Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìṣọ̀kan Ìsìn Ha Sún Mọ́lé Bí?

Ìṣọ̀kan Ìsìn Ha Sún Mọ́lé Bí?

Ìṣọ̀kan Ìsìn Ha Sún Mọ́lé Bí?

Christian Krause, ààrẹ Ẹ̀sìn Luther Lágbàáyé sọ pé: “Ọjọ́ pàtàkì kan nínú ìtàn ṣọ́ọ̀ṣì wa la wà yìí.” Bákan náà ni Póòpù John Paul kejì sọ̀rọ̀ nípa “ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan tó wà lọ́nà tó ṣòro láti tún ìṣọ̀kan àárín àwọn Kristẹni ṣe ní kíkún.”

Fífi tí wọ́n fọwọ́ sí Ìwé Àdéhùn Ẹgbẹ́ ní October 31, 1999, ní Augsburg, Jámánì, èyí tó fìdí Ìpolongo Àjọṣe Lórí Ẹ̀kọ́ Ìgbàgbọ́ Ìdáláre múlẹ̀, ló fa ìpolongo tí wọ́n ń fi ìtara ṣe wọ̀nyí. Wọ́n fara balẹ̀ yan àkókò tí wọ́n ṣe é àti ibi tí wọ́n ti ṣe é. A gbọ́ pé ní October 31, 1517, Martin Luther kan àwọn àbá ìjiyànlé rẹ̀ márùn-dín-lọ́gọ́rùn-ún mọ́ ilẹ̀kùn ṣọ́ọ̀ṣì ńlá tó wà ní Wittenberg, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe ti Pùròtẹ́sítáǹtì. Ní ti gidi, Augsburg ni àwọn ẹlẹ́sìn Luther ti sọ ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn jáde ní 1530, èyí tí wọ́n pè ní Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ ní Augsburg, tí Ìjọ Kátólíìkì kò tẹ́wọ́ gbà, tó wá fa ọ̀gbun tí kò ṣeé dí tó wà láàárín ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì àti ẹ̀sìn Kátólíìkì.

Ǹjẹ́ Ìpolongo Àjọṣe náà lè jẹ́ ìgbésẹ̀ kan tó ṣeé fọkàn tán láti yanjú ìyapa tó wà láàárín ṣọ́ọ̀ṣì náà, bí wọ́n ti sọ? Kì í ṣe gbogbo wọn ló gbà pé ó lè ṣeé ṣe. Ó lé ní àádọ́ta lé rúgba [250] àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì tó fọwọ́ sí ìwé kan tí wọ́n fi sọ pé àwọn kò ní bá Ìjọ Kátólíìkì lẹ̀dí àpò pọ̀. Inú tún bí àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì nígbà tí Ìjọ Kátólíìkì kéde ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ kan fún ọdún 2000, àṣà tó jẹ́ pé òun gan-an ló ṣokùnfà ọ̀gbun tó ti wà láti nǹkan bi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún sẹ́yìn. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ ní Augsburg àti ìjiyàn Kátólíìkì tí Àpérò Trent ṣe kò tíì kásẹ̀ nílẹ̀, ìṣọ̀kan kò tíì sún mọ́lé rárá.

Ìpínyà àti àìgbọ́ra ẹni yé tó wà láàárín Kirisẹ́ńdọ̀mù pọ̀ kọjá ohun tí fífi ọwọ́ sí ìpolongo àjọṣe èyíkéyìí lè ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ. Síwájú sí i, ìṣọ̀kan nínú ẹ̀sìn sinmi lórí ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Éfésù 4:3-6) Dípò tí ìṣọ̀kan yóò fi tipasẹ̀ fífi ìgbàgbọ́ ẹni dọ́rẹ̀ẹ́ wá, látinú kíkọ́ àti ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ wa ni ìṣọ̀kan tòótọ́ ti ń wá. Wòlíì Míkà olóòótọ́ là á mọ́lẹ̀ pé: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—Míkà 4:5.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

© Àwọn fọ́tò Ralph Orlowski/REUTERS/Archive