pa mọ́ àti sísá káàkiri sú mi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí mo fi sọ fún ìyàwó mi pé, ó tiẹ̀ dà bí i pé ara á tù mí tí ọwọ́ àwọn sójà bá kúkú tẹ̀ mí. Bẹ́ẹ̀ làwọn ọ̀rọ̀ inú orin kan bá sọ sí mi lọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Ẹ kan sáárá sí ìgbàgbọ́ kan tí kì í yẹ̀, bí onírúurú ọ̀tá tilẹ̀ ń gbógun.” a Ríronú jinlẹ̀ lórí orin yẹn fún mi ní àkọ̀tun agbára, ó tún jẹ́ kí ń rántí àwọn òbí mi ní ilẹ̀ Jámánì àti ọjọ́ tí àwọn ọ̀rẹ́ mi kọ orin yìí láti fi dágbére fún mi. Ṣé mo lè sọ àwọn ohun tí mo rántí yìí fún ọ?

Àpẹẹrẹ Àwọn Òbí Mi

Mẹ́ńbà Ìjọ Ajíhìnrere ni àwọn òbí mi nígbà tí wọ́n bí mi ní ìlú Copitz, ní Jámánì, lọ́dún 1913. b Ní 1920, ìyẹn ọdún méje lẹ́yìn náà, bàbá fi ìjọ yẹn sílẹ̀. Ní April 6, ó béèrè fún Kirchenaustrittsbescheinigung, (Ìwé Ẹ̀rí Ìfìjọsílẹ̀). Ọ̀gá tó wà ní ọ́fíìsì ìforúkọsílẹ̀ ìlú náà kọ ọ̀rọ̀ sínú ọ̀kan. Àmọ́ o, bó ṣe di ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà ni bàbá bá tún padà lọ sí ọ́fíìsì náà, ó sì ṣàlàyé pé wọn ò kọ orúkọ ọmọbìnrin òun sínú ìwé ẹ̀rí náà. Ni ọ̀gá yẹn bá tún kọ ọ̀rọ̀ sínú ìwé àkọsílẹ̀ kejì láti fi sọ pé ìfìjọsílẹ̀ náà kan Martha Margaretha Müller. Ọmọ ọdún kan àtààbọ̀ ni Margaretha, àbúrò mi nígbà náà. Bàbá kì í gba bọ̀ ọ́ wọ̀wọ̀ tó bá ti dọ̀rọ̀ sísin Jèhófà!

Lọ́dún yẹn kan náà, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn, batisí àwọn òbí mi. Ọwọ́ líle koko ni bàbá fi tọ́ àwa ọmọ, àmọ́ ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí Jèhófà jẹ́ kó rọrùn fún wa láti tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Ìdúróṣinṣin tún mú kí àwọn òbí mi ṣe àwọn ìyípadà kan. Fún àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí wọn kì í jẹ́ ká bọ́ síta ṣeré ní ọjọ́ Sunday. Ṣùgbọ́n, nígbà tó di ọjọ́ Sunday kan ní 1925, àwọn òbí wa sọ fún wa pé a máa jọ ṣeré jáde lọ. A di àwọn ìpápánu díẹ̀ dání, a sì gbádùn ara wa dọ́ba—ìyípadà ńlá mà lèyí jẹ o, sí dídé tí wọ́n ti máa ń dé wa mọ́lé láti àárọ̀ ṣúlẹ̀! Bàbá ní òun gbọ́ àwọn kókó kan ní àpéjọpọ̀ àìpẹ́ kan tó tún èrò òun ṣe nípa àwọn ìgbòkègbodò ọjọ́ Sunday. Láwọn àkókò mìíràn, bẹ́ẹ̀ ló ṣe tún ṣe tán láti ṣe ìyípadà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara àwọn òbí mi kò fi bẹ́ẹ̀ dá ṣáṣá, wọn kò ṣíwọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Fún àpẹẹrẹ, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, a wọ ọkọ̀ ojú irin lọ sí ìlú Regensburg pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà ìjọ tó kù láti lọ pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ecclesiastics Indicted, nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] kìlómítà ni ibẹ̀ sí Dresden. A pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà káàkiri gbogbo ìlú yẹn lọ́jọ́ kejì, nígbà táa sì ṣe tán, a wọ ọkọ̀ ojú irin náà padà. Nígbà táa máa fi padà délé, nǹkan bíi wákàtí mẹ́rìnlélógún ti kọjá.

Fífi Ilé Sílẹ̀

Wíwà tí mo wà nínú Jugendgruppe (Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́) nínú ìjọ wa tún ràn mí lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá sókè àti díẹ̀ nínú àwọn arákùnrin tó jẹ́ àgbà nínú ìjọ máa ń pàdé pọ̀. A máa ń ṣeré ìdárayá a sì tún máa ń fi àwọn ohun èlò ìkọrin dára yá, a ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a sì tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá àti sáyẹ́ǹsì. Àmọ́ lọ́dún 1932, nígbà tí mo di ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú ẹgbẹ́ yẹn dópin.

Ní April ọdún yẹn, bàbá gba lẹ́tà kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Magdeburg. Society ń fẹ́ ẹnì kan tó lè wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó sì ń fẹ́ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Mo mọ̀ pé ó wu àwọn òbí mi pé kí ń ṣe aṣáájú ọ̀nà, ṣùgbọ́n mo ronú pé mi ò lè ṣé e. Níwọ̀n bí àwọn òbí mi ti jẹ́ aláìní, láti ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí tún kẹ̀kẹ́ àti maṣíìnì ìránṣọ ṣe, títí kan ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àti àwọn ohun èlò ọ́fíìsì mìíràn. Báwo ni mo ṣe wá lè fi ìdílé mi sílẹ̀? Wọ́n nílò ìtìlẹ́yìn mi. Yàtọ̀ síyẹn, mi ò tiẹ̀ tíì ṣe batisí. Bàbá pè mí jókòó ó sì bi mí ní àwọn ìbéèrè kan láti mọ̀ bóyá mo lóye ohun tí ìbatisí ní nínú. Nígbà tí àwọn ìdáhùn mi mú kó dáa lójú pé mo ti lóye tó nípa tẹ̀mí láti lè ṣe ìrìbọmi, ló bá ní: “Ó yẹ kóo yọ̀ǹda ara ẹ fún iṣẹ́ yìí o.” Mo bá yọ̀ǹda ara mi.

Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà ni mo gba ìkésíni láti wá sí Magdeburg. Nígbà tí mo sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ mi nínú Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́, wọ́n fẹ́ kọ orin aládùn kan láti fi dágbére fún mi. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wọn nígbà tí mo sọ orin tí mo fẹ́, nítorí wọ́n kà á sí èyí tó ṣe pàtàkì gan-an fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, kíá, àwọn kan ti gbé gòjé wọn, mandolin àti gìtá, wọ́n sì kọrin báyìí pé: “Ẹ kan sáárá sí ìgbàgbọ́ kan tí kì í yẹ̀ bí onírúurú ọ̀tá tilẹ̀ ń gbógun; ọ̀kan tí kì í gbọ̀n lójú àjálù ayé èyíkéyìí.” Mi ò mọ̀ rárá lọ́jọ́ yẹn pé àwọn ọ̀rọ̀ orin yẹn ṣì máa wá fún mi lókun lọ́pọ̀ ìgbà láwọn ọdún tó ń bọ̀ níwájú.

Ìbẹ̀rẹ̀ Tí Kò Fararọ

Lẹ́yìn tí àwọn arákùnrin ní Magdeburg ti dán bí mo ṣe mọ ọkọ̀ wà sí wò, wọ́n gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan fún èmi àtàwọn arákùnrin mẹ́rin mìíràn, a sì kọrí sí Schneifel, ní agbègbè kan nítòsí Belgium. Kò pẹ́ rárá táa fi mọ̀ pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa wúlò fún wa gan-an ni. Inú Ìjọ Kátólíìkì tó wà ní àgbègbè náà kò dùn sí báa ṣe wà níbẹ̀ rárá, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni àwọn ará abúlé tí àwọn àlùfáà ń dẹ sí wa máa ń dúró dè wá láti lé wa lọ. Àìmọye ìgbà ló jẹ́ pé ọpẹ́lọpẹ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà la fi ń sá lọ kí ọwọ́ wọn má bàa tẹ̀ wá.

Lẹ́yìn ìṣe ìrántí ọdún 1933, Paul Grossmann, tó jẹ́ alábòójútó ẹkùn ibẹ̀ sọ fún wa pé wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ Society ní Jámánì. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ẹ̀ka iléeṣẹ́ sọ pé kí ń gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà wá sí Magdeburg láti wá kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà níbẹ̀, kí n kó o lọ sí ìpínlẹ̀ Saxony, ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kìlómítà sí Magdeburg. Àmọ́, nígbà tí màá fi dé Magdeburg, Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti ìjọba Násì ti ti ọ́fíìsì Society pa. Mo fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yẹn sílẹ̀ lọ́dọ̀ arákùnrin kan ní Leipzig mo sì padà sílé—ṣùgbọ́n fúngbà díẹ̀ ni.

Ọ́fíìsì Society tó wà ní Switzerland ké sí mi pé kí n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Netherlands. Ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì sígbà yẹn ni mo ṣì ń rò pé màá gbéra. Ṣùgbọ́n Bàbá gbà mí nímọ̀ràn pé kí ń gbéra lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Mo tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀, mo sì filé sílẹ̀ láàárín wákàtí díẹ̀. Lọ́jọ́ kejì, àwọn ọlọ́pàá wá sílé bàbá mi láti wá mú mi lórí ẹ̀sùn ìsáǹsá tó kọ ìlú rẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n kí wọ́n tó dé, mo ti lọ.

Bíbẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ní Netherlands

Ní August 15, 1933 mo dé sí ibùgbé àwọn aṣáájú ọ̀nà ní Heemstede, ìlú kan tó wà ní kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ìlú Amsterdam. Ní ọjọ́ kejì, mo jáde lọ wàásù láìmọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan rárá nínú èdè Dutch. Bí káàdì ìjẹ́rìí kan tí a tẹ ìwàásù sí ṣe ń bẹ lọ́wọ́ mi, mo bá bẹ̀rẹ̀. Ìṣírí ńlá gbáà ló mà jẹ́ fún mi o, nígbà tí obìnrin ọmọ ìjọ Kátólíìkì kan gba ìwé Reconciliation lọ́wọ́ mi! Mó tún fi ìwé kékeré mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n sóde lọ́jọ́ yẹn kan náà. Lópin ọjọ́ àkọ́kọ́ yẹn, ṣìnkìn ni inú mi ń dùn pé ó tún ṣeé ṣe fún mi láti wàásù fàlàlà.

Láyé ìgbà yẹn, àwọn aṣáájú ọ̀nà kò ní ibòmíràn tí wọ́n ti ń rówó ná ju látinú àwọn ọrẹ tí wọ́n bá gbà nígbà tí wọ́n bá fìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde lọ. Oúnjẹ àtàwọn nǹkan mìíràn tó bá jẹ́ dandan ni wọ́n máa ń lo owó yẹn fún. Tí owó díẹ̀ bá wá ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí oṣù bá parí, wọ́n máa ń pín in láàárín àwọn aṣáájú ọ̀nà láti lò fún ìnáwó tara wọn. A ò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan ìní tara, ṣùgbọ́n Jèhófà pèsè fún wa gan-an débi pé, lọ́dún 1934, ó ṣeé ṣe fún mi láti lọ sí àpéjọpọ̀ kan ní Switzerland.

Alábàákẹ́gbẹ́ Olùṣòtítọ́ Kan

Ní àpéjọpọ̀ náà, mo rí Erika Finke tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún. Ìgbà tí mo ti wà nílé ni mo ti mọ̀ ọ́n. Ọ̀rẹ́ ló jẹ́ fún Margaretha àbúrò mi, kò sì sígbà kan tí ìdúróṣinṣin Erika fún òtítọ́ kì í wú mi lórí. Kò pẹ́ lẹ́yìn tó ṣe batisí ní 1932, ni ẹnì kan lọ sọ fáwọn Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìjọba Násì pé Erika kọ̀ láti sọ pé, “Ti Hitler Ni Ìgbàlà! Ni Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìjọba Násì bá wá a kàn wọ́n sì fẹ́ mọ ìdí tó fi kọ̀. Ní àgọ́ ọlọ́pàá, Erika ka Ìṣe 17:3 fún ọ̀gá ọlọ́pàá tó wà níbẹ̀ ó sì ṣàlàyé pé ọkùnrin kan ṣoṣo péré ni Ọlọ́run yàn ṣe Olùgbàlà, ìyẹn Jésù Kristi. Ọ̀gá náà béèrè pé: “Ṣé àwọn kan ṣì kù tó gba nǹkan kan náà bíi tìẹ gbọ́?” Erika kọ̀ láti dárúkọ ẹnikẹ́ni. Nígbà tí ọlọ́pàá náà halẹ̀ mọ́ ọn pé òun á tì í mọ́lé, Erika sọ fún un pé, ó tẹ́ òun lọ́run kóun kú ju kóun dárúkọ ẹnikẹ́ni lọ. Ó wò ó ṣùnṣùn, ló bá jágbe mọ́ ọn pé: “Bọ́ síta. Kóo gbọ̀nà ilé yín. Ti Hitler Ni Ìgbàlà!”

Lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà, mo padà sí Netherlands ṣùgbọ́n Erika ní tiẹ̀ dúró sí Switzerland. Àmọ́ ṣá, àwa méjèèjì gbà pé ọ̀rẹ́ wa ti wọra. Erika kò tí ì kúrò ní Switzerland nígbà tó gbọ́ pé Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìjọba Násì ń wá òun kiri nílé. Ló bá kúkú pinnu láti dúró sí Switzerland láti máa ṣe aṣáájú ọ̀nà lọ níbẹ̀. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, Society sọ pé kó lọ sí Sípéènì. Ó ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìlú Madrid, ó tún ṣe ní Bilbao, àti lẹ́yìn náà ní San Sebastián, níbi tóun àti aṣáájú ọ̀nà alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ ti dèrò ẹ̀wọ̀n nítorí inúnibíni táwọn àlùfáà dá sílẹ̀. Ní 1935, wọ́n pàṣẹ fún wọn láti kúrò ní ilẹ̀ Sípéènì. Erika wá sí Netherlands, ní ọdún yẹn gan-an la sì ṣègbéyàwó.

Ogun Fẹ́ Bẹ́ Sílẹ̀

Lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, a ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìlú Heemstede, ẹ̀yìn ìgbà náà la wá ṣí lọ sí ìlú Rotterdam. Ibẹ̀ ni a ti bí Wolfgang ọmọkùnrin wa ní 1937. Ọdún kan lẹ́yìn náà a tún ṣí lọ sí ìlú Groningen, ní àríwá ilẹ̀ Netherlands, níbi táa ti jọ ń gbé ilé kan náà pẹ̀lú Ferdinand àti Helga Holtorf tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà ará Jámánì pẹ̀lú ọmọbìnrin wọn. Ní July 1938, Society sọ fún wa pé ìjọba Netherlands ti ṣòfin pé àwọn kò fàyè gba àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Germany mọ́ láti máa wàásù. Àárín àkókò kan náà ni wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ẹ̀ka ìpínlẹ̀ (alábòójútó àyíká), ni ìdílé wa bá lọ ń gbé inú Lichtdrager (Atànmọ́lẹ̀), ìyẹn ni ọkọ̀ ojú omi tó jẹ́ ti Society, èyí tí àwọn aṣáájú ọ̀nà tó ń wàásù ní ẹkùn àríwá Netherlands fi ṣe ilé àti ibi ìkẹ́rùsí. Láwọn ìgbà tó pọ̀ jù lọ, n kì í wà pẹ̀lú ìdílé mi, ńṣe ni mo máa ń gun kẹ̀kẹ́ láti ìjọ kan lọ sí òmíràn láti fún àwọn ará níṣìírí láti máa bá a lọ ní wíwàásù. Ohun tí àwọn ará náà sì ṣe gan-an nìyẹn. Àwọn kan tiẹ̀ fi kún ìgbòkègbodò wọn. Àpẹẹrẹ kan tó dáa ni ti Wim Kettelarij.

Nígbà tí mo pàdé Wim, ó jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó dá òtítọ́ mọ̀, ṣùgbọ́n ọwọ́ ẹ̀ máa ń dí nítorí iṣẹ́ lébìrà tó ń ṣe nínú oko. Mo gbà á nímọ̀ràn pé, “Tóo bá fẹ́ rí àkókò láti sin Jèhófà, o ní láti wáṣẹ́ míì ṣe.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà táa tún pàdé lẹ́yìn náà, mo rọ̀ ọ́ pé kó ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ló bá dáhùn pé: “Ó ṣáà di dandan kí n ṣiṣẹ́, kí n bàa lè róúnjẹ jẹ.” Mo mú kí ó dá a lójú pé: “Wàá kúkú jẹun. Jèhófà á bójú tó ẹ.” Bi Wim ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nìyẹn o. Lẹ́yìn náà, ó sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò, kódà láàárín ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́ pàápàá. Lónìí, tí Wim ti lé ní ẹni ọgọ́rin ọdún, ó ṣì jẹ́ Ẹlẹ́rìí onítara síbẹ̀. Ní tòótọ́, Jèhófà bójú tó o.

Wọ́n Fòfin Dè Wá, Wọ́n Ń Wá Mi Kiri

Ní May 1940, ìyẹn bí ọdún kan lẹ́yìn tí a bí Reina ọmọ wa kejì, àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Netherlands juwọ́ sílẹ̀, ìjọba Násì sì gba orílẹ̀-èdè náà. Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìjọba Násì gba ọ́fíìsì Society àti ilé ìtẹ̀wé rẹ̀ ní July. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fàṣẹ ọba mú àwọn Ẹlẹ́rìí lójú méjèèjì, wọ́n sì mú èmi náà pẹ̀lú. Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí àti ẹni tó ṣì wà lọ́jọ́ orí ogun jíjà, kò ṣòro rárá láti finú ro nǹkan táwọn Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìjọba Násì máa fojú mi rí. Mo bá tètè gba kámú pé mi ò tún lè rí ìdílé mi mọ́.

Àmọ́ nígbà tó di May 1941, Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìjọba Násì tú mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, wọ́n sì pàṣẹ pé kí ń lọ forúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ológun. Ó yà mí lẹ́nu gidigidi. Lọ́jọ́ yẹn gan an ni wọ́n ti wá mi tì, oṣù yẹn náà ni mo sì tún padà sẹ́nu iṣẹ́ àyíká. Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìjọba Násì fi mí sára àwọn tí wọ́n ń wá lójú méjèèjì.

Bí Ìdílé Mi Ṣe Kojú Ipò Náà

Ìyàwó mi àtàwọn ọmọ mi ti ṣí lọ sí abúlé kan tó ń jẹ́ Vorden ní apá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà. Bó ti wù kó rí, kí n má bàa kó wọn sínú ewu jù, ó di dandan kí n dín bí mo ṣe ń bẹ ilé wò kù gan-an ni. (Mátíù 10:16) Fún ààbò mi, àwọn ará kì í lo orúkọ mi gidi, orúkọ àdàpè mi tí ń jẹ́, Duitse Jan (Jòhánù ará Jámánì) ni wọ́n fi ń pè mí. Kódà gan-an, wọn kò gbà kí Wolfgang ọmọ mi tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin máa sọ̀rọ̀ nípa “Dádì” àfi kí ó sọ̀rọ̀ nípa “Ome Jan” (Arákùnrin Jòhánù). Èyí jẹ́ ohun tó ṣòro fún un gan-an ní ti ìmí ẹ̀dùn.

Ní gbogbo ìgbà tí mo ń forí pa mọ́ kiri, Erika ló bójú tó àwọn ọmọ, ó sì ń bá ìwàásù nìṣó. Nígbà tí Reina pé ọmọ ọdún méjì, Erika máa ń gbé e sórí ibi tí wọ́n máa ń kẹ́rù sí lórí kẹ́kẹ́, wọn á jọ lọ wàásù ní àwọn ìgbèríko. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtirí oúnjẹ wá di ìṣòro, kò sígbà kankan tí Erika ṣàìrí oúnjẹ mọ́ rárá fún ìdílé. (Mátíù 6:33) Àgbẹ̀ kan tó jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì tí mó ti bá tún maṣíìnì ìránṣọ ṣe nígbà kan rí ń fún un ní ànàmọ́. Ó tún máa ń gba iṣẹ́ jẹ́ látọ̀dọ̀ mi fún Erika. Ìgbà kan wà tí Erika san gulden kan (owó ilẹ̀ Netherlands) fún nǹkan kan tó rà ní ṣọ́ọ̀bù oògùn kan. Ni ẹni tó ni ibẹ̀, tó ti mọ̀ pé ńṣe ló ń forí pa mọ́, àti pé kò lè rí káàdì tí wọ́n fi ń ra oúnjẹ ní ẹ̀dínwó gbà, bá fún un ní ohun tó fẹ́ yẹn, ó tiẹ̀ tún fún un ní gulden méjì mọ tọwọ́ ẹ̀. Irú àwọn ojú àánú tí wọn ń fi hàn sí i bí èyí ló mú kí ó la àkókò yẹn já.—Hébérù 13:5.

Mo Ṣiṣẹ́ Ní Ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ Pẹ̀lú Àwọn Arákùnrin Onígboyà

Láàárín àkókò náà, mo ń bá a lọ ní bíbẹ àwọn ìjọ wò—bó tilẹ̀ jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin tó lẹ́rù iṣẹ́ nínú ìjọ nìkan ni mo ń kàn sí. Nítorí pé àwọn Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìjọba Násì kò yé mi í wá, kò ṣeé ṣe fún mi láti dúró níbì kan ju ìwọ̀nba wákàtí díẹ̀ lọ. Èyí tò pọ̀ jù lọ lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin ni kò ṣeé ṣe fún láti rí mi. Kìkì àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú àwùjọ kékeré tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan ni wọ́n mọ̀. Fún ìdí yẹn, àwọn obìnrin méjì kan tó jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò tiẹ̀ wà tí wọ́n ń gbé apá ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìlú kan náà, tó jẹ́ pé, ẹ̀yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí ni wọ́n tó mọ̀ pé ìgbà ogun yẹn làwọn méjèèjì di Ẹlẹ́rìí.

Iṣẹ́ ńlá míì tó tún wà fún mi ni àtirí ibi kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Society pa mọ́ sí. A tún máa ń kó bébà àti àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé fún ṣíṣe àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ jáde pa mọ́, nítorí bóyá a lè nílò wọn. Nígbà míì, ó máa ń gba pé ká kó àwọn ìwé tí Society tẹ̀ láti ibi ìpamọ́ kan sí ibòmíràn. Mo rántí bí mo ṣe kó ọgbọ̀n páálí, tó kún fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ síbì kan, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ṣọ́ra kí wọ́n máà rí mi—iṣẹ́ tí ń jáni láyà gbáà ni!

Láfikún sí ìyẹn, a tún ṣètò kíkó oúnjẹ láti àwọn oko kan ní apá ìlà oòrùn Netherlands lọ sí àwọn ìlú tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Netherlands, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin ò fàyè gba èyí. Ńṣe la ń kó oúnjẹ kúnnú ọkọ̀ kan tí a ń fi ẹṣin fà tí a ó sì kọrí sí ọ̀nà ìwọ̀ oòrùn. Nígbà táa débi odò kan, kò ṣeé ṣe rárá fún wa láti kọjá lórí àwọn afárá rẹ̀ nítorí pé àwọn sójà ń ṣọ́ ọ. Ohun táa ṣe ni pé, a já àwọn ẹrù náà sínú àwọn ọkọ̀ ojú omi kéékèèké, a wá kó àwọn oúnjẹ náà kọjá sí òdìkejì odò náà, a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún wá kó àwọn ẹrù náà padà sínú ọkọ̀ mìíràn tí ẹṣin ń fà. Nígbà táa dé ìlú tí à ń lọ, a dúró kí ilẹ̀ fi ṣú, a fi ìbọ̀sẹ̀ bọ pátákò ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin náà, bẹ́ẹ̀ la rọra ń lọ jẹ́ẹ́ sí ibi ìkọ̀kọ̀ tí ìjọ náà ń kó oúnjẹ pa mọ́ sí. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti ń pín oúnjẹ náà fún àwọn ará tí wọ́n ṣaláìní.

Bí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì bá lọ rí ibi ìkóúnjẹ pa mọ́ sí yẹn pẹ́nrẹ́n, ẹ̀mí èèyàn lè lọ sí i. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn arákùnrin bíi mélòó kan yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́. Fún àpẹẹrẹ, ìdílé Bloemink tó wà nílùú Amersfoort gbà kí wọ́n lo pálọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ibi ìkóúnjẹ pa mọ́ sí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé tòsí ilé wọn ni ibùdó àwọn ọmọ ogun Jámánì kan wà! Irú àwọn Ẹlẹ́rìí onígboyà bí ìwọ̀nyí fi ẹ̀mí wọn wewu nítorí àwọn arákùnrin wọn.

Jèhófà ran èmi àti ìyàwó mi lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ jálẹ̀jálẹ̀ àwọn ọdún ìfòfindè náà. Ní May 1945, wọ́n ṣẹ́gun ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jámánì, bẹ́ẹ̀ ni ìgbésí ayé ìsáǹsá mi dópin. Society ní kí n ṣì máa bá a lọ ná gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò títí di ìgbà tí àwọn arákùnrin mìíràn fi máa dé. Ní 1947, Bertus van der Bijl gbaṣẹ́ lọ́wọ́ mi. c Ní àkókò yẹn la bí ọmọ wa kẹta, a sì fìdí kalẹ̀ sí apá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà.

Ìbànújẹ́ àti Ìdùnnú

Lẹ́yìn ogun náà, mo gbọ́ pé nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí mo kúrò nílé lọ sí Netherlands ni wọ́n ju bàbá mi sẹ́wọ̀n. Wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì nítorí àìlera, àmọ́ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe tún ń fi sẹ́wọ̀n padà lẹ́yìn náà. Ní February ọdún 1938, wọ́n rán an lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Buchenwald àti lẹ́yìn náà sí ti Dachau. Níbẹ̀ ni bàbá mi kú sí ní May 14, 1942. Ó dúró gbọn-in, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin títí dópin.

Wọ́n tún rán màmá pẹ̀lú lọ sí àgọ́ Dachau. Ibẹ̀ ló wà títí dìgbà tí wọ́n tó dá a sílẹ̀ ní 1945. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin àwọn òbí mi ló túbọ̀ jẹ́ kí n lè rí àwọn ìbùkún tẹ̀mí tí mo ti gbádùn, ó dùn mọ́ mi láti mú màmá tira ní 1954. Margaretha àbúrò mi—tó ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà láti ọdún 1945 lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì ní Ìlà Oòrùn Jámánì—náà tún wà pẹ̀lú wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara màmá ò le, tí kò sì lè sọ èdè Dutch, ó ń bá a lọ ní kíkópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá títí tó fi fi ìṣòtítọ́ parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní October ọdún 1957.

Àkànṣe ni àpéjọpọ̀ tó wáyé ní Nuremberg ní orílẹ̀-èdè Jámánì lọ́dún 1955 jẹ́. Lẹ́yìn tí a gúnlẹ̀ síbẹ̀, àwọn ará láti Dresden sọ fún Erika pé màmá rẹ̀ náà wá sí àpéjọpọ̀ yẹn. Nítorí pé abẹ́ àkóso Ìlà Oòrùn Jámánì ni Dresden wà, Erika kò tíì fojú kan màmá rẹ̀ fún ọdún mọ́kànlélógún. A ṣètò bí wọ́n ṣe máa pàdé, bẹ́ẹ̀ ni ìyá àtọmọ fojú gán-an-ní ara wọn tí wọ́n sì dìrọ̀ mọ́ra wọn. Ìdùnnú tí ìpàdépọ̀ yẹn mú wá kò ṣeé fẹnu sọ!

Bí àkókò ti ń lọ, ìdílé wa di ìdílé ọlọ́mọ mẹ́jọ. Ó báni nínú jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin wa bá jàǹbá ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan rìn. Síbẹ̀ bí a ṣe ń rí i pé àwọn ọmọ wa tó kù ń sin Jèhófà jẹ́ orísun ayọ̀ ńlá fún wa. A láyọ̀ pé ọmọkùnrin wa Wolfgang àti aya rẹ̀ wà lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká àti pé ọmọkùnrin tiwọn náà ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká pẹ̀lú.

Mo dúpẹ́ pé ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ Jèhófà ní Netherlands ṣojú mi. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Netherlands lọ́dún 1933, kìkì nǹkan bí ọgọ́rùn-ún Ẹlẹ́rìí ló wà nígbà yẹn. Lónìí, a lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000]. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé okun ń tán lọ lára wa, ìpinnu èmi àti Erika ṣì ni láti máa ṣe bí àwọn ọ̀rọ̀ orin ayé ọjọ́un yẹn ṣe wí, pé: “Ẹ kan sáárá sí ìgbàgbọ́ kan tí kì í yẹ̀.”

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orin 194.—Orin Ìyìn sí Jèhófà (1928).

b Ìlú Copitz, táa wá mọ̀ sí Pirna báyìí wà nítòsí Odò Elbe, ní kìlómítà méjìdínlógún sí ìlú Dresden.

c Fún ìtàn ìgbésí ayé arákùnrin Van der Bijl, wo àkòrí yìí, “Kò Sí Ohun Tí Ó Dára Bí Òtítọ́,” nínú Ilé Ìṣọ́, January 1, 1998.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn “Jugendgruppe” (ẹgbẹ́ ọ̀dọ́) lásìkò ìsinmi lẹ́yìn iṣẹ́ ìsìn pápá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Èmi àtàwọn aṣáájú ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ mi ṣe gbogbo ìpínlẹ̀ Schneifel. Ọmọ ogún ọdún ni mí nígbà náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti Erika àti Wolfgang ní 1940

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Láti apá òsì sí ọ̀tún: Jonathan, ọmọ ọmọ mi àti ìyàwó rẹ̀ Mirjam; Eríka, èmi, Wolfgang ọmọkùnrin mi àti ìyàwó rẹ̀, Julia

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Arákùnrin kan tóun àti bàbá mi jọ wà lẹ́wọ̀n ló fọwọ́ ya bàbá báyìí ní 1941