Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Pa Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Kí o Sì Máa Bá a Lọ Ní Wíwà Láàyè”

“Pa Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Kí o Sì Máa Bá a Lọ Ní Wíwà Láàyè”

“Pa Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Kí o Sì Máa Bá a Lọ Ní Wíwà Láàyè”

Ọ̀DỌ́ ló ṣì jẹ́, olóye ni, ó sì jẹ́ “ẹlẹ́wà ní wíwò àti ẹlẹ́wà ní ìrísí.” Oníṣekúṣe kan báyìí àti ògbójú ni ìyàwó ọ̀gá rẹ̀. Ojoojúmọ́ ayé yìí lobìnrin yìí fi máa ń gbìyànjú láti mú kí ọ̀dọ́kùnrin tó máa ń dá a lọ́rùn yìí bá òun ṣèṣekúṣe. “Ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọjọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ àtẹ̀yìnwá, ó lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́ àmójútó rẹ̀, kò sì sí ìkankan nínú àwọn ènìyàn inú ilé ibẹ̀ nílé. Nígbà náà ni ó dì í ní ẹ̀wù mú pé: ‘Sùn tì mí!’” Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù, ọmọ Jákọ́bù baba ńlá, fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀, ó sì sá lọ kúrò lọ́dọ̀ aya Pọ́tífárì.—Jẹ́nẹ́sísì 39:1-12.

Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló máa sá fún irú ipò kan tó ń fani mọ́ra bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ìwọ wo ọ̀ràn ti ọ̀dọ́kùnrin kan tí Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ rí ní òpópónà lálẹ́. Bí obìnrin oníwàkiwà kan ṣe fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́ báyìí, “kíá, lẹ́sẹ̀ kan náà ló tẹ̀ lé e bí màlúù tó ń lọ fún pípa.”—Òwe 7:21, 22, New International Version.

A ṣí àwọn Kristẹni létí pé kí wọ́n “sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì, Kristẹni ọ̀dọ́ tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn, pé: “Sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.” (2 Tímótì 2:22) Nígbà tí a bá dojú kọ àwọn ipò tó lè mú wa ṣe àgbèrè, panṣágà, tàbí hu àwọn ìwà pálapàla mìíràn, àwa náà gbọ́dọ̀ sá kúrò níbẹ̀ láìjáfara gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù ti sá fún aya Pọ́tífárì. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu àtiṣe bẹ́ẹ̀? Ní orí keje ìwé Òwe nínú Bíbélì, Sólómọ́nì fún wa ní àwọn àmọ̀ràn kan tó níye lórí gan-an. Kì í kàn ṣe àwọn ẹ̀kọ́ tó ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ìtànjẹ àwọn èèyàn tó jẹ́ oníṣekúṣe nìkan ló sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àmọ́ ó tún fi àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣe é hàn wá nípa lílo àpèjúwe ojúkorojú kan níbi tí obìnrin aláìmọ́ kan ti sún ọ̀dọ́kùnrin kan dẹ́ṣẹ̀.

‘So Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Ìka Rẹ’

Ọba náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ràn bíi ti bàbá pé: “Ọmọ mi, pa àwọn àsọjáde mi mọ́, kí o sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ. Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ kí o sì máa bá a lọ ní wíwà láàyè, àti òfin mi bí ọmọlójú rẹ.”Òwe 7:1, 2.

Àwọn òbí, àgàgà àwọn bàbá, ló ni ẹrù iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi fún wọn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa ìlànà Ọlọ́run lórí ohun tó jẹ́ rere àti búburú. Mósè gba àwọn bàbá níyànjú pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:6, 7) Bákan náà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Fún ìdí yìí, ó dájú pé ìtọ́ni òbí tó yẹ fún pípamọ́ bí ìṣúra tàbí táa gbọ́dọ̀ mọrírì rẹ̀ gidigidi ní àwọn ìránnilétí, àwọn àṣẹ, àti àwọn òfin tí a rí nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú.

Ẹ̀kọ́ àwọn òbí tún lè ní àwọn ìlànà mìíràn nínú—ìyẹn ni àwọn òfin ìdílé. Àǹfààní àwọn mẹ́ńbà ìdílé lèyí wà fún. Lóòótọ́, àwọn òfin náà lè yàtọ̀ látinú ìdílé kan sí òmíràn, ó sinmi lórí àwọn ohun tó jẹ́ àìní wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, iṣẹ́ àwọn òbí ni láti pinnu ohun tó dára jù lọ fún ìdílé wọn. Àwọn òfin tí wọ́n bá sì ṣe náà jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n fi ń fi ojúlówó ìfẹ́ wọn àti àníyàn wọn hàn. Ìmọ̀ràn tí a gba àwọn ọ̀dọ́ ni pé kí wọ́n pa àwọn òfin wọ̀nyí mọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ tí àwọn òbí wọn ń fún wọn. Bẹ́ẹ̀ ni o, ìdí wà fún pípa àwọn ìtọ́ni yẹn mọ́ “bí ọmọlójú rẹ”—kóo tọ́jú wọn gidigidi. Ọ̀nà tóo lè gbà yẹra fún àbájáde tó ń ṣekú pani tí ṣíṣàìka àwọn ìlànà Jèhófà sí máa ń mú wá nìyẹn o, tí wàá sì tipa bẹ́ẹ̀ “máa bá a lọ ní wíwà láàyè.”

Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “So wọ́n [àwọn àṣẹ mi] mọ́ ìka rẹ, kí o sì kọ wọ́n sára wàláà ọkàn-àyà rẹ.” (Òwe 7:3) Bó ṣe jẹ́ pé ìgbà gbogbo la máa ń yẹ àwọn ìka wa wò tí wọ́n sì tún ṣe pàtàkì fún wa láti ṣe àwọn nǹkan táa ní í ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀kọ́ táa kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ láti kékeré tàbí ìmọ̀ Bíbélì táa jèrè ṣe gbọ́dọ̀ máa jẹ́ ìránnilétí fún wa nígbà gbogbo kó sì máa tọ́ wa nínú gbogbo ohun táa bá ń ṣe. A ní láti kọ wọ́n sínú wàláà ọkàn-àyà wa, ká sọ wọ́n di apá kan ara wa.

Láìgbàgbé bí ọgbọ́n àti òye ti ṣe pàtàkì tó, ọba náà gbani níyànjú pé: “Sọ fún ọgbọ́n pé: ‘Arábìnrin mi ni ọ́’; kí o sì pe òye ní ‘Ẹbí mi obìnrin.” (Òwe 7:4) Ọgbọ́n jẹ́ mímọ bí a ti ń lo ìmọ̀ tí Ọlọ́run ń fi fúnni lọ́nà tó tọ́. Ó yẹ ká ní ìfẹ́ni fún ọgbọ́n gẹ́gẹ́ bí a ṣe máa ń nífẹ̀ẹ́ arábìnrin wa táa fẹ́ràn gan-an. Kí wá ni òye? Ìyẹn ni láti lè fojú inú wo ọ̀ràn kan dáadáa kí ó sì yé wa, nípa mímọ gbogbo apá tó so mọ́ ọn àti ohun tí ọ̀ràn náà gan-an fúnra rẹ̀ ní nínú. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe máa ń sún mọ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn kan, bẹ́ẹ̀ náà ni òye ṣe gbọ́dọ̀ sún mọ́ wa dáadáa.

Èé ṣe tó fi yẹ ká fiyè sí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ ká sì tún jẹ́ kí ọgbọ́n àti òye sún mọ́ wa dáadáa? Ká lè “máa ṣọ́ [ara wa] lọ́wọ́ obìnrin tí ó jẹ́ àjèjì, lọ́wọ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ó ti mú kí àwọn àsọjáde rẹ̀ dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in.” (Òwe 7:5) Bẹ́ẹ̀ ni o, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀rọ̀ dídùn àti àwọn ọ̀nà ayíniléròpadà ti àjèjì kan—ìyẹn ẹnì kan tó jẹ́ oníṣekúṣe. a

Ọ̀dọ́kùnrin Náà Pàdé ‘Obìnrin Aládàkàdekè Kan’

Ọba Ísírẹ́lì náà tún ṣàpèjúwe ìran kan tóhun fúnra rẹ̀ wò pé: “Lójú fèrèsé ilé mi, láti àárín àgánrándì fèrèsé mi ni mo ti bojú wolẹ̀, kí èmi lè tẹjú mọ́ àwọn aláìní ìrírí. Mo ní ọkàn-ìfẹ́ nínú fífi òye mọ ọ̀dọ́kùnrin tí ọkàn-àyà kù fún nínú àwọn ọmọkùnrin, tí ó ń kọjá lọ ní ojú pópó nítòsí igun ọ̀nà rẹ̀, ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀ ni ó sì gbà lọ, ní wíríwírí ọjọ́, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́, nígbà dídé òru àti ìṣúdùdù.”Òwe 7:6-9.

Àgánrándì wà lójú fèrèsé tí Sólómọ́nì ń gbà wòta—ó dájú pé iṣẹ́ ọ̀nà kan ló jẹ́, èyí tó láwọn ọ̀pá tín-ínrín-tín-ínrín lára, bóyá tó tiẹ̀ tún ní àwọn ohun gbígbẹ́ táa fi ṣe ẹ̀ṣọ́ sí i lára pẹ̀lú. Bí ìmọ́lẹ̀ àṣálẹ́ ti ń pòórá, tí àwọn òpópónà sì di èyí tó ṣú dùdù. Ó rí ọ̀dọ́kùnrin kan tó fira ẹ̀ sínú ewu. Nítorí pé kò ní ìfòyemọ̀, tàbí agbára ìmòye rere, ọkàn àyà kù fún un. Ó ṣeé ṣe kó mọ irú àdúgbò tí òun wà yẹn àti nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ sóun níbẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin náà sún mọ́ ìtòsí “igun ọ̀nà rẹ̀,” ìyẹn igun tó wà ní ọ̀nà tó lọ sí ilé obìnrin náà. Ta ni obìnrin ọ̀hún? Àrà wo ló sì wà lọ́wọ́ ẹ̀?

Ọba tó ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Wò ó! obìnrin kan ń bẹ tí ó fẹ́ pàdé rẹ̀, nínú ẹ̀wù kárùwà àti àlùmọ̀kọ́rọ́yí ọkàn-àyà. Ó jẹ́ aláriwo líle àti alágídí. Ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í gbé ilé rẹ̀. Nísinsìnyí, ó wà lóde, nísinsìnyí, ó wà ní àwọn ojúde ìlú, nítòsí gbogbo igun ọ̀nà sì ni ó ń lúgọ sí.”Òwe 7:10-12.

Bí obìnrin yìí ṣe múra nìkan ti tó láti sọ irú èèyàn tó jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 38:14, 15) Bó ṣe múra kò sé ti ẹnì kan tó jẹ́ oníṣekúṣe kò yà á, àfi bí aṣẹ́wó. Yàtọ̀ síyẹn o, ó jẹ́ alálùmọ̀kọ́rọ́yí ní ọkàn-àyà—èrò inú rẹ̀ kún fún “àdàkàdekè”, ète ọkàn rẹ̀ sì dá lórí “àrékérekè.” (An American Translation; New International Version) Ó jẹ́ aláìlọ́wọ̀ àti olórí kunkun, ó jẹ́ ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́ àti alágídí, aláriwo àti aṣetinú ẹni ni, aṣa sì tún ni pẹ̀lú. Dípò kó gbélé ẹ̀, ó fẹ́ràn kó máa pààrà àwọn ibi táwọn èrò pọ̀ sí, kó máa fara pa mọ́ sí àwọn igun òpópó ọ̀nà láti dẹkùn mú àwọn ẹran ọdẹ rẹ̀. Irú èèyàn kan bí i ti ọ̀dọ́kùnrin yẹn ló sì ń dúró dè.

‘Ọ̀pọ̀ Yanturu Ìyíniléròpadà’

Bí ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe ṣe kòńgẹ́ obìnrin aláìmọ́ kan nìyẹn o, tó ní àwọn ète alárèékérekè. Ẹ ò ríi bí ìyẹn ti máa gba àfiyèsí Sólómọ́nì tó! Ó ṣàlàyé pé: “Obìnrin náà sì rá a mú, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Ó sì mójú kuku, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: ‘Àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ já lé mi léjìká. Òní ni mo san àwọn ẹ̀jẹ́ mi. Ìdí nìyẹn tí mo fi jáde wá pàdé rẹ, láti wá ojú rẹ, kí n lè rí ọ.’”Òwe 7:13-15.

Ètè obìnrin yìí mà dùn o. Kò tiẹ̀ tijú, ó sì ń sọ̀rọ̀ láìfìkan pe méjì. Ó ń ro gbogbo nǹkan tó ń sọ dáadáa kó tó sọ ọ́, kí ó ṣáà lè rí ọkùnrin yìí mú. Nípa sísọ pé òun ti ṣe àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ lọ́jọ́ yẹn gan-an àti pé òun ti san àwọn ẹ̀jẹ́ òun, ńṣe ló ń fi hàn pé òun jẹ́ olódodo, ó sì ń jẹ́ kó mọ̀ pé òun kò kù síbì kan nípa tẹ̀mí. Ní tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ máa ń ní ẹran, ìyẹ̀fun, òróró àti wáìnì nínú. (Léfítíkù 19:5, 6; 22:21; Númérì 15:8-10) Níwọ̀n ìgbà tó sì kúkú jẹ́ pé ẹni tó ń ṣèrúbọ lè mú lára ẹbọ ìdàpọ̀ náà fún ara rẹ̀ àtàwọn ìdílé rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi ń sọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà fún jíjẹ àti mímu ní ilé òun. Ohun tó ń sọ ṣe kedere: Ọ̀dọ́kùnrin yẹn á gbádùn ara rẹ̀ dọ́ba níbẹ̀. Nítorí kó lè rí i ló kúkú ṣe jáde kúrò nílé. Ó mà ṣe o, bí ẹnì kan bá lọ gba irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ gbọ́. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ pé, “òótọ́ ni pé obìnrin náà jáde láti wá ẹnì kan rí, àmọ́ ṣé ẹni yìí gan-an ní pàtàkì ló ń wá kiri ni? Òpònú èèyàn—bóyá bí irú ẹni yìí—nìkan ló lè gba nǹkan tóbìnrin yẹn sọ gbọ́.”

Lẹ́yìn tó ti fi aṣọ ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ lọ́nà tí ń fani mọ́ra tán, tó sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tí ń tanni jẹ, tó tún lo ìfarakanra nípa ìgbánimọ́ra àti adùn ètè rẹ̀, oníṣekúṣe náà tún wá lo agbára òórùn. Ó sọ pé: “Mo ti fi àwọn aṣọ ìtẹ́lébùsùn ṣe ọ̀ṣọ́ fún àga ìnàyìn mi, pẹ̀lú àwọn ohun tí ó jẹ́ kàlákìnní, aṣọ ọ̀gbọ̀ Íjíbítì. Mo ti fi òjíá, álóè àti sínámónì wọ́n ibùsùn mi.” (Òwe 7:16, 17) Ó ti ṣe ibùsùn rẹ̀ lọ́nà tó lẹ́wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ Íjíbítì aláwọ̀ mèremère, ó sì ti fi àwọn òórùn dídùn ti òjíá, álóè àti sínámónì wọ́n ibùsùn náà.

Ó tẹ̀ síwájú pé: “Wá, jẹ́ kí a mu ìfẹ́ ní àmuyó títí di òwúrọ̀; jẹ́ kí a fi àwọn ìfihàn ìfẹ́ gbádùn ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” Ìkésíni yẹn ju kìkì pé káwọn èèyàn méjì wulẹ̀ gbádùn oúnjẹ alẹ́ alárinrin kan pa pọ̀ lọ. Ìlérí tó ń ṣe fún un jẹ́ ti gbígbádùn ìbálòpọ̀ pa pọ̀. Lójú ọmọkùnrin yẹn ní tiẹ̀, kò sóhun tó tún lè dùn ju ìyẹn lọ! Kó lè túbọ̀ kó sí i lórí pátápátá, ló bá tún fi kún-un pé: “Nítorí ọkọ kò sí ní ilé rẹ̀; ó ti rin ìrìn àjò lọ sí ọ̀nà tí ó jìn. Ó mú àpò owó lọ́wọ́. Ọjọ́ òṣùpá àrànmọ́jú ni yóò wá sí ilé rẹ̀.” (Òwe 7:18-20) Ó fi yé e pé kó séwu fáwọn, nítorí ọkọ̀ rẹ̀ ti lọ sí àjò lọ ṣòwò, yóò sì ṣe díẹ̀ kó tó padà dé. Ẹ ò rí i pé ó mọ ọgbọ́n tí wọ́n fi ń mú ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ gan-an ni! “Ó ti fi ọ̀pọ̀ yanturu ìyíniléròpadà rẹ̀ ṣì í lọ́nà. Ó fi dídùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in ètè rẹ̀ sún un dẹ́ṣẹ̀.” (Òwe 7:21) Àyàfi irú èèyàn kan tó níwà bíi ti Jósẹ́fù nìkan ló lè dènà irú ìfanimọ́ra tí ń réni lọ bí èyí. (Jẹ́nẹ́sísì 39: 9, 12) Ṣé ọ̀dọ́kùnrin yìí kúnjú ìwọ̀n?

‘Bí Akọ Màlúù Tó Ń Lọ fún Pípa’

Sólómọ́nì ròyìn pé: “Lójijì, ó ń tọ obìnrin náà lẹ́yìn, bí akọ màlúù tí ń bọ̀ àní fún ìfikúpa, àti gan-an gẹ́gẹ́ bí pé a fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dì í fún ìbáwí òmùgọ̀ ènìyàn, títí ọfà fi la ẹ̀dọ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ti ń ṣe kánkán sínú pańpẹ́, kò sì mọ̀ pé ó wé mọ́ ọkàn òun gan-an.”Òwe 7:22, 23.

Ìkésíni yẹn ti wọ ọ̀dọ́kùnrin yìí lára débi tí kò fi lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ó gbàgbé gbogbo agbára ìmòye rere pátá, gọ̀ọ́gọ̀ọ́ ló tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ‘bí akọ màlúù tó ń lọ fún pípa.’ Bí kò ṣe ṣeé ṣe fún ọkùnrin kan tí wọ́n kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí lẹ́sẹ̀ láti bọ́ lọ́wọ́ ìjìyà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́kùnrin náà di ẹni tí a fà sínú ẹ̀ṣẹ̀. Kò rí ewu tó wà nínú ẹ̀ rárá, “títí ọfà fi la ẹ̀dọ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀,” ìyẹn túmọ̀ sí pé, àfìgbà tó gba ọgbẹ́ tó lè yọrí sí ikú rẹ̀. Ikú yẹn lè jẹ́ èyí tó ṣeé fojú rí nítorí pé ó ti ṣí ara rẹ̀ payá sí àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń fà èyí tí ń ṣekú pani. b Ọgbẹ́ yẹn tún lè fa ikú ẹ̀ nípa tẹ̀mí nítorí pé “ó wé mọ́ ọkàn òun gan-an.” Gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé rẹ̀ pátá ni ọ̀ràn náà nípa tó lágbára lé lórí, ó sì tún ti dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo sí Ọlọ́run. Ó tipa bẹ́ẹ̀ yára kánkán kó sínú ẹ̀mú ikú bí ẹyẹ kan tó kó sínú pańpẹ́!

“Má Rìn Gbéregbère Wọ Àwọn Òpópónà Rẹ̀”

Ọlọgbọ́n ọba náà mú ẹ̀kọ́ kan jáde látinú ohun tó ti rí, ó rọni pé: “Wàyí o, ẹ̀yin ọmọ, ẹ fetí sí mi, kí ẹ sì fiyè sí àwọn àsọjáde ẹnu mi. Kí ọkàn-àyà rẹ má yà sí àwọn ọ̀nà obìnrin náà. Má rìn gbéregbère wọ àwọn òpópónà rẹ̀. Nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti mú ṣubú lulẹ̀ ní òkú, gbogbo àwọn tí a ti ọwọ́ rẹ̀ pa sì pọ̀ níye. Àwọn ọ̀nà sí Ṣìọ́ọ̀lù ni ilé rẹ̀ jẹ́; wọ́n ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú àwọn yàrá inú lọ́hùn-ún ti ikú.”Òwe 7:24-27.

Ó ṣe kedere pé, ìmọ̀ràn tí Sólómọ́nì fúnni ni pé ká yà kúrò ní àwọn ọ̀nà ènìyàn kan tó jẹ́ oníṣekúṣe ká “sì máa bá a lọ ní wíwà láàyè.” (Òwe 7:2) Ẹ ò rí i pé ìmọ̀ràn tó bá àkókò wa mu gẹ́ẹ́ lèyí jẹ́! Láìsíyèméjì, ó pọndandan fún wa láti yẹra fún àwọn ibi tí àwọn tó ń dúró láti mú ẹran ọdẹ máa ń jẹ̀ sí. Kí ló dé tóo fi fẹ́ jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wọn nípa lílọ sírú àwọn ibi báyẹn? Àní, kí ló dé tí wàá fi wá di ẹnì kan tí “ọkàn-àyà kù fún” tí wàá sì wá lọ máa rìn gbéregbère ní àwọn òpópónà “ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” kan?

“Obìnrin tí ó jẹ́ àjèjì” tí ọba rí náà ré ọ̀dọ́kùnrin náà lọ pẹ̀lú ìkésíni náà pé: “jẹ́ kí a fi àwọn ìfihàn ìfẹ́ gbádùn ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” Ǹjẹ́ ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́—àgàgà àwọn ọ̀dọ́bìnrin—kọ́ ni wọ́n ti bà jẹ́ ní irú ọ̀nà yìí? Ìwọ tiẹ̀ rò ó ná: Tẹ́nì kan bá ń gbìyànjú láti mú kóo lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe, ṣe ojúlówó ìfẹ́ ló ní fún ọ tàbí ó kàn fẹ́ lò ẹ́ fún ète ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lásán? Kí ló dé tí ọkùnrin kán tó nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan tinútinú ṣe máa fipá mú un láti ba gbogbo ìdálẹ́kọ̀ọ́ Kristẹni tó ti gbà àti ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ jẹ́? Sólómọ́nì Ọba ṣí wa létí pé “kí ọkàn-àyà rẹ má yà sí” irú àwọn ọ̀nà yẹn.

Àwọn ọ̀rọ̀ ẹni tí ń súnni dẹ́ṣẹ̀ sábà máa ń dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in, ó sì máa ń ro ohun tó fẹ́ sọ dáadáa kó tó sọ ọ́. Jíjẹ́ kí ọgbọ́n àti òye máa wà pẹ̀lú wa nígbà gbogbo yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ohun tó máa ń tẹ̀yìn irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ jáde. Ààbò ni yóò jẹ́ fún wa o, bí a kò bá gbàgbé ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ láti máa ‘pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ ká sì máa bá a lọ ní wíwàláàyè,’ àní títí láé.—1 Jòhánù 2:17.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ náà “àjèjì” ni a lò fún àwọn tó sọ ara wọn dàjèjì sí Jèhófà nípa yíyí padà kúrò nínú àwọn Òfin rẹ̀. Ìdí nìyẹn táa fi pe oníṣekúṣe obìnrin kan, irú bí aṣẹ́wó kan, ní “obìnrin tí ó jẹ́ àjèjì.”

b Àwọn àrùn kan tí ìbálòpọ̀ ń fà máa ń ba ẹ̀dọ̀ jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, bí àrùn rẹ́kórẹ́kó bá ti lọ gogò tán, ńṣe làwọn kòkòrò àrùn yẹn máa bo ẹ̀dọ̀ pátápátá. Kòkòrò tó sì máa ń fa àtọ̀sí lè mú ẹ̀dọ̀ wú.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ojú wo lo fi ń wo òfin àwọn òbí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Pípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ túmọ̀ sí ìyè