Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Sáré ní Irúfẹ́ Ọ̀nà Bẹ́ẹ̀”

“Ẹ Sáré ní Irúfẹ́ Ọ̀nà Bẹ́ẹ̀”

“Ẹ Sáré ní Irúfẹ́ Ọ̀nà Bẹ́ẹ̀”

FOJÚ inú wo ara rẹ ní pápá ìṣeré ìdárayá kan tó kún fún àwọn èèyàn tó ń hára gàgà. Àwọn eléré ìdárayá náà yan wá sórí pápá. Àwọn èrò ń hó yèè bí àwọn tí wọ́n wá wò ṣe ń yọ. Àwọn onídàájọ́ ti wà ní sẹpẹ́ láti fẹsẹ̀ òfin múlẹ̀. Bí onírúurú eré ìdárayá ti ń lọ lọ́wọ́ ni igbe ayọ̀ ìṣẹ́gun àti igbe ìjákulẹ̀ jọ ń dún pa pọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àtẹ́wọ́ ń dún wàá-wàá-wàá fún àwọn tó borí!

Eré ìdárayá tóo ń wò kì í ṣe èyí tí wọ́n ń ṣe láyé òde òní, bí kò ṣe èyí tí wọ́n ṣe ní ẹgbàá ọdún sẹ́yìn ní Isthmus ti Kọ́ríńtì. Níhìn-ín, ọdún méjìméjì síra láti ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa sí ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa ni wọ́n fi ṣe àwọn Eré Ìdárayá Isthmus tó lókìkí. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni gbogbo àwọn ará Gíríìsì fi máa ń wo ìdíje náà. Ohun tí àwọn eré ìdárayá náà wà fún ju kìkì ìdíje adánilárayá lásán lọ. Ńṣe ni wọ́n fi ń múra àwọn eléré ìdárayá náà láti lọ sójú ogun. Àwọn tó borí—tí wọ́n ń júbà fún bí akọni—máa ń gba adé tí wọ́n fi koríko ṣe. Ńṣe ni wọ́n máa ń fún wọn lẹ́bùn lọ́tùn-ún lósì, wọ́n tún máa ń gba owó ìfẹ̀yìntì tó pọ̀ gan-an títí di ọjọ́ ikú wọn.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ nípa àwọn Eré Ìdárayá Isthmus tí wọ́n máa ń ṣe nítòsí Kọ́ríńtì yìí dáadáa, ó sì fi ipa ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni wé ìdíje adánilárayá kan. Nípa títọ́ka sí àwọn sárésáré, àwọn tó ń ja ìjàkadì, àtàwọn tó ń kan ẹ̀ṣẹ́, ó ń fi ohun tó bá a mu wẹ́kú ṣàpèjúwe èrè tó wà nídìí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó péye, ìsapá tó gbéṣẹ́, àti ìfaradà. Láìsí àní-àní, àwọn Kristẹni tó ń kọ̀wé sí náà mọ̀ nípa àwọn eré ìdárayá ọ̀hún. Ó dájú pé àwọn kan lára wọn ti ní láti wà lára èrò tó ń hó yèè níbi eré ìdárayá náà rí. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á mọrírì àwọn àpèjúwe Pọ́ọ̀lù dáadáa. Àwa ńkọ́ lónìí? Àwa náà wà nínú eré ìje kan—fún ìyè àìnípẹ̀kun. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú títọ́ka tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí àwọn ìdíje wọ̀nyẹn?

‘Dídíje Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àwọn Ìlànà Àfilélẹ̀’

Àwọn ohun tí wọ́n ń béèrè pọ̀ gan-an kéèyàn tó lè tóótun láti kópa nínú àwọn eré ìdárayá ayé ọjọ́un. Olùkéde kan yóò mú eléré ìdárayá kọ̀ọ̀kan jáde wá síbi táwọn èrò ìwòran wà, yóò sì kígbe pé: ‘Ǹjẹ́ a rí ẹni tó lè fi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn èyíkéyìí kan ọkùnrin yìí? Ṣé adigunjalè ni tàbí ẹni burúkú tí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ àti ìṣe rẹ̀ jẹ́ ti oníwà ìbàjẹ́ ni?’ Gẹ́gẹ́ bí ìwé Archaeologia Graeca ti wí, “kò sí ẹnikẹ́ni tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí arúfin tàbí ẹni tó sún mọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ [pẹ́kípẹ́kí] tí wọ́n gbà láyè láti kópa nínú ìdíje náà.” Wọn kì í sì í jẹ́ kí ẹni tí ó bá rú òfin eré ìdárayá náà kópa nínú eré náà mọ́.

Kókó yìí ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù pé: “Bí ẹnì kan bá díje nínú àwọn eré pàápàá, a kì í dé e ládé láìjẹ́ pé ó díje ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà àfilélẹ̀.” (2 Tímótì 2:5) Bákan náà, ká tó lè sáré nínú eré ìje ìyè, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa, kí a máa pa àwọn ìlànà ìwà rere rẹ̀ tó ga mọ́, bí a ṣe tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ sínú Bíbélì. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Nípa bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn táa bá ti bẹ̀rẹ̀ eré ìje náà pàápàá, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti máa bá a lọ láti díje ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà àfilélẹ̀ kí a lè máa rí ojú rere Jèhófà nìṣó, kí a sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.

Ìfẹ́ fún Ọlọ́run ni yóò ràn wá lọ́wọ́ jù lọ láti ṣe èyí. (Máàkù 12:29-31) Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò mú kí a fẹ́ láti wu Jèhófà, kí a sì ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.—1 Jòhánù 5:3.

“Mú Gbogbo Ẹrù Wíwúwo Kúrò”

Nínú àwọn eré ìje ayé ọjọ́un, aṣọ tàbí àwọn ohun èlò kì í dẹrù pa àwọn sárésáré. Ìwé náà, The Life of the Greeks and Romans, sọ pé: “Nínú eré àfẹsẹ̀sá, . . . àwọn sárésáré náà kì í wọṣọ sọ́rùn rárá.” Aṣọ tí wọn kò wọ̀ yẹn ń mú kí ara àwọn sárésáré fúyẹ́ gẹgẹ, ohunkóhun ò ní dí wọn lọ́wọ́, ẹsẹ wọn á sì yá nílẹ̀. Kò sí ọ̀rọ̀ pé à ń fagbára ẹni ṣòfò nítorí ẹrù tí kò ní láárí. Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ní èyí lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò . . . , ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.”—Hébérù 12:1.

Irú ẹrù wíwúwo wo ló lè dí wa lọ́wọ́ nínú eré ìje ìyè? Ọ̀kan lè jẹ́ ìfẹ́ láti kó àwọn ohun ìní ti ara tí kò pọndandan jọ tàbí kí a máa gbé ìgbésí ayé olówó. Àwọn kan lè gbọ́kàn lé ọrọ̀ tàbí kí wọ́n fi ṣe orísun ayọ̀ wọn. Irú àwọn “ẹrù” jánganjàngan bẹ́ẹ̀ lè fa sárésáré kan sẹ́yìn débi pé, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Ọlọ́run lè má fi bẹ́ẹ̀ jọ ọ́ lójú mọ́. (Lúùkù 12:16-21) Ìyè àìnípẹ̀kun lè wá dà bí ìrètí kan tí kò tíì sún mọ́ tòsí rárá. Ẹnì kan lè ronú pé, ‘Ayé tuntun náà yóò dé lọ́jọ́ kan, àmọ́ ní báyìí ná, a ṣì lè gbádùn ohun tó wà nínú ayé yìí.’ (1 Tímótì 6:17-19) Irú èrò onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì bẹ́ẹ̀ lè mú kéèyàn yọsẹ̀ kúrò nínú eré ìje ìyè tàbí kí ó má tilẹ̀ jẹ́ kí ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ rárá.

Nínú Ìwàásù lórí Òkè, Jésù sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” Lẹ́yìn náà, nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àìní àwọn ẹranko àtàwọn ewéko, tí ó sì sọ pé àwọn èèyàn níye lórí ju àwọn wọ̀nyẹn lọ, ó wá ṣíni létí pé: “Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:24-33.

“Fi Ìfaradà Sá Eré”

Kì í ṣe gbogbo eré àfẹsẹ̀sá ayé ọjọ́un ni ó jẹ́ eré àsápajúdé sí ibi tí kò jìnnà. Eré kan wà tí wọ́n ń pè ní doʹli·khos, eré yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ nasẹ̀ tó kìlómítà mẹ́rin. Eré tí ń tánni lókun, tó sì ń béèrè ìfaradà ni. Ìtàn táa gbọ́ ni pé, ní ọdún 328 ṣááju Sànmánì Tiwa, lẹ́yìn tí eléré ìdárayá kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ageas borí nínú ìdíje yìí, ó gbéra, ó sì sáré lọ sí Argos, ìlú rẹ̀, láti lọ ròyìn fún wọn pé òun lòhún jáwé olùborí. Eré tó sá ní ọjọ́ yẹn nìkan ń lọ sí nǹkan bí àádọ́fà kìlómítà!

Eré ìje Kristẹni pẹ̀lú jẹ́ eré sísá ọlọ́nà jíjìn tó ń béèrè ìfaradà. Fífaradà á títí dé òpin nínú eré ìje yìí la fi lè rí ojú rere Jèhófà, ká sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Pọ́ọ̀lù sá eré ìje náà ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀. Nígbà tó sún mọ́ òpin ìgbésí ayé rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún un láti sọ pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́. Láti àkókò yìí lọ, a ti fi adé òdodo pa mọ́ dè mí.” (2 Tímótì 4:7, 8) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, a ní láti sá eré náà “dé ìparí.” Bí a ò bá lè fara dà á mọ́ kìkì nítorí pé eré ìje náà gùn ju báa ṣe rò pé ó máa rí níbẹ̀rẹ̀, a jẹ́ pé a kò ní rí èrè wa gbà nìyẹn. (Hébérù 11:6) Ẹ ò rí i pé àdánù gbáà nìyẹn máa jẹ́, nígbà tó jẹ́ pé a ti sún mọ́ òpin eré ìje náà!

Ẹ̀bùn Náà

Àwọn olùborí nínú eré ìje Gíríìkì ayé ọjọ́un ni wọ́n máa ń fún ní nǹkan ọ̀ṣọ́ tí wọ́n sábà máa ń fi ewé igi ṣe, tí wọ́n á wá fi òdòdó ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Nínú Eré Ìdárayá ti Pythia, adé kan tí wọ́n fi ewé igi lọ̀rẹ́ẹ̀lì ṣe làwọn olùborí máa ń gbà. Àwọn adé tí wọ́n fi ewé igi ólífì inú igbó ṣe ni wọ́n máa ń fún àwọn tó borí nínú Eré Ìdárayá ti Òlíńpíìkì, nígbà tó sì jẹ́ pé àwọn adé tí wọ́n fi ewé igi ahóyaya ṣe ni wọ́n máa ń fún àwọn tó borí nínú Eré Ìdárayá Isthmus. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ pé: “Kí wọ́n lè ru ẹ̀mí ìgbónára àwọn sárésáré náà sókè, wọ́n máa ń pàtẹ àwọn adé, àwọn èrè táwọn tó bá borí yóò rí gbà, àti imọ̀ ọ̀pẹ sórí irin ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta kan tàbí tábìlì kan tí wọ́n gbé síbi tí àwọn tó ń kópa nínú ìdíje náà ti lè rí i nígbà tí ìdíje bá ń lọ lọ́wọ́ ní pápá ìṣeré ọ̀hún. Dídé adé náà jẹ́ àmì iyì ńláǹlà fún olùborí. Nígbà tó bá sì ń padà bọ̀ wálé, tayọ̀tayọ̀, tẹ̀yẹtẹ̀yẹ ló máa fi gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọ̀lú.

Èyí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé gbogbo àwọn sárésáré nínú eré ìje ní ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣoṣo ní ń gba ẹ̀bùn náà? Ẹ sáré ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kí ọwọ́ yín lè tẹ̀ ẹ́. . . . Wàyí o, dájúdájú, wọ́n ń ṣe é kí wọ́n lè gba adé tí ó lè díbàjẹ́, ṣùgbọ́n àwa kí a lè gba èyí tí kò lè díbàjẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 9:24, 25; 1 Pétérù 1:3, 4) Ẹ ò ri pé ìyàtọ̀ wà ńbẹ̀! Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí adé tó ń ṣá, èyí tí wọ́n máa ń gbà nínú eré ìdárayá ayé ọjọ́un, ẹ̀bùn tó ń dúró de àwọn tó bá sáré ìje ìyè dópin kò ní bà jẹ́ láé.

Tìtorí adé ìkẹyìn yìí ni àpọ́sítélì Pétérù fi kọ̀wé pé: “Nígbà tí a bá sì fi olórí olùṣọ́ àgùntàn hàn kedere, ẹ ó gba adé ògo tí kì í ṣá.” (1 Pétérù 5:4) Ǹjẹ́ a lè fi ẹ̀bùn èyíkéyìí tí ayé yìí lè fúnni wé àìleèkú, ìyẹn ẹ̀bùn ìwàláàyè tí kò lè díbàjẹ́ nínú ògo ti ọ̀run pẹ̀lú Kristi?

Lóde òní, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni tó ń sáré ni Ọlọ́run kò fòróró yàn láti jẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí, wọn ò sì ní ìrètí àtilọ sí ọ̀run. Eré tí wọ́n ń sá kì í ṣe nítorí àtirí ẹ̀bùn àìleèkú gbà. Àmọ́, Ọlọ́run tún gbé ẹ̀bùn kan tí kò láfiwé ka iwájú wọn. Èyí ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú ìjẹ́pípé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba ti ọ̀run. Ẹ̀bùn yòówù kí Kristẹni kan tó ń sáré máa fojú sọ́nà fún, ó gbọ́dọ̀ fi ìpinnu tó ga àti gbogbo okun rẹ̀ sá eré náà ju àwọn tó ń sáré nínú ìdíje adánilárayá lọ. Èé ṣe? Nítorí pé ẹ̀bùn náà jẹ́ èyí tí kò lè ṣá láé: “Èyí ni ohun ìlérí tí òun fúnra rẹ̀ ṣèlérí fún wa, ìyè àìnípẹ̀kun.”—1 Jòhánù 2:25.

Pẹ̀lú irú ẹ̀bùn tí kò láfiwé bẹ́ẹ̀ táa gbé ka iwájú Kristẹni kan tó ń sáré, irú ojú wo ló yẹ kó máa fi wo àwọn nǹkan tó ń fani mọ́ra nínú ayé yìí? Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ irú ojú tí Pọ́ọ̀lù fi wò ó, ẹni tó sọ pé: “Ní tòótọ́ mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi. Ní tìtorí rẹ̀, èmi ti gba àdánù ohun gbogbo, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí.” Nítorí ìdí èyí, Pọ́ọ̀lù mà fi gbogbo agbára rẹ̀ sáré náà o! “Ẹ̀yin ará, èmi kò tíì ka ara mi sí ẹni tí ó ti gbá a mú nísinsìnyí; ṣùgbọ́n ohun kan wà nípa rẹ̀: Ní gbígbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn àti nínàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú, mo ń lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje.” (Fílípì 3:8, 13, 14) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń sáré náà ló ń tẹjú mọ́ ẹ̀bùn náà. Bó ṣe yẹ kí àwa náà ṣe nìyẹn.

Ẹni Àwòkọ́ṣe Wa

Nínú eré ìje ayé ọjọ́un, ibi gbogbo ni wọ́n ti máa ń kan sáárá sáwọn olùborí. Àwọn tó ń kọ ewì á kọ̀wé nípa wọn, àwọn agbẹ́gilére náà á gbẹ́ ère wọn. Òpìtàn Věra Olivová sọ pé “ẹni àríjó àríyọ̀ ni wọ́n, wọ́n sì gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta.” Wọ́n tiẹ̀ tún máa ń di ẹni àwòkọ́ṣe fún ìran àwọn olùborí tó ń bọ̀ lẹ́yìn.

Tá ni “olùborí” tó ń fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ fún àwọn Kristẹni? Pọ́ọ̀lù dáhùn pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa, bí a ti tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù. Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” (Hébérù 12:1, 2) Bẹ́ẹ̀ ni o, báa bá fẹ́ jẹ́ aṣẹ́gun nínú eré ìje ìyè ayérayé tí à ń sá, a ní láti tẹjú mọ́ Jésù Kristi, tó jẹ́ Àpẹẹrẹ wa. A lè ṣe èyí nípa kíka àwọn ìtàn inú ìwé Ìhìn Rere déédéé, kí a sì máa ṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀nà táa lè gbà fara wé e. Irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ ká rí i pé Jésù Kristi ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run, ẹ̀mí ìfaradà tó ní sì fi hàn gbangba pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí èrè ìfaradà rẹ̀, ó rí ojú rere Jèhófà Ọlọ́run àti ọ̀pọ̀ àgbàyanu àǹfààní gbà.—Fílípì 2:9-11.

Láìsí àní-àní, èyí tó tayọ jù lọ nínú àwọn ànímọ́ Jésù ni ìfẹ́ tó ní. “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:13) Ó fún ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” ní ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ nípa sísọ fún wa pé kí a nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa pàápàá. (Mátíù 5:43-48) Nítorí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run, inú rẹ̀ máa ń dùn láti ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. (Sáàmù 40:9, 10; Òwe 27:11) Wíwò tí a ń wo Jésù gẹ́gẹ́ bí Àpẹẹrẹ wa àti gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ nínú eré ìje ìyè tí ń tánni lókun yìí yóò tún sún wa láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa, yóò sì jẹ́ kí a ní ojúlówó ayọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí à ń ṣe. (Mátíù 22:37-39; Jòhánù 13:34; 1 Pétérù 2:21) Rántí pé Jésù kò béèrè ohun tí kò ṣeé ṣe lọ́wọ́ wa. Ó mú un dá wa lójú pé: “Onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28-30.

Bíi ti Jésù, a ní láti tẹjú mọ́ ẹ̀bùn tí a fi lélẹ̀ fún gbogbo ẹni tó bá fara dà á dé òpin. (Mátíù 24:13) Bí a bá díje ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà àfilélẹ̀, bí á bá mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò, bí a bá sì fi ìfaradà sáré, ó dájú pé a óò ṣẹ́gun. Òpin eré ìje táa ń wò níwájú ń mú ká tẹ̀ síwájú! Ó ń sọ agbára wa dọ̀tun nítorí ayọ̀ tó ń fún wa, ayọ̀ tó ń mú kí ọ̀nà tó wà níwájú wa rọrùn láti rìn ni.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Eré ìje Kristẹni jẹ́ eré sísá ọlọ́nà jíjìn —ó gba ìfaradà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Láìdà bí ti àwọn eléré ìdárayá táa dé ládé, àwọn Kristẹni ń wọ̀nà fún ẹ̀bùn tí kì í bà jẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ẹ̀bùn náà wà fún gbogbo ẹni tó bá fara dà á dé òpin

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]

Copyright British Museum