Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Ń Mú Ọ Sin Ọlọ́run?

Kí Ló Ń Mú Ọ Sin Ọlọ́run?

Kí Ló Ń Mú Ọ Sin Ọlọ́run?

Nígbà kan rí, ọba kan tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run fún ọmọkùnrin rẹ̀ ní ìmọ̀ràn yìí pé: “Mọ Ọlọ́run baba rẹ kí o sì fi ọkàn-àyà pípé pérépéré àti ọkàn tí ó kún fún inú dídùn sìn ín.” (1 Kíróníkà 28:9) Ó ṣe kedere pé, Jèhófà fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ òun fi ọkàn-àyà tó kún fún ìmoore àti ìmọrírì sin òun.

GẸ́GẸ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a ò jẹ́ jiyàn ẹ̀ pé ọkàn-àyà wa kún fún ìmọrírì nígbà tí a kọ́kọ́ gbọ́ nípa àwọn ìlérí Bíbélì. Ojoojúmọ́ la ń kọ́ ohun tuntun nípa àwọn ète Ọlọ́run. Báa ṣe túbọ̀ ń mọ̀ nípa Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ wa láti “fi ọkàn-àyà pípé pérépéré àti ọkàn tí ó kún fún inú dídùn sìn ín” túbọ̀ ń lágbára sí i.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń báa lọ láti sin Jèhófà pẹ̀lú ayọ̀ tí kò lábùlà jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé wọn. Àmọ́ ṣá o, àwọn Kristẹni kan wà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ dáadáa, ṣùgbọ́n bí àkókò ti ń lọ, wọ́n pàdánù àwọn ìdí tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ tó ń sún wa láti sin Ọlọ́run. Ṣe ìyẹn ti ṣẹlẹ̀ sí ọ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má sọ̀rètí nù. Ayọ̀ tó ti sọ nù tún lè padà wá. Lọ́nà wo?

Ronú Lórí Àwọn Ìbùkún Tóo Rí Gbà

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ṣàṣàrò lórí àwọn ìbùkún tóò ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́. Ronú nípa àwọn ẹ̀bùn rere látọ̀dọ̀ Jèhófà: àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ lónírúurú—èyí tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn láìka ipò ẹni láwùjọ tàbí béèyàn ṣe lówó lọ́wọ́ sí—ìyẹn ni àwọn tó dá fún ìlò wa fún jíjẹ àti mímu, ìlera tóo ń gbádùn, ìmọ̀ rẹ nípa òtítọ́ Bíbélì, àti èyí tó wá ṣe pàtàkì jù, ẹ̀bùn Ọmọ rẹ̀ tó fún wa. Ikú rẹ̀ ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ láti fi ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ sin Ọlọ́run. (Jòhánù 3:16; Jákọ́bù 1:17) Bóo ṣe túbọ̀ ń ṣàṣàrò sí i nípa oore Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìmọrírì tóo ní fún un á ṣe túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Nígbà náà, ọkàn-àyà rẹ á wá sún ọ láti sìn ín kí o lè fi ìmoore hàn fún gbogbo ohun tó ti ṣe. Kò sí àní-àní pé wàá tún bẹ̀rẹ̀ sí ronú bíi ti onísáàmù náà, ẹni tó kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa; kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé. . . . Wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.”—Sáàmù 40:5.

Dáfídì, ọkùnrin kan tóun náà láwọn ìṣòro nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ló kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tí Dáfídì wà ní ọ̀dọ́kùnrin èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò rẹ̀ ló fi ń sá kiri bí Sọ́ọ̀lù Ọba àtàwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ ti ń wá a láti pa á. (1 Sámúẹ́lì 23:7, 8, 19-23) Dáfídì tún ní àwọn àìlera tirẹ̀ láti bá jà. Ó jẹ́wọ́ èyí nínú Sáàmù ogójì pé: “Àwọn ìyọnu àjálù ká mi mọ́ títí iye wọn kò fi ṣeé kà. Ọ̀pọ̀ ìṣìnà tèmi lé mi bá ju bí mo ti lè rí i; wọ́n pọ̀ níye ju irun orí mi.” (Sáàmù 40:12) Lóòótọ́ ni, Dáfídì ní ọ̀pọ̀ wàhálà, àmọ́ kò jẹ́ kí wọ́n bo òun mọ́lẹ̀ pátápátá. Láìka àwọn ìṣòro rẹ̀ sí, ó pọkàn pọ̀ sórí àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bù kún un, ó sì wá rí i pé àwọn ìbùkún yẹn pọ̀ ju àwọn wàhálà òun lọ fíìfíì.

Nígbà tó bá dà bí ẹni pé àwọn ìṣòro tóo ní fẹ́ gbé ọ mì, tàbí tí ìmí ẹ̀dùn pé o kò kúnjú ìwọ̀n fẹ́ bò ọ́ mọ́lẹ̀, ó dára kóo dúró díẹ̀ kóo sì ronú lórí àwọn ìbùkún rẹ bí Dáfídì ti ṣe. Kò sí iyèméjì pé, ìmọrírì tóo ní fún irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ ló sún ọ láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà; irú èrò bẹ́ẹ̀ tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú kí ayọ̀ tó ti kú sọ jí, kí ó sì tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sin Ọlọ́run látinú ọkàn tó kún fún ìmọrírì.

Àwọn Ìpàdé Ìjọ Lè Ṣèrànwọ́

Láfikún sí dídá ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun rere tí Jèhófà ń ṣe, ó tún pọn dandan kí á bá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kẹ́gbẹ́. Pípàdé déédéé pẹ̀lú àwọn ọkùnrin, obìnrin, àtàwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì ti pinnu láti sìn ín máa ń fúnni níṣìírí. Àpẹẹrẹ wọn lè ru wá sókè sí ìgbòkègbodò táà ń fi tọkàntọkàn ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Wíwá táà ń wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tún lè fún àwọn náà níṣìírí pẹ̀lú.

Kò sírọ́ ńbẹ̀ pé, táa bá délé lẹ́yìn táa ti ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tó sì ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu, tàbí nígbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá mú wa nítorí àwọn ìṣòro tàbí àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó bíi mélòó kan, ó lè má rọrùn nígbà yẹn láti ronú nípa lílọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nírú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, a ò ní fẹ́ gba ìyẹn láyè fúnra wa rárá, a óò fẹ́ ‘lu ara wa kíkankíkan,’ ká sọ ọ́ lọ́nà yẹn, ká bàa lè ṣègbọràn sí àṣẹ náà pé ká pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa.—1 Kọ́ríńtì 9:26, 27; Hébérù 10:23-25.

Tó bá wa di pé à ń fipá mu ara wa ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ká wá parí èrò pé a ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tinútinú ló fà á? Rárá o. Àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú láyé ọjọ́un, tí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run ò ní pé a ń jiyàn ẹ̀ náà ní láti sapá gidigidi láti ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. (Lúùkù 13:24) Ọ̀kan lára irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nígbà tó ṣàpèjúwe bọ́ràn ṣe rí lára rẹ̀ báyìí pé: “Mo mọ̀ pé nínú mi, èyíinì ni, nínú ẹran ara mi, kò sí ohun rere tí ń gbé ibẹ̀; nítorí agbára àti-fẹ́-ṣe wà pẹ̀lú mi, ṣùgbọ́n agbára àtiṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ kò sí. Nítorí rere tí mo fẹ́ ni èmi kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́ ni èmi fi ń ṣe ìwà hù.” (Róòmù 7:18, 19) Ó sì tún sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Wàyí o, bí mo bá ń polongo ìhìn rere, kì í ṣe ìdí kankan fún mi láti ṣògo, nítorí àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi. . . . Bí mo bá ń ṣe èyí tinútinú, mo ní èrè; ṣùgbọ́n bí mo bá ń ṣe é ní ìlòdìsí ohun tí mo fẹ́, síbẹ̀síbẹ̀ mo ní iṣẹ́ ìríjú kan tí a fi sí ìkáwọ́ mi.”—1 Kọ́ríńtì 9:16, 17.

Bí ọ̀pọ̀ lára wa, Pọ́ọ̀lù ní àwọn ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ tó máa ń dí ìfẹ́ rẹ̀ láti ṣe ohun tó tọ́ lọ́wọ́. Bó ti wù kó rí, ó bá àwọn ìtẹ̀sí náà wọ̀jà, lọ́pọ̀ ìgbà ló sì máa ń borí. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe agbára Pọ́ọ̀lù ló fi ṣàṣeparí èyí. Ó kọ̀wé pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:13) Jèhófà, ẹni tó fún Pọ́ọ̀lù lágbára, yóò fún ìwọ náà lágbára láti ṣe ohun tó tọ́ bóo bá béèrè fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. (Fílípì 4:6, 7) Nítorí náà, ja “ìjà líle fún ìgbàgbọ́,” Jèhófà yóò sì bù kún ọ.—Júúdà 3.

Kò sídìí fún ẹ láti dá nìkan ja ìjà yìí. Nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn Kristẹni alàgbà tó dàgbà dénú, táwọn fúnra wọn ń báa lọ nínú ‘ìjà fún ìgbàgbọ́’ ṣe tán láti ràn ọ́ lọ́wọ́. Tóo bá tọ alàgbà kan lọ fún ìrànlọ́wọ́, yóò gbìyànjú láti “sọ̀rọ̀ ìtùnú” fún ọ. (1 Tẹsalóníkà 5:14) Ohun tó máa jẹ́ góńgó rẹ̀ ni láti hùwà lọ́nà tí yóò fi “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.”—Aísáyà 32:2.

“Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” ó sì ń fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ òun fi ìfẹ́ sin òun. (1 Jòhánù 4:8) Bí ìfẹ́ rẹ fún Ọlọ́run bá nílò pé kóo ta á jí, gbégbèésẹ̀ tó yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀, nípa ṣíṣe àwọn ohun táa tò lẹ́sẹẹsẹ sókè yìí. Inú rẹ yóò dùn pé o ṣe bẹ́ẹ̀.