Bíbélì—Wọ́n Gbé E Gẹ̀gẹ̀, Wọ́n Tún Tẹ̀ Ẹ́ Rì
Bíbélì—Wọ́n Gbé E Gẹ̀gẹ̀, Wọ́n Tún Tẹ̀ Ẹ́ Rì
Desiderius Erasmus, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ará Netherlands, tí wọ́n ń kan sáárá sí ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, kọ̀wé pé: “Èmi yóò fẹ́ kí a túmọ̀ àwọn ìwé ọlọ́wọ̀ náà sí gbogbo èdè.”
OHUN tí Erasmus fẹ́ ni pé kí gbogbo ènìyàn lè rí Ìwé Mímọ́ kà, kí wọ́n sì lóyè rẹ̀. Àmọ́, àwọn tó lòdì sí Bíbélì kò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ irú èrò bẹ́ẹ̀ sétí rárá. Àní, ibi eléwu gan-an ni Yúróòpù jẹ́ lákòókò yẹn fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ tọpinpin àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì bó ti wù kó mọ. Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìgbìmọ̀ aṣòfin gbé òfin kan kalẹ̀ tó pa á láṣẹ pé “ilẹ̀, aásìkí, dúkìá, àti ẹ̀mí ẹnikẹ́ni tó bá ka Ìwé Mímọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì gbọ́dọ̀ lọ sí i . . . àti pé, bí wọ́n bá ń ṣorí kunkun tàbí tí wọ́n bá tún ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn táa bá dárí jì wọ́n, a ó yẹgi fún wọn nítorí àìṣòdodo sí ọba, lẹ́yìn náà la ó dáná sun wọ́n nítorí ṣíṣe àdámọ̀ lòdì sí Ọlọ́run.”
Láàárín ilẹ̀ Yúróòpù ni àwọn Kátólíìkì Tó Ń Ṣe Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ ti ń wá àwọn ẹ̀ya ìsìn “aládàámọ̀” níwàákúwàá, irú bí Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ti Faransé, tí wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wọn nítorí pé wọ́n ń wàásù “láti inú àwọn ìwé Ìhìn Rere, àti àwọn ẹ̀písítélì àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn . . . níwọ̀n bí wọ́n ti ka wíwàásù àti kíka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ léèwọ̀ fún àwọn gbáàtúù.” Àìmọye àwọn ọkùnrin àtobìnrin ni wọ́n dá lóró lọ́nà tó burú jáì, tí wọ́n sì pa wọ́n nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Bíbélì. Wọ́n fẹ̀mí ara wọn wewu gan-an kìkì nítorí pé wọ́n fẹ́ ka Àdúrà Olúwa tàbí Òfin
Mẹ́wàá, kí wọ́n sì fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.Irú ìfọkànsìn bẹ́ẹ̀ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣì wà nínú ọkàn-àyà àwọn arìnrìn-àjò onísìn tí wọ́n tukọ̀ ojú omi kọjá láti lọ máa gbé Àríwá Amẹ́ríkà. Ìwé náà, A History of Private Life—Passions of the Renaissance, sọ pé, ní Amẹ́ríkà ìgbàanì, “kíka ìwé àti ẹ̀sìn so pọ̀ mọ́ra pẹ́kípẹ́kí, èyí sì ń túmọ̀ àṣà kan táa gbé karí dídi ojúlùmọ̀ Bíbélì láìkù síbì kan.” Àní ṣẹ́, ìwàásù kan tí wọ́n tẹ̀ sínú ìwé ìròyìn Boston ní 1767 dámọ̀ràn pé: “Máa ka Ìwé Mímọ́ taápọntaápọn. O gbọ́dọ̀ máa ka orí kan nínú Bíbélì rẹ láràárọ̀ àti ní alaalẹ́.”
Gẹ́gẹ́ bí Ẹgbẹ́ Olùwádìí ti Barna ní Ventura, California ti sọ, ní ìpíndọ́gba, ó lé ní ìpín àádọ́rùn-ún nínú àwọn ará Amẹ́ríkà tó ní Bíbélì mẹ́ta. Àmọ́ ṣá o, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì ń gbé Bíbélì gẹ̀gẹ̀ níbẹ̀, “wíwá àyè láti kà á, láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, àti láti fi ohun tí wọ́n kà sílò . . . ti di ohun àtijọ́.” Ọ̀pọ̀ jù lọ ni kò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ mọ ohun tó wà nínú rẹ̀ mọ́. Akọ̀ròyìn kan sọ pé: “Èrò pé [Bíbélì] ṣì lè ní ojútùú kíákíá sí àwọn ìṣòro lọ́ọ́lọ́ọ́ àti àwọn àníyàn kò fi bẹ́ẹ̀ sí mọ́.”
Ìrònú Ayé Ń Lọ Síwá Sẹ́yìn
Ohun kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ ni pé kìkì tí a bá mọ bí a ṣe ń ronú tí a sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn la lè ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé. Wọ́n ń wo Bíbélì bí ọ̀kan lára àwọn ìwé táwọn èèyàn wulẹ̀ kọ láti ṣàlàyé èrò wọn nípa ìsìn àti àwọn ìrírí ara wọn, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tó ṣe kókó tó sì jẹ́ òtítọ́.
Nípa bẹ́ẹ̀, báwo làwọn èèyàn ṣe ń kojú àwọn ìṣòrò lílọ́júpọ̀, tó ń kó wọ́n sí wàhálà nínú ìgbésí ayé? Kò sí ohun tẹ̀mí kankan nínú ìgbésí ayé wọn, láìsí ọ̀rọ̀ nípa ìwà rere tàbí ìsìn tó ń tọ́ wọ́n sọ́nà, tó sì ń darí wọ́n. Wọ́n ti dà bí àwọn ọkọ̀ òkun tí kò ní ìtọ́kọ̀, “tí a ń gbé síwá sẹ́yìn, tí a sì ń tipasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ àwọn ènìyàn fẹ́ káàkiri, . . . nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àti àlùmọ̀kọ́rọ́yí àwọn ènìyàn.”—Éfésù 4:14, The Twentieth Century New Testament.
Nígbà náà, ó yẹ ká béèrè pé, Ṣé ìwé ìsìn kan lásán ni Bíbélì ni? Àbí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní àwọn ìsọfúnni tó wúlò tó sì gbéṣẹ́ ni lóòótọ́? (2 Tímótì 3:16, 17) Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ ká gbé Bíbélì yẹ̀ wò? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Desiderius Erasmus
[Credit Line]
Láti inú ìwé Deutsche Kulturgeschichte
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn Waldo nítorí pé wọ́n ń wàásù ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́
[Credit Line]
Stichting Atlas van Stolk, Rotterdam