Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ń fi Agbára Fún Ẹni Tó Ti Rẹ̀

Jèhófà Ń fi Agbára Fún Ẹni Tó Ti Rẹ̀

Jèhófà Ń fi Agbára Fún Ẹni Tó Ti Rẹ̀

“[Jèhófà] ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga.”—AÍSÁYÀ 40:29.

1. Ṣàpèjúwe bí agbára tó wà nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá ti pọ̀ tó.

 AGBÁRA Jèhófà kò ní ààlà. Agbára ńlá tó wà nínú àwọn ohun tó dá sì kọjá àfẹnusọ! Àwọn ohun tín-tìn-tín—tí wọ́n jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún ohun gbogbo tó kù—kéré tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ẹ̀kán omi kan ṣoṣo péré fi ní bílíọ̀nù lọ́nà bílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún àwọn ohun tín-tìn-tín nínú. a Orí agbára tí oòrùn ń pèsè ni gbogbo ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé wa sinmi lé. Ṣùgbọ́n báwo ni agbára oòrùn táa nílò kí ìgbésí ayé lórí ilẹ̀ ayé lè máa bá a nìṣó ṣe pọ̀ tó? Ohun tí ilẹ̀ ayé ń gbà lára agbára tí oòrùn ń pèsè kéré jọjọ. Síbẹ̀síbẹ̀, ìwọ̀nba bíńtín tó ń bọ́ sórí ilẹ̀ ayé lára agbára oòrùn ju gbogbo agbára tí wọ́n ń lò ní gbogbo ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ lágbàáyé lọ fí ìfí ì.

2. Ní pàtàkì jù lọ, kí ni Aísáyà 40:26 ń sọ nípa agbára Jèhófà?

2 Ì bàá jẹ́ àwọn nǹkan akéréjojú la ń ronú nípa rẹ̀ ni o, ì báà sì jẹ́ àgbáálá ayé tó lọ salalu la yí àfiyèsí wa sí, ńṣe ni ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ agbára Jèhófà ń mú kórí wa wú. Abájọ tó fi lè sọ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí”! (Aísáyà 40:26) Dájúdájú, Jèhófà ní ‘agbára ńlá,’ òun tún ni Orísun ‘okun alágbára ńlá’ èyí tó mú kí gbogbo àgbáálá ayé wà.

A Nílò Agbára Tó Ju Ti Ẹ̀dá Lọ

3, 4. (a) Àwọn ohun díẹ̀ wo ló lè káàárẹ̀ bá wa? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?

3 Nígbà tó jẹ́ pé agbára tí Ọlọ́run ní kò láàlà, ó máa ń rẹ àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Ibi yòówù ká yíjú sí, a máa ń rí àwọn èèyàn ti àárẹ̀ ti mú. Wọ́n á bá àárẹ̀ ara jí, àárẹ̀ ara náà ni wọ́n á gbé lọ síbi iṣẹ́ tàbí lọ síléèwé, á tún ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu nígbà tí wọ́n á bá fi délé, kì í wá ṣe pé ó ń rẹ̀ wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń lọ sùn nìkan ni, ṣùgbọ́n kì í sókun mọ́ lára wọn pẹ̀lú. Ó ń ṣe àwọn kan bíi kí wọ́n ríbi gbà lọ, kí wọ́n sì lọ fún ara wọn ní ìsinmi tó nílò lójú méjèèjì. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, ó máa ń rẹ àwa náà, níwọ̀n bí ìgbésí ayé ìfọkànsin Ọlọ́run táa ń gbé ti ń béèrè pé ká lo ara wa tokuntokun. (Máàkù 6:30, 31; Lúùkù 13:24; 1 Tímótì 4:8) Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan míì ló sì tún wà tó ń tán wa lókun.

4 Bí a tilẹ̀ jẹ́ Kristẹni, àwọn ìṣòro tí gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ń ní kò yọ wá sílẹ̀. (Jóòbù 14:1) Ìṣòro àìsàn, àìrówóná, tàbí àwọn ìṣòro mìíràn tó tún wọ́pọ̀ nínú ìgbésí ayé lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, pẹ̀lú ipò ìbànújẹ́ tó máa ń bá a rìn. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn, àwọn kan tún ń kojú àdánwò tó máa ń bá àwọn tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo. (2 Tímótì 3:12; 1 Pétérù 3:14) Nítorí àwọn wàhálà tó ń báni nínú ayé lójoojúmọ́ àti àtakò sí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba tí a ń ṣe, àárẹ̀ lè mú àwọn díẹ̀ lára wa débi tó lè dà bíi pé ká dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Síwájú sí i, bí Sátánì Èṣù ti ń sapá láti ba ìwà títọ́ wa sí Ọlọ́run jẹ́, gbogbo ohun tó ní lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ̀ ló ń lò. Nígbà náà, báwo la ṣe lè rí okun tẹ̀mí táa nílò gbà tí àárẹ̀ kò fi ní mú wa pátápátá, ká sì jáwọ́?

5. Èé ṣe táa fi nílò ohun tó ju okun ti ẹ̀dá ènìyàn láti lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa?

5 Láti lè ní okun tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ gbára lé Jèhófà, Ẹlẹ́dàá alágbára gbogbo. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù là á mọ́lẹ̀ pé a óò nílò agbára tó ré kọjá ti ẹ̀dá ènìyàn aláìpé láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Ó kọ̀wé pé: “Àwa ní ìṣúra yìí nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe, kí agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń ṣe “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́,” àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tí wọ́n ní ìrètí ti ilẹ̀ ayé sì ń kọ́wọ́ tì wọ́n lẹ́yìn. (2 Kọ́ríńtì 5:18; Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 7:9) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lójú inúnibíni làwa ẹ̀dá ènìyàn aláìpé ti ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, a ò lè ṣe é kìkì nínú okun tiwa nìkan. Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, nípa bẹ́ẹ̀, àìlera wa ń fi bí agbára rẹ̀ ṣe pọ̀ tó hàn. Ẹ tún wo bí a ti tù wá nínú tó pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìdánilójú náà pé: “Jèhófà yóò máa ti àwọn olódodo lẹ́yìn”!—Sáàmù 37:17.

‘Jèhófà Ni Ìmí Wa’

6. Ọ̀nà wo ni Ìwé Mímọ́ gbà mú un dá wa lójú pé Jèhófà ni Orísun okun wa?

6 Baba wa ọ̀run ní ‘agbára ńlá,’ ó sì rọrùn fún un láti fi okun kún okun wa. Àní, a sọ fún wa pé: “[Jèhófà] ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga. Àárẹ̀ yóò mú àwọn ọmọdékùnrin, agara yóò sì dá wọn, àwọn ọ̀dọ́kùnrin pàápàá yóò sì kọsẹ̀ dájúdájú, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà. Wọn yóò fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì. Wọn yóò sáré, agara kì yóò sì dá wọn; wọn yóò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.” (Aísáyà 40:29-31) Nítorí wàhálà tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i, nígbà míì, a lè nímọ̀lára bíi ti sárésáré kan tó ti rẹ̀ tẹnutẹnu, táwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dà bí ẹni pé wọn ò lè sáré mọ́. Àmọ́, òpin eré ìje fún ìyè náà kò jìnnà mọ́, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, a ò sì gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀. (2 Kíróníkà 29:11) Elénìní wa náà, Èṣù, ń rìn káàkiri “bíi kìnnìún tí ń ké ramúramù,” ó fẹ́ ká jáwọ́. (1 Pétérù 5:8) Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ‘Jèhófà ni okun wa àti apata wa,’ ó sì ti pèsè àwọn nǹkan lọ́pọ̀ yanturu ‘láti fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀.’—Sáàmù 28:7.

7, 8. Àwọn ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jèhófà fún Dáfídì, Hábákúkù, àti Pọ́ọ̀lù lókun?

7 Jèhófà fún Dáfídì ní okun tó nílò láti máa bá a lọ lójú àwọn ìṣòro títóbi. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kíkún àti ìgbọ́kànlé, Dáfídì wá kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa yóò jèrè ìmí, òun fúnra rẹ̀ yóò sì tẹ àwọn elénìní wa mọ́lẹ̀.” (Sáàmù 60:12) Jèhófà tún fún Hábákúkù pẹ̀lú ní okun kí ó lè parí iṣẹ́ táa yàn fún un gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. Hábákúkù 3:19 sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni ìmí mi; yóò sì ṣe ẹsẹ̀ mi bí ti àwọn egbin, yóò sì mú kí n rìn ní àwọn ibi gíga mi.” Àpẹẹrẹ ti Pọ́ọ̀lù tún yẹ fún àfiyèsí wa, ẹni tó kọ̀wé pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye [Ọlọ́run] ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13.

8 Gẹ́gẹ́ bíi Dáfídì, Hábákúkù, àti Pọ́ọ̀lù, àwa náà gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run láti fún wa ní okun, àti nínú agbára rẹ̀ láti gbà wá là. Nígbà táa ti mọ̀ pé Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ ni Orísun “ìmí” wa, ẹ jẹ́ ká wá gbé àwọn ọ̀nà díẹ̀ yẹ̀ wò, táa ti lè gba okun tẹ̀mí látinú ọ̀pọ̀ yanturu ìpèsè tó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

Àwọn Ìpèsè Tẹ̀mí Láti Fi Okun Kún Okun Wa

9. Ipa wo ni àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni ń kó nínú fífún wa lókun?

9 Fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni lè fi okun kún okun wa, kó sì mú wa dúró. Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn . . . tí inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” (Sáàmù 1:1-3) Bó ṣe jẹ́ pé dandan ni pé ká jẹun ká lè ní okun tara, a gbọ́dọ̀ máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí Ọlọ́run ń pèsè nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni, ká lè máa ní okun tẹ̀mí. Nítorí náà, ó pọn dandan ká máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tó nítumọ̀ ká sì máa ṣàṣàrò.

10. Ìgbà wo la lè rí àyè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò?

10 Láìsí àní-àní, ṣíṣàṣàrò lórí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” ń mú èrè wá. (1 Kọ́ríńtì 2:10) Àmọ́, ìgbà wo la lè rí àyè fún ṣíṣàṣàrò? Ísákì, ọmọkùnrin Ábúráhámù “ń rìn níta kí ó lè ṣe àṣàrò nínú pápá nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ ní ìrọ̀lẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 24:63-67) Onísáàmù náà, Dáfídì, “ṣe àṣàrò nípa [Ọlọ́run] ní àwọn ìṣọ́ òru.” (Sáàmù 63:6) A lè kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì tún ṣàṣàrò lórí rẹ̀ ní òwúrọ̀, ní ìrọ̀lẹ́, ní alẹ́—àní, nígbàkigbà. Irú ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí nǹkan mìíràn tí Jèhófà pèsè tó ń fúnni lókun nípa tẹ̀mí—ìyẹn ni àdúrà.

11. Èé ṣe tó fi yẹ kí á ka gbígbàdúrà déédéé sí nǹkan tó ṣe pàtàkì gan-an?

11 Gbígbàdúrà sí Ọlọ́run déédéé máa ń fi okun kún okun wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká “máa ní ìforítì nínú àdúrà.” (Róòmù 12:12) Nígbà míì, ó pọndandan pé ká béèrè ní pàtó, fún ọgbọ́n àti okun táa nílò láti kojú àdánwò kan. (Jákọ́bù 1:5-8) Ẹ jẹ́ ká tún máa dúpẹ́ ká sì máa yin Ọlọ́run nígbà táa bá rí i tí àwọn ète rẹ̀ ń ní ìmúṣẹ tàbí táa rí i pé ó ti fún wa lágbára láti máa bá a lọ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Fílípì 4:6, 7) Bí a bá ń sún mọ́ Jèhófà dáadáa nínú àdúrà, kò ní fi wá sílẹ̀ láé. Dáfídì kọrin pé: “Wò ó! Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi.”—Sáàmù 54:4.

12. Èé ṣe tó fi yẹ ká bẹ Ọlọ́run pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀?

12 Baba wa ọ̀run máa ń fi okun kún okun wa ó sì máa ń fún wa lágbára nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo tẹ eékún mi ba fún Baba . . . kí ó bàa lè yọ̀ǹda fún yín ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọrọ̀ ògo rẹ̀ kí a lè sọ yín di alágbára ńlá nínú ẹni tí ẹ jẹ́ ní inú pẹ̀lú agbára nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀.” (Éfésù 3:14-16) A gbọ́dọ̀ gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́, ká sì fọkàn balẹ̀ pé Jèhófà yóò bù kún wa pẹ̀lú rẹ̀. Jésù wòye pé: Bí ọmọ kan bá béèrè ẹja, ǹjẹ́ bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ lè gbé ejò lé e lọ́wọ́? Kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ó kádìí rẹ̀ pé: “Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ [ẹlẹ́ṣẹ̀ tẹ́ ẹ sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́] ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:11-13) Ẹ jẹ́ ká ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé yẹn báa ti ń gbàdúrà, ká sì máa rántí nígbà gbogbo pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run olóòótọ́ ni a lè ‘sọ di alágbára ńlá’ nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀.

Ìjọ Jẹ́ Àrànṣe Kan Tí Ń Fúnni Lókun

13. Ojú wo ló yẹ ká fi máa wo àwọn ìpàdé Kristẹni?

13 Jèhófà ń fi okun kún okun wa nípasẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ Kristẹni. Jésù wí pé: “Níbi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọpọ̀ sí ní orúkọ mi, èmi wà níbẹ̀ láàárín wọn.” (Mátíù 18:20) Nígbà tí Jésù ṣèlérí yẹn, àwọn ọ̀ràn kan tó nílò àfiyèsí àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ ló ń jíròrò lọ́wọ́. (Mátíù 18:15-19) Àmọ́ o, àwọn ìlànà tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹn ṣe é fi sílò nínú àwọn ìpàdé wa, àwọn àpéjọ, àti àpéjọpọ̀ wa tó jẹ́ pé àdúrà ní orúkọ rẹ̀ la fi máa ń bẹ̀rẹ̀ wọn táa sì fi máa ń kádìí wọn. (Jòhánù 14:14) Nítorí náà, àǹfààní ló jẹ́ o, láti pésẹ̀ sírú ibi táwọn Kristẹni ti ń kóra jọ bẹ́ẹ̀, yálà àwọn díẹ̀ ló wà níbẹ̀ tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló pésẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fi ìmoore hàn fún àwọn ohun táa ṣètò yìí láti fún wa lókun nípa tẹ̀mí àti láti ru wá sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.—Hébérù 10:24, 25.

14. Àwọn àǹfààní wo la ń rí gbà látinú ìsapá àwọn Kristẹni alàgbà?

14 Àwọn Kristẹni alàgbà ń pèsè ìrànwọ́ tẹ̀mí àti ìṣírí. (1 Pétérù 5:2, 3) Pọ́ọ̀lù ran àwọn ìjọ tó bẹ̀ wò lọ́wọ́ ó sì tún fún wọn níṣìírí, gẹ́gẹ́ bí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ti ń ṣe lónìí. Kódà, ńṣe ló máa ń yánhànhàn láti wà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, kí wọ́n lè ṣe pàṣípààrọ̀ ìṣírí tí ń gbéni ró. (Ìṣe 14:19-22; Róòmù 1:11, 12) Ẹ jẹ́ ká máa fi ìmọrírì hàn fún àwọn alàgbà ìjọ wa àtàwọn Kristẹni alábòójútó mìíràn, tí wọ́n ń kópa tó jọjú nínú fífún wa lókun tẹ̀mí.

15. Ọ̀nà wo ni àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nínú ìjọ gbà jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún wa?

15 Àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n para pọ̀ di ìjọ wa náà tún lè jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún wa. (Kólósè 4:10, 11) Gẹ́gẹ́ bí “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́,” wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ lásìkò wàhálà. (Òwe 17:17) Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n kó okòó lé rúgba [220] àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run jáde nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen lábẹ́ ìjọba Násì ní 1945, wọ́n ní láti fẹsẹ̀ rin igba kìlómítà. Wọ́n rìnrìn àjò náà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, àwọn tó lókun díẹ̀ wá ń fi kẹ̀kẹ́ ẹrù kéékèèké fa àwọn tí kò ní ìmí mọ́ rárá nínú wọn lọ. Kí ni àbájáde èyí? Kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó kú sínú ìrìn àjò àfẹsẹ̀rìn tó lè ṣekú pani yẹn, èyí tó gbẹ̀mí àwọn tó lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́wàá lára àwọn tí wọ́n jọ wà nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ náà. Irú àwọn àkọsílẹ̀ yìí, tó máa ń fara hàn nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower, títí kan inú àwọn Yearbook of Jehovah’s Witnesses àti ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ń fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀, kí wọ́n má baà juwọ́ sílẹ̀.—Gálátíà 6:9. b

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Ń Fún Wa Lókun

16. Ọ̀nà wo ni kíkópa déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ń gbà fún wa lókun nípa tẹ̀mí?

16 Kíkópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ń fún wa lókun nípa tẹ̀mí. Ńṣe ni irú àwọn ìgbòkègbodò yẹn máa ń jẹ́ ká kó àfiyèsí wa sórí Ìjọba Ọlọ́run, ó sì tún ń jẹ́ ká lè máa wo ìyè ayérayé àtàwọn ìbùkún rẹ̀ táa ń fojú sọ́nà fún níwájú. (Júúdà 20, 21) Àwọn ìlérí Ìwé Mímọ́ tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa máa ń fún wa nírètí, ó sì ń jẹ́ ká di ìpinnu wa mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bíi ti wòlíì Míkà, ẹni tó sọ pé: “Àwa . . . yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—Míkà 4:5.

17. Àwọn àbá wó la fún wa nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé?

17 Àjọṣe tiwa pẹ̀lú Jèhófà tún ń lágbára sí i bí a ti túbọ̀ ń lo Ìwé Mímọ́ láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà táa bá ń fi ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, ó bọ́gbọ́n mu ká ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi mélòó kan táa tọ́ka sí, ká sì jíròrò wọn. Ìyẹn á ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́, á sì tún mú kí òye tẹ̀mí túbọ̀ yé àwa náà sí i. Tó bá ṣòro fún akẹ́kọ̀ọ́ kan láti lóye kókó tàbí àpèjúwe kan nínú Bíbélì nígbà táa bá ń bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀, kò pọndandan kí a parí àkòrí kan lẹ́ẹ̀kan. Inú wa á mà dùn o, táa bá ń múra sílẹ̀ dáadáa táa sì túbọ̀ ń sapá láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run!

18. Ṣàpèjúwe bí a ti ń lo ìwé ìmọ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́.

18 Ọdọọdún la ń lo ìwé Ìmọ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ láti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ Jèhófà tó yara wọn sí mímọ́, èyí sì kan ọ̀pọ̀ tí kò tiẹ̀ ní ìmọ̀ kankan nípa Bíbélì tẹ́lẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ọkùnrin kan tó jẹ́ onísìn Híńdù ní Sri Lanka wà lọ́mọdé, ó gbọ́ tí Ẹlẹ́rìí kan ń sọ̀rọ̀ nípa Párádísè. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà ó lọ bá a, kò sì pẹ́ rárá tí ọkọ Ẹlẹ́rìí náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àní, ojoojúmọ́ ni ọ̀dọ́kùnrin yìí ń wá fún ìkẹ́kọ̀ọ́, kò sì pẹ́ rárá tí wọ́n fi parí ìwé Ìmọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí gbogbo ìpàdé, ó yọwọ́yọsẹ̀ nínú ìsìn rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó sì di akéde Ìjọba. Nígbà tó fi máa ṣe batisí, ó tí bẹ̀rẹ̀ sí í bá ojúlùmọ̀ rẹ̀ kan ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.

19. Bí a ti ń wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́, kí la lè ní ìdánilójú rẹ̀?

19 Wíwá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ túbọ̀ ń fi kún ayọ̀ wa. (Mátíù 6:33) Báa tilẹ̀ ń kojú onírúurú àdánwò, síbẹ̀ a ń bá a lọ láti máa fi tayọ̀tayọ̀ àti tìtaratìtara pòkìkí ìhìn rere náà. (Títù 2:14) Ọ̀pọ̀ lára wa ló ń dójú ìwọ̀n ohun tí a béèrè fún ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún, bẹ́ẹ̀ sì làwọn kan ń sìn níbi tí àìní fún àwọn oníwàásù ti pọ̀. Ì báà jẹ́ ní ọ̀nà yìí tàbí àwọn ọ̀nà mìíràn la ń gbà fi tayọ̀tayọ̀ gbárùkù ti ire Ìjọba náà, a ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà kò ní gbàgbé iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ táa fi hàn sí orúkọ rẹ̀.—Hébérù 6:10-12.

Máa Bá A Nìṣó Nínú Agbára Jèhófà

20. Báwo la ṣe lè fi hàn pé Jèhófà ni a ń wò fún okun?

20 Ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti fi hàn gbangba pé a nírètí nínú Jèhófà àti pé òun ni a ń wò fún okun wa. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa rírí i pé a ń lo àwọn ìpèsè tẹ̀mí náà lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, èyí tó ń fún wa nípasẹ̀ ‘ẹrú olóòótọ́’ náà. (Mátíù 24:45) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnra wa àti pẹ̀lú ìjọ nípa lílo àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni, àdúrà táa fi tọkàntọkàn gbà, ìrànwọ́ tẹ̀mí ti àwọn alàgbà, àpẹẹrẹ àtàtà ti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, àti lílọ́wọ́ déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wà lára àwọn ìpèsè tó ń fún àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà lókun, tó sì ń fún wa lágbára láti máa bá a lọ nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ rẹ̀.

21. Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fì hàn pé a nílò okun tí Ọlọ́run ń fi fúnni?

21 Láìka àìlera ẹ̀dá ènìyàn tí a ní sí, Jèhófà yóò fún wa lókun láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ bí a bá gbára lé e fún ìrànlọ́wọ́. Àpọ́sítélì Pétérù tó mọ̀ pé a nílò irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́, kí ó ṣe ìránṣẹ́ bí ẹni tí ó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń pèsè.” (1 Pétérù 4:11) Pọ́ọ̀lù sì tún fi hàn pé okun tí Ọlọ́run ń fi fúnni lòún gbára lé nígbà tó sọ pé: “Mo ní ìdùnnú nínú àwọn àìlera, nínú àwọn ìwọ̀sí, nínú àwọn ọ̀ràn àìní, nínú àwọn inúnibíni àti àwọn ìṣòro, fún Kristi. Nítorí nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́ríńtì 12:10) Ẹ jẹ́ kí àwa náà máa fi irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀ hàn, ká sì máa mú ògo wá fún Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ, ẹni tí ń fi agbára fún ẹni tó ti rẹ̀.—Aísáyà 12:2.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí a bá lo ìlànà tí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi ń ka nǹkan, iye yìí jẹ́ oókan tí a to ogún oódo sí lẹ́yìn.

b Ìwé tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Èé ṣe táwọn èèyàn Jèhófà fi nílò agbára tó ré kọjá ti ẹ̀dá?

• Àwọn ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ wo ló wà pé Ọlọ́run máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára?

• Àwọn ìpèsè tẹ̀mí wo ni Jèhófà ti ṣe láti fún wa lókun?

• Báwo la ṣe lè fi hàn pé Ọlọ́run la gbára lé láti pèsè okun fún wa?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà la túbọ̀ ń mú lágbára sí i báa ti ń fi Bíbélì kọ́ àwọn ẹlòmíràn