Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfẹ́ Sún Wọn Láti Ṣiṣẹ́ Sìn

Ìfẹ́ Sún Wọn Láti Ṣiṣẹ́ Sìn

Ìfẹ́ Sún Wọn Láti Ṣiṣẹ́ Sìn

Ẹ GBỌ́ ná, kí ló lè mú àwọn tọkọtaya méjìdínláàádọ́ta tí wọ́n wà nígbà tára wọ́n jí pépé jù lọ nínú ìgbésí ayé láti fi ìdílé wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn, àti àyíká tó ti mọ́ wọn lára sílẹ̀ láti lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ òkèèrè? Kí ló dé tó fi jẹ́ ìdùnnú wọn ni láti lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè bíi Papua New Guinea, Taiwan, títí kan àwọn orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ Áfíríkà àti Látìn Amẹ́ríkà? Ṣé torí kí wọ́n lè mọ̀lú lọ ni? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojúlówó ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àti aládùúgbò wọn ló mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀.—Mátíù 22:37-39.

Ta làwọn èèyàn wọ̀nyí? Àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kọkàndínláàádọ́fà ti Watchtower Bible School of Gilead ni. Ní ọjọ́ Sátidé, September 9, 2000, àpapọ̀ iye àwọn tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé méjìdínnígba [5,198] pàdé pọ̀ ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower ní Patterson, New York, àti láwọn ibi táa ti lo ẹ̀rọ sátẹ́láìtì láti fi tẹ́tí sí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tó lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà lọ́wọ́ láti di míṣọ́nnárì tó ṣàṣeyọrí.

Stephen Lett ni alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ó sì jẹ́ mẹ́ńbà kan lára Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tó wà nínú Mátíù 5:13, èyí tó sọ pé: “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ilẹ̀ ayé” ló gbé ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀ kà. Arákùnrin Lett ṣàlàyé pé kò sí àní-àní pé àwọn ọ̀rọ̀ Jésù yìí kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó yege náà. Fún àpẹẹrẹ, iyọ̀ máa ń mú nǹkan dùn. Nítorí náà, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn míṣọ́nnárì dà bí iyọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù wọn gbígbéṣẹ́.

Ọ̀rọ̀ Ìdágbére Tó Kún fún Ìṣírí

Lẹ́yìn náà, arákùnrin Lett pe àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí wọ́n sọ àwọn ọ̀rọ̀ táa gbé karí Ìwé Mímọ́ ní ṣókí àmọ́ lọ́nà tó fa kíki. Ẹni àkọ́kọ́ nínú wọn ni John Wischuk, Ẹ̀ka Ìkọ̀wé lòún ti ń sìn. Àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó pè ní “Sáàmù Tó Kúrú Jù Lọ Gbé Ẹ̀mí Míṣọ́nnárì Lárugẹ” ló gbé karí Sáàmù Kẹtàdínlọ́gọ́fà. Lónìí, jákèjádò ayé ni ìdí wà fún jíjẹ́rìí nípa Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ fún àwọn “orílẹ̀-èdè” àtàwọn “agbo ìdílé.” Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni a rọ̀ láti mú ohun tí Sáàmù Kẹtàdínlọ́gọ́fà sọ ṣẹ nípa rírọ àwọn ẹlòmíràn láti “Yin Jáà.”

Lẹ́yìn náà ni alága ké sí Guy Pierce ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso láti sọ̀rọ̀. Ó sọ̀rọ̀ lórí kókó tó sọ pé, “Ẹ Mú Ara Yín Bá Onírúurú Ipò Mu, Síbẹ̀ Ẹ Má Gbàgbàkugbà.” Gbọn-in gbọn-in ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ní Diutarónómì 32:4 a pe Jèhófà Ọlọ́run ní Àpáta náà, síbẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń bá onírúurú ipò mu nítorí pé àwọn ènìyàn tó ń sọ onírúurú èdè àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ la kọ ọ́ fún—bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo èèyàn pátá ló wà fún. Ó ṣí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí láti wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n jẹ́ kí ìsọfúnni tó wà nínú rẹ̀ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn ṣinṣin kó sì tún nípa lórí ẹ̀rí ọkàn wọn. (2 Kọ́ríńtì 4:2) Arákùnrin Pierce gbà wọ́n níyànjú pé “ẹ jẹ́ ẹni tó dúró gbọn-in fún ìlànà tó tọ́, àmọ́ ẹ mú ara yín bá onírúurú ipò mu. Ẹ má fojú kéré àwọn èèyàn tó wà níbi táa yàn yín sí nítorí pé àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀.”

Karl Adams, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ni ní Gílíádì, ẹni tó ti ń sìn ní oríléeṣẹ́ àgbáyé fún ohun tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta, sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó gbàrònú náà “Èwo Ni Ṣíṣe Báyìí?” Lóòótọ́ ló jẹ́ pé ogún orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yí ká ayé làwọn tọkọtaya méjìdínláàádọ́ta náà ń lọ fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn, àmọ́ ìbéèrè tó yọjú ni pé, Tẹ́ẹ bá ti wá débẹ̀, tẹ́ẹ sì ti rí bí ibẹ̀ ṣe rí, kí ló kù tẹ́ẹ máa ṣe? Ayé táa ń gbé, ayé ságbà súlà ni. Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti lọ síbi tí wọn ò dé rí, kí wọ́n sì ṣe ohun tí wọn ò ṣe rí kí wọ́n sáà lè múnú ara wọn dùn. Àmọ́ tàwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí yàtọ̀ o, wọ́n gba iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún wọn níbi tó fẹ́ kí wọ́n máa gbé kí wọ́n sì máa fi àìmọtara ẹni nìkan bójú tó àwọn “àgùntàn” rẹ̀. Wọn ò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn kan ní Ísírẹ́lì ìgbàanì tó jẹ́ pé torí tara wọn nìkan tí wọ́n mọ̀ ni wọ́n fi pàdánù àǹfààní jíjẹ́ kí Jèhófà lò wọ́n láti bù kún gbogbo aráyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fara wé Jésù Kristi, ẹni tó ń fi àìmọtara ẹni nìkan ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, tó sì ṣègbọràn nínú gbogbo ipò tó dojú kọ.—Jòhánù 8:29; 10:16.

“Máa Fojú Ribiribi Wo Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ Wallace Liverance, tó ń gborúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Gílíádì sílẹ̀. Lemọ́lemọ́ ni Ìwé Mímọ́ fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé ọrọ̀, ohun ṣíṣeyebíye, irin tó níye lórí gan-an, àtàwọn nǹkan táa kà sí pàtàkì táa sì máa ń wá kiri. Òwe orí kejì, ẹsẹ ìkejì sí ìkarùn-ún fi hàn pé ká tó lè rí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an,” a gbọ́dọ̀ wá a kiri bí “ìṣúra fífarasin.” Olùbánisọ̀rọ̀ náà rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti tẹra mọ́ wíwalẹ̀ jìn nínú àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí wọ́n ti ń sìn láwọn ibi táa ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn wọ́n sí. Arákùnrin Liverance wòye pé: “Ohun tó gbéṣẹ́ lèyí jẹ́ o, nítorí yóò mú ìgbàgbọ́ yín àti ìgbẹ́kẹ̀lé yín nínú Jèhófà gbèrú, yóò sì mú ìpinnu yín lágbára sí i láti má ṣe jáwọ́ nínú iṣẹ́ táa yàn yín sí. Yóò ràn yín lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú, á sì jẹ́ kẹ́ẹ jẹ́ olùkọ́ tó gbéṣẹ́ bí ẹ ti ń ṣàlàyé àwọn ète Ọlọ́run fún àwọn mìíràn.”

Olùkọ́ni mìíràn ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ ọ̀rọ̀ tirẹ̀ bí ìgbà tí wọ́n wà nínú kíláàsì, ó ṣàtúnyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe bù kún ìgbòkègbodò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà nínú iṣẹ́ ìsìn pápá láàárín oṣù márùn-ún tó kọjá. Lawrence Bowen, tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nínú Ìṣe orí ogún, ẹsẹ ogun nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn èyí tó ṣe ní Éfésù, ó sì tẹnu mọ́ ọn pé Pọ́ọ̀lù lo gbogbo àǹfààní tó ní láti jẹ́rìí. Ìrírí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fi hàn kedere pé bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àwọn tí ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run àti aládùúgbò wọn ń sún ṣiṣẹ́ kì í fà sẹ́yìn nínú sísọ òtítọ́, àti jíjẹ́ kí agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa nípa lórí àwọn ẹlòmíràn. Èyí máa ń yọrí sí ìbùkún jìngbìnnì látọ̀dọ̀ Jèhófà.

Àwọn Ẹni Ìrírí Sọ̀rọ̀

Láàárín àsìkò tí wọ́n fi wà níléèwé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní kíláàsì Gílíádì yìí jàǹfààní àrà ọ̀tọ̀, ní ti pé wọ́n kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélógún, táwọn náà wà ní Ibùdó Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Patterson fún àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Leon Weaver àti Merton Campbell láti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn darí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà onírúurú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, tí àwọn kan lára wọn náà jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́yege Gílíádì. Ńṣe ni gbígbọ́ tí wọ́n gbọ́rọ̀ látẹnu àwọn míṣọ́nnárì onírìírí yìí túbọ̀ fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, àwọn ìdílé wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn lọ́kàn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.

Láti ran kíláàsì tó yege náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè mú ara wọn bá iṣẹ́ táa yàn fún wọn ní ilẹ̀ òkèèrè mu, àwọn ìmọ̀ràn táa fún wọn ní àwọn ọ̀rọ̀ bí irú èyí nínú: “Ẹ ní ẹ̀mí nǹkan yóò dára. Bí ohun kan tó ṣàjèjì gan-an tàbí tí ẹ kò lóye bá ṣẹlẹ̀ sí yín, ẹ má juwọ́ sílẹ̀. Ẹ gbára lé Jèhófà”; “ẹ kọ́ bí ẹ ṣe lè láyọ̀ pẹ̀lú ohunkóhun tí ẹ ní, ẹ sì ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò pèsè àwọn ohun kòṣeémáàní fún yín.” Àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn dá lórí ríran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ láti máa bá a lọ láti láyọ̀ nínú iṣẹ́ táa yàn fún wọn. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ ọ̀hún ni: “Ẹ má fi ibi táa ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn yín sí wéra pẹ̀lú ibi tẹ́ẹ ti wá”; ẹ kọ́ èdè àdúgbò náà kí ẹ sì máa sọ ọ́ dáadáa kí ẹ bàa lè báwọn ènìyàn sọ̀rọ̀”; “ẹ kọ́ àṣà ìbílẹ̀ àti ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ènìyàn náà, nítorí ìyẹn á ràn yín lọ́wọ́ láti dúró ti iṣẹ́ táa yàn fún yín.” Ìṣírí ńlá làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́ fún àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà.

Lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà, David Splane, tó jẹ́ míṣọ́nnárì nígbà kan rí, tó sì kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kejìlélógójì ti Gílíádì, ẹni tó wá ń sìn báyìí gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ àsọyé pàtàkì kan tó dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó gbàfiyèsí náà, “Akẹ́kọ̀ọ́ tàbí Ẹni Tó Ti Kẹ́kọ̀ọ́ Yege—Èwo Lẹ Jẹ́?” Ó béèrè lọ́wọ́ kíláàsì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà pé: “Ojú wo lẹ óò máa fi wo ara yín báyìí bí ẹ ti ń lọ sí ibi iṣẹ́ míṣọ́nnárì táa yàn fún yín? Ṣé bí akẹ́kọ̀ọ́yege tí kò sóhun tí kò mọ̀ nípa iṣẹ́ míṣọ́nnárì ni, àbí bí akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣì ní ohun púpọ̀ láti kọ́?” Arákùnrin Splane là á mọ́lẹ̀ pé ńṣe ni akẹ́kọ̀ọ́yege tó gbọ́n máa ń wo ara rẹ̀ bí akẹ́kọ̀ọ́. Àwọn míṣọ́nnárì gbọ́dọ̀ máa ní èrò náà pé gbogbo ẹni tí àwọ́n bá bá pàdé nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn ló lè rí ohun kan kọ́ wọn. (Fílípì 2:3) A rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ wọn, pẹ̀lú ẹ̀ka iléeṣẹ́ àti pẹ̀lú ìjọ. Arákùnrin Splane rọ̀ wọ́n pé, “ẹ ti yege ìdánwò àṣekágbá yín o, àmọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ṣì ni yín. Ẹ fi yé gbogbo èèyàn pé ẹ wá síbẹ̀ láti wá kẹ́kọ̀ọ́ ni.”

Lẹ́yìn àsọyé yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gba ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà wọn, a sì kéde ibi táa yàn fún wọn sétí ìgbọ́ àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀. Orí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó yege náà wú bí ẹni tó ṣojú fún kíláàsì wọn ti ń ka ìpinnu wọn, èyí tó sọ nípa bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà ti múra tán láti jẹ́ kí àwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ sún wọn láti ṣe púpọ̀púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀.

Gbogbo àwọn tó pésẹ̀ kò ní ṣàìgbà pé ìmọ̀ràn táwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà rí gbà ti túbọ̀ fún ìpinnu wọn lókun láti fi ìfẹ́ hàn fún Ọlọ́run àti aládùúgbò wọn. Ó tún jẹ́ kí wọ́n múra tán ju tí ìgbàkigbà rí lọ láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì táa yàn fún wọn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 10

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yàn wọ́n sí: 20

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 33.7

Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 16.2

Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 12.5

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Kíláàsì Kọkàndínláàádọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead

Ní ti ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Collins, E.; Miles, L.; Alvarado, A.; Lake, J. (2) Van Dusen, L.; Biharie, A.; Heikkinen, H.; Koós, S.; Smith, H. (3) Ashford, J.; Ashford, C.; Boor, C.; Richard, L.; Wilburn, D.; Lake, J. (4) Chichii, K.; Chichii, H.; Ramirez, M.; Baumann, D.; Becker, G.; Biharie, S.; Ramirez, A. (5) Van Dusen, W.; Lemâtre, H.; Pisko, J.; Cutts, L.; Russell, H.; Johnson, R. (6) Becker, F.; Baumann, D.; Johnson, K.; Pifer, A.; Madsen, C.; Lemâtre, J.; Heikkinen, P. (7) Smith, R.; Russell, J.; Collins, A.; Pisko, D.; Wilburn, R.; Koós, G. (8) Cutts, B.; Boor, J.; Madsen, N.; Pifer, S.; Richard, E.; Miles, B.; Alvarado, R.