Àwọn Ọgbẹ́ Ogun
Àwọn Ọgbẹ́ Ogun
ẸNÌ kan tó jẹ́ sójà tẹ́lẹ̀, tó bá wọn ja Ogun Àgbáyé Kejì, sọ pé: “Nínú ogun, kì í sí aṣẹ́gun. Kìkì àwọn tó pàdánù ló wà.” Ọ̀pọ̀ ló máa gba ohun tó sọ yìí gbọ́. Ohun tí ogun ń fà kò ṣeé kó; àtàwọn tó ṣẹ́gun àtàwọn tó pàdánù ló máa ń fojú winá. Kódà lẹ́yìn tí wọ́n ti bọ́ra ogun sílẹ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ni àwọn ọgbẹ́ yànmàkàn tí ogun náà dá sí wọn lára ṣì máa ń pọ́n lójú.
Irú àwọn ọgbẹ́ wo ni? Ogun lè pa àwọn ènìyàn nípakúpa, kó wá fi àìmọye àwọn ọmọ òrukàn àtàwọn opó sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó là á já ló máa ń ní àwọn ọgbẹ́ gidi tó ṣeé fojú rí àti àwọn àpá tó máa ń dá sínú ọkàn wọn. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lè di aláìní dúkìá kankan mọ́ tàbí kí wọ́n di ẹni táa fagbára sọ di olùwá-ibi-ìsádi. Ǹjẹ́ a lè fojú inú wo irú ìkórìíra àti ìbànújẹ́ tó máa wà lọ́kàn àwọn tó la irú ogun bẹ́ẹ̀ já?
Àwọn Ọgbẹ́ Tí Ń Gbinnikún
Àwọn ọgbẹ́ tí ogun máa ń dá sí ọkàn àwọn èèyàn máa ń gbinnikún sí i ni, kódà lẹ́yìn tó ti pẹ́ tí wọ́n ti dáwọ́ ìjà dúró, tí ìbọn kò dún mọ́, táwọn sójà sì ti padà sílé wọn. Àwọn ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìn lè ní ẹ̀tanú kíkorò sí ara wọn. Nípa báyìí, ó lè jẹ́ àwọn ọgbẹ́ tí ogun kan dá sílẹ̀ ló máa ṣokùnfà ogun mìíràn.
Fún àpẹẹrẹ, Àdéhùn Versailles, tí wọ́n fọwọ́ sí ní ọdún 1919 láti fòpin sí Ogun Àgbáyé Kìíní, gbé àwọn ipò kan ka Jámánì lórí, èyí tí àwọn aráàlú náà gbà pé ó ti le koko jù, tí wọ́n sì kà sí ríránró. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Encyclopædia Britannica wí, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àdéhùn náà “bí àwọn ará Jámánì nínú, òun ló sì sún wọn láti máa wá ọ̀nà tí wọn ó fi gbẹ̀san.” Ní ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, “ìbínú tí àdéhùn àlàáfíà náà fà ló jẹ́ kí Hitler mọ ibi tó ti máa bẹ̀rẹ̀,” ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣamọ̀nà sí Ogun Àgbáyé Kejì.
Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ ní Poland, ó sì tàn kálẹ̀ dé àgbègbè Balkan. Àwọn ọgbẹ́ tí onírúurú ẹ̀yà dá sí ara wọn lára láwọn ọdún 1940, ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ogun tí wọ́n jà ní àgbègbè Balkan láwọn ọdún 1990. Ìwé ìròyìn Die Zeit, ti Jámánì ròyìn pé: “Ẹ̀mí ìkórìíra àti ìforóyaró náà wá di egbìnrìn ọ̀tẹ̀, tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń pa ọ̀kan ni òmíràn ń rú, ó sì wá gbèèràn títí tó fi dé àkókò tiwa yìí.”
Kí àwọn èèyàn tó lè ní àlàáfíà, ó dájú pé a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wo àwọn ọgbẹ́ ogun sàn. Báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Kí la lè ṣe láti mú ìkórìíra àti ẹ̀dùn ọkàn kúrò? Ta ló lè wo àwọn ọgbẹ́ ogun sàn?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Fatmir Boshnjaku
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Fọ́tò U.S. Coast Guard; FỌ́TÒ ÀJỌ UN 158297/J. Isaac