Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Nǹkan Tó Yẹ Kó Múnú Gbogbo Ènìyàn Dùn”

“Nǹkan Tó Yẹ Kó Múnú Gbogbo Ènìyàn Dùn”

“Nǹkan Tó Yẹ Kó Múnú Gbogbo Ènìyàn Dùn”

IYE ènìyàn tó ń gbé Tuvalu, orílẹ̀-èdè rírẹwà kan tó ní àwọn erékùṣù mẹ́sàn-án ní Gúúsù Pàsífíìkì nínú, tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àtààbọ̀ [10,500]. Síbẹ̀síbẹ̀, nítorí pé “ó jẹ́ ìfẹ́ [Ọlọ́run] pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,” àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò náà tiraka láti ní àwọn ìtẹ̀jáde táa fi ṣàlàyé Bíbélì ní èdè tiwọn. (1 Tímótì 2:4) Èyí jẹ́ ohun kan tó ṣòro níwọ̀n bí wọn kò ti ní ìwé atúmọ̀ tí wọ́n lè fi túmọ̀ èdè wọn lárọ̀ọ́wọ́tó. Ní 1979, míṣọ́nnárì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń sìn ní Tuvalu gba iṣẹ́ yẹn ṣe. Òun àti aya rẹ̀ gbé lọ́dọ̀ ìdílé kan ládùúgbò ọ̀hún, bí wọ́n ṣe kọ́ èdè náà nìyẹn, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ́n kó àwọn ọ̀rọ̀ Tuvaluan jọ sínú ìwé kan. Ní ọdún 1984, Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ ìwé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, jáde ní èdè Tuvaluan.

Dókítà T. Puapua, tó jẹ́ olórí ìjọba Tuvalu tẹ́lẹ̀ kọ lẹ́tà kan to fi sọ nípa bó ṣe mọrírì ìwé Walaaye Titilae náà tó. Ohun tó kọ rèé: “Ìwé yìí tún jẹ́ àfikún tuntun àti èyí tó ṣe pàtàkì sí ‘búrùjí’ ilẹ̀ Tuvalu. Ó yẹ kí inú yín dùn gan-an sí ipa tí ẹ kó—ìyẹn ipa títayọlọ́lá tí ẹ kó nínú gbígbé ìwàláàyè tẹ̀mí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè yìí ró. Ó dá mi lójú pé a óò kọ ọ̀rọ̀ nípa ìwé yìí sínú ìtàn Tuvalu nípa ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú títẹ àwọn ìwé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ jáde. . . . [Àṣeyọrí] yìí jẹ́ nǹkan tó yẹ kó múnú gbogbo ènìyàn dùn.”

Àwọn olùtumọ̀ náà kó onírúurú ọ̀rọ̀ jọ tó mú kí wọ́n tẹ ìwé atúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Tuvaluan jáde ní ọdún 1993. Òun ni ìwé atúmọ̀ èdè àkọ́kọ́ fún gbogbo ẹni tó ń sọ èdè yẹn. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni Ìgbìmọ̀ Èdè ti Orílẹ̀-Èdè Tuvalu béèrè àṣẹ láti lò ó ní mímú ìwé atúmọ̀ èdè ìbílẹ̀ wọn àkọ́kọ́ jáde.

Láti January 1, 1989, ni a ti ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù jáde ní èdè Tuvaluan. Tóo bá lè ka ìwé ìròyìn yìí ní èdè tóo gbọ́ ṣìkejì, o ò ṣe yẹ ojú ìwé kejì wò kí o sì rí i bóyá èdè ìbílẹ̀ tìrẹ gan-an wà lára àwọn èdè táa fi ń tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde? Ó dájú pé kíkà á ní èdè ìbílẹ̀ rẹ yóò túbọ̀ múnú rẹ dùn sí i.