Ǹjẹ́ o Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Lọ́nà Tó Kọyọyọ?
Ǹjẹ́ o Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Lọ́nà Tó Kọyọyọ?
“Ọkàn mi ti pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́, mo sì nífẹ̀ẹ́ wọn lọ́nà tí ó peléke.”—SÁÀMÙ 119:167.
1. Ibo ní pàtàkì, la ti tọ́ka sí àwọn ìránnilétí Jèhófà léraléra?
JÈHÓFÀ fẹ́ káwọn ènìyàn òun jẹ́ aláyọ̀. Táa bá fẹ́ gbádùn ayọ̀ tòótọ́, ó dájú pé a gbọ́dọ̀ máa rìn nínú òfin Ọlọ́run ká sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Ká lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń fún wa ní àwọn ìránnilétí rẹ̀. Léraléra ni a mẹ́nu kàn wọ́n nínú Ìwé Mímọ́, àgàgà nínú Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà, èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Hesekáyà, ọ̀dọ́ Ọmọọba Júdà nì, ló kọ ọ́. Orin ẹlẹ́wà yẹn bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ yìí: “Aláyọ̀ ni àwọn aláìní-àléébù ní ọ̀nà wọn, àwọn tí ń rìn nínú òfin Jèhófà. Aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa àwọn ìránnilétí rẹ̀ mọ́; wọ́n ń fi gbogbo ọkàn-àyà wá a.”—Sáàmù 119:1, 2.
2. Báwo ni àwọn ìránnilétí Ọlọ́run ṣe tan mọ́ ayọ̀?
2 A ń ‘rìn nínú òfin Jèhófà’ nípa gbígba ìmọ̀ pípéye Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sínú àti nípa fífi í sílò nínú ìgbésí ayé wa. Àmọ́, níwọ̀n bí a ti jẹ́ aláìpé, a nílò àwọn ìránnilétí. Ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí a lò fún “ìránnilétí” túmọ̀ sí pé Ọlọ́run máa ń pe àwọn òfin, àṣẹ, àti ìlànà rẹ̀ padà sí wa lọ́kàn. (Mátíù 10:18-20) Àyàfi táa bá ń bá a lọ láti máa pa irú àwọn ìránnilétí bẹ́ẹ̀ mọ́ la fi lè jẹ́ aláyọ̀, nítorí ńṣe ni wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti yàgò fún jíjìn sínú ọ̀fìn tẹ̀mí, èyí tó ń yọrí sí àjálù àti ìbànújẹ́.
Rọ̀ Mọ́ Àwọn Ìránnilétí Jèhófà
3. Lórí ìpìlẹ̀ ohun tó wà ní Sáàmù 119:60, 61, ìgbọ́kànlé wo ni a ní?
3 Àwọn ìránnilétí Ọlọ́run ṣeyebíye sí onísáàmù náà, ẹni tó kọ ọ́ lórin pé: “Mo ṣe wéré, n kò sì jáfara láti pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́. Àní ìjàrá àwọn ẹni burúkú yí mi ká. Òfin rẹ ni èmi kò gbàgbé.” (Sáàmù 119:60, 61) Àwọn ìránnilétí Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da inúnibíni, nítorí a ní ìgbọ́kànlé pé Baba wa ọ̀run lè gé okùn ìdíwọ́ táwọn ọ̀tá ta yí wa ká. Nígbà tí àkókò bá sì tó lójú rẹ̀, ó ń yọ wá kúrò nínú àwọn ìṣòro yẹn, kí ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà.—Máàkù 13:10.
4. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa sí àwọn ìránnilétí Ọlọ́run?
4 Nígbà míì, àwọn ìránnilétí Jèhófà máa ń tún èrò wa ṣe. Ẹ jẹ́ ká máa mọrírì irú àwọn ìbáwí yẹn nígbà gbogbo, àní gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti ṣe. Ó fi tàdúràtàdúrà sọ fún Ọlọ́run pé: “Àwọn ìránnilétí rẹ ni mo ní ìfẹ́ni fún . . . Èmi nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí rẹ.” (Sáàmù 119:24, 119) A ní ọ̀pọ̀ ìránnilétí Ọlọ́run ju èyí tí onísáàmù ní lọ. Kì í ṣe àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n wà lábẹ́ Òfin nìkan ni ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn àyọkà látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì rán wa létí rẹ̀, àmọ́, ó tún rán wa létí àwọn ète rẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọ Kristẹni. Nígbà tí Ọlọ́run bá rí i pé ó yẹ láti rán wa létí àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn òfin rẹ̀, a máa ń kún fún ọpẹ́ fún irú àwọn ìdarí bẹ́ẹ̀. Bí a bá sì ń ‘rọ̀ mọ́ àwọn ìránnilétí Jèhófà,’ a ó máa yẹra fún àwọn nǹkan ẹ̀ṣẹ̀ tó lè ré wa lọ, èyí tí kì í mú inú Ẹlẹ́dàá wa dùn tó sì máa ń gba ayọ̀ lọ́wọ́ ẹni.— Sáàmù 119:31.
5. Báwo la ṣe lè wá nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí Jèhófà lọ́nà tó kọyọyọ?
5 Báwo ló ṣe yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí Jèhófà tó? Onísáàmù náà kọrin pé: “Ọkàn mi ti pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́, mo sì nífẹ̀ẹ́ wọn lọ́nà tí ó peléke [kọyọyọ].” (Sáàmù 119:167) A ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí Jèhófà lọ́nà tó kọyọyọ táa bá tẹ́wọ́ gbà wọ́n tí a sì wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìṣílétí látẹnu Bàbá kan tó ń bójú tó wa dáadáa. (1 Pétérù 5:6, 7) A nílò àwọn ìránnilétí rẹ̀, bí a sì ti ń rí àǹfààní tí wọ́n ń ṣe fún wa ni ìfẹ́ táa ní fún wọn yóò máa pọ̀ sí i.
Ìdí Táa Fi Nílò Àwọn Ìránnilétí Ọlọ́run
6. Kí ni ìdí kan pàtó táa fi nílò àwọn ìránnilétí Jèhófà, kí ni yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti máa rántí wọn?
6 Ìdí kan táa fi nílò àwọn ìránnilétí Jèhófà ni pé a máa ń gbàgbé nǹkan. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia, sọ pé: Gbogbo èèyàn lápapọ̀ ló máa ń gbàgbé nǹkan bí àkókò ti ń lọ. . . . Bóyá ó ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà rí tí o ò lè rántí orúkọ kan tàbí àwọn ìsọfúnni kan mọ́, tó sì jẹ́ pé jíjẹ lo máa ń jẹ ẹ́ lẹ́nu tẹ́lẹ̀. . . . Irú gbígbàgbé nǹkan fún àkókò kúkúrú bẹ́ẹ̀, tó sì máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa léraléra ni wọ́n ń pè ní, kí iyè èèyàn má lè sọ sí nǹkan. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fi wé wíwá nǹkankan tó sọnù nínú yàrá kan tó dí fọ́fọ́. . . . Ọ̀nà kan tó dára láti rántí ìsọfúnni kan ni láti tún un kà lẹ́yìn tó bá ti pẹ́ gan-an sí àkókò tóo rò pé o ti mọ̀ ọ́n dáadáa.” Fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ àti pípe nǹkan ní àpètúnpè yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa rántí àwọn ìránnilétí Ọlọ́run, àá sì lè máa gbé níbàámu pẹ̀lú wọn fún àǹfààní ara wa.
7. Èé ṣe táa fi nílò ìránnilétí Ọlọ́run lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ?
7 A nílò àwọn ìránnilétí Jèhófà lónìí ju ti ìgbàkigbà rí lọ, nítorí pé ìwà ibi ti wá dé ògógóró rẹ̀ báyìí nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Báa bá ń fiyè sí àwọn ìránnilétí Ọlọ́run, àá ní ìjìnlẹ̀ òye tó pọndandan láti yàgò fún dídi ẹni táa fà lọ sínú àwọn ọ̀nà búburú ayé. Onísáàmù náà sọ pé: “Mo ti wá ní ìjìnlẹ̀ òye ju gbogbo àwọn olùkọ́ mi, nítorí pé àwọn ìránnilétí rẹ ni ìdàníyàn mi. Èmi ń fi òye tí ó ju ti àwọn àgbà hùwà, nítorí pé mo ti pa àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ mọ́. Èmi ti kó ẹsẹ̀ mi ní ìjánu kúrò nínú gbogbo ipa ọ̀nà búburú, kí èmi kí ó lè máa pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.” (Sáàmù 119:99-101) Nípa pípa àwọn ìránnilétí Ọlọ́run mọ́, àá yàgò fún “gbogbo ipa ọ̀nà búburú,” a ò sì tún ní dà bí àwùjọ ìran ènìyàn, tí wọ́n wà “nínú òkùnkùn ní ti èrò orí, tí a sì sọ wọ́n di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run.”—Éfésù 4:17-19.
8. Báwo la ṣe lè di ẹni tó gbára dì dáadáa láti lè kojú àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ pẹ̀lú àṣeyọrí?
8 A tún nílò àwọn ìránnilétí Ọlọ́run nítorí wọ́n ń fún wa lókun láti lè fara da ọ̀pọ̀ àdánwò ní “àkókò òpin” yìí. (Dáníẹ́lì 12:4) Bí kò bá sí irú àwọn ìránnilétí yẹn, ńṣe la máa di “olùgbọ́ tí ń gbàgbé.” (Jákọ́bù 1:25) Àmọ́, fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ fúnra wa àti nínú ìjọ, pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn ìtẹ̀jáde tó ń wá látọ̀dọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ pẹ̀lú àṣeyọrí. (Mátíù 24:45-47) Irú àwọn ìpèsè tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ ká mọ ohun táa gbọ́dọ̀ ṣe láti múnú Jèhófà dùn nígbà táa bá bára wa nínú àwọn ipò tí kò bára dé.
Ipa Pàtàkì Táwọn Ìpàdé Wa Ń Kó
9. Àwọn wo ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” báwo ni wọ́n sì ṣe ń ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́?
9 Lọ́nà kan, a máa ń rí àwọn ìránnilétí Ọlọ́run tí a nílò gbà ní àwọn ìpàdé Kristẹni, níbi táwọn arákùnrin tí a yàn ti ń pèsè ìtọ́ni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé nígbà tí Jésù “gòkè lọ sí ibi gíga lókè, ó kó àwọn òǹdè lọ; ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.” Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “[Kristi] fúnni ní àwọn kan gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì, àwọn kan gẹ́gẹ́ bíi wòlíì, àwọn kan gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, àwọn kan gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́, láti lè ṣe ìtọ́sọ́nàpadà àwọn ẹni mímọ́, fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, fún gbígbé ara Kristi ró.” (Éfésù 4:8, 11, 12) Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká kún fún ìmoore pé “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” yìí—ìyẹn àwọn alàgbà tí a yàn sípò—ń darí àfiyèsí wa sórí àwọn ìránnilétí Jèhófà nígbà tí a bá pàdé pọ̀ fún ìjọsìn!
10. Kókó pàtàkì wo ló wà nínú Hébérù 10:24, 25?
10 Mímọyì àwọn ìpèsè Ọlọ́run yóò sún wa láti máa pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé ìjọ wa márààrún táa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ ká máa pàdé déédéé. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”—Hébérù 10:24, 25.
11. Báwo ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpàdé wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ṣe ń ṣàǹfààní fún wa?
11 Ǹjẹ́ o mọyì ohun táwọn ìpàdé wa ń ṣe fún wa? Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí a ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìránnilétí Jèhófà, ó sì tún ń fún wa lágbára láti gbógun ti “ẹ̀mí ayé.” (1 Kọ́ríńtì 2:12; Ìṣe 15:31) Ní Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn, àwọn olùbánisọ̀rọ̀ máa ń fúnni nítọ̀ọ́ni látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, títí kan àwọn ìránnilétí Jèhófà àti àgbàyanu “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun” tí Jésù sọ. (Jòhánù 6:68; 7:46; Mátíù 5:1–7:29) Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ń mú kí a jáfáfá sí i nínú kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kò ṣeé díye lé nínú ríràn wá lọ́wọ́ láti dẹni tó túbọ̀ sunwọ̀n sí i nínú bí a ti ń gbé ìhìn rere náà kalẹ̀ láti ilé dé ilé, nínú ìpadàbẹ̀wò, nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti nínú àwọn apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa mìíràn. Àwùjọ kékeré tó ń wá sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ ń fún wa láǹfààní tó túbọ̀ pọ̀ sí i, láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ń fìgbà gbogbo ní àwọn ìránnilétí Ọlọ́run nínú.
12, 13. Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run ní orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà ṣe fi ìmọrírì hàn fún àwọn ìpàdé Kristẹni?
12 Wíwá sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé ń rán wa létí àwọn òfin Ọlọ́run ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí nígbà tí ogun bá ń jà, lásìkò ìṣòro ìṣúnná owó, àtàwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ wa mìíràn. Nǹkan bí àádọ́rin àwọn Kristẹni tó wà ní orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà túbọ̀ mọyì ìjẹ́pàtàkì àwọn ìpàdé nígbà tí wọ́n lé wọn kúrò nílé wọn, tó sì di dandan fún wọn láti lọ máa gbé nínú igbó kìjikìji. Pẹ̀lú ìpinnu wọn láti máa pàdé pọ̀ déédéé, wọ́n padà lọ sínú ìlú wọn ti ogun ti fọ́ túútúú, wọ́n tú ìwọ̀nba nǹkan tó kù lára Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n sì lọ tún un kọ́ sínú ẹgàn.
13 Lẹ́yìn táwọn èèyàn Jèhófà ti fara da ọ̀pọ̀ ọdún tí ogun fi jà ní apá ibòmíràn nínú orílẹ̀-èdè yẹn kan náà, wọ́n ṣì ń bá a lọ láti máa fi ìtara sìn. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ alàgbà kan pé: “Kí lohun tó ṣèrànwọ́ jù lọ láti mú kí àwọn ará wà pa pọ̀?” Báwo ló ṣe dáhùn? “Fún odindi ọdún mọ́kàndínlógún, a ò pa ẹyọ ìpàdé kan jẹ. Nígbà míì, nítorí bọ́ǹbù tí wọ́n ń jù tàbí àwọn ìṣòro mìíràn, díẹ̀ nínú àwọn ará kò lè wá síbi ìpàdé, àmọ́, kò sígbà kan tí a kò ṣèpàdé.” Dájúdájú, àwọn arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n yìí mọrírì pé ‘ṣíṣàì kọ ìpéjọpọ̀ ara wọn sílẹ̀’ ṣe pàtàkì.
14. Kí la lè rí kọ́ látinú ohun tí Ánà tó jẹ́ àgbàlagbà máa ń ṣe?
14 Ánà, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin tó jẹ́ opó “kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ.” Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé ó wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n gbé Jésù ọmọ ọwọ́ náà wá, kété lẹ́yìn tí wọ́n bí i. (Lúùkù 2:36-38) Ṣé ìpinnu tìẹ náà ni pé kò sóhun tó máa mú ẹ pa ìpàdé jẹ? Ṣé o máa ń sa gbogbo ipá ẹ láti wà ní gbogbo apá tí àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ wa ní? Àwọn ìtọ́ni tó ń ṣeni láǹfààní tẹ̀mí, èyí tí a ń rí gbà láwọn ìpàdé yìí fún wa ní ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Baba wa ọ̀run ń bìkítà fáwọn ènìyàn rẹ̀. (Aísáyà 40:11) Irú àwọn àkókò yẹn máa ń fi kún ayọ̀ wa, wíwà táa sì wà níbẹ̀ ń fi ìmọrírì wa fún àwọn ìránnilétí Jèhófà hàn.—Nehemáyà 8:5-8, 12.
Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Ń Yà Wá Sọ́tọ̀
15, 16. Báwo ní pípa àwọn ìránnilétí Jèhófà mọ́ ṣe kan ìwà wa?
15 Pípa àwọn ìránnilétí Ọlọ́run mọ́ ń ṣèrànwọ́ láti yà wá sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé búburú yìí. Fún àpẹẹrẹ, kíkọbi ara sáwọn ìránnilétí Ọlọ́run ń jẹ́ ká lè yàgò fún lílọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe. (Diutarónómì 5:18; Òwe 6:29-35; Hébérù 13:4) Tí a bá ń gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìránnilétí Ọlọ́run, a lè ṣẹ́pá ìtẹ̀sí náà láti purọ́, láti ṣàbòsí, tàbí láti jalè. (Ẹ́kísódù 20:15, 16; Léfítíkù 19:11; Òwe 30:7-9; Éfésù 4:25, 28; Hébérù 13:18) Pípa àwọn ìránnilétí Jèhófà mọ́ tún ń ká wa lọ́wọ́ kò láti má ṣe gbẹ̀san, láti má di kùnrùngbùn sẹ́nikẹ́ni, tàbí fọ̀rọ̀ èké ba ẹnikẹ́ni jẹ́.—Léfítíkù 19:16, 18; Sáàmù 15:1, 3.
16 Nípa ṣíṣègbọràn sáwọn ìránnilétí Ọlọ́run, àá máa bá a lọ ní jíjẹ́ ẹni táa sọ di mímọ́ tàbí táa yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Dídi ẹni táa yà sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé yìí mà kúkú ṣe pàtàkì o! Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Jèhófà lóru tó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ yìí nítorí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn, ṣùgbọ́n ayé ti kórìíra wọn, nítorí pé wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé. Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé. Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:14-17) Ẹ jẹ́ ká máa báa lọ ní fífọwọ́ pàtàkì mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó yà wá sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ rẹ̀.
17. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa táa bá dágunlá sáwọn ìránnilétí Ọlọ́run, kí ló wá yẹ ká ṣe?
17 Níwọ̀n bí a tí jẹ ìránṣẹ́ Jèhófà, a fẹ́ kó máa tẹ́wọ́ gbà wá fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Àmọ́, táa bá dágunlá sáwọn ìránnilétí Ọlọ́run, a lè di ẹni tí ẹ̀mí ayé yìí ṣẹ́pá rẹ̀, ìyẹn ẹ̀mí táwọn ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ rẹ̀, ìwé rẹ̀, eré ìnàjú rẹ̀ àti ìwà rẹ̀ ń gbé lárugẹ. Ó tún dájú pé a ò ní fẹ́ jẹ́ olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, òǹrorò, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run—kí á kàn mẹ́nu kan díẹ̀ lára ìṣesí àwọn tó sọra wọn dàjèjì sí Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:1-5) Níwọ̀n bí àkókò òpin ètò àwọn nǹkan búburú tí a ń gbé yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bùṣe, ẹ́ jẹ́ ká máa bá a lọ ní gbígbàdúrà fún agbára Ọlọ́run, ká lè máa bá a nìṣó ní pípa àwọn ìránnilétí Jèhófà mọ́, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ ‘ṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀.’—Sáàmù 119:9.
18. Pípa àwọn ìránnilétí Ọlọ́run mọ́ yóò sún wa láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ títọ́ wo?
18 Kì í ṣe àwọn ohun tí kò yẹ ká ṣe nìkan ni àwọn ìránnilétí Jèhófà ń jẹ́ ká wà lójúfò sí. Pípa àwọn ìránnilétí rẹ̀ mọ́ á jẹ́ ká gbégbèésẹ̀ tó tọ́, á sì sún wa láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà, ká sì tún nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àyà wa, ọkàn wa, èrò inú wa, àti agbára wa. (Diutarónómì 6:5; Sáàmù 4:5; Òwe 3:5, 6; Mátíù 22:37; Máàkù 12:30) Àwọn ìránnilétí Ọlọ́run tún máa ń sún wa láti nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. (Léfítíkù 19:18; Mátíù 22:39) Ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù lọ tí a fi ń fìfẹ́ táa ní sí Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa hàn ni nípa ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àti bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa “ìmọ̀ Ọlọ́run” tí ń fúnni ní ìyè.—Òwe 2:1-5.
Pípa Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Mọ́ Ń Túmọ̀ sí Ìyè!
19. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn rí i pé ohun tó bọ́gbọ́n mu tó sì tún ṣàǹfààní ni láti ṣègbọràn sí àwọn ìránnilétí Jèhófà?
19 Báa bá pa àwọn ìránnilétí Jèhófà mọ́ táa sì tún ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, a ó gba ara wa àtàwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa là. (1 Tímótì 4:16) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn rí i pé ṣíṣègbọràn sí àwọn ìránnilétí Jèhófà bọ́gbọ́n mu, ó sì tún ṣàǹfààní? Nípa fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé tiwa fúnra wa. Àwọn tí wọ́n ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” á wá tipa bẹ́ẹ̀ rí i pé ọ̀nà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là sílẹ̀ gan-an lèyí tó dára jù lọ láti tọ̀. (Ìṣe 13:48) Wọ́n á tún wá rí i pé ‘Ọlọ́run wà láàárín wa ní ti tòótọ́’ wọ́n á sì dẹni táa sún láti dára pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ.—1 Kọ́ríńtì 14:24, 25.
20, 21. Kí ni àwọn ìránnilétí Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe?
20 Nípa bíbá a lọ ní kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ní fífi ohun tí a ń kọ́ sílò, àti lílo gbogbo àǹfààní ìpèsè tẹ̀mí tí Jèhófà ṣe, a ó dẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí rẹ̀ lọ́nà tó kọyọyọ. Táa bá kọbi ara sí wọn, àwọn ìránnilétí yìí á ràn wá lọ́wọ́ láti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:20-24) Àwọn ìránnilétí Jèhófà àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ á jẹ́ ká lè fi ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn—àwọn ànímọ́ tó yàtọ̀ pátápátá sí ìṣesí ayé tó wà lábẹ́ agbára Sátánì! (Gálátíà 5:22, 23; 1 Jòhánù 5:19) Nítorí náà, ó yẹ ká kún fún ìmoore nígbà táa bá rán wa létí àwọn ohun tí Jèhófà béèrè pé ká ṣe, nígbà táa bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nípasẹ̀ àwọn alàgbà táa yàn sípò, àti láwọn ìpàdé, àpéjọ àti àpéjọpọ̀ wa gbogbo.
21 Nítorí pé a ń pa àwọn ìránnilétí Jèhófà mọ́, ó ṣeé ṣe fún wa láti máa yọ̀ àní nígbà táa bá tilẹ̀ ń jìyà nítorí òdodo pàápàá. (Lúùkù 6:22, 23) Ọlọ́run la ń wò láti dáàbò bò wá nínú àwọn ipò lílekoko tó ń halẹ̀ mọ́ wa. Àkókò yìí gan-an, tí a ń kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” ní Ha–Mágẹ́dọ́nì lèyí túbọ̀ wá ṣe pàtàkì jù.—Ìṣípayá 16:14-16.
22. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa nípa àwọn ìránnilétí Jèhófà?
22 Táa bá máa gba ẹ̀bùn àìlẹ́tọ̀ọ́sí ti ìyè àìnípẹ̀kun, ó di dandan ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí Jèhófà lọ́nà tó kọyọyọ ká sì máa pa wọ́n mọ́ tọkàntọkàn. Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká ní irú ẹ̀mí tí onísáàmù náà ní nígbà tó kọrin pé: “Òdodo àwọn ìránnilétí rẹ jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin. Mú mi lóye, kí n lè máa wà láàyè nìṣó.” (Sáàmù 119:144) Ẹ jẹ́ ká tún fi irú ìpinnu ṣíṣe kedere tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù náà hàn pé: “Mo ti ké pè ọ́ [Jèhófà]. Gbà mí là! Ṣe ni èmi yóò máa pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́.” (Sáàmù 119:146) Bẹ́ẹ̀ ni o, nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe wa, ẹ jẹ́ ká máa fi hàn pé ní tòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí Jèhófà lọ́nà tó kọyọyọ.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ojú wo ni onísáàmù náà fi wo àwọn ìránnilétí Jèhófà?
• Èé ṣe táa fi nílò àwọn ìránnilétí Ọlọ́run?
• Ipa wo làwọn ìpàdé wa ń kó nígbà tó bá kan àwọn ìránnilétí Ọlọ́run?
• Báwo ni àwọn ìránnilétí Jèhófà ṣe yà wá sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé yìí?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Onísáàmù náà nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí Jèhófà lọ́nà tó kọyọyọ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Ánà, ṣé o ti pinnu pé kò sóhun tó lè mú ẹ pa ìpàdé jẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kíkọbiara sáwọn ìránnilétí Jèhófà ń yà wá sọ́tọ̀ pé a jẹ́ mímọ́, pé a sì tẹ́wọ́ gbà wá fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀