Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwàásù Ìjọba Náà Lórí Òkè Altiplano ní Peru

Wíwàásù Ìjọba Náà Lórí Òkè Altiplano ní Peru

Àwa Jẹ́ Irú Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́

Wíwàásù Ìjọba Náà Lórí Òkè Altiplano ní Peru

ÀÁRÍN ìhà ìlà oòrùn àti ìhà ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ olókè ńlá ti Àwọn Òkè Andes—níbi tí Bolivia àti Peru ti pàdé—ni Altiplano wà. Orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “pẹ̀tẹ́lẹ̀ gíga,” tàbí “òkè olórí títẹ́jú.” Ara Bolivia ni apá tó pọ̀ jù lọ níbẹ̀ wà.

Fífẹ̀ Altiplano jẹ́ ọgọ́rùn-ún kìlómítà, gígùn rẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún kìlómítà, ó sì fi ìpíndọ́gba nǹkan bí egbèjìdínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún [3,700] mítà ga ju ìtẹ́jú òkun lọ. Tóo bá wọ ọkọ̀ òfuurufú tó gbéra láti Lima, tó jẹ́ olú ìlú etíkun Peru, wàá gba El Misti tí yìnyín bò kọjá, ìyẹn ni òkè ayọnáyèéfín tó ga la ìkuukùu kọjá dé ìwọ̀n ẹgbọ̀kàndínlọ́gbọ̀n ó lé méjìlélógún [5,822] mítà. Tóo bá túbọ̀ lọ sókè kọjá ẹgbàáta [6,000] mítà, wàá rí àwọn ṣóńṣó Nevado Ampato àti Nevado Coropuna jíjìnnà réré tí yìnyín bò mọ́lẹ̀. Ohun tó máa wá yọ sí ọ lójijì ni òkè olórí títẹ́jú gbígbòòrò kan—ìyẹn ni Altiplano ti gúúsù Peru.

Puno ni olú ìlú Altiplano ti Peru, ó wà ní ìkángun àríwá ìwọ̀ oòrùn Adágún Titicaca, tó jẹ́ adágún tó fẹ̀ jù lọ láyé tí àwọn ọkọ̀ ńlá lè gbà kọjá. Nítorí pé ẹkùn ilẹ̀ náà ga ju kìlómítà mẹ́ta lọ, ó máa ń gba àkókò díẹ̀ kí atẹ́gùn ibẹ̀ tó mọ́ àwọn àlejò lára. Àwọn Íńdíà tó ń sọ èdè Quechua àti Aymara ló ń gbé létí Adágún Titicaca. A lè rí wọn nínú àwọn ẹ̀wù aláwọ̀ mèremère pupa, aláwọ̀ ewé, tàbí aláwọ̀ búlúù, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ nínú chacras tàbí àwọn oko wọn kéékèèké. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Spanish gan-an ni èdè tí wọ́n ń sọ ní Peru, wọ́n tún ń sọ èdè Quechua àti Aymara ní Altiplano.

Mímú Ipò Iwájú Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù

Ọ̀pọ̀ àwọn onírẹ̀lẹ̀, alákíkanjú ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè Quechua àti Aymara, ló ti wá sínú ìmọ̀ pípéye ti òtítọ́ Bíbélì lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ìbùkún Jèhófà lórí ìsapá àwọn olùpòkìkí Ìjọba alákòókò kíkún tí wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe.

Fún àpẹẹrẹ, wọ́n yan José àti Silvia gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe sí ìlú Putina, tó jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà sí Adágún Titicaca. Láàárín oṣù méjì, Silvia ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé mẹ́rìndínlógún, José náà sì ń darí mẹ́rìnlá. Láàárín oṣù mẹ́fà péré, iye àwọn akéde ti lọ sókè láti orí mẹ́tàlélógún sí mọ́kànlélógójì. Láàárín àkókò náà, iye àwọn tó ń wá sípàdé ti lọ sókè láti méjìdínláàádọ́ta [48] sí méjìléláàádóje [132] lọ́jọ́ térò pọ̀ jù.

José sọ pé: “Nígbà táa fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìpàdé ìjọ láwọn àwùjọ àdádó wọ̀nyí, a rí i pé ó bọ́gbọ́n mu jù láti fi Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ bẹ̀rẹ̀. Èyí mú kó túbọ̀ rọrùn fáwọn olùfìfẹ́hàn láti bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé.”

Àwọn arábìnrin méjì—tí ọ̀kan jẹ́ aṣáájú ọ̀nà—ló kọ́kọ́ mú ìhìn rere náà wá sí àwùjọ àdádó Muñani, tó jẹ́ nǹkan bí ogún kìlómítà sí Putina. Ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí bá ọkùnrin afọ́jú kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lucio ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. a Ó ké sí Miguel, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin, tó jẹ́ míṣọ́nnárì ìjọ Kátólíìkì, tó sì tún jẹ́ aṣáájú àwùjọ àgbègbè kan tó wà nítòsí. Nígbà tí ọ̀rẹ́ kan béèrè ìdí tí Miguel fi ń lọ sí Muñani lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ó sọ pé kí òun lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni. Ìbéèrè wá dìde pé: “Kí ló dé táa kì í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níhìn-ín?” Nítorí ìfẹ́ táwọn ará abúlé Miguel fi hàn, kò pẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìpàdé níbẹ̀.

Miguel bẹ̀rẹ̀ sí sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn ẹlòmíràn. Àmọ́, ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì àwọn Kátólíìkì àti igbá kejì gómìnà wá ńkọ́? Nínú ìpàdé kan tí wọ́n ṣe nínú gbọ̀ngàn tó wà lábúlé náà, ó kéde pé òun ti jáwọ́ nínú iṣẹ́ òun gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì àwọn Kátólíìkì. Ṣé wọ́n máa yan ẹlòmíràn ni? Ẹnì kan nínú àwùjọ náà wá sọ pé: “Kí la tún fẹ́ yan ẹlòmíràn fún nígbà táa ti ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?” Láìsí àní-àní, ẹ̀kọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ wọn ló ń tọ́ka sí. Ẹlòmíràn fi kún un pé: “A ò lè gbà kí ìwọ nìkan jáwọ́. Kí ló dé tí gbogbo wa ó kúkú jáwọ́ ńbẹ̀?” Bí gbogbo àwọn tó wá láwùjọ ṣe kígbe lẹ́ẹ̀kan náà nìyẹn, tí wọ́n sọ pé: “Gbogbo wa ti jáwọ́ ńbẹ̀!”

Wọ́n jíròrò nípa àwọn ère àtàwọn àgbélébùú nínú ìpàdé tí wọ́n ṣé láìpẹ́ sí àkókò yẹn. Ọkùnrin kan sọ pé kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ka Diutarónómì 7:25, tó sọ pé: “Ère fífín àwọn ọlọ́run wọn ni kí ẹ fi iná sun. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ojú rẹ wọ fàdákà àti wúrà tí ó wà lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe mú un fún ara rẹ, kí ó má bàa di pé a dẹkùn mú ọ ní tòótọ́ nípasẹ̀ rẹ̀; nítorí ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ni ó jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”

Ọkùnrin náà wá béèrè pé ẹni tó bá fẹ́ kí wọ́n jó àwọn ère wọ̀nyí, kó nawọ́ sókè. Kíá ni gbogbo wọn nawọ́ sókè. (Ìṣe 19:19, 20) Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ìdílé mẹ́tàlélógún lára ìdílé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó wà láwùjọ yẹn ló ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹni méjì ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tíì ṣe batisí, àwọn tọkọtaya márùn-ún sì ń wéwèé láti fi ìdí ìgbéyàwó wọn múlẹ̀ lábẹ́ òfin kí wọ́n lè ní ìdúró mímọ́ níwájú Jèhófà.—Títù 3:1; Hébérù 13:4.

Fífi Ohùn Táa Gbà Sórí Kásẹ́ẹ̀tì Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Nítorí pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń gbé lórí Altiplano ni kò mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà, fídíò àti kásẹ́ẹ̀tì Watch Tower Society táa ka èdè àdúgbò wọn sí nínú ń ṣèrànwọ́ gan-an—kódà fún dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé pàápàá. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ kásẹ́ẹ̀tì kan, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dora darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Yóò jẹ́ kí kásẹ́ẹ̀tì náà ka ìpínrọ̀ kan, yóò wá bi akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà láwọn ìbéèrè lórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́.

Ilé iṣẹ́ rédíò kan ládùúgbò máa ń gbé àwọn abala inú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lédè Quechua sáfẹ́fẹ́ déédéé. Ó tún máa ń gbé àwọn apá kan nínú ìwé ìròyìn Jí! lédè Spanish sáfẹ́fẹ́ pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tipa bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìhìn Ìjọba náà, tí wọ́n sì túbọ̀ fẹ́ mọ̀ sí i nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wá sílé wọn.

Altiplano ò já mọ́ nǹkankan rárá lójú àwọn èèyàn, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run. Nítorí ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún ìran ènìyàn, ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé lórí òkè Andean Altiplano ti wá ń di ara ẹgbẹ́ tó ń fi ògo kún ilé ńlá ti ìjọsìn tòótọ́ rẹ̀.—Hágáì 2:7.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ yìí.