O Lè Máa Bá Híhùwà Mímọ́ Nìṣó
O Lè Máa Bá Híhùwà Mímọ́ Nìṣó
“Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—1 JÒHÁNÙ 5:3.
1. Ìyàtọ̀ wo ni a ń rí nínú ìwà àwọn ènìyàn lónìí?
NÍGBÀ pípẹ́ sẹ́yìn, Ọlọ́run mí sí wòlíì Málákì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò kan tí ìwà àwọn tó jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run máa yàtọ̀ gédégédé ní ìfiwéra pẹ̀lú ti àwọn tí kò sin Ọlọ́run. Wòlíì náà kọ̀wé pé: “Dájúdájú, ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” (Málákì 3:18) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń ní ìmúṣẹ lónìí. Pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, títí kan àwọn tó ń béèrè pé ká hùwà tó mọ́, ni ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu tó sì bójú mu láti tọ̀ ní ìgbésí ayé. Àmọ́ o, ọ̀nà yẹn kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Ìdí rèé tí Jésù fi sọ pé àwọn Kristẹni ní láti tiraka tokuntokun láti lè rí ìgbàlà.—Lúùkù 13:23, 24.
2. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká ẹni wo ló mú kó ṣòro fáwọn kan láti máa bá a lọ láìba ara wọn jẹ́?
2 Èé ṣe tó fi ṣòro láti máa bá híhùwà tó mọ́ nìṣó? Ìdí kan ni pé, àwọn nǹkan kan ń ṣẹlẹ̀ láyìíká ẹni tó ń mú kó ṣòro fúnni. Àwọn eléré máa ń fi ìṣekúṣe hàn bí ohun tó gbayì, tó gbádùn mọ́ni, tó sì ń fi hàn pé èèyàn kì í ṣọmọdé mọ́, láìkọbiara sí àwọn ìṣòro tó ń tinú wọn wá. (Éfésù 4:17-19) Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìdọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀ tí wọ́n ń fi hàn ló jẹ́ pé láàárín àwọn ọkùnrin àtobìnrin tí wọn kì í ṣe tọkọtaya ni. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn sinimá àtàwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n máa ń fi hàn pé ìbálòpọ̀ wáyé láàárín àwọn tí àjọṣe kàn dà pọ̀ lásán. Lọ́pọ̀ ìgbà wọ̀nyẹn sì rèé, kì í sí ojúlówó ìkẹ́ àti ọ̀wọ̀ nínú wọn. Látìgbà tí ọ̀pọ̀ ti wà lọ́mọdé ni wọ́n sì ti ń rí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Síwájú sí i, ẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe tó lágbára kò gbẹ́yìn nínú sísún àwọn èèyàn sínú ìwà ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ tó gbòde kan lónìí, béèyàn ò bá sì ti lọ́wọ́ sí i, wọ́n á máa fi ṣẹlẹ́yà tàbí kí wọ́n máa bú wọn nígbà míì.—1 Pétérù 4:4.
3. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tó ń mú ki ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé ṣe ìṣekúṣe?
3 Ogun tí ara èèyàn fúnra ẹ̀ ń bá ara jà tún máa ń mú kó nira láti máa hùwà mímọ́ nìṣó. Jèhófà dá ìfẹ́ ọkàn fún ìbálòpọ̀ mọ́ ènìyàn ni, ìfẹ́ ọkàn yẹn sì máa ń lágbára. Ìfẹ́ ọkàn yìí ń kópa tó pọ̀ nínú àwọn ohun tí a ń rò lọ́kàn, bẹ́ẹ̀ ìṣekúṣe rèé, tòun tàwọn ìrònú tí kò sí níbàámu pẹ̀lú àwọn èrò Jèhófà ni wọ́n jọ ń rìn. (Jákọ́bù 1:14, 15) Fún àpẹẹrẹ, níbàámu pẹ̀lú ìwádìí àìpẹ́ yìí kan tó wà nínú ìwé ìròyìn British Medical Journal, ọ̀pọ̀ àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ló jẹ́ pé wọ́n kàn fẹ́ tọ́ ìbálòpọ̀ wò ni láti mọ bó ṣe máa ń rí. Àwọn kan sì gbà gbọ́ pé, o fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ojúgbà àwọn ló ń ní ìbálòpọ̀ déédéé, nítorí náà àwọn náà ò fẹ́ wà ní ipò wúńdíá mọ́. Ohun tí àwọn kan sì tún sọ ni pé, bí ara àwọn ṣe dìde lára ò bá gbà á mọ́, tàbí pé “ọtí ló ń pa àwọn nígbà yẹn” táwọn ò fi mọ nǹkan táwọn ń ṣe mọ́. Táa bá fẹ́ láti máa múnú Ọlọ́run dùn, ìrònú tiwa gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí. Irú ìrònú wo ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní híhùwà tó mọ́?
Ní Ìpinnu Tó Lágbára
4. Láti máa bá híhùwà mímọ́ nìṣó, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
4 Láti máa bá híhùwà mímọ́ nìṣó, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ̀ pé gbígbé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀, tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí wà níbàámu pẹ̀lú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé rẹ̀ sí àwọn Kristẹni ní Róòmù pé kí wọ́n ‘ṣàwárí fúnra wọn, ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.’ (Róòmù 12:2) Àmọ́ o, gbígbà pé híhùwà mímọ́ jẹ́ ohun tó tọ́ tó sì yẹ ní nínú ju wíwulẹ̀ mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dá ìṣekúṣe lẹ́bi lọ. Ó tún kan lílóye àwọn ìdí tí ó fi dá a lẹ́bi àti bí a ṣe ń jàǹfààní látinú yíyàgò fún un. A gbé díẹ̀ nínú àwọn ìdí wọ̀nyí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí.
5. Ìdí pàtàkì wo làwọn Kristẹni fi fẹ́ máa bá a nìṣó ní híhùwà mímọ́?
5 Ká sòótọ́, àwọn ìdí tó lágbára jù lọ tó ń mú kí àwa Kristẹni yẹra fún ìṣekúṣe wá látinú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ó mọ ohun tó dára jù lọ fún wa. Fífẹ́ táa fẹ́ràn rẹ̀ á ràn wá lọ́wọ́ láti kórìíra nǹkan tó burú. (Sáàmù 97:10) Ọlọ́run ni Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17) Ó fẹ́ràn wa. Nípa ṣíṣègbọràn sí i, a ń fi hàn pé a fẹ́ràn rẹ̀ àti pé a mọrírì gbogbo ohun tó ti ṣe fún wa. (1 Jòhánù 5:3) A ò ní fẹ́ láti já Jèhófà kulẹ̀ láé tàbí ká ṣe ohun tó máa dùn ún nípa rírú àwọn òfin òdodo rẹ̀. (Sáàmù 78:41) A kò fẹ́ hùwà lọ́nà tó lè mú káwọn èèyàn sọ́rọ̀ èébú sí ọ̀nà ìjọsìn rẹ̀ tó jẹ́ mímọ́ àti òdodo. (Títù 2:5; 2 Pétérù 2:2) Nípa bíbá a nìṣó ní híhùwà mímọ́, a ń múnú Ẹni Gíga Jù Lọ náà dùn.—Òwe 27:11.
6. Báwo ni jíjẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mọ̀ nípa àwọn ìlànà ìwà rere wa ṣe ń ṣèrànwọ́?
6 Táa bá ti pinnu láti máa bá a lọ ní híhùwà tó mọ́, jíjẹ́ káwọn ẹlòmíràn mọ̀ nípa ìpinnu yẹn tún jẹ́ ààbò kan. Jẹ́ kó di mímọ̀ fáwọn èèyàn pé ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ni ọ́, àti pé ìpinnu rẹ ni láti máa bá a lọ ní títẹ̀lé àwọn ìlànà rẹ̀ gíga. Ìwàláàyè rẹ ló jẹ́ o, ara rẹ ni, ohun tóo sì ti yàn láti ṣe tún ni pẹ̀lú. Kí ló wà nínú ewu? Àjọṣe oníyebíye tóo ní pẹ̀lú Bàbá rẹ ọ̀run ni. Nítorí náà, jẹ́ kó di mímọ̀ kedere pé ìwà mímọ́ rẹ kò ṣeé fi bani dúnàádúrà. Jẹ́ kó máa wú ọ lórí pé o ń ṣojú fún Ọlọ́run nípa gbígbé àwọn ìlànà rẹ̀ lárugẹ. (Sáàmù 64:10) Má ṣe jẹ́ kó tì ọ́ lójú láti jíròrò ohun tóo gbà gbọ́ nípa ìwà rere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Lílahùn lè túbọ̀ fún ọ lókun, ó lè dáàbò bò ọ́, ó sì tún lè sún àwọn mìíràn láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ.—1 Tímótì 4:12.
7. Báwo lá ṣe lè máa bá a lọ nínú ìpinnu wa láti máa hùwà mímọ́?
7 Lẹ́yìn táa ti pinnu láti máa bá híhùwà mímọ́ nìṣó, táa sì ti jẹ́ kí ìpinnu wa di mímọ̀, a gbọ́dọ̀ gbégbèésẹ̀ táa ó fi lè rọ̀ mọ́ ìpinnu wa. Ọ̀nà kan táa lè gbà ṣe èyí ni nípa ṣíṣọ́ra nígbà táa bá ń yan ọ̀rẹ́. Bíbélì sọ pé, “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” Àwọn tó ń hu irú ìwà rere tí ò ń hù ni kóo máa bá rìn; wọ́n á fún ẹ lókun. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí tún sọ pé: “Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Bó bá ṣe lè ṣeé ṣe fún ẹ tó, yẹra fáwọn tó lè sọ́ ìpinnu rẹ di ahẹrẹpẹ.—1 Kọ́ríńtì 15:33.
8. (a) Èé ṣe tí a fi gbọ́dọ̀ fi àwọn ohun tó dára kún èrò inú wa? (b) Kí la gbọ́dọ̀ yẹra fún?
8 Síwájú sí i, àwọn nǹkan tó jẹ́ òótọ́, ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, tó jẹ́ òdodo, tó jẹ́ mímọ́ níwà, tó dára ní fífẹ́, táa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, tó jẹ́ ti ìwà funfun, tó sì yẹ fún ìyìn la gbọ́dọ̀ fi máa bọ́ èrò inú wa. (Fílípì 4:8) À ń ṣe èyí nípa ṣíṣe àṣàyàn àwọn ohun tí a ń wò tí a sì ń kà àti àwọn orin tí a ń tẹ́tí sí. Téèyàn bá sọ pé kò sí láburú kankan tí ìwé tó ń sọ nípa ìṣekúṣe ń ṣe fúnni bí ìgbà tí onítọ̀hún ń sọ pé kò sí oore tí ìwé tó ń sọ nípa ìwà rere ń ṣe fúnni ni. Rántí pé ó rọrùn fún ẹ̀dá ènìyàn aláìpé láti tètè jìn sí ọ̀fìn ìṣekúṣe o. Nítorí náà, àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, fídíò àti orin tó ń ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè nínú ẹni yóò mú kí ọkàn ẹni máa fà sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àwọn wọ̀nyí ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ sì lè múni dẹ́ṣẹ̀. Láti lè máa bá a lọ ní híhùwà mímọ́, a gbọ́dọ̀ fi ọgbọ́n Ọlọ́run kún èrò inú wa.—Jákọ́bù 3:17.
Àwọn Ìgbésẹ̀ Tó Ń Yọrí sí Ìṣekúṣe
9-11. Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ti ṣàlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, àwọn ìgbésẹ̀ wo ló ti ọ̀dọ́kùnrin kan ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ lọ sínú ìṣekúṣe?
9 Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìgbésẹ̀ kan wà táa mọ̀ pé ó máa ń yọrí sí ìṣekúṣe. Béèyàn ṣe ń gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan ìgbésẹ̀ yìí, bẹ́ẹ̀ ni yóò túbọ̀ máa ṣòro láti padà sẹ́yìn. Ṣàkíyèsí bí a ṣe ṣàpèjúwe èyí nínú Òwe 7:6-23. Sólómọ́nì kíyè sí ‘ọ̀dọ́kùnrin kan tí ọkàn-àyà kù fún,’ tàbí tí kò ní èrò ọkàn tó dáa. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà “ń kọjá lọ ní ojú pópó nítòsí igun ọ̀nà rẹ̀ [igun ọ̀nà aṣẹ́wó kan], ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀ ni ó sì gbà lọ, ní wíríwírí ọjọ́, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́.” Àṣìṣe rẹ̀ àkọ́kọ́ nìyẹn o. Ní wíríwírí ọjọ́, “ọkàn àyà” rẹ̀ ò darí ẹ̀ gba òpópó mìíràn, àfi ibi tó mọ̀ pé òun tí lè rí aṣẹ́wó kan.
10 Lẹ́yìn náà, a tún rí i kà pé: “Sì wò ó! obìnrin kan ń bẹ tí ó fẹ́ pàdé rẹ̀, nínú ẹ̀wù kárùwà àti àlùmọ̀kọ́rọ́yí ọkàn-àyà.” Ó rí obìnrin yẹn wàyí! Ó ṣì lè yíjú padà kó sì kọrí sílé o, àmọ́ eléyìí ti túbọ̀ wá nira ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, nígbà tó kúkú jẹ́ pé èrò òun náà kò mọ́. Ni obìnrin náà bá rá a mú, ó sì fẹnu kò ó lẹ́nu. Bí ìyẹn sì ṣe fẹnu kò ó lẹ́nu tán, lòun náà wá tẹ́tí sí àrọwà ẹlẹ̀tàn tí obìnrin náà ń pa pé: “Àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ já lé mi léjìká. Òní ni mo san àwọn ẹ̀jẹ́ mi.” Àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ ní ẹran, ìyẹ̀fun, òróró, àti wáìnì nínú. (Léfítíkù 19:5, 6; 22:21; Númérì 15:8-10) Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni obìnrin yìí ń dọ́gbọ́n sọ pé òun kò jìnnà sí ohun tẹ̀mí o, lẹ́sẹ̀ kan náà, ó sì tún lè máa jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ohun dídára láti jẹ àti láti mu wà nílé òun. Ó rọ̀ ọ́ pé: “Wá, jẹ́ kí a mu ìfẹ́ ní àmuyó títí di òwúrọ̀; jẹ́ kí a fi àwọn ìfihàn ìfẹ́ gbádùn ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.”
11 Kò ṣòro láti sọ ohun tó máa tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. “Ó fi dídùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in ètè rẹ̀ sún un dẹ́ṣẹ̀.” Ni òun náà bá ń tẹ̀ lé e gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sílé “bí akọ màlúù tí ń bọ̀ àní fún ìfikúpa” àti “gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ti ń ṣe kánkán sínú pańpẹ́.” Sólómọ́nì wá fi àwọn ọ̀rọ̀ amúnironú yìí kún un pé: “Kò sì mọ̀ pé ó wé mọ́ ọkàn òun gan-an.” Ohun tó kan ẹ̀mí, tàbí ìwàláàyè rẹ̀ ni, nítorí pé “Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Hébérù 13:4) Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ńlá mà lèyí jẹ́ o fún tọkùnrin tobìnrin wa! Àní, a gbọ́dọ̀ yàgò fún gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ pàápàá, ní ipa ọ̀nà kan tí yóò yọrí sí rírí ìbínú Ọlọ́run.
12. (a) Kí ni gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “ọkàn-àyà kù fún” túmọ̀ sí? (b) Báwo lèèyàn ṣe lè dúró láìyẹhùn lórí ọ̀ràn ìwà rere?
12 Ṣàkíyèsí pé “ọkàn-àyà kù fún” ọ̀dọ́kùnrin inú ìtàn yìí. Gbólóhùn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èrò rẹ̀, ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ìfẹ́ni rẹ̀, ìmọ̀lára rẹ̀, àti àwọn góńgó rẹ̀ nínú ìgbésí ayé kò sí níbàámu pẹ̀lú ohun tí Ọlọ́run fọwọ́ sí. Ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ rẹ̀ yọrí sí àwọn àbájáde bíburú jáì. Ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tó le koko yìí, ó gba ìsapá kéèyàn tó lè dúró láìyẹhùn lórí ọ̀ràn ìwà rere. (2 Tímótì 3:1) Ọlọ́run ṣe àwọn ìpèsè láti ràn wá lọ́wọ́. Ó pèsè àwọn ìpàdé ìjọ Kristẹni láti fún wa níṣìírí lójú ọ̀nà tó tọ́ àti láti mú wa pàdé àwọn mìíràn tí àwọn náà ní irú góńgó kan náà bíi tiwa. (Hébérù 10:24, 25) A ní àwọn alàgbà ìjọ tí wọ́n ń bojú tó wa tí wọ́n sì ń kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà òdodo. (Éfésù 4:11, 12) A ní Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, láti darí wa àti láti tọ́ wa sọ́nà. (2 Tímótì 3:16) Gbogbo ìgbà la sì ní àǹfààní láti gbàdúrà fún ẹ̀mí Ọlọ́run láti ràn wá lọ́wọ́.—Mátíù 26:41.
Fífi Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì Ṣe Àríkọ́gbọ́n
13, 14. Báwo ni Dáfídì Ọba ṣe lọ dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo?
13 Àmọ́ o, ó báni nínú jẹ́ pé, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n tayọ pàápàá ti lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe. Ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì Ọba, ẹni tó ti fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. Kò sí iyèméjì pé ó fẹ́ràn Ọlọ́run gidigidi. Síbẹ̀, ó jìn sí ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀. Gẹ́gẹ́ bó ti rí pẹ̀lú ọ̀dọ́kùnrin tí Sólómọ́nì ṣàpèjúwe rẹ̀, àwọn ìgbésẹ̀ kan wà tó fa ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì tó sì tún wá mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ burú sí i.
14 Dáfídì ti ń dẹni àgbà lásìkò yẹn, o ṣeé ṣe kí ọjọ́ orí rẹ̀ ti lé díẹ̀ ní àádọ́ta ọdún. Láti orí òrùlé ilé rẹ̀, ó rí Bátí-ṣébà obìnrin arẹwà tó ń wẹ̀. Ó wádìí nípa rẹ̀ ó sì mọ ẹni tó jẹ́. Ó rí i pé Ùráyà tó jẹ́ ọkọ rẹ̀ wà níbi ìgbóguntì ní Rábà, ọ̀kan lára ìlú àwọn ará Ámónì. Dáfídì ní kí wọ́n mú un wá sí ààfin òun, ó sì bá a lò pọ̀. Kò pẹ́ kò jìnnà, wàhálà ṣẹlẹ̀—obìnrin náà rí i pé òun ti lóyún fún Dáfídì. Dáfídì pàṣẹ pé kí Ùráyà padà wálé látojú ogun, pẹ̀lú ìrètí pé yóò lọ sùn ti ìyàwó rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yẹn, á wá dà bí ẹni pé Ùráyà ni bàbá ọmọ tí Bátí-ṣébà bá bí. Ṣùgbọ́n Ùráyà kò mà lọ sí ilé rẹ̀ o. Bí Dáfídì ti ń wá ọ̀nà lójú méjèèjì láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó ní kí Ùráyà padà sí Rábà, ó sì fi lẹ́tà kan rán an sí ẹni tó jẹ́ olórí ogun náà, pé kó fi Ùráyà síbi tí ogun á ti pa á. Bí Ùráyà ṣe kú nìyẹn o, ni Dáfídì bá fẹ́ aya rẹ̀ opó sílé kí ọ̀rọ̀ oyún náà tó di mímọ̀ ní ìlú.—2 Sámúẹ́lì 11:1-27.
15. (a) Báwo ni àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì ṣe tú? (b) Kí ni ìṣarasíhùwà Dáfídì sí ìbáwí tí Nátánì fọgbọ́n fún un?
15 Lójú Dáfídì, ète tó pa láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ ti ṣiṣẹ́. Ọ̀pọ̀ oṣù kọjá. Wọ́n bí ọmọ ọ̀hún—ọkùnrin ni. Tó bá jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló wà lọ́kàn Dáfídì nígbà tó kọ Sáàmù kejìlélọ́gbọ̀n, a jẹ́ pé ó dájú pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá a jà. (Sáàmù 32:3-5) Àmọ́ o, ẹ̀ṣẹ̀ yẹn kò pa mọ́ lójú Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ohun tí Dáfídì ṣe jẹ́ ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.” (2 Sámúẹ́lì 11:27) Jèhófà rán wòlíì Nátánì sí i, ẹni tó fi ọgbọ́n gbé ohun tí Dáfídì ṣe kò ó lójú. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Dáfídì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Jèhófà. Ojúlówó ìrònúpìwàdà rẹ̀ mú kó dọ̀rẹ́ Ọlọ́run padà. (2 Sámúẹ́lì 12:1-13) Dáfídì kò fi ìbáwí náà ṣèbínú rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi irú ìṣarasíhùwà tó wà ní Sáàmù 141:5 hàn, tó sọ pé: “Bí olódodo bá gbá mi, yóò jẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́; bí ó bá sì fi ìbáwí tọ́ mi sọ́nà, yóò jẹ́ òróró ní orí, èyí tí orí mi kì yóò fẹ́ láti kọ̀.”
16. Ìkìlọ̀ àti ìmọ̀ràn wo ni Sólómọ́nì fúnni nípa ẹ̀ṣẹ̀?
16 Sólómọ́nì, tó jẹ́ ọmọ tí Dáfídì àti Bátí-ṣébà bí ṣìkejì, lè ti ronú jinlẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ bíbaninínújẹ́ tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé bàbá rẹ̀ yìí. Ó kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.” (Òwe 28:13) Bí a bá ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo, ká ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn onímìísí yìí ni o, èyí tó jẹ́ ìkìlọ̀ tó sì tún jẹ́ ọ̀rọ̀ àmọ̀ràn pẹ̀lú. A gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ fún Jèhófà ká sì tọ àwọn alàgbà ìjọ lọ fún ìrànlọ́wọ́. Ọ̀kan lára ẹrù iṣẹ́ pàtàkì tí àwọn alàgbà ní ni láti ran àwọn tó bá hu ìwà àìtọ́ lọ́wọ́ láti padà bọ̀ sípò.—Jákọ́bù 5:14, 15.
Fífara Da Àwọn Àbájáde Ẹ̀ṣẹ̀
17. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, àwọn nǹkan wo ni kò ní dènà rẹ̀ kó má ṣẹlẹ̀ sí wa?
17 Jèhófà dárí ji Dáfídì. Èé ṣe? Nítorí pé Dáfídì jẹ́ ẹni tó pa ìwà títọ́ mọ́, nítorí pé ó ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, àti pé ó fi ojúlówó ìrònúpìwàdà hàn. Síbẹ̀síbẹ̀ ńkọ́, Dáfídì kò bọ́ lọ́wọ́ àwọn àrélù tí èyí padà wá fà bá a lẹ́yìn náà. (2 Sámúẹ́lì 12:9-14) Bákan náà lọ̀ràn rí lónìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kì í mú ibi bá àwọn tó bá ronú pìwà dà, kì í dènà àwọn ohun tí ìwà búburú tí wọn hù bá fà bá wọn. (Gálátíà 6:7) Ìkọ̀sílẹ̀, oyún tí a kò fẹ́, àrùn tí ìbálòpọ̀ ń fà, àti ìgbọ́kànlé àti ọ̀wọ̀ tí kì í sí mọ́ lè wà lára àwọn nǹkan tí ìṣekúṣe ń yọrí sí.
18. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe sọ pé kí ìjọ Kọ́ríńtì bójú tó ẹjọ́ kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣekúṣe tó burú jáì? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ àti àánú hàn sáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀?
18 Tí àwa bí ẹnì kan bá ti ṣe àṣemáṣe tó burú gan-an, ó rọrùn láti bọkàn jẹ́ táa bá ń jìyà àbájáde àṣìṣe tí a ṣe yẹn. Síbẹ̀síbẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà, ká sì bá Ọlọ́run rẹ́ padà. Ní ọ̀rúndún kìíní, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n yọ ọkùnrin kan tó ń ṣàgbèrè nípa bíba ìbátan rẹ̀ lò pọ̀. (1 Kọ́ríńtì 5:1, 13) Lẹ́yìn tí ọkùnrin náà ti fi tinútinú ronú pìwà dà, Pọ́ọ̀lù fún ìjọ náà ní ìtọ́ni pé: “Ẹ fi inú rere dárí jì í, kí ẹ sì tù ú nínú [kí ẹ sì] fìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín fún un múlẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 2:5-8) Nínú ìmọ̀ràn tí a mí sí yìí, a rí ìfẹ́ àti àánú tí Jèhófà ní fáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà. Inú àwọn áńgẹ́lì máa ń dùn ní ọ̀run nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà.—Lúùkù 15:10.
19. Àwọn àǹfààní wo ló lè jẹ yọ látinú ìbànújẹ́ gidi tí àṣemáṣe tí a ṣe kó bá wa?
19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣemáṣe kan tí a ṣe lè kó ìbànújẹ́ bá wa, bí a ṣe kábàámọ̀ rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti ‘ṣọ́ra wa ká má ṣe tún yíjú sí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ mọ́.’ (Jóòbù 36:21) Láìsí àní-àní, ìyà ẹ̀ṣẹ̀ kíkorò tí a jẹ yẹ kó mú wa yàgò fún pípadà ṣe irú àṣìṣe kan náà. Ní àfikún sí i, Dáfídì lo èèmọ̀ tójú ẹ rí látinú ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ láti fún àwọn ẹlòmíràn nímọ̀ràn. Ó sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò kọ́ àwọn olùrélànàkọjá ní àwọn ọ̀nà rẹ, kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá lè yí padà tààràtà sọ́dọ̀ rẹ.”—Sáàmù 51:13.
Ayọ̀ Ń Wá Látinú Sísin Jèhófà
20. Àwọn àǹfààní wo ló ń tinú ṣíṣègbọràn sí àwọn àṣẹ òdodo Ọlọ́run wá?
20 Jésù wí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!” (Lúùkù 11:28) Ṣíṣègbọràn sí àwọn àṣẹ òdodo Ọlọ́run ń mú ayọ̀ wá nísinsìnyí àti títí ayé tí kò lópin. Táa bá ti ń hùwà mímọ́ tẹ́lẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ nípa lílo gbogbo àǹfààní tí Jèhófà ti pèsè láti fi ràn wá lọ́wọ́. Tó bá sì jẹ́ pé a ti jìn sí ọ̀fìn ìṣekúṣe ni, ẹ jẹ́ ká ṣọkàn gírí nítorí mímọ̀ táa mọ̀ pé Jèhófà ṣe tán láti dárí ji àwọn tó fi òótọ́ inú ronú pìwà dà, ẹ jẹ́ ká sì pinnu pé láéláé, a ò tún ní tún ẹ̀ṣẹ̀ yẹn dá mọ́.—Aísáyà 55:7.
21. Fífi ìṣílétí àpọ́sítélì Pétérù wo sílò ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá híhùwà mímọ́ nìṣó?
21 Láìpẹ́, ayé aláìṣòdodo yìí yóò kọjá lọ, àti gbogbo ìwàkiwà àti ìṣekúṣe rẹ̀. Nípa bíbá a lọ ní híhùwà mímọ́, a ó jàǹfààní nísinsìnyí àti títí ayérayé. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, níwọ̀n bí ẹ ti ń dúró de nǹkan wọ̀nyí, ẹ sa gbogbo ipá yín kí òun lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà. . . . Bí ẹ ti ní ìmọ̀ èyí tẹ́lẹ̀, ẹ ṣọ́ ara yín kí a má bàa mú yín lọ pẹ̀lú wọn nípa ìṣìnà àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà, kí ẹ sì ṣubú kúrò nínú ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin tiyín.”—2 Pétérù 3:14, 17.
Ṣé O Lè Ṣàlàyé?
• Èé ṣe tó fi lè ṣòro láti máa bá híhùwà mímọ́ nìṣó?
• Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìpinnu wa láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere gíga?
• Àwọn ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni a lè rí kọ́ látinú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀dọ́mọkùnrin tí Sólómọ́nì mẹ́nu kàn?
• Kí ni àpẹẹrẹ Dáfídì kọ́ wa nípa ìrònúpìwàdà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ààbò ló jẹ́ fún wa bí a bá jẹ́ káwọn èèyàn mọ ìhà tí a kọ sí ọ̀ràn ìwà rere
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Nítorí pé Dáfídì ronú pìwà dà tinútinú, Jèhófà dárí jì í