Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àlàáfíà fún Ẹgbẹ̀rúndún Tuntun Kẹ̀?

Àlàáfíà fún Ẹgbẹ̀rúndún Tuntun Kẹ̀?

Àlàáfíà fún Ẹgbẹ̀rúndún Tuntun Kẹ̀?

WỌ́N ṣe ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ Ọdún Ètò Àlàáfíà Kárí Ayé ní Paris àti New York City ní September 14, 1999. Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gíga Jù Lọ fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló polongo èyí fún ọdún 2000. Federico Mayor, olùdarí àgbà fún àjọ UNESCO tẹ́lẹ̀, fi taratara rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé àkókò ti tó “láti dá àjọ kan sílẹ̀ fún ètò àlàáfíà àti àìsí ìwà ipá kárí ayé.”

Àjọ UNESCO ní ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n máa ń sọ pé, “níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ọkàn èèyàn ni ogun ti máa ń bẹ̀rẹ̀, inú ọkàn èèyàn náà la gbọ́dọ̀ kọ́ ohun tó máa mú àlàáfíà wá sí.” Láti lè ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àjọ náà pinnu láti gbé ètò àlàáfíà lárugẹ nípasẹ̀ “ẹ̀kọ́ kíkọ́, ìfikùnlukùn, àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀.” Ọ̀gbẹ́ni Mayor sọ pé kò tó “kéèyàn wulẹ̀ jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ lásán, kódà sísá fógun pàápàá kò tó, bí kò ṣe pe kéèyàn kúkú jẹ́ olùwá àlàáfíà.”

Ó ṣeni láàánú pé àlàáfíà jìnnà pátápátá sí ọdún 2000. Àwọn ìtàn òde òní—títí kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nínú ọdún 2000—ti fi hàn pé èèyàn ò tóótun láti dènà ogun àti ìwà ipá, láìfi ìsapá àtọkànwá wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ pè.

Àmọ́, ó yẹ ká kíyè sí i pé àlàáfíà tan mọ́ ẹ̀kọ́ kíkọ́ lóòótọ́. Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rìnlá ó dín ọgọ́rùn-ún [2,700] ọdún sẹ́yìn pé: “Gbogbo ọmọ rẹ yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀ yanturu.” (Aísáyà 54:13) Wòlíì yìí kan náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò kan tí àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè yóò máa wọ́ tìrítìrí lọ sínú ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà Ọlọ́run láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà Rẹ̀. Kí ni àbájáde rẹ̀? “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Aísáyà 2:2-4) Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan jákèjádò ayé, èyí tó ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá ìkórìíra láàárín orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà, èyí tó máa ń dá ọ̀pọ̀ jù lọ ogun sílẹ̀.

Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, kò ní sí ogun mọ́ nínú Ìjọba Ọlọ́run, èyí tó máa mú àlàáfíà àti ààbò tí kì yóò dópin wá sórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 72:7; Dáníẹ́lì 2:44) Nígbà náà, ọ̀rọ̀ onísáàmù náà yóò wá nímùúṣẹ pé: “Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, bí ó ti gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayanilẹ́nu kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 46:8, 9.