Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Dandan Ni Kí O Gbà á Gbọ́?

Ṣé Dandan Ni Kí O Gbà á Gbọ́?

Ṣé Dandan Ni Kí O Gbà á Gbọ́?

AKẸ́KỌ̀Ọ́ kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá ń tiraka láti lóye àwọn ìlànà tó pilẹ̀ ìṣirò. Olùkọ́ rẹ̀ gbé ìṣirò kan tó jọ pé kò le fún kíláàsì náà.

Ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ ni pé: “Ká fi lẹ́tà x wé lẹ́tà mìíràn tí í ṣe y. Ká wá gbà pé x jẹ́ oókan, tí y náà sì jẹ́ oókan.”

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ronú pé, ‘ìyẹn ṣì dára.’

Àmọ́ lẹ́yìn tí olùkọ́ náà ti ṣe ìṣirò náà dé ìlà kẹrin tí gbogbo ẹ̀ sì ń bọ́gbọ́n mu, ó wá gbé àbájáde kan jáde tó múni ta gìrì, ó sọ pé: “Bí a ṣe lè sọ pé lẹ́tà x àti lẹ́tà y kò ju ara wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni eéjì àti oókan kò ju ara wọn lọ!”

Ó sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí gbogbo rẹ̀ ti dàrú mọ́ lójú pé: “Ẹ làdí rẹ̀ bí èyí kì í bá ṣe òótọ́.”

Ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà kò mọ bí òun yóò ṣe ṣàlàyé pé kì í ṣe òótọ́ nítorí pé kò mọ ìṣirò náà dáadáa. Ó jọ pé gbogbo ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan nípa ìṣirò náà ṣeé fara mọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tọ́ràn wá dórí àbájáde tí ń ṣeni ní kàyéfì yìí ńkọ́, kí ni kó ṣe? Ó ṣe tán olùkọ́ rẹ̀ mọ ìṣirò jù ú lọ fíìfíì. Dájúdájú, kò yẹ kó gba àbájáde yìí gbọ́! Ṣùgbọ́n ó wá ń rò ó nínú ara rẹ̀ pé, ‘kò pọndandan pé ki n làdí rẹ̀ pé kì í ṣe òótọ́. Làákàyè sọ fún mi pé èyí kò nítumọ̀.’ (Òwe 14:15, 18) Ó mọ̀ pé olùkọ́ òun tàbí èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ kíláàsì òun kò lè fi dọ́là méjì ṣe pàṣípààrọ̀ ẹyọ kan!

Bí àkókò ti ń lọ, akẹ́kọ̀ọ́ ìṣirò náà wá rí ìkùnà tó wà nínú ìṣirò ọ̀hún. Ní ti tòótọ́, ìrírí náà kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ìyẹn ni pé nígbà tí ẹnì kán tó ní ìmọ̀ jù wá lọ bá dọ́gbọ́n sọ ọ̀rọ̀ kan tó rúni lójú, tó sì dà bí èyí tí kò ṣeé ta kò, kò yẹ kí ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gba èrò tí kò bọ́gbọ́n mu gbọ́ kìkì nítorí pé kò lè já ọ̀rọ̀ náà ni koro lákòókò yẹn. Ní ti gidi, akẹ́kọ̀ọ́ náà tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì kan tó ṣeé mú lò, èyí tó wà nínú 1 Jòhánù 4:1 pé kí a má ṣe yára láti gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, kódà nígbà tó bá dà bíi pé ó wá láti orísun kan tí kò ṣeé jà níyàn.

Èyí kò wá túmọ̀ sí pé o gbọ́dọ̀ fi agídí rọ̀ mọ́ èrò tóo ti ní tẹ́lẹ̀. Àṣìṣe ló jẹ́ láti kọtí dídi sí àwọn ìsọfúnni tó lè tún èrò tí kò tọ̀nà ṣe. Àmọ́ kì í wá ṣe pé kóo “tètè mì kúrò nínú ìmọnúúrò” rẹ nígbà tí ẹnì kan tó sọ pé òun ní ìmọ̀ tàbí ọlá àṣẹ jù ọ́ lọ bá kó ọ̀rọ̀ bò ọ́. (2 Tẹsalóníkà 2:2) Ó dájú pé olùkọ́ náà wulẹ̀ ń ṣe awúrúju fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ni. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìgbà mìíràn wà tó jẹ́ pé àwọn nǹkan kì í rí bó ṣe yẹ kó rí. Àwọn èèyàn lè ṣe “àlùmọ̀kọ́rọ́yí nínú dídọ́gbọ́n hùmọ̀ ìṣìnà” lọ́nà tó lé kenkà.—Éfésù 4:14; 2 Tímótì 2:14, 23, 24.

Ṣe Gbogbo Ìgbà Làwọn Ògbógi Máa Ń Tọ̀nà?

Bó ti wù kí wọ́n ní ìmọ̀ tó, àwọn ògbógi nínú ẹ̀ka ẹ̀kọ́ èyíkéyìí lè ní àwọn èrò tó forí gbárí àti àwọn ìpinnu tí kò dúró sójú kan. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn iyàn jíjà tó ń lọ lọ́wọ́ nínú ìmọ̀ ìṣègùn yẹ̀ wò, èyí tó dá lórí àwọn ohun tó ń fa àìsàn. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ìmọ̀ ìṣègùn ní Yunifásítì Harvard kọ̀wé pé: “Ipa tí ìṣẹ̀dá àti àyíká rẹ̀ kó nínú ọ̀ràn àìsàn ni kókó tó fa ìjiyàn líle koko tó ń lọ láàárín àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì.” Àwọn tí wọ́n ní èrò pé a ti pinnu ìgbésẹ̀ ẹ̀dá látilẹ̀ gbà gbọ́ gidigidi pé apilẹ̀ àbùdá wa ló fà á ti onírúurú àìsàn fi ń ṣe wá. Àmọ́ àwọn mìíràn gbà pé àyíká àti ọ̀nà tí a ń gbà gbé ìgbésí ayé jẹ́ kókó pàtàkì nínú ìlera ènìyàn. Àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì ló tọ́ka sí ìwádìí àti àwọn àkọsílẹ̀ tó ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀ràn iyàn jíjà náà kò tíì parí.

Léraléra la ti já àwọn táa gbà pé wọ́n mọnúúrò jù lọ ní koro, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n fi kọ́ni dà bí èyí tó kọjá ohun táa lè jiyàn rẹ̀ lákòókò yẹn. Bertrand Russell, tí í ṣe onímọ̀ ọgbọ́n orí, ṣàpèjúwe Aristotle gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára “àwọn tó jẹ́ akọni jù lọ nínú gbogbo onímọ̀ ọgbọ́n orí.” Síbẹ̀ Russell tún là á mọ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ lára ẹ̀kọ́ Aristotle ló jẹ́ “irọ́ paraku.” Ó kọ̀wé pé: “Lóde òní, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìlọsíwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, nínú ohun tó bọ́gbọ́n mu, tàbí nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí ló ti yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Aristotle sọ.”—History of Western Philosophy.

“Ohun Tí A Fi Èké Pè Ní ‘Ìmọ̀’”

Ó ṣeé ṣe kí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ bá ọ̀pọ̀ lára àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì, bíi Socrates, Plato, àti Aristotle pàdé. Àwọn tó kàwé lákòókò yẹn ka ara wọn sí ẹni tó lóye ju ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni lọ. Wọn kò ka ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sí “ọlọ́gbọ́n nípa ti ara.” (1 Kọ́ríńtì 1:26) Àní sẹ́, èrò àwọn tó ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí lákòókò yẹn ni pé ohun tí àwọn Kristẹni gbà gbọ́ wulẹ̀ jẹ́ “ọ̀rọ̀ òmùgọ̀” tàbí “ìranù lásánlàsàn.”—1 Kọ́ríńtì 1:23; Phillips.

Ká ní o wà lára àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn, ṣé àwọn àríyànjiyàn tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú olóye fi ń yíni lérò padà láyé ìgbà yẹn ì bá ti mórí rẹ wú tàbí ṣé bí wọ́n ṣe ń fi ọgbọ́n tí wọ́n ní yangàn ì bá ti dẹ́rù bà ọ́? (Kólósè 2:4) Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí, ì bá má ti sí ìdí kankan fún ìyẹn láti ṣẹlẹ̀. Ó rán àwọn Kristẹni létí pé Jèhófà wo “ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n” àti “làákàyè àwọn amòye” ayé ìgbà yẹn bí ìwà òmùgọ̀. (1 Kọ́ríńtì 1:19) Ó béèrè pé: “Kí ni àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí, àwọn òǹkọ̀wé àti àwọn olùṣelámèyítọ́ ayé yìí lè sọ pé àwọn fi gbogbo ọgbọ́n àwọn ṣe?” (1 Kọ́ríńtì 1:20, Phillips) Pẹ̀lú gbogbo ìgbọ́nṣámúṣámú àwọn amòye, àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí, àwọn òǹkọ̀wé, àti àwọn olùṣelámèyítọ́ ọjọ́ ayé Pọ́ọ̀lù, wọn kò rí ojútùú gidi sí àwọn ìṣòro ìràn ènìyàn.

Nítorí ìdí èyí, àwọn Kristẹni kẹ́kọ̀ọ́ láti yẹra fún ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ó jẹ́ “àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’” (1 Tímótì 6:20) Ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi pe irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ní ‘èké’ ni pé kò ní ohun pàtàkì kan nínú—ìyẹn ni orísun tàbí ìtọ́ka láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, èyí tí wọ́n lè fi dán àbá èrò orí wọn wò. (Jóòbù 28:12; Òwe 1:7) Níwọ̀n bí wọn kò ti ní ohun pàtàkì yẹn, tí olórí ẹlẹ́tàn ni, Sátánì sì tún fọ́ wọn lójú lákòókò kan náà, àwọn tó rọ̀ mọ́ irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ kò lè retí pé àwọn óò rí òtítọ́ láé.—1 Kọ́ríńtì 2:6-8, 14; 3:18-20; 2 Kọ́ríńtì 4:4; 11:14; Ìṣípayá 12:9.

Bíbélì—Amọ̀nà Tí A Mí Sí

Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò ṣiyèméjì rárá pé Ọlọ́run ti ṣí ìfẹ́ rẹ̀, ète rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ payá nínú Ìwé Mímọ́. (2 Tímótì 3:16, 17) Èyí dáàbò bò wọ́n kúrò nínú dídi ẹni tí a ‘gbé lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn.’ (Kólósè 2:8) Bákan náà ni ipò nǹkan ṣe rí lónìí. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ìdàrúdàpọ̀ àti ìforígbárí tó wà nínú èrò ènìyàn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a mí sí fúnni ní ìpìlẹ̀ tó lágbára lórí èyí tí a lè gbé ìgbàgbọ́ wa kà. (Jòhánù 17:17; 1 Tẹsalóníkà 2:13; 2 Pétérù 1:21) Tí kì í bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ rẹ̀ ni, ńṣe là bá ṣì wà nínú ipò kan tó ṣòro, táa ti ń làkàkà láti kọ́lé sórí yanrìn tí í ṣe àbá èrò orí àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn ènìyàn.—Mátíù 7:24-27.

Ẹnì kan lè sọ pé, ‘Àmọ́, dúró ná o. Ṣé àwọn àṣeyọrí sáyẹ́ǹsì kò fi hàn pé Bíbélì kùnà, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ìwé kan tí kò ṣeé gbára lé bíi ti ìmọ̀ ọgbọ́n orí ẹ̀dá ènìyàn tí kì í dúró sójú kan?’ Fún àpẹẹrẹ, Bertrand Russell sọ pé: “Ńṣe ni Copernicus, Kepler, àti Galileo gbéjà ko Aristotle àti Bíbélì kí wọ́n tó lè fìdí èròǹgbà náà múlẹ̀ pé kì í ṣe agbedeméjì àgbáálá ayé ni ayé wà.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Àti pé, fún àpẹẹrẹ, ṣé kì í ṣe òótọ́ ni àwọn tó gbà gbọ́ nínú ìṣẹ̀dà rin kinkin pé Bíbélì kọ́ wa pé a dá ayé ní ọjọ́ mẹ́fà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ jẹ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún, nígbà tí gbogbo òkodoro òtítọ́ sì fi hàn pé ayé fúnra rẹ̀ ti wà fún àìmọye bílíọ̀nù ọdún?

Ní ti gidi, Bíbélì kò sọ pé agbedeméjì àgbáálá ayé ni ayé wà. Ẹ̀kọ́ tí àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì fi kọ́ni nìyẹn, tó sì jẹ́ pé àwọn fúnra wọn kò tẹ̀ lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì nípa ìṣẹ̀dá fi hàn pé ayé ti wà fún àìmọye bílíọ̀nù ọdún, kò sì fi ọjọ́ ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan mọ sórí wákàtí mẹ́rìnlélógún. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1, 5, 8, 13, 19, 23, 31; 2:3, 4) Àyẹ̀wò kan táa ṣe nípa Bíbélì láìṣàbòsí fi hàn pé bí kì í tilẹ̀ ṣe ìwé sáyẹ́ǹsì, ó dájú pé kì í ṣe “ìranù lásánlàsàn.” Ká sọ tòótọ́, ó bá sáyẹ́ǹsì tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mu rẹ́gí. a

“Agbára Ìmọnúúrò”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni kì í ṣe èèyàn ńlá, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọn kò kàwé púpọ̀, síbẹ̀ wọ́n ní ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye mìíràn tí Ọlọ́run fún wọn. Láìka ipò àtilẹ̀wá wọn sí, gbogbo wọn ló ní agbára ìmọnúúrò àti agbára ìrònú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú láti lo “agbára ìmọnúúrò” wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, kí wọ́n lè “ṣàwárí fúnra [wọn] ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—Róòmù 12:1, 2.

Pẹ̀lú “agbára ìmọnúúrò” tí Ọlọ́run fún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, wọ́n rí i kedere pé ìmọ̀ ọgbọ́n orí èyíkéyìí tàbí ẹ̀kọ́ tí kò bá wà ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣí payá jẹ́ èyí tí kò ní láárí. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn ọlọ́gbọ́n ìgbà ayé wọn ń “tẹ òtítọ́ rì” ní ti gidi, wọ́n sì kọ gbogbo ẹ̀rí tó yí wọn ká pé Ọlọ́run kan wà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, wọ́n ya òmùgọ̀.” Nítorí pé wọ́n kọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti ète rẹ̀ sílẹ̀, “wọ́n di olórí òfìfo nínú èrò wọn, ọkàn-àyà wọn tí kò mòye sì di èyí tí ó ṣókùnkùn.”—Róòmù 1:18-22; Jeremáyà 8:8, 9.

Àwọn tó ń tẹnu mọ́ ọn pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n sábà máa ń ní irú ìrònú bíi “Kò sí Ọlọ́run” tàbí “Kò yẹ kí a gbọ́kàn lé Bíbélì” tàbí “‘Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn’ kọ́ nìwọ̀nyí.” Irú èrò wọ̀nyẹn jẹ́ ti òmùgọ̀ pátápátá lójú Ọlọ́run bíi kéèyàn parí èrò sí pé “eéjì jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú oókan.” (1 Kọ́ríńtì 3:19) Ọlá àṣẹ yòówù táwọn èèyàn lè sọ pé àwọn ní, kì í ṣe dandan láti fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ, tí wọ́n bá ta ko Ọlọ́run, tí wọ́n kọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, tí wọn ò sì ní làákàyè. Ní òpin gbogbo rẹ̀, ipa ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé nígbà gbogbo, kí á máa “jẹ́ kí a rí Ọlọ́run ní olóòótọ́, bí a tilẹ̀ rí olúkúlùkù ènìyàn ní òpùrọ́.”—Róòmù 3:4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, wo ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s? àti Is There a Creator Who Cares About You?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èrò àwọn ènìyàn tí kì í dúró sójú kan, Bíbélì pèsè ìpìlẹ̀ tó lágbára tí a lè gbé ìgbàgbọ́ wa kà

[Àwọn Credit Line]

Lápá òsì, Epicurus: Fọ́tò táa yà nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure British Museum; òkè láàárín, Plato: Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀m̀báyé Awalẹ̀pìtàn Sí ti Orílẹ̀-Èdè Gíríìsì ní Áténì; lápá ọ̀tún, Socrates: Roma, Musei Capitolini