Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Ìsìn Ń fún Àwọn Kristẹni Láyọ̀

Iṣẹ́ Ìsìn Ń fún Àwọn Kristẹni Láyọ̀

Iṣẹ́ Ìsìn Ń fún Àwọn Kristẹni Láyọ̀

“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—ÌṢE 20:35.

1. Ẹ̀mí burúkú wo ló gbòde kan lóde òní, èé sì tí ṣe tó fi léwu?

 NÍ ÀWỌN ẹ̀wádún tó kẹ́yìn ọ̀rúndún ogún, ẹ̀mí “tèmi nìkan ṣáá” wọ́pọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Ohun tí ọ̀rọ̀ yìí, “tèmi nìkan ṣáá,” túmọ̀ sí ní ti gidi ni pé kéèyàn “níwà ànìkànjọpọ́n.” Ìyẹn fi hàn pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwọra, kì í sì í gba ti àwọn ẹlòmíràn rò. Ó sì dá wa lójú pé ẹ̀mí tèmi nìkan ṣáá kò tíì kásẹ̀ nílẹ̀ rárá nínú ọdún 2000 yìí. Ìgbà mélòó lo máa ń gbọ́ ìbéèrè náà, “Ṣé nǹkan á yọ fún mi ńbẹ̀?” tàbí, “Ṣé màá rí tèmi pọ́n lá ńbẹ̀?” Irú ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Òdì kejì pátápátá ló jẹ́ sí ìlànà tí Jésù là sílẹ̀ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

2. Kí ló fi hàn pé fífúnni máa ń mú ayọ̀ wá?

2 Ṣé lóòótọ́ ni fífúnni máa ń mú ayọ̀ púpọ̀ wá ju rírígbà lọ? Bẹ́ẹ̀ ni. Ronú nípa Jèhófà Ọlọ́run. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni “orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:9) Ó pèsè ohun gbogbo táa nílò láti mú kí a láyọ̀, kí ìgbésí ayé wa sì nítumọ̀. Ní ti tòótọ́, òun ni Orísun “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17) Ìgbà gbogbo ni Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀,” máa ń fúnni. (1 Tímótì 1:11) Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn tó ṣẹ̀dá, ó sì fún wọn lọ́pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. (Jòhánù 3:16) Tún ronú nípa ìdílé ènìyàn. Ká ní òbí ni ọ́, ìwọ náà mọ bóo ṣe ń fi nǹkan du ara rẹ tó, o mọ ohun tó ń ná ọ kóo tó lè tọ́ ọmọ kan dàgbà. Ọ̀pọ̀ ọdún sì lọmọ ọ̀hún ò fi mọ ohun tóo ń ṣe. Tí kò ka gbogbo rẹ̀ sí nǹkan kan. Síbẹ̀, inú rẹ ń dùn bóo ṣe ń rí ọmọ rẹ tó ń dàgbà nítorí pé o ń fún un láwọn nǹkan láìfawọ́sẹ́yìn. Kí nìdí? Torí pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni.

3. Èé ṣe tó fi jẹ́ ohun ìdùnnú láti lo ara wa fún Jèhófà àtàwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa?

3 Lọ́nà kan náà, fífúnni táa gbé karí ìfẹ́ la fi ń dá ìjọsìn tòótọ́ mọ̀. Níwọ̀n bí a ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà táa sì nífẹ̀ẹ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, ohun ìdùnnú ni láti lo ara wa fún wọn, kí á wúlò fún wọn. (Mátíù 22:37-39) Ẹnikẹ́ni tó bá ń fi ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan jọ́sìn kò ní fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀ níkẹyìn. Àmọ́ àwọn tó ń fi àìmọtara-ẹni-nìkan sìn, tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n máa fúnni ló ń ká wọn lára ju ohun tí wọ́n ń retí àtirí gbà lọ, máa ń rí ayọ̀ ní ti gidi. Òtítọ́ yìí la ó fòye mọ̀ nípa ṣíṣàyẹ̀wò bí a ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì kan tó tan mọ́ ìjọsìn wa nínú Ìwé Mímọ́. A óò jíròrò mẹ́ta nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tí ó tẹ̀ lé e.

Iṣẹ́ Ìsìn Tí Jésù Ṣe fún Gbogbo Ènìyàn

4. Báwo ni “iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn” ṣe rí ní Kirisẹ́ńdọ̀mù?

4 Nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ pàtàkì kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn ni lei·tour·giʹa, tí a túmọ̀ sí “iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn” nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù, ọ̀rọ̀ náà, lei·tour·giʹa, ti wá mú ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, “liturgy” (ààtò ìsìn) jáde. a Àmọ́ ṣá o, àwọn ààtò ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù kì í ṣe iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣàǹfààní fún gbogbo ènìyàn.

5, 6. (a) Iṣẹ́ ìsìn wo ni wọ́n ṣe fún gbogbo ènìyàn ní Ísírẹ́lì, àwọn àǹfààní wo ló sì ní? (b) Iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn tó tóbi lọ́lá gan-an wo ló rọ́pò èyí tí wọ́n ṣe ní Ísírẹ́lì, èé sì ti ṣe?

5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó tan mọ́ lei·tour·giʹa nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àlùfáà Ísírẹ́lì. Ó sọ pé: “Olúkúlùkù àlùfáà a máa mú ìdúró rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn [ìyẹn irú lei·tour·giʹa kan] àti láti rú àwọn ẹbọ kan náà lọ́pọ̀ ìgbà.” (Hébérù 10:11) Àwọn àlùfáà ọmọ Léfì ṣe iṣẹ́ ìsìn kan tó níye lórí gan-an fún gbogbo ènìyàn ní Ísírẹ́lì. Wọ́n ń kọ́ni ní Òfin Ọlọ́run, wọ́n sì ń rú ẹbọ tó kájú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn náà. (2 Kíróníkà 15:3; Málákì 2:7) Nígbà táwọn àlùfáà àtàwọn èèyàn náà bá tẹ̀ lé Òfin Jèhófà, orílẹ̀-èdè náà máa ń kún fún ìdùnnú.—Diutarónómì 16:15.

6 Àǹfààní gidi ló jẹ́ fún àwọn àlùfáà Ísírẹ́lì láti ṣe iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn lábẹ́ Òfin, àmọ́ iṣẹ́ ìsìn wọn kò ní láárí mọ́ nígbà tí Ọlọ́run kọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ nítorí àìṣòótọ́ wọn. (Mátíù 21:43) Jèhófà wá ṣètò fún ohun kan tó tóbi lọ́lá gan-an ju ìyẹn lọ—ìyẹn ni iṣẹ́ ìsìn tí Jésù, Àlùfáà Àgbà ńlá, ṣe fún gbogbo èèyàn. A kà nípa rẹ̀ pé: “Òun nítorí bíbá a lọ ní wíwàláàyè títí láé, ó ní iṣẹ́ àlùfáà rẹ̀ láìsí àwọn arọ́pò kankan. Nítorí náà, ó lè gba àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹ̀lú, nítorí tí òun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn.”—Hébérù 7:24, 25.

7. Èé ṣe tí iṣẹ́ ìsìn tí Jésù ṣe fún gbogbo ènìyàn fi mú àwọn àǹfààní tí kò láfiwé wá?

7 Jésù ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà títí láé, láìsí àwọn arọ́pò. Nípa bẹ́ẹ̀, òun nìkan ló lè gba àwọn ènìyàn là pátápátá. Ó ṣe iṣẹ́ ìsìn aláìlẹ́gbẹ́ yẹn fún gbogbo ènìyàn, kì í ṣe nínú tẹ́ńpìlì táa fọwọ́ kọ́ o, àmọ́ nínú tẹ́ńpìlì amápẹẹrẹṣẹ náà, ìyẹn ètò gíga tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa. Jésù wá ń sìn nísinsìnyí nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ inú tẹ́ńpìlì yẹn, nínú ọ̀run. Òun ni “ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn [lei·tour·gosʹ] ní ibi mímọ́ àti ní àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà gbé ró, kì í sì í ṣe ènìyàn.” (Hébérù 8:2; 9:11, 12) Bí ipò Jésù ti ga tó yẹn, síbẹ̀ ó jẹ́ “ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn.” Ó lo ọlá àṣẹ gíga tó ní láti fúnni, kì í ṣe láti gbà. Irú fífúnni bẹ́ẹ̀ sì mú ayọ̀ wá fún un. Ó jẹ́ ara “ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀” àti èyí tó fún un lókun láti fara da gbogbo ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.—Hébérù 12:2.

8. Báwo ni Jésù ṣe ṣe iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn láti dípò májẹ̀mú Òfin?

8 Apá mìíràn tún wà nínú iṣẹ́ ìsìn tí Jésù ṣe fún gbogbo ènìyàn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Jésù ti rí iṣẹ́ ìsìn kan fún gbogbo ènìyàn gbà tí ó tayọ lọ́lá, tí ó fi jẹ́ pé òun tún ni alárinà májẹ̀mú tí ó dára jù lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí, èyí tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin lórí àwọn ìlérí dídárajù.” (Hébérù 8:6) Mósè ṣalárinà májẹ̀mú tó jẹ́ ìpìlẹ̀ àjọṣe tó wà láàárín Ísírẹ́lì àti Jèhófà. (Ẹ́kísódù 19:4, 5) Jésù ṣalárinà májẹ̀mú tuntun kan, tó mú kó ṣeé ṣe láti bí orílẹ̀-èdè tuntun kan, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” tó ní àwọn Kristẹni tí a fòróró yàn láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nínú. (Gálátíà 6:16; Hébérù 8:8, 13; Ìṣípayá 5:9, 10) Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ìsìn tó tayọ lọ́lá fún gbogbo ènìyàn nìyẹn! Inú wa mà dùn o, láti mọ Jésù, ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn táa lè tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe ìjọsìn tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà!—Jòhánù 14:6.

Àwọn Kristẹni Pẹ̀lú Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn fún Gbogbo Ènìyàn

9, 10. Kí ni irú àwọn iṣẹ́ ìsìn kan fún gbogbo ènìyàn táwọn Kristẹni ń ṣe?

9 Kò sí ẹ̀dá ènìyàn kan tí iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe fún gbogbo ènìyàn lè ga lọ́lá tó ti Jésù. Àmọ́, nígbà tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bá gba èrè wọn ti ọ̀run, wọn óò mú ipò wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù, wọn ó sì kópa nínú iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà ní ọ̀run. (Ìṣípayá 20:6; 22:1-5) Síbẹ̀, àwọn Kristẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé ń ṣe iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn, wọ́n sì ń rí ayọ̀ ńláǹlà nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí àìtó oúnjẹ wà ní Palẹ́sìnì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kó àwọn ọrẹ wá látọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin tó wà ní Yúróòpù láti lè dín ìṣòro àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni ní Jùdíà kù. Iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn nìyẹn. (Róòmù 15:27; 2 Kọ́ríńtì 9:12) Lóde òní, inú àwọn Kristẹni máa ń dùn láti ṣe irú iṣẹ́ ìsìn kan náà, wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ ojú ẹsẹ̀ nígbà tí àwọn arákùnrin wọn bá wà nínú ìpọ́njú, ìjábá, tàbí àwọn àjálù mìíràn.—Òwe 14:21.

10 Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí iṣẹ́ ìsìn mìíràn fún gbogbo ènìyàn nígbà tó kọ̀wé pé: “Bí a bá tilẹ̀ ń tú mi jáde bí ọrẹ ẹbọ ohun mímu sórí ẹbọ àti iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn èyí tí ìgbàgbọ́ ti ṣamọ̀nà yín sí, mo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, mo sì bá gbogbo yín yọ̀.” (Fílípì 2:17) Iṣẹ́ àṣekára tí Pọ́ọ̀lù ṣe nítorí àwọn ará Fílípì ti jẹ́ iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn, èyí tó fi ìfẹ́ àti aápọn ṣe. Irú iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn bákan náà ń lọ lọ́wọ́ lónìí, àgàgà látọwọ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tó ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lákòókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. (Mátíù 24:45-47) Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, àwọn wọ̀nyí jẹ́ “àlùfáà mímọ́,” tí a yanṣẹ́ fún “láti máa rú àwọn ẹbọ ti ẹ̀mí tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi” àti láti “polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá ẹni tí ó pè [wọ́n] jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Pétérù 2:5, 9) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, wọ́n ń yọ̀ nínú irú àwọn àǹfààní bẹ́ẹ̀, kódà bí wọ́n tilẹ̀ ‘ń tú ara wọn jáde’ láti ṣe ojúṣe wọn. Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ìyẹn “àwọn àgùntàn mìíràn” dara pọ̀ mọ́ wọn, wọ́n sì ń tì wọ́n lẹ́yìn nínú iṣẹ́ sísọ nípa Jèhófà àtàwọn ète rẹ̀ fọ́mọ aráyé. b (Jòhánù 10:16; Mátíù 24:14) Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn tó kọ yọyọ tó sì kún fún ìdùnnú nìyẹn!—Sáàmù 107:21, 22.

Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀

11. Báwo ni Ánà, wòlíì obìnrin nì, ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún gbogbo Kristẹni?

11 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì mìíràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa ni la·treiʹa, táa túmọ̀ sí “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀” nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ṣíṣe ìjọsìn. Fún àpẹẹrẹ, a ṣàpèjúwe Ánà, wòlíì obìnrin opó nì, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ, tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ [ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó ní í ṣe pẹ̀lú la·treiʹa] lóru àti lọ́sàn-án pẹ̀lú ààwẹ̀ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.” (Lúùkù 2:36, 37) Ánà jọ́sìn Jèhófà láìyẹsẹ̀. Ó jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún gbogbo wa—lọ́mọdé lágbà, lọ́kùnrin lóbìnrin. Àní gẹ́gẹ́ bí Ánà ṣe fi taratara gbàdúrà sí Jèhófà, tó sì jọ́sìn rẹ̀ déédéé nínú tẹ́ńpìlì ni iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ tiwa náà ṣe ní àdúrà gbígbà àti lílọ sí àwọn ìpàdé déédéé nínú.—Róòmù 12:12; Hébérù 10:24, 25.

12. Kí ni apá pàtàkì kan nínú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa, báwo sì lèyí náà ṣe jẹ́ iṣẹ́ ìsìn kan fún gbogbo ènìyàn?

12 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa nígbà tó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run, ẹni tí mo ń fi ẹ̀mí mi ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìhìn rere nípa Ọmọ rẹ̀, ni ẹlẹ́rìí mi nípa bí mo ṣe ń dárúkọ yín nígbà gbogbo láìṣíwọ́ nínú àwọn àdúrà mi.” (Róòmù 1:9) Dájúdájú, iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà kì í wulẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn fún àwọn tó gbọ́ ọ nìkan, bí kò ṣe pé ó tún jẹ́ jíjọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run pẹ̀lú. Yálà àwọn èèyàn fetí sílẹ̀ ni o, tàbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù náà jẹ́ iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà. Ó dájú pé sísakun tí à ń sakun láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa àwọn ànímọ́ rere àti àwọn ète ọlọ́làwọ́ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ń mú ayọ̀ ńláǹlà wá fún wa.—Sáàmù 71:23.

Ibo La Ti Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀?

13. Kí ni ìrètí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún tẹ́ńpìlì Jèhófà tí ó jẹ́ tẹ̀mí, àwọn wo ló sì ń bá wọn yọ̀?

13 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: “Níwọ̀n bí a ó ti gba ìjọba kan tí kò ṣeé mì, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ láti ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, nípasẹ̀ èyí tí a fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run lọ́nà tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀.” (Hébérù 12:28) Pẹ̀lú ẹ̀rí tó dájú pé àwọn ó jogún Ìjọba náà, àwọn ẹni àmì òróró jẹ́ aláìṣeéṣínípò nínú ìgbàgbọ́ bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn Ẹni Gíga Jù Lọ náà. Àwọn nìkan ló lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un nínú Ibi Mímọ́ àti nínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún tẹ́ńpìlì Jèhófà tí ó jẹ́ tẹ̀mí, wọ́n sì ń fi ìháragàgà fojú sọ́nà láti sìn pẹ̀lú Jésù nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ náà, tí í ṣe ọ̀run fúnra rẹ̀. Àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn bá wọn yọ̀ fún àgbàyanu ìrètí yìí.—Hébérù 6:19, 20; 10:19-22.

14. Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe jàǹfààní nínú iṣẹ́ ìsìn tí Jésù ṣe fún gbogbo ènìyàn?

14 Àwọn àgùntàn mìíràn wọ̀nyẹn wá ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù rí tẹ́lẹ̀, ogunlọ́gọ̀ ńlá lára wọn tí fara hàn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, “wọ́n sì ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 7:14) Èyí túmọ̀ sí pé, bí ti àwọn ẹni àmì òróró olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn tí Jésù ṣe fún gbogbo ènìyàn, ìyẹn ni fífi ìwàláàyè pípé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rúbọ nítorí aráyé. Àwọn àgùntàn mìíràn náà tún jàǹfààní láti inú iṣẹ́ ìsìn tí Jésù ṣe fún gbogbo ènìyàn ní ti pé wọ́n ń “rọ̀ mọ́ májẹ̀mú [Jèhófà].” (Aísáyà 56:6) Rárá, wọn kì í ṣe olùkópa nínú májẹ̀mú tuntun náà, àmọ́ wọ́n rọ̀ mọ́ ọn ní ti pé wọ́n ṣègbọràn sí àwọn òfin tó wé mọ́ ọn, wọ́n sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ètò tó tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe. Wọ́n bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run kẹ́gbẹ́, wọ́n ń jẹun lórí tábìlì tẹ̀mí kan náà, wọ́n sì ń bá àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀, wọ́n ń yin Ọlọ́run lógo ní gbangba, wọ́n sì ń rú ẹbọ tẹ̀mí tó ń múnú rẹ̀ dùn sí i.—Hébérù 13:15.

15. Ibo ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀, ipa wo sì ni ìbùkún yìí ní lórí wọn?

15 Látàrí èyí, a rí àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n “dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n wọ aṣọ funfun.” Síwájú sí i, “wọ́n . . . wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run; wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀; Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ yóò sì na àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n.” (Ìṣípayá 7:9, 15) Ní Ísírẹ́lì, àwọn aláwọ̀ṣe jọ́sìn ní àgbàlá òde tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì. Lọ́nà kán náà, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ń jọ́sìn Jèhófà ní àgbàlá òde tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀. Sísìn níbẹ̀ ń fún wọn láyọ̀. (Sáàmù 122:1) Kódà lẹ́yìn tí èyí tó kẹ́yìn nínú àwọn ẹni àmì òróró alábàákẹ́gbẹ́ wọn bá ti gba ogún rẹ̀ ti ọ̀run tán, wọn óò máa bá a nìṣó láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn rẹ̀.—Ìṣípayá 21:3.

Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀ Tí Kò Ní Ìtẹ́wọ́gbà

16. Ìkìlọ̀ wo la fúnni lórí iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀?

16 Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin Jèhófà. (Ẹ́kísódù 30:9; Léfítíkù 10:1, 2) Bákan náà ni lóde òní, àwọn ohun kan wà táa gbọ́dọ̀ ṣe bí iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa yóò bá ní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé sí àwọn ará Kólósè pé: “Àwa kò ṣíwọ́ gbígbàdúrà fún yín àti bíbéèrè pé kí ẹ lè kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí, kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún bí ẹ ti ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo, tí ẹ sì ń pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.” (Kólósè 1:9, 10) Kì í ṣe tiwa láti pinnu ọ̀nà tí ó tọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run. Ìmọ̀ pípéye nínú Ìwé Mímọ́, ìfinúmòye tẹ̀mí, àti ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe pàtàkì púpọ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nǹkan ò lè yọrí sí rere.

17. (a) Báwo ni wọ́n ṣe gbé iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ gbòdì nígbà ayé Mósè? (b) Báwo ni iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ ṣe lè di èyí táa gbé gbòdì lóde òní?

17 Rántí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Mósè. A kà á pé: “Ọlọ́run yí padà, ó sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run.” (Ìṣe 7:42) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn ti rí àwọn ohun alágbára tí Jèhófà gbé ṣe lórí wọn. Síbẹ̀, wọ́n yíjú sí àwọn ọlọ́run mìíràn nígbà tí wọ́n ronú pé èyí yóò ṣe wọ́n láǹfààní. Wọn ò dúró ṣinṣin, ìdúróṣinṣin sì pọndandan bí iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa yóò bá mú inú Ọlọ́run dùn. (Sáàmù 18:25) Lóòótọ́, àwọn díẹ̀ lóde òní ni yóò yí padà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà láti lọ jọ́sìn àwọn ìràwọ̀ tàbí àwọn ère ọmọ màlúù oníwúrà, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ìbọ̀rìṣà mìíràn tún wà. Jésù kìlọ̀ nípa jíjọ́sìn “Ọrọ̀,” Pọ́ọ̀lù náà sì pe ojúkòkòrò ní ìbọ̀rìṣà. (Mátíù 6:24; Kólósè 3:5) Sátánì gbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọlọ́run kan. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Irú àwọn ìbọ̀rìṣà bẹ́ẹ̀ pọ̀ lọ jàra, ìdẹkùn sì ni wọ́n. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa ẹnì kan tó sọ pé òun ń tẹ̀ lé Jésù, àmọ́ tó jẹ́ pé ohun tó fi ṣe olórí ète rẹ̀ nínú ìgbésí ayé ni pé kí òun di ọlọ́rọ̀ tàbí kó jẹ́ pé ara rẹ̀ àtàwọn èrò inú tirẹ̀ gan-an ló gbẹ́kẹ̀ lé. Tá ló wá ń sìn ní ti gidi? Kí ló fi yàtọ̀ sáwọn Júù ọjọ́ Aísáyà, àwọn tí wọ́n fi orúkọ Jèhófà búra, àmọ́ tí wọ́n fi ògo àwọn ohun ńlá látọ̀dọ̀ Jèhófà fún àwọn òrìṣà àìmọ́?—Aísáyà 48:1, 5.

18. Báwo ni wọ́n ṣe gbé iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ gbòdì láyé ìgbàanì àti lóde òní?

18 Jésù tún kìlọ̀ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí olúkúlùkù ẹni tí ó bá pa yín yóò lérò pé òun ti ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run.” (Jòhánù 16:2) Ó dájú pé Ọlọ́run ni Sọ́ọ̀lù tó wá di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rò pé òun ń sìn nígbà tó ‘fọwọ́ sí ṣíṣìkàpa Sítéfánù’ tó sì “ń mí èémí ìhalẹ̀mọ́ni àti ìṣìkàpànìyàn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa.” (Ìṣe 8:1; 9:1) Lóde òní, díẹ̀ lára àwọn tó ń dá ìpẹ̀yàrun àti ìpànìyàn nípakúpa sílẹ̀ náà máa ń sọ pé Ọlọ́run làwọn ń sìn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run, àmọ́ tó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ọlọ́run ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, ti ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ọrọ̀, tàbí àwọn ọlọ́run àjúbàfún mìíràn, ni wọ́n ń darí ìjọsìn wọn sí.

19. (a) Ojú wo la fi ń wo iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa? (b) Irú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wo ni yóò mú ayọ̀ wá fún wa?

19 Jésù wí pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.” (Mátíù 4:10) Sátánì ló ń bá sọ̀rọ̀ lóòótọ́, àmọ́ ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa kọbi ara sí ọ̀rọ̀ rẹ̀! Ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Olúwa Ọba Aláṣẹ àgbáyé jẹ́ àǹfààní ńlá tí kò ṣeé fẹnu sọ. Kí la wá lè sọ nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn, èyí tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa? Ṣíṣe èyí nítorí àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa jẹ́ iṣẹ́ kan tó kún fún ìdùnnú tó sì ń mú ayọ̀ ńlá wá. (Sáàmù 41:1, 2; 59:16) Síbẹ̀síbẹ̀, irú iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ ń mú ojúlówó ayọ̀ wá, àmọ́ kìkì táa bá fi tọkàntọkàn ṣe é, táa sì ṣe é lọ́nà tó tọ́ ni. Àwọn wo ló ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́? Iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ àwọn wo ni Jèhófà tẹ́wọ́ gbà? A lè dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ táa bá gbé ọ̀rọ̀ Bíbélì kẹta tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa yẹ̀ wò. Èyí la ó ṣe nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ààtò ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù sábà máa ń jẹ́ ṣíṣe ìsìn tàbí àwọn ààtò ìsìn kan pàtó, irú bí ayẹyẹ gbígba ara Olúwa tí wọ́n máa ń ṣe nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì.

b Nínú Ìṣe orí kẹtàlá, ẹsẹ ìkejì, a ròyìn pé àwọn wòlíì àtàwọn olùkọ́ ní Áńtíókù “ń ṣèránṣẹ́ . . . ní gbangba” (tó túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó tan mọ́ lei·tour·giʹa) fún Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ ìsìn ní gbangba yìí ní wíwàásù fún gbogbo ènìyàn nínú.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni iṣẹ́ ìsìn kíkọyọyọ tí Jésù ṣe fún gbogbo ènìyàn?

• Irú iṣẹ́ ìsìn wo làwọn Kristẹni ń ṣe fún gbogbo ènìyàn?

• Kí ni iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ Kristẹni, ibo ni wọ́n sì ti ń ṣe é?

• Kí la gbọ́dọ̀ ní kí iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa tó lè múnú Ọlọ́run dùn?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn òbí máa ń rí ayọ̀ ńláǹlà nínú fífúnni

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Àwọn Kristẹni ń ṣe iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n bá ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti nígbà tí wọ́n bá ń polongo ìhìn rere náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

A nílò ìmọ̀ pípéye àti òye láti ní ìdánilójú pé iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run