Kí Lo Fi Ń Díwọ̀n Àṣeyọrí?
Kí Lo Fi Ń Díwọ̀n Àṣeyọrí?
ÌWÉ atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ àṣeyọrí sí “dídi ọlọ́rọ̀, rírí ojú rere àwọn èèyàn, tàbí wíwà ní ipò ọlá.” Ṣé ìtumọ̀ tó kún rẹ́rẹ́ nìyẹn? Ṣé kìkì ọrọ̀, ojú rere, tàbí ipò ọlá nìkan la fi ń díwọ̀n àṣeyọrí? Kóo tó dáhùn, gbé èyí yẹ wò: Jésù Kristi ò kó ọrọ̀ jọ nígbà ayé rẹ̀. Kò rí ojú rere ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn; bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń pinnu bí nǹkan ṣe ń lọ nígbà ayé rẹ̀ kò kà á sí èèyàn ńlá. Síbẹ̀ ọkùnrin kan tó ṣàṣeyọrí ni Jésù. Kí nìdí rẹ̀?
Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó “ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:21) Lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, Ọlọ́run san èrè fún un nípa fífi “ògo àti ọlá” dé e ládé. Jèhófà gbé Ọmọ rẹ̀ ga “sí ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.” (Hébérù 2:9; Fílípì 2:9) Ọ̀nà ìgbésí ayé Jésù mú ọkàn-àyà Jèhófà yọ. (Òwe 27:11) Ó ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé nítorí pé ó mú ète tó tìtorí rẹ̀ wá ṣẹ. Jésù ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sì bọlá fún orúkọ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bọlá fún Jésù nípa fífún un ní ọrọ̀, ojú rere, àti ọlá tí kò sí ọ̀jọ̀gbọ́n, òṣèlú, tàbí akọni nínú eré ìdárayá kankan tó lè ní irú rẹ̀ láé. Ká sọ tòótọ́, Jésù ni ẹni tó ṣàṣeyọrí jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tó tíì gbé ayé rí.
Àwọn Kristẹni òbí mọ pé bí àwọn ọmọ wọn bá lè tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Kristi, kí wọ́n di ọlọ́rọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bíi ti Jésù, àwọn óò rí ìbùkún yàbùgà yabuga nísinsìnyí àti àwọn èrè tó pọ̀ jaburata nínú ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀. Kò tún sí ọ̀nà mìíràn tó dára jù tí ọ̀dọ́ kan fi lè tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Kristi ju pé kí ó ṣe iṣẹ́ tí Jésù ṣe—nípa kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tíyẹn bá ṣeé ṣe.
Àmọ́ o, láwọn àgbègbè kan, àṣà tó gbòde níbẹ̀ ni pé kí àwọn ọ̀dọ́ má ṣe tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin kan bá kàwé tán, wọ́n lè máa retí pé kó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ tó máa gbà á ní gbogbo ọjọ́, kó gbéyàwó, kó sì ní ìdílé tirẹ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n wá láti irú àgbègbè bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe àṣìṣe nípa lílọ́tìkọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. (Òwe 3:27) Èé ṣe? Nítorí pé wọ́n fẹ́ ṣe bí àwọn ẹgbẹ́ wọn ti ń ṣe, wọ́n ń jẹ́ kí àṣà tó gbalẹ̀ kan níbẹ̀ nípa lórí wọn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Robert nìyẹn. a
Nígbà Tí Àṣà Ìbílẹ̀ àti Ẹ̀rí-Ọkàn Bá Forí Gbárí
Wọ́n tọ́ Robert dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó wà ní ọ̀dọ́langba, ìwà rẹ̀ àtàwọn tó ń bá kẹ́gbẹ́ kò bójú mu rárá. Ìyá rẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í dààmú nípa rẹ̀. Nítorí náà, ó ní kí aṣáájú ọ̀nà kan, ìyẹn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gbà á níyànjú. Robert ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà.
“Mo mọrírì ìfẹ́ tí arákùnrin aṣáájú ọ̀nà náà fi hàn sí mi gan-an ni. Àpẹẹrẹ rere rẹ̀ mú kí n fẹ́ láti fi iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ṣe iṣẹ́ ìgbésí ayé mi ní gbàrà tí mo bá kàwé tán. Ìgbà yẹn ni Mọ́mì tún bẹ̀rẹ̀ sí í dààmú—àmọ́ nǹkan mìíràn ló wá ń dà á láàmú lọ́tẹ̀ yìí. Ó ní ṣé o mọ̀ pé nínú àṣà ìbílẹ̀ wa, ó dáa kí ọmọbìnrin bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní gbàrà tó bá kàwé tán, ṣùgbọ́n nǹkan táa retí pé kí ọmọkùnrin ṣe ni pé kó kọ́kọ́ lówó lọ́wọ́ ná, lẹ́yìn ìyẹn ó lè wá ronú nípa iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà.
“Bí mo ṣe kọ́ṣẹ́ kan nìyẹn, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣòwò tèmi. Kó pẹ́ tí òwò náà fi wọ̀ mí lára gan-an débi pé mi ò lè ṣe ju kí n kàn lọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí tó ti dàṣà wa. Ẹ̀rí-ọkàn mi dà mí láàmú—mo mọ̀ pé mo lè sin Jèhófà jù bẹ́ẹ̀ lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, ìṣòro ńlá ló jẹ́ láti jáwọ́ nínú ohun tí àwọn èèyàn ń retí látọ̀dọ̀ mi, àmọ́ mo láyọ̀ pé mo ṣe bẹ́ẹ̀. Mo ti gbéyàwó báyìí, èmi àti ìyàwó mi sì ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà láti ọdún méjì sẹ́yìn. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. Mo lè fi tinútinú sọ pé mo ti wá ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn nísinsìnyí, mo sì ń fi gbogbo ọkàn-àyà mi sin Jèhófà, dé ibi tí agbára mi mọ.”
Léraléra ni ìwé ìròyìn yìí ti máa ń rọ àwọn ọ̀dọ́ láti kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ kan tàbí kí wọ́n rí i pé àwọn mọ iṣẹ́ kan dunjú—tó bá ṣeé ṣe kó jẹ́ nígbà tí wọ́n bá ṣì wà nílé ìwé. Èé ṣe? Ṣé kí wọ́n lè di ọlọ́rọ̀ ni? Ó tì o. Olórí ìdí ti wọ́n fi ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà ara wọn dáadáa nígbà tí wọ́n bá dàgbà, kí wọ́n sì lè sin Jèhófà dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibi tí wọ́n bá lè sìn ín dé, àgàgà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Àmọ́ ṣá o, ó ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin máa ń kó ara wọn sínú lílépa iṣẹ́ ayé débi pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ ò ní fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì lójú wọn mọ́. Àwọn kan kì í tiẹ̀ ronú nípa kíkópa nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún rárá. Kí ló fà á?
Ọ̀rọ̀ tí Robert sọ túbọ̀ jẹ́ ká lóye kókó náà. Gbàrà tí Robert kọ́ṣẹ́ tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣòwò. Kò pẹ́ púpọ̀ tó fi rí i pé ohun tí kò lérè ni òun ń lé kiri. Ète Mátíù 6:33 ṣe máa ń tu àwọn Kristẹni nínú gan-an.
rẹ̀ ni pé kí òun ní owó tó pọ̀ tó. Àmọ́, ǹjẹ́ a rí ẹnikẹ́ni yálà nínú ìjọ Kristẹni tàbí lóde rẹ̀ tó tíì lé góńgó yìí bá lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ rí? Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ tiraka láti lè gbọ́ bùkátà ara wọn, kí wọ́n fi taápọntaápọn bójú tó ọ̀rọ̀ ìnáwó wọn; àmọ́ wọ́n tún ní láti mọ̀ pé nínú àkókò tí kò dáni lójú wọ̀nyí, ìwọ̀nba kéréje ènìyàn ló tíì lówó débi tí wọn fi lè ka ara wọn sí ẹni tó ti ní owó tó pọ̀ tó. Ìdí nìyẹn tí ìlérí Jésù táa kọ sínúInú Robert dùn pé òun pinnu láti tẹ̀ lé ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn òun dípò ohun tí àṣà ìbílẹ̀ òun sọ. Lónìí, ó ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tó ń ṣe. Láìsí àní-àní, iṣẹ́ tó lọ́wọ̀ ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ọkàn Robert balẹ̀ nítorí pé ó ń sin Jèhófà, gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ ọ́, ‘dé ibi tí agbára òun gbé e dé.’
Lo Ẹ̀bùn Rẹ Dé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló lẹ́bùn títayọ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn kan ní ọgbọ́n tó ta yọ; àwọn mìíràn sì ní ẹ̀bùn láti ṣe iṣẹ́ agbára. Àtọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí ti wá, ẹni tó ń fún “gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.” (Ìṣe 17:25) Béèyàn ò bá wà láàyè, òtúbáńtẹ́ ni gbogbo ẹ̀bùn wọ̀nyí máa já sí.
Ó jẹ́ ohun tó bẹ́tọ̀ọ́ mu nígbà náà pé kí a lo ìgbésí ayé wa tí a ti yà sí mímọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ohun tí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ní ẹ̀bùn tó ta yọ pinnu láti ṣe nìyẹn. Ó gbé ayé ni ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Ó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé kan tó lókìkí, ó sì lo ìgbà èwe rẹ̀ ní ìlú ńlá Tásù ní Sìlíṣíà táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ àwọn Júù ni wọ́n bí i sí, ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Róòmù nítorí pé ọmọ ibẹ̀ ni baba rẹ̀. Ìyẹn wá jẹ́ kó ní ẹ̀tọ́ àti àǹfààní tó pọ̀ rẹpẹtẹ. Nígbà tó dàgbà, ó kẹ́kọ̀ọ́ Òfin lọ́dọ̀ ọ̀kan lára “àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n” tó gbawájú jù lọ lákòókò yẹn—Gàmálíẹ́lì. Ó dà bí ẹni pé kò ní pẹ́ tí ‘ọrọ̀, ojú rere, àti ipò ọlá’ fi máa tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́.—Ìṣe 21:39; 22:3, 27, 28.
Ta ni ọ̀dọ́kùnrin yìí? Sọ́ọ̀lù lorúkọ rẹ̀. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù wá di Kristẹni, ó sì di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù níkẹyìn. Ó pa àwọn ohun tó jẹ́ ìlépa rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì yọ̀ǹda gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni kan. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe di ẹni tí gbogbo èèyàn mọ̀ nìyẹn o, wọn ò mọ̀ ọ́n sí amòfin títayọ o, ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ ọ́n sí ẹni tí ń fi ìtara wàásù ìhìn rere náà. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n ọdún gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, ó wá kọ ìwé kan sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó wà ní ìlú Fílípì. Inú rẹ̀ ló ti sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó ṣe kó tó di Kristẹni, ó tún wá sọ pé: “Ní tìtorí [Jésù Kristi], èmi ti gba àdánù ohun gbogbo, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí, kí n lè jèrè Kristi.” (Fílípì 3:8) Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù ń kábàámọ̀ nípa ọ̀nà tó gbà lo ìgbésí ayé rẹ̀ o!
Ẹ̀kọ́ tí Pọ́ọ̀lù wá kọ́ lọ́dọ̀ Gàmálíẹ́lì ńkọ́? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ rí nǹkan fi ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni o! Láwọn ìgbà bíi mélòó kan, ó kópa nínú “gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin.” Àmọ́, lájorí iṣẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe ni iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà—ohun kan tí ilé ẹ̀kọ́ tó ti lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀ kò lè kọ́ ọ láé.—Fílípì 1:7; Ìṣe 26:24, 25.
Bákan náà ló rí lóde òní, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn kan láti lo ẹ̀bùn àbínibí wọn, àti ìwé tí wọ́n kà pàápàá láti mú kí ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú. Fún àpẹẹrẹ, Amy jẹ́ obìnrin tó gba oyè nínú ẹ̀kọ́ òwò aládàáńlá ní yunifásítì, ó sì tún gba oyè mìíràn nínú ìmọ̀ òfin. Ó fìgbà kan ń ṣe iṣẹ́ kan tó ń mówó wọlé ní ọ́fíìsì amòfin kan, àmọ́ lónìí, ó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ kan tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ láìgbowó oṣù ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society. Bí Amy ṣe ṣàpèjúwe ìgbésí ayé tó ń gbé báyìí rèé: “Mo gbà gbọ́ pé mo ti yan ohun tó dára jù lọ nínú ìgbésí ayé. . . . Mí o fọkàn sí pé kí n tún lọ máa bá èyíkéyìí lára àwọn ojúgbà mi tí a jọ lọ sí yunifásítì dupò. Mo ń fi ipa ọ̀nà tí mo yàn yangàn. Mo ní gbogbo ohun tí mo nílò àti èyí tí mo fẹ́—mo ń gbé ìgbésí ayé tó tẹ́ mi lọ́rùn tó sì ń fún mi láyọ̀, mo ń ṣiṣẹ́ tó tẹ́ mi lọ́rùn tó sì fọkàn mi balẹ̀ dẹ́dẹ́.”
Amy yan ipa ọ̀nà kan tó jẹ́ kó ní ìfọ̀kànbalẹ̀, ìtẹ́lọ́rùn, àti ìbùkún Jèhófà. Ó dájú pé àwọn òbí Kristẹni kò fẹ́ ohun tó yàtọ̀ sí èyí fún àwọn ọmọ wọn!
Àṣeyọrí Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, ó ṣe pàtàkì láti ní èrò tó tọ́ nípa ṣíṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni fúnra
rẹ̀. Kò ṣòro láti gbà pé a ṣàṣeyọrí nígbà táa bá ti lo àkókò tó gbádùn mọ́ni nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, táa fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì síta tàbí táa bá onílé jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tó tani jí láti inú Bíbélì. Àmọ́ tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé àwọn èèyàn ò fetí sí ọ̀rọ̀ wa mọ́, a lè fẹ́ parí èrò sí pé ṣe ni a kàn ń fi àkókò ṣòfò. Àmọ́ o, rántí pé ọ̀kan lára ohun tí a túmọ̀ àṣeyọrí sí ni ‘rírí ojú rere.’ Ojú rere ta la fẹ́ rí? Ti Jèhófà ni. A lè rí èyí yálà àwọn èèyàn fetí sí wa tàbí wọn ò fetí sí wa. Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ kan tó lágbára lórí ọ̀rọ̀ yìí.Wàá rántí pé Jésù rán àwọn àádọ́rin oníwàásù Ìjọba náà jáde lọ “sínú gbogbo ìlú ńlá àti ibi tí òun fúnra rẹ̀ yóò dé.” (Lúùkù 10:1) Wọ́n ní láti wàásù láwọn ìlú àtàwọn abúlé, Jésù ò sì ní bá wọn lọ. Ohun tuntun gbáà lèyí jẹ́ fún wọn. Nítorí náà, Jésù fún wọn ní ìtọ́ni tó kún rẹ́rẹ́ kó tó rán wọn jáde. Nígbà tí wọ́n bá pàdé “ọ̀rẹ́ àlàáfíà,” kí wọ́n jẹ́rìí kúnnákúnná fún un nípa Ìjọba náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá kọ̀ wọ́n, kí wọ́n máa bá ọ̀nà wọn lọ láìbínú. Jésù ṣàlàyé fún wọn pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ni àwọn tó kọ̀ láti fetí sí wọn ń kọ̀ sílẹ̀.—Lúùkù 10:4-7, 16.
Nígbà tí àwọn àádọ́rin náà parí iṣẹ́ ìwàásù tí a yàn fún wọn, wọ́n padà lọ ròyìn fún Jésù “pẹ̀lú ìdùnnú, wọ́n wí pé: ‘Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá ni a mú tẹrí ba fún wa nípasẹ̀ lílo orúkọ rẹ.’” (Lúùkù 10:17) Inú àwọn ọkùnrin aláìpé wọ̀nyẹn á mà dùn gan-an pé àwọn lè lé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára wọ̀nyẹn jáde! Àmọ́, Jésù dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ onítara náà lẹ́kun pé: “Ẹ má ṣe yọ̀ lórí èyí, pé a mú àwọn ẹ̀mí tẹrí ba fún yín, ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ nítorí pé a ti ṣàkọọ́lẹ̀ orúkọ yín ní ọ̀run.” (Lúùkù 10:20) Àwọn àádọ́rin náà lè ṣàì fìgbà gbogbo lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo ìgbà ni nǹkan yóò máa ṣẹnuure fún wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Àmọ́ bí wọ́n bá dúró bí olóòótọ́, wọn ó máa rí ojú rere Jèhófà ní gbogbo ìgbà.
Ǹjẹ́ O Mọyì Àwọn Ìránṣẹ́ Alákòókò Kíkún?
Ọ̀dọ́kùnrin kan sọ fún Kristẹni alàgbà kan pé: “Nígbà tí mo bá gboyè jáde nílé ìwé gíga, màá gbìyànjú láti wáṣẹ́ ṣe. Bí mi ò bá wá ríṣẹ́, mo lè wá gbé bíbẹ̀rẹ̀ irú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kan yẹ̀ wò.” Àmọ́, kì í ṣe irú èrò yẹn ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní. Àwọn kan ti fi àwọn àǹfààní tí wọ́n ní láti lépa iṣẹ́ tó ń mówó wọlé sílẹ̀ kí wọ́n bàa lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Àwọn kan ti kọ àwọn àǹfààní tí wọ́n ní láti kàwé sílẹ̀. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n ti fi àwọn nǹkan du ara wọn, ṣùgbọ́n bíi ti Pọ́ọ̀lù, Robert, àti Amy, wọn ò kábàámọ̀ yíyàn tí wọ́n ṣe. Wọ́n mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti fi ẹ̀bùn wọn yin Jèhófà, ẹni tí ó lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ohun tó dára jù lọ tí wọ́n bá lè ṣe.
Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni kò láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nítorí ìdí kan tàbí òmíràn. Wọ́n lè ní àwọn ẹrù iṣẹ́ tí Ìwé Mímọ́ tì lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́dọ̀ bójú tó. Síbẹ̀, bí wọ́n bá ń sin Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ‘ọkàn-àyà, ọkàn, àti èrò inú’ wọn, Jèhófà ní inú dídùn sí wọn. (Mátíù 22:37) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn fúnra wọn kò lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, síbẹ̀ wọ́n gbà pé àwọn tó ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ti yan iṣẹ́ àtàtà.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.” (Róòmù 12:2) Ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù, a kò gbọ́dọ̀ fàyè gba àṣà ìbílẹ̀ tàbí ọ̀pá-ìdiwọ̀n ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí láti darí ìrònú wa. Yálà o lè ṣe aṣáájú ọ̀nà ni o, tàbí o kò lè ṣe é, ṣáá fi ìṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Wàá ṣàṣeyọrí, níwọ̀n ìgbà tóo bá ti ń rí ojú rere Jèhófà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ náà padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Má ṣe ranrí mọ́ líle ohun tí kò lérè kiri