Àwọn Àṣà Kérésìmesì—Ṣé Wọ́n Bá Ìsìn Kristẹni Mu?
Àwọn Àṣà Kérésìmesì—Ṣé Wọ́n Bá Ìsìn Kristẹni Mu?
KÉRÉSÌMESÌ dé. Kí nìyẹn túmọ̀ sí fún ọ, kí ló túmọ̀ sí fún ìdílé rẹ, àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ? Ṣe ayẹyẹ tó ní í ṣe pẹ̀lú nǹkan tẹ̀mí ni, àbí ìgbà ọdún àti àsìkò pọ̀pọ̀ṣìnṣìn lásán ló wulẹ̀ jẹ́? Ṣé àkókò láti ronú jinlẹ̀ lórí ìbí Jésù Kristi ni, àbí ìgbà tí kò yẹ kí á ka àwọn ìlànà tó bá ìsìn Kristẹni mu sí?
Bóo ṣe ń gbé àwọn ìbéèrè yẹn yẹ̀ wò, má gbàgbé pé àwọn àṣà Kérésìmesì lè yàtọ̀ síra wọn, ó sinmi lórí ibi tí ò ń gbé. Fún àpẹẹrẹ, ní Mẹ́síkò àti láwọn orílẹ̀-èdè Látìn-Amẹ́ríkà mìíràn, orúkọ tí wọ́n ń pè é tiẹ̀ tún yàtọ̀ síra wọn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí a túmọ̀ sí Kérésìmesì “jáde láti inú Christes Masse, tí ó jẹ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì tí a ń lò ní sànmánì ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀làjú, èyí tó túmọ̀ sí Máàsì ti Kristi.” Bó ti wù kó rí, La Navidad tàbí Ìbí Jésù, ìyẹn bí wọ́n ṣe ń pè é láwọn orílẹ̀-èdè Látìn-Amẹ́ríkà yìí, ń tọ́ka sí ìgbà ìbí, tàbí ìbí Kristi. Lo àkókò díẹ̀ láti gbé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ bíi mélòó kan láti ilẹ̀ Mẹ́síkò yẹ̀ wò. Èyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ èrò tí wàá dì mú nípa àsìkò ọlidé yìí.
Posadas, “Àwọn Amòye Mẹ́ta,” àti Nacimiento
December 16 ni pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọdún náà ti máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú posadas. Ìwé náà, Mexico’s Feasts of Life, ṣàlàyé pé: Àkókò posadas ti tó, ọjọ́ mẹ́sàn-án tó wà fún idán pípa tó sì máa jálẹ̀ sí Alẹ́ tó Ṣáájú Kérésìmesì, èyí tó ń ránni létí bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe ń dá nìkan rìn kiri nínú ìlú ńlá Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àti ìgbà tí wọ́n rí inúrere àti ibì kan láti wọ̀ sí. Àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ máa ń kóra jọ pọ̀ lálaalẹ́ láti ṣàṣefihàn àwọn ọjọ́ tó ṣáájú ìbí Kristi.”
Ó jẹ́ àṣà láti rí àwùjọ èèyàn kan tó gbé ère Màríà àti Jósẹ́fù lọ sínú ilé kan, tí wọ́n sì ń fi orin béèrè ibi tí wọ́n lè wọ̀ sí tàbí fún posada. Àwọn tó wà nínú ilé náà á wá forin dáhùn padà títí dìgbà tí wọ́n á fi fún àwọn àlejò náà láyè láti wọlé. Ìgbà yẹn ni àríyá á wá bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu, táwọn kan tí wọ́n faṣọ bojú pẹ̀lú igi lọ́wọ́ á sì fọ́ piñata, ìyẹn ìkòkò amọ̀ ńlá kan tí wọ́n ṣọ̀ṣọ́ sí lára tí wọ́n sì fi okùn gbé kọ́. Tí wọ́n bá ti lè fọ́ ọ, àwọn aláyẹyẹ náà á wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣa àwọn nǹkan tó wà nínú ìkòkò náà (midinmíìdìn, èso àtàwọn nǹkan míì). Jíjẹ, mímu, orin àti ijó jíjó ló máa ń tẹ̀ lé e. Àríyá posada mẹ́jọ ni wọ́n máa ń ṣe láti December 16 sí December 23. Tó bá wá di ọjọ́ kẹrìnlélógún, wọ́n máa ń ṣayẹyẹ Nochebuena, (alẹ́ tó ṣáájú Kérésìmesì), àwọn ẹbí sì máa ń gbìyànjú láti wà pa pọ̀ fún oúnjẹ alẹ́ pàtàkì kan.
Kò pẹ́ kò jìnnà, Ọjọ́ Ọdún Tuntun ti dé, èyí tí wọ́n máa ń fi àwọn àríyá aláriwo ṣayẹyẹ rẹ̀. Nírọ̀lẹ́ January 5, ni wọ́n gbà pé àwọn Tres Reyes Magos (“àwọn amòye mẹ́ta”) á mú ohun ìṣiré wá fún àwọn ọmọdé. Àṣekágbá rẹ̀ ni àríyá tó ń wáyé ní January 6, nígbà tí wọ́n máa ń pín rosca de Reyes (àkàrà òyìnbó onírìísí òrùka). Bí wọ́n bá ṣe ń jẹ àkàrà yìí lọ́wọ́, ẹni kan á rí ọmọlangidi kékeré kan nínú àkàrà tirẹ̀ tó ń ṣàpẹẹrẹ Jésù tó jẹ́ ìkókó. Ẹni tó rí i yìí ló ni ẹrù iṣẹ́ láti ṣètò àti láti bójú tó àríyá tó máa kẹ́yìn ní February 2. (Láwọn ibì kan, àwọn ọmọlangidi kékeré mẹ́ta ló wà, tí wọn ń dúró fún “àwọn amòye mẹ́ta náà.”) Bí ìwọ náà ṣe lè rí i, àríyá tó ń bá Kérésìmesì rìn kò lópin.
Láàárín àkókò yìí, nacimiento (àwòrán Ìbí Jésù) máa ń wọ́pọ̀ gan-an. Kí lèyí ní nínú? Tóò,
láwọn ibi téèyàn máa ń pọ̀ sí, títí kan inú ṣọ́ọ̀ṣì àti inú ilé, ni wọ́n máa ń pàtẹ àwọn ère (ńlá àti kékeré) sí, èyí tí wọ́n fi amọ̀ ṣe àti èyí tí wọ́n fi igi gbẹ́. Àwọn yẹn ṣàpẹẹrẹ Jósẹ́fù àti Màríà níbi tí wọ́n kúnlẹ̀ sí ní ibùjẹ ẹran tí wọ́n tẹ́ ọmọ kékeré jòjòló kan sí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn Los Reyes Magos (“àwọn amòye”) tún máa ń wà níbẹ̀. Ibi táwọn ẹran ń gbé ni wọ́n ti máa ń ṣe é, àwọn ẹran kan sì lè wá kádìí ìran náà. Àmọ́ o, ọmọ jòjòló yẹn, tí wọ́n ń pè ní el Niño Dios lédè Spanish (Ọlọ́run Ọmọ) lohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìran náà. Nǹkan pàtàkì yìí tó dúró fún ọmọ jòjòló náà ni wọ́n lè ti fi síbẹ̀ ní Alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ Kérésìmesì.Wíwo Àwọn Àṣà Ìbí Jésù Dáadáa
Ní ti bí gbogbo èèyàn ṣe mọ ayẹyẹ Kérésìmesì sí yíká ayé, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Encyclopedia Americana, sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn àṣà tó wá jẹ́ ti Kérésìmesì báyìí ni kì í ṣe àṣà Kérésìmesì rárá nípilẹ̀ṣẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n jẹ́ àwọn àṣà tó ti wà ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé àti ti àwọn tí kì í ṣe Kristẹni rárá táwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni wá sọ di tiwọn. Saturnalia, àsè àwọn ará Róòmù tí wọ́n máa ń ṣayẹyẹ rẹ̀ ní ìdajì oṣù December, ló jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ọ̀pọ̀ lára àwọn àṣà onípọ̀pọ̀ṣìnṣìn tí wọ́n máa ń ṣe nígbà Kérésìmesì. Fún àpẹẹrẹ, nínú ayẹyẹ yìí ní wọ́n ti rí síse àsè rẹpẹtẹ, fífúnni lẹ́bùn, àti jíjó àbẹ́là.”
Ní Látìn Amẹ́ríkà, wọ́n lè tẹ̀ lé àwọn àṣà Ìgbà Ìbí Jésù, kí wọ́n tiẹ̀ tún fi àwọn mìíràn kún un. O lè wá wò ó pé, ‘ibo làwọn àṣà yìí tiẹ̀ ti wá’. Ká kúkú sọjú abẹ níkòó, ọ̀pọ̀ tó ń fẹ́ láti rọ̀ mọ́ ohun tí Bíbélì sọ rí i pé díẹ̀ lára àwọn àṣà náà kò yàtọ̀ rárá sí àwọn ààtò Aztec. Ìwé ìròyìn kan ní ìlú Mẹ́síkò tó ń jẹ́ El Universal sọ pé: “Àwọn mẹ́ńbà látinú onírúurú ìsìn lo àǹfààní kàlẹ́ńdà ààtò ayẹyẹ ọdún àwọn ará Íńdíà tó bọ́ sígbà kan náà pẹ̀lú ti ìjọsìn àwọn Kátólíìkì, nítorí náà, wọ́n lo ìyẹn láti fi ti iṣẹ́ ìjíhìnrere àti ti míṣọ́nnárì tí wọ́n ń ṣe lẹ́yìn. Wọ́n wá fi ṣíṣe ìrántí àwọn ọlọ́run tí wọ́n ti wà ṣáájú àkókò àwọn ará Sípéènì rọ́pò ṣíṣe àjọ̀dún fún àwọn ọlọ́run Kristẹni, wọ́n mú àjọ̀dún àwọn ará Yúróòpù àtàwọn ìgbòkègbodò
wọn wá, wọ́n tún fi àjọ̀dún àwọn ará Íńdíà kún un, èyí tó yọrí sí àmúlùmálà àṣà nínú èyí tí ojúlówó ọ̀rọ̀ táwọn ará Mẹ́síkò ń pè é ti jáde wá.”Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Encyclopedia Americana, ṣàlàyé pé: “Fífi Ìbí Jésù ṣe eré bí wọ́n ti máa ń ṣe ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá di apá kan ayẹyẹ Kérésìmesì . . . Eré Ìbí Jésù [ní ibùjẹ ẹran] tí wọ́n ń ṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n sọ pé Francis Mímọ́ ló dá a sílẹ̀.” Àwọn eré ìtàgé yìí, tó ń fi bí wọ́n ṣe bí Kristi hàn ni wọ́n ń ṣe nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì nígbà tí ilẹ̀ Mẹ́síkò ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ sábẹ́ ìjọba ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé ti Francis ló ṣètò wọn, kí wọ́n lè kọ́ àwọn ará Íńdíà nípa Ìbí Jésù. Lẹ́yìn náà, posadas túbọ̀ wá di èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn tẹ́wọ́ gbà. Ohun tó wù kó jẹ́ ìdí tí wọ́n fi ń ṣe é ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe posadas yìí ti fi bó ṣe jẹ́ gan-an hàn. Bóo bá wà ní Mẹ́síkò lásìkò yìí, o lè rí tàbí kó o máa gbúròó ohun tí òǹkọ̀wé kan tó ń kọ ìròyìn fún ìwé ìròyìn El Universal tẹnu mọ́ nínú àlàyé rẹ̀ pé: “Posadas, tó ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀nà kan láti rán wa létí ìrìn-àjò àwọn òbí Jésù, níbi tí wọ́n ti ń wá ilé tí wọ́n lè yà sí láti lè bí Ọlọ́run Ọmọ náà, ti wá di ọjọ́ ìmutípara, àṣejù, Àjẹkì, ọjọ́ asán, pẹ̀lú ìwà ọ̀daràn tó túbọ̀ pọ̀ sí i lónìí.”
Àárín ìgbà táwọn Ilẹ̀ Òkèèrè ń ṣàkóso Mẹ́síkò ni èrò nípa nacimiento fara hàn, látinú ohun táwọn èèyàn rí nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fa àwọn kan mọ́ra, ǹjẹ́ ó bá ohun tí Bíbélì wí mu ní ti tòótọ́? Ìyẹn jẹ́ ìbéèrè tó bọ́gbọ́n mu. Nígbà táwọn tí wọ́n fẹnu lásán pè ní amòye mẹ́ta náà—àmọ́ tí wọ́n jẹ́ awòràwọ̀ ní ti gidi—bẹ Jésù wò, òun àti ìdílé rẹ̀ kò gbé inú ibùjẹ ẹran mọ́ lákòókò yẹn. Ọjọ́ ti gorí ọjọ́, ìdílé náà sì ti ń gbé inú ilé. Yóò dùn mọ́ ọ láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí nínú àkọsílẹ̀ tí a mí sí nínú Mátíù orí 2:1, 11. O tún lè rí i pé Bíbélì kò sọ iye àwọn awòràwọ̀ tó wà níbẹ̀. a
Ní Latin America, àwọn amòye mẹ́ta yẹn ló wá rọ́pò Santa Claus. Síbẹ̀síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí wọn ti máa ń ṣe ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ọ̀pọ̀ àwọn òbí máa ń tọ́jú ohun ìṣiré sínú ilé. Lẹ́yìn náà, tó bá wá di àárọ̀ January 6, àwọn ọmọ á bẹ̀rẹ̀ sí í wá wọn kiri, bí ẹni pé àwọn amòye mẹ́ta yẹn ló kó wọn wá. Àsìkò yìí làwọn tó ń ta ohun ìṣiré ọmọdé máa ń rí towó ṣe, àwọn kan sì ti di ọlọ́là nídìí ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó jẹ́ aláìlábòsí-ọkàn mọ̀ pé yẹ̀yẹ́ lásán ni. Ìtàn àròsọ àwọn amòye mẹ́ta yẹn kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ nǹkankan sí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ́, kódà sáwọn ọmọdé pàápàá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àwọn kan kò dùn sí báwọn tó gba ìtàn àròsọ yìí gbọ́ ṣe ń dín kù, kí lèèyàn retí tẹ́lẹ̀ pé kó ṣẹlẹ̀ sí ohun tó jẹ́ yẹ̀yẹ́ lásán, tó jẹ́ pé torí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àti ọ̀ràn ìṣòwò ni wọ́n ṣe ń ṣe é?
Àwọn Kristẹni ìjímìjí kò ṣayẹyẹ Kérésìmesì tàbí Ìbí Jésù. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ nípa rẹ̀ pé: “Wọn kò ṣayẹyẹ yìí nínú ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun táwọn Kristẹni lápapọ̀ tẹ́wọ́ gbà ni ṣíṣayẹyẹ ikú àwọn ẹni pàtàkì dípò ọjọ́ ìbí wọn.” Bíbélì so ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí pọ̀ mọ́ àwọn kèfèrí, kì í ṣe mọ́ àwọn tí ń jọ́sìn Ọlọ́run ní ti tòótọ́.—Mátíù 14:6-10.
Àmọ́ ṣá o, èyí kò wá túmọ̀ sí pé kò sí àǹfààní tó wà nínú mímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gidi tó wáyé nígbà ìbí Ọmọ Ọlọ́run, ká sì tún rántí wọn. Àkọsílẹ̀ Bíbélì tó jẹ́ òtítọ́ pèsè ìjìnlẹ̀ òye àti ẹ̀kọ́ ṣíṣe pàtàkì fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
Bí Bíbélì Ṣe Ṣàlàyé Nípa Ìbí Jésù
Wàá rí ìsọfúnni tó ṣe é gbára lé nípa ìbí Jésù nínú Ìhìn Rere Mátíù àti Lúùkù. Wọ́n fi hàn wá pé áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì bẹ ọ̀dọ́bìnrin kan tí kò tíì lọ́kọ wò. Màríà lorúkọ rẹ̀, ó sì ń gbé ní ìlú kan tó ń jẹ́ Násárétì ní Gálílì. Iṣẹ́ wo ló jẹ́ fún un? “Wò ó! ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. Ẹni yìí yóò jẹ́ ẹni ńlá, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ; Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.”—Lúùkù 1:31-33.
Ìsọfúnni yìí ya Màríà lẹ́nu gan-an ni. Nígbà tó sì jẹ́ pé kò tíì ṣègbéyàwó, ló bá béèrè pé: “Báwo ni èyí yóò ṣe rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí èmi kò ti ń ní ìbádàpọ̀ kankan pẹ̀lú ọkùnrin?” Áńgẹ́lì náà wá dá a lóhùn pé: “Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.” Bí Màríà sì ti mọ̀ pé ìfẹ́ Ọlọ́run nìyẹn, ló bá sọ pé: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà! Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ.”—Lúùkù 1:34-38.
Áńgẹ́lì kan sọ fún Jósẹ́fù nípa ìbímọ lọ́nà ìyanu náà, kí ó má baà kọ Màríà sílẹ̀, èyí tó ti ń múra láti ṣe lẹ́yìn tó ti mọ̀ pé ó lóyún. Èyí mú kó múra tán láti gbé ẹrù iṣẹ́ bíbójútó Ọmọ Ọlọ́run.—Mátíù 1:18-25.
Lẹ́yìn náà, àṣẹ kan wá látọ̀dọ̀ Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì tó fipá mú Jósẹ́fù àti Màríà láti rìnrìn àjò, láti Násárétì ní Gálílì lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Jùdíà tí í ṣe ìlú àwọn baba ńlá wọn, láti lọ forúkọ sílẹ̀. “Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ pé fún un láti bímọ. Ó sì bí ọmọkùnrin rẹ̀, àkọ́bí, ó sì fi àwọn ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran kan, nítorí pé kò sí àyè fún wọn nínú yàrá ibùwọ̀.”—Lúùkù 2:1-7.
Lúùkù 2:8-14 sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà pé: “Àwọn olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú wà ní ìgbèríko kan náà, tí wọ́n ń gbé ní ìta, tí wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru. Lójijì, áńgẹ́lì Jèhófà dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, ògo Jèhófà sì ràn yòò yí wọn ká, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà wí fún wọn pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù, nítorí, wò ó! Èmi ń polongo fún yín ìhìn rere ti ìdùnnú ńlá kan tí gbogbo ènìyàn yóò ní, nítorí pé a bí Olùgbàlà kan fún yín lónìí, ẹni tí í ṣe Kristi Olúwa, ní ìlú ńlá Dáfídì. Èyí sì ni àmì fún yín: ẹ óò rí ọmọdé jòjòló kan tí a fi àwọn ọ̀já wé, ó sì wà ní ìdùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran.’ Lójijì, ògìdìgbó ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run sì wà pẹ̀lú áńgẹ́lì náà, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń sọ pé: ‘Ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ibi gíga lókè, àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.’”
Àwọn Awòràwọ̀
Àkọsílẹ̀ Mátíù sọ pé àwọn awòràwọ̀ láti Ìlà Oòrùn wá sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ń wá ibi tí wọ́n ti bí Ọba àwọn Júù. Ọba Hẹ́rọ́dù nífẹ̀ẹ́ sóhun tó gbọ́ yìí gan-an—àmọ́ kì í ṣe pé inú rẹ̀ dùn sí i. “Nígbà tí ó sì ń rán wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó wí pé: ‘Ẹ lọ fẹ̀sọ̀ wá ọmọ kékeré náà káàkiri, nígbà tí ẹ bá sì ti rí i, kí ẹ padà ròyìn fún mi, kí èmi náà lè lọ, kí n sì wárí fún un.’” Àwọn awòràwọ̀ náà rí ọmọ kékeré náà wọ́n sì ‘ṣí àwọn ìṣúra wọn, wọ́n sì fún un ní àwọn ẹ̀bùn, wúrà àti oje igi tùràrí àti òjíá.’ Ṣùgbọ́n wọn ò padà lọ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù. “A fún wọn ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nínú àlá láti má padà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù.” Ọlọ́run lo áńgẹ́lì kan láti kìlọ̀ fún Jósẹ́fù nípa ohun tó wà lọ́kàn Hẹ́rọ́dù. Ni Jósẹ́fù àti Màríà bá sá lọ sí Íjíbítì pẹ̀lú ọmọkùnrin wọn. Ohun tó wá ṣẹlẹ̀ ni pé, nínú ìsapá Ọba Hẹ́rọ́dù òǹrorò láti pa Ọba tuntun náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n lọ pa gbogbo àwọn ọmọdékùnrin tó wà lágbègbè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Àwọn ọmọdékùnrin wo? Àwọn tó jẹ́ láti ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀.—Mátíù 2:1-16.
Kí La Lè Rí Kọ́ Nínú Àkọsílẹ̀ Náà?
Àwọn awòràwọ̀ tó wá ṣèbẹ̀wò náà—bó ti wù kí iye wọn pọ̀ tó—kò jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́. Ẹ̀dà Bíbélì La Nueva Biblia Latinoamérica (Ẹ̀dà ti 1989) sọ nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé kan pé: “Àwọn awòràwọ̀ náà kì í ṣe ọba, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ aríran àti àlùfáà ìsìn kèfèrí.” Ìmọ̀ wọn nípa àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n ń jọ́sìn ló gbé wọn wá. Ká ní Ọlọ́run fẹ́ darí wọn sọ́dọ̀ ọmọ kékeré yẹn ni, ibẹ̀ gan-an ni wọn ì bá ti kọ́kọ́ kọrí sí láìsí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lọ sí Jerúsálẹ́mù àti sí ààfin Hẹ́rọ́dù. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run dá sí
ọ̀rọ̀ náà, nípa yíyí ipa ọ̀nà wọn padà láti dáàbò bo ọmọ náà.Lásìkò Kérésìmesì, wọ́n sábà máa ń fi ìtàn àròsọ àtàwọn nǹkan tí wọ́n kàn fọkàn yàwòrán rẹ̀ bo àkọsílẹ̀ tó ní ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ nínú yìí mọ́lẹ̀: ìyẹn ni pé ọmọ yìí ni a bí láti jẹ́ Ọba ọlọ́lá ńlá, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti polongo rẹ̀ fún Màríà àtàwọn olùṣọ́ àgùntàn náà. Rárá o, Jésù Kristi kì í tún ṣe ọmọ jòjòló mọ́, kì í tiẹ̀ ṣe ọmọ kékeré pàápàá. Òun ni Ọba tí ń ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí yóò pa gbogbo àkóso tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run run láìpẹ́, òun ni yóò sì yanjú gbogbo ìṣòro aráyé. Ìjọba yẹn la ń gbàdúrà fún nínú Àdúrà Olúwa.—Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10.
Nípasẹ̀ ohun tí áńgẹ́lì yẹn polongo fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn, a mọ̀ pé àǹfààní láti rí ìgbàlà ni a nawọ́ rẹ̀ sí gbogbo ẹni tó ń fẹ́ láti gbọ́ nípa ìhìn rere náà. Àwọn tó bá rí ojú rere Ọlọ́run á wá di “àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.” A ní ìfojúsọ́nà àgbàyanu fún àlàáfíà kárí ayé lábẹ́ Ìjọba Jésù Kristi, àmọ́, àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ múra tán láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ṣé àsìkò Kérésìmesì fúnni láǹfààní láti ṣe èyí, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ fi hàn pé àwọn ènìyàn ní irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́kàn lásìkò yẹn? Ọ̀pọ̀ àwọn aláìlábòsí èèyàn tí wọ́n fẹ́ láti tẹ̀ lé Bíbélì mọ̀ pé ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn kò mù.—Lúùkù 2:10, 11, 14.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kúlẹ̀kúlẹ̀ kan tún wà tá ò gbọ́dọ̀ di ojú wa sí: Nínú nacimiento àwọn ará Mẹ́síkò yìí, ọmọ yẹn ni wọ́n tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run Ọmọ,” pẹ̀lú èrò náà pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló wá sáyé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọwọ́. Àmọ́, Bíbélì fi Jésù hàn pé ó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run tí á bí sáyé; òun kọ́ ni Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè, bẹ́ẹ̀ ni kò sì bá a dọ́gba. Ṣàyẹ̀wò bí èyí ṣe jẹ́ òtítọ́ sí, nínú Lúùkù 1:35; Jòhánù 3:16; 5:37; 14:1, 6, 9, 28; 17:1, 3; 20:17.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
YÓÒ YA ÀWỌN KAN LẸ́NU
Nínú ìwé rẹ̀, The Trouble With Christmas, Òǹkọ̀wé Tom Flynn ṣàlàyé àwọn ìparí èrò tó dé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tó lò lẹ́nu ìwádìí nípa Kérésìmesì:
“Ọ̀pọ̀ jaburata àwọn àṣà táa wá so pọ̀ mọ́ Kérésìmesì báyìí ló ta gbòǹgbò látinú àwọn àṣà kèfèrí, èyí tó ti wà ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tóó dé. Díẹ̀ lára wọn ní ìtumọ̀ abẹ́nú tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ti ìbálòpọ̀, tàbí ti ìmọ̀ nípa àgbáálá ayé, èyí tó lè mú káwọn ọ̀mọ̀wé, tí wọ́n bìkítà nípa àṣà òde òní, jáwọ́ nínú àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ náà, tí wọ́n bá fi lè mọ̀ nípa àwọn gbòǹgbò wọn pẹ́nrẹ́n, tó sì yé wọn yékéyéké.”—Ojú ìwé 19.
Lẹ́yìn tí Flynn ti pèsè àwọn ìsọfúnni rẹpẹtẹ láti kín ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó tún padà sí kókó ṣíṣe pàtàkì náà pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun tí kò mú kí Kérésìmesì jọra pẹ̀lú ìsìn Kristẹni tòótọ́ ni bí ohun tó jọ ti Kristẹni nínú rẹ̀ ṣe kéré jọjọ. Táa bá mú àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tóó dé kúrò, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ohun tó máa ṣẹ́ kù sílẹ̀ á jẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀sìn Kristẹni dé, dípò kí wọ́n bá ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ mu.”—Ojú ìwé 155.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìkéde nípa ìbí Jésù jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ipa tí yóò kó lọ́jọ́ iwájú gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run ti yàn