Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìwà Mímọ́
Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìwà Mímọ́
“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.”—AÍSÁYÀ 48:17.
1, 2. (a) Irú ojú wo làwọn èèyàn ní gbogbo gbòò fi ń wo ọ̀ràn ìbálòpọ̀? (b) Ojú wo làwọn Kristẹni fi ń wo ọ̀ràn ìbálòpọ̀?
LÓNÌÍ, lápá ibi tó pọ̀ jù láyé, kóńkó jabele, kálukú ló ń ṣe tiẹ̀ làwọn èèyàn ń fi ọ̀ràn híhùwà tó mọ́ ṣe. Ńṣe làwọn èèyàn ka ìbálòpọ̀ sí ọ̀nà tí ẹ̀dá lè gbà fi ìfẹ́ni hàn, èyí téèyàn lè ṣe ní ìgbàkígbà tó bá sáà ti wù ú, wọn kò wò ó bí nǹkan tó jẹ́ pé inú ìgbéyàwó nìkan ló gbọ́dọ̀ mọ. Wọ́n rò pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn pinnu fúnra rẹ̀ nípa bó ṣe máa hùwà, tí kò bá sáà ti pa ẹnikẹ́ni lára. Lójú wọn, kò yẹ ká máa ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni lórí ọ̀ràn ìwà híhù, àgàgà tó bá kan ti ìbálòpọ̀.
2 Àmọ́ o, ojú táwọn tó ti mọ Jèhófà fi ń wò ó yàtọ̀. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà Ìwé Mímọ́ nítorí pé wọ́n fẹ́ràn Jèhófà wọ́n sì fẹ́ láti múnú rẹ̀ dùn. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ràn àwọn, ó sì ń fún àwọn ní ìtọ́ni tó máa ṣe àwọn níre, ìtọ́ni tó dájú pé ó máa ṣe wọ́n láǹfààní tí yóò sì mú wọn láyọ̀. (Aísáyà 48:17) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ni Orísun ìwàláàyè, ó bọ́gbọ́n mu pé òun ló yẹ kí wọ́n máa wò fún ìtọ́sọ́nà ní ti bí wọn yóò ṣe lo ara wọn, pàápàá lórí ọ̀ràn to wé mọ́ títàtaré ìwàláàyè.
Ẹ̀bùn Kan Látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá Onífẹ̀ẹ́
3. Kí ni wọ́n fi kọ́ ọ̀pọ̀ nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù nípa ìbálòpọ̀, báwo sì ni ìyẹn ṣe rí pẹ̀lú ohun tí Bíbélì fi kọ́ni?
3 Òdìkejì ohun tí àwọn èèyàn ayé dì mú làwọn kan nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù fi ń kọ́ni, wọ́n ní nǹkan ìtìjú ni ìbálòpọ̀, pé nǹkan ẹ̀ṣẹ̀ ni, àti pé “ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́” ní ọgbà Édẹ́nì ni mímú tí Éfà mú kí Ádámù bá òun lò pọ̀. Irú ojú ìwòye bẹ́ẹ̀ kò sí níbàámu pẹ̀lú nǹkan tí Ìwé Mímọ́ tí a mí sí sọ. Àkọsílẹ̀ Bíbélì tọ́ka sí tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ bí “ọkùnrin náà àti aya rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:25) Ọlọ́run sọ fún wọn pé kí wọ́n máa bímọ, ó ní: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Kò ní bọ́gbọ́n mú fún Ọlọ́run láti pàṣẹ pé kí Ádámù àti Éfà máa bímọ, kó sì tún wá jẹ wọ́n níyà fún mímú ìtọ́ni yẹn ṣẹ.—Sáàmù 19:8.
4. Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fún ènìyàn lágbára ìbálòpọ̀?
4 Nínú àṣẹ tí Ọlọ́run fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ yẹn, tó sì tún tún sọ fún Nóà àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀, a rí ète pàtàkì tí ìbálòpọ̀ ní: ìyẹn ni láti bímọ. (Jẹ́nẹ́sísì 9:1) Àmọ́ ṣá o, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé kò pọn dandan kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi ìbálòpọ̀ mọ sórí kìkì àtibímọ. Irú àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ tún lè kúnjú àìní nípa tara àti ti ìmí ẹ̀dùn, ó sì tún lè jẹ́ orísun ìgbádùn fún tọkọtaya. Ó jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n lè gbà fí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ hàn síra wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 26:8, 9; Òwe 5:18, 19; 1 Kọ́ríńtì 7:3-5.
Òté Tí Ọlọ́run Fi Lé E
5. Kí ni àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ nínú ọ̀ràn ìbálòpọ̀ láàárín ẹ̀dá ènìyàn?
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìbálòpọ̀ jẹ́, a kò gbọ́dọ̀ lo ẹ̀bùn náà láìníjàánu. Kódà, ìlànà yìí tún kan inú ètò ìgbéyàwó. (Éfésù 5:28-30; 1 Pétérù 3:1, 7) Ìbálòpọ̀ ni a kà léèwọ̀ tí kì í bá ti í ṣe nínú ìgbéyàwó. Bíbélì kò fọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ lórí ọ̀ràn yìí. Ọlọ́run sọ ọ́ nínú Òfin tí ó fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.” (Ẹ́kísódù 20:14) Lẹ́yìn náà, Jésù ka “àgbèrè àti “panṣágà” mọ́ “àwọn èrò tí ń ṣeni léṣe,” èyí tó ń wá látinú ọkàn-àyà ènìyàn tó sì ń sọni di ẹlẹ́gbin. (Máàkù 7:21, 22) A mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti ṣí àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì létí pé: “Ẹ máa sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Bákan náà, nínú lẹ́tà rẹ̀ sáwọn Hébérù, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.”—Hébérù 13:4.
6. Nínú Bíbélì, àwọn ohun wo ni ọ̀rọ̀ náà, “àgbèrè” dúró fún?
6 Kí ni ọ̀rọ̀ náà, “àgbèrè” túmọ̀ sí? Ó wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà por·neiʹa, èyí táa máa ń lò nígbà míì fún ìbálòpọ̀ láàárín àwọn èèyàn tí kò tíì ṣègbéyàwó. (1 Kọ́ríńtì 6:9) Níbòmíràn, irú bíi ní Mátíù orí karùn-ún ẹsẹ kejìlélọ́gbọ̀n àti ní Mátíù orí kọkàndínlógún ẹsẹ kẹsàn-án, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí túbọ̀ gbòòrò sí i, ó tún tọ́ka sí panṣágà, ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan àti bíbá ẹranko lò pọ̀ pẹ̀lú. Àwọn ìṣekúṣe yòókù láàárín àwọn tí kò ṣègbéyàwó, àwọn bí ìbálòpọ̀ láti ẹnu tàbí láti ihò ìdí, àti ọ̀nà mìíràn téèyàn lè gbà lo ẹ̀yà ìbímọ ọmọnìkejì rẹ̀ fún ìbálòpọ̀ la tún lè pè ní por·neiʹa. Gbogbo irú àwọn àṣà wọ̀nyí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dá lẹ́bi—bóyá ní tààràtà o tàbí lọ́nà míì.—Léfítíkù 20:10, 13, 15, 16; Róòmù 1:24, 26, 27, 32. a
Jíjàǹfààní Nínú Àwọn Òfin Ìwà Rere Tí Ọlọ́run Fúnni
7. Báwo la ṣe ń jàǹfààní bí a bá jẹ́ oníwà mímọ́?
7 Ó lè máà rọrùn fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé láti pa àṣẹ Jèhófà nípa ìbálòpọ̀ mọ́. Maimonides, Júù olókìkí kan ní ọ̀rúndún kejìlá, tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí, kọ̀wé pé: “Kò tún sí òfin mìíràn tó ṣòro láti pa mọ́ nínú gbogbo Torah [Òfin Mósè] bí èyí tó ka àwọn ìdàpọ̀ kan àti gbogbo ìṣekúṣe léèwọ̀.” Síbẹ̀, à ń jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ bí a bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. (Aísáyà 48:18) Fún àpẹẹrẹ, ṣíṣègbọràn nínú ọ̀ràn yìí ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń tàtaré rẹ̀, èyí táwọn kan lára wọn ò gbóògùn tí wọ́n sì lè pani. b A bọ́ lọ́wọ́ oyún ẹ̀sín. Fífi ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún wa sílò tún ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ ká túbọ̀ jẹ́ ẹni iyì, káwọn mìíràn sì tún bọ̀wọ̀ fún wa, títí kan àwọn ẹbí wa, àwọn ojúgbà wa, àwọn ọmọ wa, àti àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa. Bẹ́ẹ̀ ló sì tún ń jẹ́ ká fojú tó tọ́ wo ìbálòpọ̀, èyí tí yóò fi kún ayọ̀ tó máa ń wà nínú ìgbéyàwó. Obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni kọ̀wé pé: “Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ààbò tó tíì dára jù lọ. Mo ń dúró de ìgbà tí màá ṣègbéyàwó, tó bá dìgbà yẹn, ẹnu mi á gbà á láti sọ fún ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni tí mo fẹ́ pé ń kì í ṣe oníṣekúṣe.”
8. Àwọn ọ̀nà wo ni ìwà mímọ́ wa lè gbà gbé ìjọsìn mímọ́ wa lárugẹ?
8 Táa bá ń bá a lọ láti máa hùwà tó mọ́, á ṣeé ṣe fún wa láti borí àwọn àṣìlóye tí àwọn èèyàn ní nípa ìjọsìn tòótọ́, a ó sì tún mú kí àwọn èèyàn fà mọ́ Ọlọ́run tí a ń jọ́sìn. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.” (1 Pétérù 2:12) Àní, bí àwọn tí kò sin Jèhófà ò bá tiẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìwà wa tó mọ́, tàbí kí wọ́n fara mọ́ ọn, kí ó dá wa lójú pé Bàbá wa ọ̀run rí ìsapá wa, ó fọwọ́ sí i, ó sì tún ń yọ̀ pẹ̀lú fún akitiyan tí à ń ṣe láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀.—Òwe 27:11; Hébérù 4:13.
9. Èé ṣe tó fi yẹ ká fọkàn tán ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, àní bí a kò tilẹ̀ lóye àwọn ìdí rẹ̀ ní kíkún? Mú àpẹẹrẹ wá.
9 Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kan fífọkàn tán an pé ó mọ ohun tó dára jù lọ fún wa, àní bí a ò tiẹ̀ mọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ gbogbo ìdí tó fi tọ́ wa sí ọ̀nà kan. Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò nínú Òfin Mósè. Ìlànà kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ibùdó àwọn ọmọ ogun sọ pé kí wọ́n máa bo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀ lẹ́yìn ibùdó. (Diutarónómì 23:13, 14) Bóyá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa ṣe kàyéfì nípa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀; àwọn kan tiẹ̀ lè ti rò pé ìyẹn ò pọn dandan. Àmọ́ o, látìgbà náà wá, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn ti wá rí i pé ńṣe lòfin yìí ń ṣèrànwọ́ láti mú kí àwọn orísun omi wọn bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀gbin, ó sì pèsè ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn àìsàn tí àwọn kòkòrò máa ń gbé káàkiri. Bákan náà, fún àwọn ìdí tó jẹ́ tẹ̀mí, tẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ti ìmí ẹ̀dùn, tara, àti ti ìrònú òun ìhùwà, ni Ọlọ́run fi fi ìbálòpọ̀ mọ sórí ibùsùn ìgbéyàwó nìkan. Níbi táa dé yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ látinú Bíbélì yẹ̀ wò nípa àwọn tí kò jáwọ́ nínú híhu ìwà tó mọ́.
A Bù Kún Jósẹ́fù fún Ìwà Mímọ́ Rẹ̀
10. Ta ló fi ìṣekúṣe lọ Jósẹ́fù, báwo ló sì ṣe fèsì?
10 Ó ṣeé ṣe kóo mọ̀ nípa àpẹẹrẹ Jósẹ́fù tó jẹ́ ọmọ Jékọ́bù nínú Bíbélì. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni, nígbà tó rí i pé òun di ẹrú fún Pọ́tífárì, olórí ẹ̀ṣọ́ Fáráò ti Íjíbítì. Jèhófà bù kún Jósẹ́fù, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi yàn án ṣe olórí gbogbo ilé Pọ́tífárì. Nígbà tí Jósẹ́fù fi máa di ẹni tó lé lọ́mọ ogún ọdún, ó ti di “ẹlẹ́wà ní wíwò àti ẹlẹ́wà ní ìrísí.” Ó bẹ̀rẹ̀ sí wu ìyàwó Pọ́tífárì, ẹni tó wọ́nà láti fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́. Jósẹ́fù sọ ibi tí òun dúró sí nínú ọ̀ràn yìí fún un, ní ṣíṣàlàyé pé gbígbà láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ̀gá òun nìkan, ó tún jẹ́ ‘ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọ́run.’ Kí ló mú Jósẹ́fù ronú lọ́nà yẹn?—Jẹ́nẹ́sísì 39:1-9.
11, 12. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí òfin Ọlọ́run tí a kọ sílẹ̀, èyí tó ka àgbèrè àti panṣágà léèwọ̀, kí ló gbọ́dọ̀ ti mú Jósẹ́fù ronú lọ́nà yẹn?
11 Ẹ̀rí fi hàn pé, kì í ṣe ìbẹ̀rù pé kí àwọn èèyàn máà rí òun ló mú Jósẹ́fù ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Ibi tí ìdílé Jósẹ́fù ń gbé jìnnà gan-an síbẹ̀, èrò bàbá rẹ̀ sì ni pé ó ti kú. Bí Jósẹ́fù bá tiẹ̀ ṣe ìṣekúṣe, kò sí bí ìdílé rẹ̀ ṣe lè mọ̀ nípa ẹ̀. Ó sì lè ṣeé ṣe kí irú ẹ̀ṣẹ̀ yẹn má hàn sí Pọ́tífárì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ọkùnrin, nígbà tó kúkú jẹ́ pé àwọn àsìkò kan wà tí wọn kì í sí nílé. (Jẹ́nẹ́sísì 39:11) Síbẹ̀, Jósẹ́fù mọ̀ pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò ṣeé fi pamọ́ fún Ọlọ́run.
12 Ó ní láti jẹ́ pé Jósẹ́fù ronú lórí ohun tó mọ̀ nípa Jèhófà. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n pé ó mọ ohun tí Jèhófà kéde ní ọgbà Édẹ́nì pé: “Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin yóò ṣe fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Bákan náà, ó jọ pé Jósẹ́fù mọ̀ nípa nǹkan tí Jèhófà sọ fún ọba Filísínì náà tó ṣáà fẹ́ rí i pé òun tan Sárà ìyá ńlá Jósẹ́fù ṣe ìṣekúṣe. Jèhófà sọ fún ọba yẹn pé: “Kíyè sí i, ìwọ fẹ́rẹ̀ẹ́ má sàn ju òkú lọ nítorí obìnrin tí ìwọ mú, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ẹlòmíràn ni ó ni ín gẹ́gẹ́ bí aya rẹ̀. . . . Èmi pẹ̀lú sì ń dá ọ dúró láti má ṣe ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyẹn tí èmi kò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án.” (Jẹ́nẹ́sísì 20:3, 6) Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò tíì pèsè òfin tí a kọ sílẹ̀ lásìkò yẹn, èrò rẹ̀ nípa ìgbéyàwó ṣe kedere. Èrò tí Jósẹ́fù ní nípa ìwà rere, àti ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti mú inú Jèhófà dùn, mú un láti má ṣe lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe.
13. Kí ló lè jẹ́ ohun tó fà á tí Jósẹ́fù kò fi lè yẹra fún ìyàwó Pọ́tífárì?
13 Àmọ́, ìyàwó Pọ́tífárì kò jáwọ́ o, láti “ọjọ́ dé ọjọ́” ló ń bẹ̀ ẹ́ pé kó sùn ti òun. Kí ló dé tí Jósẹ́fù ò kúkú yẹra fún un? Tóò, ẹrú ni, ó ní àwọn iṣẹ́ tó gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ohun tó lè ṣe láti ṣàtúnṣe ipò rẹ̀. Ẹ̀rí ìwalẹ̀pìtàn fi hàn pé, ọ̀nà táwọn ará Íjíbítì ń gbà kọ́ ilé wọn mú kó di dandan láti gba àárín ilé gangan kọjá kéèyàn tó lè já sí àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí. Nítorí náà, ó lè má ṣeé ṣe rárá fún Jósẹ́fù láti yẹra fún ìyàwó Pọ́tífárì.—Jẹ́nẹ́sísì 39:10.
14. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù lẹ́yìn tó sá kúrò lọ́dọ̀ ìyàwó Pọ́tífárì? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Jósẹ́fù fún ìṣòtítọ́ rẹ̀?
14 Ó wá di ọjọ́ kan tí ó ku àwọn nìkan nínú ilé. Ìyàwó Pọ́tífárì bu Jósẹ́fù so, ó sì rọ̀ ọ́ pé: “Sùn tì mí!” Jósẹ́fù sá. Kíkọ̀ tí Jósẹ́fù kọ̀ dùn ún wọra, ló bá fẹ̀sùn kàn-án pé ó gbìyànjú láti fipá bá òun sùn. Kí ní àbájáde rẹ̀? Ǹjẹ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà san èrè ìwà títọ́ rẹ̀ fún un? Rárá o. Wọ́n ju Jósẹ́fù sẹ́wọ̀n wọ́n sì kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 39:12-20; Sáàmù 105:18) Jèhófà rí ìwà àìṣòdodo yẹn, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ó gbé Jósẹ́fù ga, ó mú kó tinú ẹ̀wọ̀n dèrò ààfin. Ó wá di ẹnì kejì tó lágbára jù lọ ní Íjíbítì, a sì fi aya kan àti àwọn ọmọ jíǹkí rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 41:14, 15, 39-45, 50-52) Síwájú sí i, ìròyìn nípa ìwà títọ́ Jósẹ́fù ni a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500] sẹ́yìn, fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti máa gbé e yẹ̀ wò látìgbà náà wá. Ìbùkún àgbàyanu mà lèyí jẹ́ o fún pípa tó pa àwọn òfin òdodo Ọlọ́run mọ́! Bákan náà lónìí, àwa pẹ̀lú lè máà rí àwọn àǹfààní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tó wà nínú pípa ìwà mímọ́ mọ́, àmọ́ kí ó dá wa lójú pé Jèhófà ń rí wa, yóò sì bù kún wa nígbà tí àkókò bá tó.—2 Kíróníkà 16:9.
‘Májẹ̀mú Tí Jóòbù Bá Ojú Rẹ̀ Dá’
15. Kí ni ‘májẹ̀mú tí Jóòbù bá ojú rẹ̀ dá’?
15 Ẹlòmíràn tó tún pa ìwà títọ́ mọ́ ni Jóòbù. Láàárín àsìkò tí Èṣù kó àdánwò bá Jóòbù, ó tún ìgbésí ayé rẹ̀ gbé yẹ̀ wò dáadáa, ó sì sọ pé òun ṣe tán láti jẹ ìyà tó gbópọn tó bá jẹ́ pé òun ti ré àwọn ìlànà Jèhófà kọjá, irú bíi ṣíṣe ìṣekúṣe. Jóòbù sọ pé: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú. Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá?” (Jóòbù 31:1) Ohun tí Jóòbù sọ yìí túmọ̀ sí pé, nínú ìpinnu rẹ̀ láti pa ìwà títọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run mọ́, ó ti sọ pé láéláé, òun ò jẹ́ wo obìnrin kan pẹ̀lú ète àtibá a ṣèṣekúṣe. Dájúdájú, á máa rí àwọn obìnrin nínú ìgbésí ayé rẹ̀ ojoojúmọ́, ó tiẹ̀ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ pàápàá tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́. Ṣùgbọ́n o, kò jẹ́ tẹjú mọ́ wọn pẹ̀lú ète àtiní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn. Kó tó di pé àdánwò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ó jẹ́ ọkùnrin kan tó lọ́rọ̀ rẹpẹtẹ, “ẹni tí ó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo àwọn Ará Ìlà-Oòrùn.” (Jóòbù 1:3) Bó ti wù kó rí, kò lo agbára ọrọ̀ láti máa fi fa ojú ọ̀pọ̀ obìnrin mọ́ra. Ó ṣe kedere pé, kò tiẹ̀ jẹ́ fi èrò pé òun yóò bá àwọn ọ̀dọ́bìnrin ṣe ìṣekúṣe ṣeré wò.
16. (a) Èé ṣe tí Jóòbù fi jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó? (b) Báwo ni ìwà àwọn ọkùnrin ọjọ́ Málákì ṣe yàtọ̀ pátápátá sí ti Jóòbù, lọ́jọ́ òní náà ńkọ́?
16 Nípa bẹ́ẹ̀, lásìkò tí nǹkan rọ̀ ṣọ̀mù àti nígbà tí nǹkan le koko, kò sígbà tí Jóòbù kò fi ìwà mímọ́ hàn. Jèhófà ṣàkíyèsí èyí ó sì bù kún un jìngbìnnì. (Jóòbù 1:10; 42:12) Àpẹẹrẹ àtàtà mà lèyí jẹ́ o fún àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ti ṣègbéyàwó! Abájọ tí Jèhófà fi fẹ́ràn rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀! Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, ìwà ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí jọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Málákì gan-an ni. Wòlíì yẹn bẹnu àtẹ́ lu bí ọ̀pọ̀ ọkọ ṣe ń já àwọn ìyàwó wọn sílẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà nítorí àtifẹ́ àwọn obìnrin tó tún kéré lọ́jọ́ orí. Ńṣe ni omijé àwọn aya tí wọ́n já jù sílẹ̀ bo pẹpẹ Jèhófà, Ọlọ́run sì bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó “ṣe àdàkàdekè” sí àwọn alábàáṣègbéyàwó wọn.—Málákì 2:13-16.
Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ Obìnrin Kan Tó Ní Ìwà Mímọ́
17. Báwo ni Ṣúlámáítì ṣe dà bí “ọgbà tí a gbégi dínà rẹ̀”?
17 Omidan Ṣúlámáítì ni ẹnì kẹta tóun náà pa ìwà títọ́ mọ́. Ọ̀dọ́ ni ó sì lẹ́wà, tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn kan báyìí nìkan ló nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó tún wu Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ pẹ̀lú. Jálẹ̀ inú ìtàn àtàtà tó wà nínú Orin Sólómọ́nì, Ṣúlámáítì pa ara rẹ̀ mọ́, nípa bẹ́ẹ̀ gbogbo àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀ bọ̀wọ̀ fún un. Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti kọ ìtàn rẹ̀ sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin náà kò gbà láti fẹ́ ẹ. Olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ yẹn náà tún bọ̀wọ̀ fún ìwà mímọ́ rẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó fi ìrònújinlẹ̀ sọ pé Ṣúlámáítì yìí dà bí “ọgbà tí a gbégi dínà rẹ̀.” (Orin Sólómọ́nì 4:12) Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn ọgbà ẹlẹ́wà máa ń ní oríṣiríṣi ewébẹ̀ tó dùn ún wò, àwọn ìtànná olóòórùn dídùn, àti àwọn igi tí ìdúró wọ́n wuni gan-an. Wọ́n sábà máa ń sọgbà tàbí ògiri yí irú àwọn ọgbà bẹ́ẹ̀ ká, kò sì sẹ́ni tó lè wọnú ẹ̀ láìgba ẹnu ọ̀nà rẹ̀ tó wà ní títì wọlé. (Aísáyà 5:5) Gẹ́gẹ́ bí ọgbà tó ní ẹwà àrà ọ̀tọ̀ yẹn, ni ìwà mímọ́ àti fífà tí Ṣúlámáítì fani mọ́ra ṣe rí sí olùṣọ́ àgùntàn náà. Òun jẹ́ ẹni tó pa ara rẹ̀ mọ́ délẹ̀délẹ̀. Kò jẹ́ gbà kí ìfẹ́ òun fà sí ẹlòmíràn àyàfi ọkọ rẹ̀ tó bá fẹ́ lọ́jọ́ iwájú.
18. Kí ni àwọn àkọsílẹ̀ nípa Jósẹ́fù, Jóòbù, àti Ṣúlámáítì rán wa létí rẹ̀?
18 Táa bá ń sọ nípa pípa ìwà mímọ́ mọ́, Ṣúlámáítì yẹn fi àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá lélẹ̀ fún àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni lónìí. Jèhófà rí ìwà mímọ́ ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì náà ó sì mọrírì rẹ̀, ó wá bù kún un bó ṣe bù kún Jósẹ́fù àti Jóòbù. Ìwà títọ́ tí wọ́n hù ni a kọ sílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà wa. Bí a ò tiẹ̀ kọ àwọn ìsapá wa láti pa ìwà títọ́ mọ́ lónìí sínú Bíbélì, Jèhófà ní “Ìwé ìrántí kan” nípa àwọn tó ń gbìyànjú láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé láé pé Jèhófà “ń fiyè sí” bí a ṣe ń fi ìdúróṣinṣin ṣakitiyan láti máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ oníwà mímọ́, ó sì ń láyọ̀.—Málákì 3:16.
19. (a) Ojú wo ló yẹ ká fi máa wo ìwà mímọ́? (b) Kí ni a óò jíròrò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tó tẹ̀ lé e?
19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláìgbàgbọ́ lè máa ṣáátá wa, a ń láyọ̀ bí a ṣe ń ṣègbọràn sí Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́. Ìwà mímọ́ wa kì í ṣẹgbẹ́ ti ẹnikẹ́ni, ìwà bíi ti Ọlọ́run ni. Ohun táa lè fi yangàn ló jẹ́, nǹkan tó sì yẹ ká máa fojú ribiribi wò ni. Bí a bá ń bá a nìṣó ní jíjẹ́ oníwà mímọ́, a ó lè máa yọ̀ nínú ìbùkún Ọlọ́run, ìrètí wa nípa àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú tí kò lópin yóò sì túbọ̀ dájú sí i. Táa bá ní ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kí la lè ṣe gan-an láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ oníwà mímọ́? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tó tẹ̀ lé èyí yóò jíròrò ìbéèrè pàtàkì yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ile-Iṣọ Naa, September 15, 1983, ojú ìwé 29-31.
b Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ipò kan wà nínú èyí tí Kristẹni kan tí kò mọwọ́-mẹsẹ̀ ti kó àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta àtaré rẹ̀ láti ara ẹnì kejì rẹ̀ nínú ìgbéyàwó tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ tí kò tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.
Ṣé O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni Bíbélì fi kọ́ni nípa ìbálòpọ̀?
• Àwọn nǹkan wo ni ọ̀rọ̀ náà, “àgbèrè” dúró fún nínú Bíbélì?
• Báwo la ṣe ń jàǹfààní nípa bíbá a nìṣó ní híhùwà mímọ́?
• Èé ṣe tí Jósẹ́fù, Jóòbù, àti omidan Ṣúlámáítì fi jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún àwọn Kristẹni lóde òní?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Jósẹ́fù sá fún ìṣekúṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọmọbìnrin Ṣúlámáítì dà bí “ọgbà tí a gbégi dínà rẹ̀”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Jóòbù ti ‘bá ojú rẹ̀ dá májẹ̀mú’