Báwo Ni Ìfẹ́ Rẹ Ṣe Gbòòrò Tó?
Báwo Ni Ìfẹ́ Rẹ Ṣe Gbòòrò Tó?
“Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”—MÁTÍÙ 22:39.
1. Bí a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, èé ṣe táa tún gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa?
NÍGBÀ tí wọ́n bi Jésù léèrè nípa àṣẹ títóbi jù lọ, ohun tó fi dáhùn ni pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” Lẹ́yìn náà ló wá mẹ́nu kan àṣẹ kejì, tó jọ tàkọ́kọ́, ó ní: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:37, 39) Dájúdájú, ìfẹ́ aládùúgbò wa jẹ́ ọ̀kan lára àmì táa fi ń dá Kristẹni mọ̀. Ní tòdodo, táa bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa. Èé ṣe? Nítorí pé báa ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni pé ká ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì pa á láṣẹ pé ká nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa. Fún ìdí yìí, bí a kò bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, a jẹ́ pé ìfẹ́ táa sọ pé a ní fún Ọlọ́run ò dénú.—Róòmù 13:8; 1 Jòhánù 2:5; 4:20, 21.
2. Irú ìfẹ́ wo ló yẹ ká ní sí aládùúgbò wa?
2 Nígbà tí Jésù sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa, kì í kàn-án ṣe ọ̀ràn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ lásán ló ń sọ. Ìfẹ́ tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí yàtọ̀ sí ìfẹ́ àbínibí tó máa ń wà nínú ìdílé tàbí ìfẹ́ àárín ọkùnrin àtobìnrin. Ìfẹ́ tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni irú ìfẹ́ tí Jèhófà ní fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti ṣèyàsímímọ́ àti irú ìfẹ́ tí àwọn náà ní fún un. (Jòhánù 17:26; 1 Jòhánù 4:11, 19) Júù kan tó jẹ́ akọ̀wé òfin—tí Jésù rí i pé ó sọ̀rọ̀ tòyetòye—gbà pẹ̀lú Jésù pé ó yẹ kéèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run “pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà ẹni àti pẹ̀lú gbogbo òye ẹni àti pẹ̀lú gbogbo okun ẹni.” (Máàkù 12:28-34) Ó kúkú tọ̀nà. Ìfẹ́ tó yẹ kí Kristẹni ní fún Ọlọ́run àti fún aládùúgbò wé mọ́ ìmọ̀lára àti làákàyè wa. Àtọkànwá ni, èrò inú ló sì ń darí rẹ̀.
3. (a) Báwo ni Jésù ṣe kọ́ “ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin” pé kí ó ní èrò tó gbòòrò nípa ẹni tó jẹ́ aládùúgbò rẹ̀? (b) Báwo ni àkàwé Jésù ṣe kan àwọn Kristẹni lónìí?
3 Gẹ́gẹ́ bí Lúùkù ti ròyìn, nígbà tí Jésù sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa, “ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin” béèrè pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Àkàwé ni Jésù fi dá a lóhùn. Àkàwé ọ̀hún lọ báyìí: Wọ́n lu ọkùnrin kan bolẹ̀, wọ́n jà á lólè, wọ́n sì fi í sílẹ̀ ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan sàréè lẹ́bàá ọ̀nà. Àlùfáà kan ló kọ́kọ́ gbabẹ̀ kọjá, ẹ̀yìn ìyẹn ni ọmọ Léf ì kan tún kọjá. Àwọn méjèèjì ò tiẹ̀ ṣe bí ẹni pé àwọn rí i. Níkẹyìn, ará Samáríà kan wá gbabẹ̀ kọjá. Ó rí ọkùnrin tí wọ́n ṣá lọ́gbẹ́ náà, ó sì ṣaájò rẹ̀ gan-an ni. Èwo lára àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni aládùúgbò ọkùnrin tí wọ́n ṣá lọ́gbẹ́? Ìdáhùn náà kò mù rárá. (Lúùkù 10:25-37) Ìyàlẹ́nu gbáà ló máa jẹ́ fún ọkùnrin tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin nígbà tó gbọ́ tí Jésù sọ pé ará Samáríà lè jẹ́ aládùúgbò rere ju àlùfáà àti ọmọ Léfì lọ. Ó ṣe kedere pé ńṣe ni Jésù ń ran ọkùnrin yẹn lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ̀ lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò sí i. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ àwọn Kristẹni rí. Ẹ jẹ́ ká gbé gbogbo ibi tí ìfẹ́ wọn gbòòrò dé yẹ̀ wò.
Ìfẹ́ Nínú Ìdílé
4. Níbo ló yẹ kí Kristẹni ti kọ́kọ́ lo ìfẹ́?
4 Àwọn Kristẹni nífẹ̀ẹ́ àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn—aya nífẹ̀ẹ́ ọkọ, ọkọ nífẹ̀ẹ́ aya, àwọn òbí nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ. (Oníwàásù 9:9; Éfésù 5:33; Títù 2:4) Òtítọ́ ni pé ìdè ìfẹ́ àbínibí wà nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé. Àmọ́, àwọn ìròyìn táa ń gbọ́ nípa àwọn ìgbéyàwó tó ń tú ká, àwọn tọkọtaya tó ń lu ara wọn, àti àwọn tí ń pa ọmọ inú wọn tì, tàbí tí wọ́n ń hùwà àìdáa sí wọn, fi hàn pé wàhálà ti bá ìdílé lóde òní, kò sì dà bí ẹni pé ìfẹ́ni àbínibí tó wà nínú ìdílé tó láti so ó pọ̀ ṣọ̀kan mọ́. (2 Tímótì 3:1-3) Bí ìdílé àwọn Kristẹni yóò bá wà pa pọ̀ digbí, wọ́n ní láti ní irú ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù ní.—Éfésù 5:21-27.
5. Ojú ta ni àwọn òbí ń wò fún ìrànlọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà, kí sì ni ó ti yọrí sí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀?
5 Àwọn Kristẹni òbí máa ń wo àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jèhófà fún wọn ṣọ́, ojú rẹ̀ sì ni wọ́n ń wò fún ìrànlọ́wọ́ láti tọ́ wọn dàgbà. (Sáàmù 127:3-5; Òwe 22:6) Wọ́n ń tipa báyìí mú ìfẹ́ Kristẹni dàgbà, èyí tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí ọ̀dọ́ lè kó sínú rẹ̀. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristẹni òbí ló ti ní irú ayọ̀ tí ìyá kan lórílẹ̀-èdè Netherlands ní. Ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára 575 tó ṣe batisí ní Netherlands lọ́dún tó kọjá. Lẹ́yìn tó rí ìbatisí ọmọ rẹ̀ ọ̀hún, ó kọ̀wé pé: “Ní wákàtí yìí, iṣẹ́ tí mo ti ń ṣe bọ̀ láti ogún ọdún sẹ́yìn ti sèso rere. Gbogbo àkókò àti ìsásókè-sódò mi—títí kan ọjọ́ ìdààmú, ọjọ́ làálàá, àti ọjọ́ ìbànújẹ́—gbogbo rẹ̀ ti dayọ̀ báyìí.” Inú rẹ̀ mà dùn o, pé ọmọ òun fínnúfíndọ̀ yàn láti sin Jèhófà. Ọ̀pọ̀ lára àròpọ̀ 31,089 akéde tó ròyìn ní Netherlands lọ́dún tó kọjá ni wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọ̀dọ̀ òbí wọn.
6. Báwo ni ìfẹ́ Kristẹni ṣe lè ṣèrànwọ́ láti fún ìdè ìgbéyàwó lókun?
6 Pọ́ọ̀lù pe ìfẹ́ ní “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé,” ó sì lè mú kí ìgbéyàwó la àwọn àkókò yánpọnyánrin pàápàá já. (Kólósè 3:14, 18, 19; 1 Pétérù 3:1-7) Nígbà tí ọkùnrin kan ní erékùṣù kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Rurutu, tí ń bẹ ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] kìlómítà sí orílẹ̀-èdè Tahiti, bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ńṣe ni ìyàwó rẹ̀ tutọ́ sókè tó fojú gbà á. Nígbà tó yá, ńṣe ló kó àwọn ọmọ, tó fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, tí wọ́n lọ ń gbé ní Tahiti. Pẹ̀lú gbogbo eléyìí náà, ọkùnrin náà ṣì ń fìfẹ́ hàn sí i, ó ń fi owó ránṣẹ́ sí obìnrin náà déédéé, ó sì ń kàn sí i lórí tẹlifóònù láti mọ̀ bóyá àwọn nǹkan míì tún wà tóun tàbí àwọn ọmọ ṣaláìní. Nípa báyìí, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. (1 Tímótì 5:8) Ìgbà gbogbo ló ń gbàdúrà pé kí ìdílé òun wà pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ìyàwó rẹ̀ padà wálé. Nígbà tó padà dé, ọkùnrin yìí tún ń fi “ìfẹ́, ìfaradà, inú tútù” bá a lò. (1 Tímótì 6:11) Ọdún 1998 lọkùnrin yìí ṣe batisí, inú rẹ̀ sì dùn gan-an lẹ́yìn náà nígbà tí ìyàwó rẹ̀ gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn jẹ́ ọ̀kan lára 1,351 tí a ṣe lọ́dún tó kọjá ní ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ ẹ̀ka Tahiti.
7. Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan láti Jámánì ti wí, kí ló fún ìgbéyàwó rẹ̀ lókun?
7 Ní orílẹ̀-èdè Jámánì, inú ọkùnrin kan kò dùn rárá sí ìfẹ́ tí aya rẹ̀ ní sí òtítọ́ Bíbélì. Ó ló dá òun lójú pé ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tàn án jẹ. Àmọ́ nígbà tó yá, ó kọ̀wé sí Ẹlẹ́rìí tó kọ́kọ́ wàásù fún ìyàwó rẹ̀, ó ní: “Mo dúpẹ́ o, pé o jẹ́ kí ìyàwó mi mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà yẹn, ọkàn mi ò balẹ̀ rárá nítorí pé etí mi ti kún fún ọ̀rọ̀ burúkú táwọn èèyàn ń sọ nípa wọn. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí mo ti ń bá ìyàwó mi lọ sípàdé, mo ti wá rí i pé èmi gan-an ló ṣìnà. Mo mọ̀ pé òtítọ́ ni mò ń gbọ́, ó sì ti fún ìgbéyàwó wa lókun.” Iye 162,932 àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bẹ ní Jámánì—àti 1,773 tí ń bẹ ní àwọn erékùṣù tó wà lábẹ́ ẹ̀ka Tahiti—ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé nínú, tí wọ́n wà níṣọ̀kan nínú ìfẹ́ lọ́nà ti Ọlọ́run.
Ìfẹ́ fún Àwọn Kristẹni Arákùnrin Wa
8, 9. (a) Ta ló kọ́ wa pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin wa, kí sì ni ìfẹ́ ń sún wa láti ṣe? (b) Tọ́ka sí àpẹẹrẹ kan nípa bí ìfẹ́ ṣe lè sún àwọn ará láti ti ara wọn lẹ́yìn.
8 Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni ará Tẹsalóníkà pé: “Ọlọ́run ti kọ́ ẹ̀yin fúnra yín láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Tẹsalóníkà 4:9) Dájúdájú, àwọn tí a “kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà” máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Aísáyà 54:13) Wọ́n máa ń fi ìfẹ́ wọn ṣèwà hù, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti fi hàn nígbà tó sọ pé: “Nípasẹ̀ ìfẹ́, ẹ máa sìnrú fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Gálátíà 5:13; 1 Jòhánù 3:18) Fún àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń ṣe èyí nípa lílọ bẹ àwọn ará tó ń ṣàìsàn wò, nípa sísọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn tó sorí kọ́, àti nípa ṣíṣètìlẹyìn fáwọn aláìlera. (1 Tẹsalóníkà 5:14) Ojúlówó ìfẹ́ táa ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni wà lára ohun tó jẹ́ kí párádísè tẹ̀mí wa máa gbèrú.
9 Àwọn ará fi ìfẹ́ gidi hàn nínú Ìjọ Ancón, tó jẹ́ ọ̀kan lára 544 ìjọ tí ń bẹ lórílẹ̀-èdè Ecuador. Àdánù ńlá kan tó ṣẹlẹ̀ kò jẹ́ kí wọ́n níṣẹ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sówó kankan tó ń wọlé fún wọn. Nítorí náà, àwọn akéde pinnu pé àwọn máa kówó jọ nípa títa oúnjẹ fáwọn apẹja tó wà lágbègbè àwọn, nígbà tí wọ́n bá darí wálé láti odò ẹja lóru. Gbogbo wọn ló fọwọ́ sowọ́ pọ̀, títí kan àwọn ọmọdé. Wọ́n gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ sísè ní agogo kan òru kí wọ́n lè ti sè é tán kí agogo mẹ́rin ìdájí tó lù, nígbà táwọn apẹja máa darí wálé. Àwọn ará wá pín owó tí wọ́n rí kó jọ láàárín ara wọn, ní ìbámu pẹ̀lú àìní kálukú. Irú ìtìlẹyìn tọ̀túntòsì bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí ojúlówó ìfẹ́ Kristẹni.
10, 11. Báwo la ṣe lè fìfẹ́ hàn sí àwọn ará tí àwa alára kò mọ̀?
10 Àmọ́ ṣá o, a kò fi ìfẹ́ wa mọ sọ́dọ̀ àwọn Kristẹni tí àwa fúnra wa mọ̀. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.” (1 Pétérù 2:17) A nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nítorí pé gbogbo wa la jọ ń sin Jèhófà Ọlọ́run pa pọ̀. A máa ń láǹfààní àtifi ìfẹ́ yìí hàn láwọn àkókò ìṣòro. Fún àpẹẹrẹ, ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000, ńṣe ni omíyalé bo orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì, ogun abẹ́lé tó ń jà ní Àǹgólà sì sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di ẹdun arinlẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára 31,725 àwọn ará ní Mòsáńbíìkì àti 41,222 ní Àǹgólà ni ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣàkóbá fún. Ìyẹn ló mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí ní orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà tó múlé gbè wọ́n kó ọ̀pọ̀ nǹkan ránṣẹ́ sí àwọn arákùnrin wọn tí ń bẹ ní ilẹ̀ wọ̀nyí láti lè dín ìṣòro wọn kù. Akitiyan wọn láti fi “àṣẹ́kùsílẹ̀” wọn ránṣẹ́ sí àwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ aláìní fi ìfẹ́ tí wọ́n ní hàn.—2 Kọ́ríńtì 8:8, 13-15, 24.
11 A tún máa ń rí ẹ̀rí pé ìfẹ́ wà láàárín wa nígbà táwọn ará ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè bá ṣètìlẹyìn fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ ní àwọn ilẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ láásìkí. Ẹ jẹ́ ká mú àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Solomon Islands wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé rúkèrúdò wà káàkiri, lọ́dún tó kọjá a rí ìbísí ìpín mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún nínú iye àwọn akéde ní Solomon Islands, pẹ̀lú góńgó 1,697. Wọ́n ń wéwèé láti kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ará erékùṣù náà ń sá fi ibẹ̀ sílẹ̀, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ti Ọsirélíà wá, láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ ọ. Nígbà tó yá, ó di dandan kí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà fi ibẹ̀ sílẹ̀, àmọ́ kí wọ́n tó lọ, wọ́n ti kọ́ àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ibẹ̀ bí wọn yóò ṣe parí iṣẹ́ náà. Wọ́n ti rọ gbogbo irin tí wọ́n máa fi ṣe ògiri gbọ̀ngàn náà wá láti Ọsirélíà, bí wọ́n bá sì lè parí ilé ìjọsìn mèremère yìí—ní àkókò tí ọ̀pọ̀ ilé táwọn èèyàn kọ́ débì kan ti di àpatì—èyí yóò jẹ́ ẹ̀rí tó dáa gan-an sí orúkọ Jèhófà àti sí ìfẹ́ àwọn ará.
A Nífẹ̀ẹ́ Ayé Gẹ́gẹ́ Bí Ọlọ́run Ti Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀
12. Báwo la ṣe ń ṣàfarawé Jèhófà nínú ìṣesí wa sí àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà ẹ̀sìn wa?
12 Ṣé ìdílé wa àti ẹgbẹ́ àwọn ará nìkan la nífẹ̀ẹ́ sí? Rárá o, ìfẹ́ wa kò ní mọ síbẹ̀ bí a bá jẹ́ “aláfarawé Ọlọ́run.” Jésù sáà sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Éfésù 5:1; Jòhánù 3:16) Gẹ́gẹ́ bíi ti Jèhófà Ọlọ́run, a ń fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn—títí kan àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà ẹ̀sìn wa. (Lúùkù 6:35, 36; Gálátíà 6:10) A ń ṣe èyí ní pàtàkì nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà, àti nípa sísọ fáwọn ẹlòmíì nípa ìfẹ́ ńlá tí Ọlọ́run ní sí wọn. Èyí lè yọrí sí ìgbàlà fún ẹnikẹ́ni tó bá fetí sílẹ̀.—Máàkù 13:10; 1 Tímótì 4:16.
13, 14. Kí ni díẹ̀ lára ìrírí àwọn ará tó f ìfẹ́ hàn sáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọ̀ wọ́n lọ́rùn rárá láti ṣe bẹ́ẹ̀?
13 Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn àwọn òjíṣẹ́ mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní Nepal yẹ̀ wò. Ìlú ńlá kan tó wà ní ìwọ̀ oòrùn gúúsù orílẹ̀-èdè yẹn ni a yàn wọ́n sí. Ọdún márùn-ún gbáko ni wọ́n sì ti fìfẹ́ hàn nípa fífi sùúrù jẹ́rìí ní ìlú náà àtàwọn abúlé tó yí i ká. Láti kárí ìpínlẹ̀ wọn, wọ́n máa ń gun kẹ̀kẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí nínú ooru tó mú kọjá ìwọ̀n ogójì lórí òṣùwọ̀n Celsius. Ìfẹ́ àti “ìfaradà [wọn] nínú iṣẹ́ rere” so èso rere nígbà táa dá ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ kan sílẹ̀ ní ọ̀kan nínú àwọn abúlé náà. (Róòmù 2:7) Ní March 2000, èèyàn méjìlélọ́gbọ̀n ló wá gbọ́ àsọyé fún gbogbo èèyàn látẹnu alábòójútó àyíká tó wá bẹ̀ wọ́n wò. Lọ́dún tó kọjá, Nepal ní góńgó 430 nínú iye akéde—èyí jẹ́ ìbísí ìpín mẹ́sàn-án nínú ọgọ́rùn-ún. Ó dájú pé Jèhófà ń bù kún ìtara àti ìfẹ́ àwọn ará ní ilẹ̀ náà.
14 Ní orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà, àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe onígbà kúkúrú lọ wàásù láàárín ẹ̀yà Íńdíà tí wọ́n ń pè ní Wayuu. Kí ìwàásù lè ṣeé ṣe, wọ́n ní láti kọ́ èdè tuntun. Àmọ́ a san èrè fún ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn nígbà tí èèyàn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n torí bọ wábiwọ́sí òjò láti wá gbọ́ àsọyé kan fún gbogbo èèyàn. Irú ìtara onífẹ̀ẹ́ táwọn aṣáájú ọ̀nà wọ̀nyí fi hàn wà lára ohun tó jẹ́ kí Kòlóńbíà ní ìbísí ìpín márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àti góńgó 107,613 iye akéde. Ní Denmark, arábìnrin àgbàlagbà kan fẹ́ wàásù ìhìn rere fáwọn ẹlòmíì, ṣùgbọ́n aláàbọ̀ ara ni. Kò tìtorí èyí jọ̀gọ̀ nù. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ lẹ́tà sí àwọn olùfìfẹ́hàn. Ní báyìí, ó ń kọ lẹ́tà sí èèyàn méjìlélógójì, ó sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́kànlá. Ó jẹ́ ọ̀kan lára 14,885 góńgó akéde tó ròyìn ní Denmark lọ́dún tó kọjá.
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọ̀tá Rẹ
15, 16. (a) Báwo ni Jésù ṣe sọ pé kí ìfẹ́ wa gbòòrò tó? (b) Báwo làwọn arákùnrin tí ń mú ipò iwájú ṣe fi ìfẹ́ bá ẹnì kan tó fẹ̀sùn èké kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lò?
15 Jésù sọ fún ọkùnrin náà tó jẹ́ ògbóǹtagí nínú Òfin pé ará Samáríà lè jẹ́ aládùúgbò rẹ̀. Nínú Ìwàásù tí Jésù ṣe lórí Òkè, kò tiẹ̀ fi mọ síbẹ̀, ó tún tẹ̀ síwájú pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ, kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé: Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:43-45) Kódà bí ẹnì kan bá gbéjà kò wá, a máa ń gbìyànjú láti “fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:19-21) Bó bá ṣeé ṣe, a óò bá a sọ̀rọ̀ nípa ohun táa ní, tó ṣeyebíye jù lọ sí wa, ìyẹn ni òtítọ́.
16 Ní orílẹ̀-èdè Ukraine, àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Kremenchuk Herald, pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹ̀ya ìsìn eléwu. Ọ̀ràn kékeré kọ́ nìyí o, torí pé ní Yúróòpù àwọn kan ń pe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ yìí kí àwọn èèyàn lè gbà pẹ̀lú wọn pé kí wọ́n ká iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ kò tàbí kí wọ́n fòfin dè é. Ìdí nìyẹn táa fi lọ bá olóòtú ìwé ìròyìn náà pé kó gbé ìròyìn míì jáde fáyé gbọ́ láti fi ṣàlàyé pé ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ó gbà, ṣùgbọ́n nínú ìròyìn tó gbé jáde ńṣe ló tún ń sọ pé òótọ́ pọ́ńbélé lohun táwọn gbé jáde tẹ́lẹ̀. Nígbà tọ́ràn ti wá rí báyìí, àwọn arákùnrin tí ń mú ipò iwájú tún lọ bá a pẹ̀lú àfikún ìsọfúnni. Níkẹyìn, olóòtú náà gbà pé ọ̀ràn ò rí báwọn ṣe kọ́kọ́ sọ ọ́, ó sì wá tẹ ọ̀rọ̀ míì jáde, tó fi sọ pé àwọn ti kó ọ̀rọ̀ àwọn jẹ. Bíbá a sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ láìfibọpo-bọyọ̀ àti lọ́nà pẹ̀lẹ́tù ni ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ láti fi yanjú ọ̀ràn yìí, ó sì so èso rere.
Báwo La Ṣe Lè Mú Ìfẹ́ Dàgbà?
17. Kí ló fi hàn pé ó lè nira nígbà míì láti fìfẹ́ bá àwọn èèyàn lò?
17 Gbàrà táa bá bí ọmọ tuntun sílé ayé làwọn òbí rẹ̀ máa ń nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Fífi ìfẹ́ bá àwọn àgbàlagbà lò kì í sábàá wá wẹ́rẹ́ báyẹn. Bóyá ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ fún wa léraléra pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa, tó fi hàn pé ohun táa gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ lé lórí ni. (1 Pétérù 1:22; 4:8; 1 Jòhánù 3:11) Jésù mọ̀ pé a óò dán ìfẹ́ wa wò, ìyẹn ló jẹ́ kó sọ pé ká máa dárí ji arákùnrin wa “títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.” (Mátíù 18:21, 22) Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú rọ̀ wá pé ká ‘máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Kólósè 3:12, 13) Abájọ táa fi sọ fún wa pé: ‘Ká máa lépa ìfẹ́’! (1 Kọ́ríńtì 14:1) Báwo la ṣe lè ṣe èyí?
18. Kí ni àwọn nǹkan tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbin ìfẹ́ fáwọn ẹlòmíì sọ́kàn?
18 Èkíní, a ò ní gbàgbé ìfẹ́ táa ní fún Jèhófà Ọlọ́run. Ìfẹ́ yìí jẹ́ amóríyá fún wa láti nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa. Èé ṣe? Nítorí pé táa bá fìfẹ́ báni lò, yóò buyì kún Baba wa ọ̀run, yóò sì mú ìyìn àti ògo bá a. (Jòhánù 15:8-10; Fílípì 1:9-11) Èkejì, a óò máa gbìyànjú láti fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Gbogbo ìgbà táa bá ṣẹ̀, Jèhófà là ń ṣẹ̀ sí; síbẹ̀, léraléra ló máa ń dárí jì wá, ó sì ń bá a nìṣó ní fífẹ́ wa. (Sáàmù 86:5; 103:2, 3; 1 Jòhánù 1:9; 4:18) Báa bá fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó, a óò nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, a ó sì máa dárí jì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá. (Mátíù 6:12) Ẹ̀kẹta, a óò máa ṣe sí àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí a ti fẹ́ kí wọ́n máa ṣe sí wa. (Mátíù 7:12) Nítorí pé aláìpé ni wá, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń fẹ́ ìdáríjì. Fún àpẹẹrẹ, táa bá sọ ohun tó bí àwọn ẹlòmíì nínú, a máa ń retí kí wọ́n rántí pé kò sẹ́ni tí kì í fi ahọ́n rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ lóòrèkóòrè. (Jákọ́bù 3:2) Báa bá fẹ́ káwọn èèyàn fìfẹ́ bá wa lò, ó yẹ kí àwa náà fìfẹ́ bá wọn lò.
19. Báwo la ṣe lè wá ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ nínú mímú ìfẹ́ dàgbà?
19 Ẹ̀kẹrin, a óò máa béèrè fún ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, nítorí pé ìfẹ́ jẹ́ ara èso tẹ̀mí. (Gálátíà 5:22, 23) Ìfẹ́ láàárín àwọn ọ̀rẹ́, ìfararora láàárín ẹbí, àti ìfẹ́ láàárín takọtabo sábà máa ń wá wẹ́rẹ́ ni. Àmọ́ a nílò ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Jèhófà láti lè ní irú ìfẹ́ tí Jèhófà ní, ìfẹ́ tó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé. A lè wá ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ nípa kíka Bíbélì tí a mí sí. Fún àpẹẹrẹ, báa bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù, a óò rí i bó ṣe bá àwọn èèyàn lò, a sì lè kọ́ láti fara wé e. (Jòhánù 13:34, 35; 15:12) Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún lè béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, pàápàá táa bá bá ara wa nínú ipò tí kò tí rọrùn fún wa láti fìfẹ́ báni lò. (Lúùkù 11:13) Boríborí rẹ̀, a lè máa lépa ìfẹ́ nípa ṣíṣàì jìnnà sí ìjọ Kristẹni. Wíwà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin onífẹ̀ẹ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ dàgbà.—Òwe 13:20.
20, 21. Ìfẹ́ títayọ wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi hàn nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000?
20 Lọ́dún tó kọjá, a ní góńgó 6,035,564 àwọn akéde ìhìn rere náà kárí ayé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo àròpọ̀ 1,171,270,425 wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ títọ àwọn èèyàn lọ, láti sọ fún wọn nípa ìhìn rere yẹn. Ìfẹ́ ló mú kí wọ́n fara da ooru, òjò, àti òtútù lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Ìfẹ́ ló sún wọn láti bá àwọn ọmọléèwé àti òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì bá àlejò tí wọn ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀ lójú pópó àti láwọn ibòmíràn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni táwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀ wò ni kò kà wọ́n sí, àwọn díẹ̀ tiẹ̀ gbéjà kò wọ́n. Ṣùgbọ́n àwọn kan fìfẹ́ hàn, ìyẹn ló fi jẹ́ pé a ṣe 433,454,049 ìpadàbẹ̀wò, a sì darí 4,766,631 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. a
21 Ẹ ò rí i pé ìfẹ́ kékeré kọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní fún Ọlọ́run wọn àti fún aládùúgbò wọn! Iná ìfẹ́ yẹn kò ní kú láé. Ó dá wa lójú pé ẹ̀rí tí a óò jẹ́ fáráyé ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2001 yóò túbọ̀ pọ̀ sí i. Ǹjẹ́ kí ìbùkún Jèhófà máa bá a lọ lórí àwọn olùjọsìn rẹ̀ olóòótọ́ àti onítara bí wọ́n ṣe ń rí i dájú pé ‘gbogbo àlámọ̀rí wọn ń ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́’!—1 Kọ́ríńtì 16:14.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún kúlẹ̀kúlẹ̀ Ìròyìn Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn 2000, wo ṣáàtì tó wà ní ojú ìwé 18 sí 21.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Ta ni a ń fara wé nígbà táa bá nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa?
• Báwo ló ṣe yẹ kí ìfẹ́ wa gbòòrò tó?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìrírí tó fi ìfẹ́ Kristẹni hàn?
• Báwo la ṣe lè mú ìfẹ́ Kristẹni dàgbà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 18-21]
ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 2000 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ
(Wo àdìpọ̀)
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìfẹ́ Kristẹni lè so ìdílé pọ̀ ṣọ̀kan
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìfẹ́ ń sún wa láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí wa