Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Máa Gbàdúrà?

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Máa Gbàdúrà?

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Máa Gbàdúrà?

“ẸŃ BÉÈRÈ, síbẹ̀ ẹ kò rí gbà, nítorí tí ẹ ń béèrè fún ète tí kò tọ́ . . . Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:3, 8) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jákọ́bù, ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ yẹn lè gún wa ní kẹ́ṣẹ́ láti yẹ àwọn ìdí tí a fi ń gbàdúrà wò.

Àdúrà kì í kan ṣe ọ̀nà kan láti sọ ohun tí a fẹ́ fún Ọlọ́run. Nínú ìwàásù rẹ̀ olókìkí lórí òkè, Jésù sọ pé: “Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.” Síbẹ̀, Jésù tún sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín.” (Mátíù 6:8; 7:7) Nítorí náà, Jèhófà fẹ́ ká sọ ohun tí a nílò fún òun. Àmọ́ ohun tí àdúrà ní nínú ṣì ju ìyẹn lọ.

Kì í ṣe kìkì ìgbà táwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ bá fẹ́ gba nǹkan lọ́wọ́ ara wọn nìkan ni wọ́n máa ń bára wọn sọ̀rọ̀. Ìgbà tí wọ́n bá sọ èrò ọkàn wọn jáde ni wọ́n tó lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí àjọṣe wọn á sì túbọ̀ máa dán mọ́rán sí i. Bọ́ràn àdúrà náà ti rí nìyẹn, ètè tó wà fún ga ju ká kàn máa lò ó láti béèrè àwọn ohun táa nílò. Ó ń fún wa láǹfààní láti mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i, nípa fífi tọkàntọkàn wa sìn ín.

Òótọ́ ni, Ọlọ́run ti fún wa ní àǹfààní àdúrà kó lè ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ ọn. Kìkì tí a bá sọ àwọn èrò inú tiwa fúnra wa fún Ọlọ́run, dípò táa ó fi máa ka àwọn àdúrà àkọ́sórí nìkan ni èyí fi lè ṣeé ṣe. Ẹ ò rí ìdùnnú tí bíbá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà máa ń fúnni! Síwájú sí i, òwe Bíbélì kan sọ pé: “Àdúrà àwọn adúróṣánṣán jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.”—Òwe 15:8.

Onísáàmù náà, Ásáfù, kọ ọ́ lórin pé: “Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.” (Sáàmù 73:28) Àmọ́ láti lè sún mọ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ ṣe ju ká kàn gbàdúrà lọ. Ìwọ wo bí àkọsílẹ̀ tó tẹ̀ lé e yìí ṣe fi hàn:

“Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn [Jésù] wí fún un pé: ‘Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà.’” Jésù fún un lésì pé: “Nígbàkigbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ wí pé, ‘Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé.’” (Lúùkù 11:1, 2) Ǹjẹ́ a lè gbàdúrà tó nítumọ̀ tá ò bá kọ́kọ́ kọ́ nípa orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ àti bí a óò ṣe sọ ọ́ di mímọ́? Ǹjẹ́ ó sì tún lè ṣeé ṣe fún wa láti gbàdúrà níbàámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù wọ̀nyí bí a kò bá lóye ohun tó ń jẹ́ Ìjọba Ọlọ́run? Bí a bá yẹ Bíbélì wò kínníkínní, a óò lóye àwọn ọ̀ràn yìí. Ìmọ̀ tí a bá wá jèrè yẹn ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run ká sì lóye àwọn ọ̀nà rẹ̀. Síwájú sí i, mímọ Jèhófà Ọlọ́run á jẹ́ ká nímọ̀lára pé a túbọ̀ ń sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, àti pé a túbọ̀ ń fọkàn tán an. Lẹ́yìn náà, èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa bá a sọ̀rọ̀ fàlàlà nínú àdúrà.

Àdúrà Lè Yanjú Àwọn Ìṣòro

Níní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro wa. Ìwọ wo bí èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ipò tó tẹ̀ lé e yìí. Wọ́n jẹ́ ká rí i pé, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn tó ń gbàdúrà láti mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i.

Ní Brazil, obìnrin kan tó ń jẹ́ Maria gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́. Ó ti fẹ́ ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ìlànà ìwà híhù èyí tí àwùjọ tẹ́wọ́ gbà, èyí lápá kan sì jẹ́ nítorí àgàbàgebè tó rí láwùjọ. Maria ti já ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ jù sílẹ̀, ó sì ti filé sílẹ̀. Ó tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í joògùn yó. Àmọ́ nígbà tí kò ṣeé ṣe fún un láti rí ayọ̀ tó ń wá, ló bá kúkú ṣí ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ payá fún Ọlọ́run, ó gbàdúrà sí i pé kó jọ̀ọ́, kó ran òun lọ́wọ́.

Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn náà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi kàn sí Maria tí wọ́n sì fún un ní ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ kan, èyí tó ní àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tó dá lórí ìníyelórí títẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nínú. Èyí wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin, ọjọ́ yẹn gan-an ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí. Níkẹyìn, èyí wá ṣamọ̀nà sí mímú ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ bọ̀ sípò. Bó ṣe ń kọ́ nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ló ń fẹ́ láti fi ìfẹ́ tó ní fún un hàn. Maria ní: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í tún ìwà mi ṣe. Ọkọ mi àti ìdílé mi ò kọ́kọ́ fara mọ́ bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣùgbọ́n bí wọn ti ń rí àwọn ìyípadà tí mò ń ṣe, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í fún mi ní ìṣírí.” Lẹ́yìn náà, Maria ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olùgbọ́ àdúrà láti máa sìn ín.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé José ní ìyàwó tó jojú ní gbèsè, tó sì tún nílé iṣẹ́ kan tó ń mówó wọlé gan-an ní Bolivia, síbẹ̀ kò láyọ̀. Ìwà àgbèrè kan tó hù ló mú kí ìyàwó rẹ̀ fi sílẹ̀. Ńṣe ló máa mutí yó kẹ́ri, táá sì wá máa wo ara rẹ̀ bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkankan. José sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi gbogbo ọkàn mi gbàdúrà, mo sì ń béèrè ohun tó yẹ ki ń ṣe lọ́wọ́ Ọlọ́run kí n bàa lè múnú rẹ̀ dùn. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sílé iṣẹ́ mi, wọ́n fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ lọ̀ mí, àmọ́ lílé ni mo lé wọn dà nù. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lèyí ṣẹlẹ̀. Gbogbo ìgbà tí mo bá ṣáà ti gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́, àwọn ni mo ń rí ṣáá. Níkẹyìn, mo pinnu pé tí wọ́n bá tún wá, màá tẹ́tí sílẹ̀. Mo ti ka Bíbélì láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin mo sì ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè, ṣùgbọ́n kò sígbà kan tí wọn kì í fun mi ní ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́run. Ńṣe ni kíkọ́ tí mo ń kọ́ nípa Jèhófà ń fún ìgbésí ayé mi ní ète tuntun, ìṣírí ńlá gbáà sì ni àwọn ọ̀rẹ́ mi tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí jẹ́ fún mi! Mo fi ọ̀rẹ́bìnrin mi àtàwọn táa jọ ń mutí kiri sílẹ̀. Kò pẹ́ kò jìnnà, tí èmi àti aya mi àtàwọn ọmọ mi tún fi wà pa pọ̀. Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1999 ni mo ṣe ìrìbọmi.”

Ní Ítálì, ìgbéyàwó Tamara ti ko ìṣòro, ló bá gbàdúrà, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ọgbọ́n. Nítorí pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá péré ni nígbà tí wọ́n lé e jáde kúrò nílé lẹ́yìn tí wọ́n nà án tán, ẹ̀mí jàgídíjàgan ló kún inú ẹ̀. Tamara ní: “Mo rí Bíbélì kan he mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, mo ka ibì kan tó sọ pé, ‘rírí ọgbọ́n dà bí rírí àwọn ìṣúra fífarasin.’ Mo gbàdúrà pé kí n lè rí ọgbọ́n yẹn. (Òwe 2:1-6) Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn sí mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n ó gba àkókò díẹ̀ kí n tó lè máa fi ohun tí mo ń kọ́ sílò. Lẹ́yìn-ọ-rẹyìn, mo pinnu láti tẹ̀ lé ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni, mo sì ṣe ìrìbọmi. Ní báyìí, pẹ̀lú ọkọ mi, mo ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti jàǹfààní látinú ọgbọ́n Ọlọ́run.”

Ọkàn lára àwọn èèyàn kàǹkàkàǹkà láwùjọ ni Beatriz ti jẹ́ rí, ní ìlú Caracas lórílẹ̀-èdè Venezuela. Síbẹ̀, ìgbéyàwó ẹ̀ yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀, wàhálà sì bá a. Nígbà kan, obìnrin yìí gbàdúrà lójú méjèèjì fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Bó ṣe di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bẹ́ẹ̀ ni aago ẹnu ọ̀nà rẹ̀ dún. Pẹ̀lú ìkanra ló fi yọjú níbi ihò ilẹ̀kùn tó sì rí àwọn èèyàn méjì kan tí wọ́n gbé àpò ìfàlọ́wọ́ dání. Ó díbọ́n bíi pé òun ò sí nílé, àmọ́ kí àwọn tọkọtaya náà tó máa lọ, wọ́n gba abẹ́ ilẹ̀kùn ti ìwé àṣàrò kúkúrú kan sínú ilé. Èyí tó dá lórí kókó náà: “Mọ Bíbélì rẹ.” Àbí àdúrà rẹ̀ tó gbà lálẹ́ àná lè ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ìbẹ̀wò wọn ni? Ó pè wọ́n pé kí wọ́n máa bọ̀. Ká tó wí, ká tó fọ̀, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ó sì ṣe ìrìbọmi lẹ́yìn náà. Bí Beatriz ṣe wá rí ayọ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín nìyẹn o, òun náà ti ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa bí wọ́n ṣe lè rí ayọ̀ báyìí.

Ipò òṣì tó ń bá Carmen fínra ni lájorí àdúrà tirẹ̀. Ọmọ mẹ́wàá ló bí, ọkọ rẹ̀, Rafael sì jẹ́ ọ̀mùtí paraku. Carmen ní: “Ńṣe ni mo ń bá àwọn èèyàn fọṣọ kí n tó lè rí owó.” Ṣùgbọ́n ṣe ni ìmukúmu Rafael túbọ̀ ń burú sí i. “Àfìgbà táa tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọkọ mi tó bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà. A kọ́ nípa ìlérí Ìjọba náà—pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Jèhófà yóò fi mú òṣì àti ìnilára kúrò láyé. Níkẹyìn, àwọn àdúrà mi sí Jèhófà di èyí tí a dáhùn!” Kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà ran Rafael lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ọtí mímu, ó sì gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.” (Éfésù 4:24) Ó wá ṣeé ṣe fún òun àti ìdílé rẹ̀ láti mú kí bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Rafael sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ̀ pé a kò lọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tún nílé tiwa fúnra wa, ṣùgbọ́n a ní àwọn ohun kòṣeémánìí nínú ìgbésí ayé, a sì jẹ́ aláyọ̀.”

Ìgbà Tí A Óò Dáhùn Gbogbo Àdúrà

Ǹjẹ́ àdúrà gbígbà ṣe àwọn èèyàn wọ̀nyí láǹfààní kankan? Bẹ́ẹ̀ ni! Ṣóo tún kíyè sí i pé, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àdúrà náà ni a dáhùn nígbà tí ẹnì kan látinú ìjọ Kristẹni wá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?—Ìṣe 9:11.

Nígbà náà, a ní àwọn ìdí tó dára láti gbàdúrà. Láìpẹ́ sí àkókò táa wà yìí, àdúrà náà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, àti pé ká máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé yóò di èyí tí a dáhùn. (Mátíù 6:10) Lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti palẹ̀ àwọn tó ń ṣòdì sí i mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé wa, “ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà.” (Aísáyà 11:9) Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà yóò gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run”—ó sì dájú pé a óò dáhùn àwọn àdúrà wọn.—Róòmù 8:18-21.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ǹjẹ́ o mọ ìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà?