Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Tiẹ̀ Láǹfààní Tádùúrà Gbígbà Ń Ṣe?

Ǹjẹ́ Ó Tiẹ̀ Láǹfààní Tádùúrà Gbígbà Ń Ṣe?

Ǹjẹ́ Ó Tiẹ̀ Láǹfààní Tádùúrà Gbígbà Ń Ṣe?

BÓYÁ la fi lè rí ẹnì kan tí kò tíì rídìí tó fi yẹ kóun gbàdúrà lásìkò kan tàbí òmíràn rí. Ká sọ tòótọ́, ṣàṣà ni ìsìn náà táwọn èèyàn inú ẹ̀ kì í fi taratara gbàdúrà. Fún àpẹẹrẹ, onísìn Búdà kan lè máa ṣe àsọtúnsọ àdúrà náà, “Ìgbàgbọ́ mi dúró lórí Amida Búdà” láìmọye ìgbà lóòjọ́.

Táa bá tún wá wo bí àwọn ìṣòro ṣe bo ayé pitimu, ó bọ́gbọ́n mu ká béèrè pé: Kí làwọn èèyàn ń retí látirí gbà nípa gbígbàdúrà? Àǹfààní wo tiẹ̀ làwọn àdúrà wọ̀nyí ń ṣe?

Kí Ló Mú Káwọn Èèyàn Máa Gbàdúrà?

Ọ̀pọ̀ àwọn ará Ìlà Oòrùn máa ń gbàdúrà sáwọn baba ńlá wọn àti sáwọn ọlọ́run Ṣintó tàbí Táò. Ohun tó mú wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè yege ìdánwò tí wọ́n bá ṣe níléèwé, kí wọ́n lè rí ìkórè wọ̀ǹtì-wọnti ká nínú oko wọn, tàbí torí kí àìsàn má baà yà lọ́ọ̀dẹ̀ wọn. Ní ti àwọn ẹlẹ́sìn Búdà, kí wọ́n lè lóye ni wọ́n ṣe ń sa gbogbo ipá wọn. Torí ìmọ̀, ọrọ̀ àti ààbò ni àwọn Híńdù sì ṣe máa ń fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí àwọn ọlọ́run àti àwọn abo-ọlọ́run tí wọ́n yàn láàyò.

Ìrètí àwọn kan lára àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni pé, tí àwọn bá yọ̀ǹda ìgbésí ayé àwọn láti sìn gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tàbí obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé ní àwọn ilé tí wọ́n kọ́ fún wọn, tí àwọn sì ń gbàdúrà ṣáá, àwọn á lè ṣe ọmọ aráyé láǹfààní. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ló ń fẹ́ kí Màríà ṣe wọ́n lóore nípa gbígba àwọn àdúrà tí wọ́n ti kọ́ sórí, wọ́n tiẹ̀ lè lo ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà fún ìrànwọ́. Láwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn, àgbá àdúrà lọ̀pọ̀ èèyàn ń lò. Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ní tiwọn máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Àdúrà Olúwa lásọtúnsọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan míì tí wọ́n tún fẹ́ kí Ọlọ́run ṣe fáwọn tún lè sá wọ inú àdúrà ọ̀hún. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù máa ń rìnrìn àjò jíjìnnà lọ síbi Odi Ìwọ̀ Oòrùn ní Jerúsálẹ́mù láti lọ gbàdúrà fún ìmúpadàbọ̀sípò tẹ́ńpìlì wọn àti fún sànmánì tuntun tó ní aásìkí àti àlàáfíà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ń sapá láti gbàdúrà, àwọn èèyàn ò mà wá tìtorí ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro àìríná-àìrílò, àwọn àṣà tó ti di bárakú, ìdílé tó ń túká, ìwà ọ̀daràn àti ogun. Àbí kẹ̀, ṣé ó lè jẹ́ pé àwọn èèyàn wọ̀nyí ò gbàdúrà ọ̀hún lọ́nà tó tọ́ ni? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe òótọ́ lẹnì kan wà tó ń tẹ́tí sí àdúrà?

Ṣé Ẹnì Kan Wà Tó Ń Gbọ́ Àdúrà?

Kò sí àǹfààní kankan tí àdúrà lè ṣe, àyàfi tí a bá gbọ́ àdúrà náà. Nígbà tí ẹnì kan bá ń gbàdúrà, ó dájú pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni pé ẹnì kan wà tó ń tẹ́tí sí òun ní ilẹ̀ àkóso ẹ̀mí níbi tójú èèyàn kan kò tó. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ìgbì afẹ́fẹ́ lásánlàsàn ló ń gbé àdúrà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé ẹnì kan tiẹ̀ wà tó lè mọ èrò ẹni tó ń gbàdúrà pàápàá. Ta lẹni yẹn lè jẹ́ ná?

Àní bí ìrònú ṣe ń bẹ̀rẹ̀ látinú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ohun tín-tìn-tín inú ọpọlọ jẹ́ àdììtú ńlá fún àwọn olùwádìí. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé, Ẹni tó wà nídìí iṣẹ́ ọnà ọpọlọ ní láti lóye àwọn ìrònú yẹn. Ẹni yẹn kì í ṣe ẹlòmíràn o, Ẹlẹ́dàá wa Jèhófà Ọlọ́run ni. (Sáàmù 83:18; Ìṣípayá 4:11) Òun ló yẹ ká darí àwọn àdúrà sí. Ṣùgbọ́n ṣe gbogbo irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà máa ń fiyè sí?

Ǹjẹ́ Gbogbo Àdúrà Ló Máa Ń Gbọ́?

Ọba Dáfídì ayé ọjọ́un jẹ́ ọkùnrin kan tó máa ń gbàdúrà gan-an. Gẹ́gẹ́ bí onísáàmù kan tí Ọlọ́run mí sí, ó kọrin pé: “Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.” (Sáàmù 65:2) Jèhófà lè gbọ́ kó sì lóye àwọn àdúrà tí a fi èdè èyíkéyìí lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún èdè tí aráyé ń sọ gbà. Kìkì nítorí pé kò ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn láti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọfúnni sínú èrò inú wọn kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run kò lè fiyè sí gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbàdúrà sí i lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà.

Bó ṣe rí nìyẹn o, Jésù Kristi—tóun pẹ̀lú jẹ́ ọkùnrin kan tó máa ń gbàdúrà gan-an—jẹ́ kó yé wa pé kì í ṣe gbogbo àdúrà ni inú Ọlọ́run dùn sí. Kíyè sí ohun tí Jésù sọ lórí ọ̀ràn sísọ àdúrà àkọ́sórí lásọtúnsọ èyí tó jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ nígbà ayé rẹ̀. Níbàámu pẹ̀lú Jerusalem Bible ti àwọn Kátólíìkì, ó ní: “Nínú àdúrà rẹ, má ṣe sọ wótòwótò, gẹ́gẹ́ bí àwọn kèfèrí ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò pé nípa lílo ọ̀rọ̀ púpọ̀, a óò gbọ́ tiwọn.” (Mátíù 6:7) A ò lè retí pé kí Jèhófà wá máa fetí sí àwọn àdúrà tí kò tọkàn wa wá.

Òwe Bíbélì kan fi ìdí tí àwọn àdúrà kan kò fi dùn mọ́ Ọlọ́run nínú hàn nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń yí etí rẹ̀ kúrò nínú gbígbọ́ òfin—àdúrà rẹ̀ pàápàá jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.” (Òwe 28:9) Òwe mìíràn sọ pé: “Jèhófà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú, ṣùgbọ́n àdúrà àwọn olódodo ni ó máa ń gbọ́.” (Òwe 15:29) Ní àkókò kan tí àwọn aṣáájú ní Júdà ìgbàanì dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, Jèhófà polongo pé: “Nígbà tí ẹ bá tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ yín, èmi yóò fi ojú mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ yín. Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀; àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.”—Aísáyà 1:1, 15.

Àpọ́sítélì Pétérù mẹ́nu ba ohun mìíràn tó tún lè máà jẹ́ kí àdúrà èèyàn ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá [àwọn aya yín] gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo, níwọ̀n bí ẹ tún ti jẹ́ ajogún ojú rere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí pẹ̀lú wọn, kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.” (1 Pétérù 3:7) Àdúrà ọkùnrin kan tí kò ka ìmọ̀ràn yẹn sí kò lè kọjá orí òrùlé ilé rẹ̀!

Ó ṣe kedere pé, àwọn ohun kan wà táa béèrè fún, táa sì ní láti kúnjú rẹ̀ bí a óò bá gbọ́ àwọn àdúrà wa. Kẹ́ẹ sì wá wò ó, ọ̀pọ̀ tó ń gbàdúrà ló jẹ́ pé ojú bín-ń-tín ni wọ́n fi ń wo ṣíṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run sọ pé kí a ṣe. Ìdí rèé tí gbogbo àdúrà àgbàkúdórógbó kò fi torí ẹ̀ mú ayé kan tó sàn jù wá.

Nígbà náà, kí wá ni Ọlọ́run ń béèrè kó tó lè gbọ́ àwọn àdúrà wa? Ìdáhùn náà ní í ṣe pẹ̀lú ìdí náà gan-an táa fi ń gbàdúrà. Àní táa bá fẹ́ mọ̀ bóyá ó tiẹ̀ láǹfààní tí àdúrà ń ṣe, ó di dandan ká mọ ète àdúrà gbígbà. Èé ṣe tí Jèhófà fi mú kó ṣeé ṣe fún wa láti bá òun sọ̀rọ̀?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

G.P.O., Jerúsálẹ́mù