Wíwo Àwọn Ọgbẹ́ Ogun Sàn
Wíwo Àwọn Ọgbẹ́ Ogun Sàn
OGÚN ọdún ni Abraham fi wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun adàlúrú. a Àmọ́ ó ti ṣíwọ́ ogun jíjà báyìí, kò sì ní lọ sójú ogun mọ́ láé. Àní sẹ́, àwọn kan lára àwọn ọ̀tá rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ti wá di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ báyìí. Kí ló mú un yí padà? Bíbélì ni. Ó fún Abraham ní ìrètí àti ìjìnlẹ̀ òye, ó ràn án lọ́wọ́ láti wo àwọn àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn bí Ọlọ́run ṣe ń wò wọ́n. Bíbélì mú ìfẹ́ láti jagun kúrò lọ́kàn rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wo àwọn ìbànújẹ́, ẹ̀dùn ọkàn, ìkórìíra, àti ìbìnújẹ́ kíkorò tó ní sàn. Ó rí i pé oògùn tó ń wo ọkàn sàn wà nínú Bíbélì.
Báwo ni Bíbélì ṣe ń ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti wo àwọn ọgbẹ́ ti èrò inú sàn? Kò lè yí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí Abraham padà. Ṣùgbọ́n, kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ṣíṣàṣàrò lórí rẹ̀ mú kí ìrònú rẹ̀ bá ti Ẹlẹ́dàá mu. Ó ti wá ní ìrètí nípa ọjọ́ iwájú báyìí, ó sì ti ní àwọn góńgó tuntun. Àwọn ohun tó ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run ti wá ṣe pàtàkì lójú òun náà. Gbàrà tí èyí bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ ni àwọn ọgbẹ́ tó wà lọ́kàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí san. Bí Abraham ṣe di ẹni tó yí padà nìyẹn.
Kíkó Sínú Ogun Abẹ́lé
Wọ́n bí Abraham ní ilẹ̀ Áfíríkà láwọn ọdún 1930. Lẹ́yìn ogun àgbáyé kejì, orílẹ̀-èdè lílágbára kan tó múlé gbè wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso orílẹ̀-èdè rẹ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Abraham ló ń fẹ́ òmìnira. Ní ọdún 1961, Abraham dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ajìjàgbara kan tó gbé ogun abẹ́lẹ̀ dìde sí orílẹ̀-èdè lílágbára náà.
Abraham ṣàlàyé pé: “Ọ̀tá wa ni wọ́n. Wọ́n wéwèé láti pa wá, àwa náà sì múra tán láti pa wọ́n.”
Gbogbo ìgbà ni ẹ̀mí Abraham máa ń wà nínú ewu, ìdí nìyẹn tó fi sá lọ sí Yúróòpù ní 1982, lẹ́yìn tó ti lo ogún ọdún nínú ogun jíjà. Ó ti wá ń lọ sí ẹni àádọ́ta ọdún wàyí, kò sì sí ohun tó ń fi àkókò rẹ̀ ṣe, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ìgbésí ayé rẹ̀ nìyẹn. Báwo ni gbogbo ohun tó fọkàn sí ṣe wá rí? Báwo ni ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ yóò ṣe rí? Abraham wá bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé wọn. Ó rántí pé nígbà tóun wà ní Áfíríkà láwọn ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, òun tí ka ìwé ìléwọ́ kan tí Ẹlẹ́rìí kan fún òun. Ìwé ìléwọ́ náà ṣàpèjúwe Párádísè tó ń bọ̀ lórí ilẹ̀ ayé àti ìjọba kan láti ọ̀run tó máa ṣàkóso lórí àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Hẹ̀n-ẹ́n, lóòótọ́?
Abraham sọ pé: “Inú Bíbélì ni mo tí kẹ́kọ̀ọ́ pé ńṣe ni mo kàn fi
gbogbo àwọn ọdún tí mo fi ń jagun wọ̀nyẹn ṣòfò. Ìjọba kan ṣoṣo tí kò ní rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ ni Ìjọba Ọlọ́run.”Kété lẹ́yìn tí Abraham ṣe batisí, tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Robert sá kúrò ní Áfíríkà, tó sì wá sí ìlú ńlá tí Abraham ń gbé ní Yúróòpù. Robert àti Abraham ti jọ dojú kọ ara wọn nínú ogun kan náà rí. Robert ti sábà máa ń ronú nípa ojúlówó ète tó wà nínú ìgbésí ayé. Ẹnì kan tó lẹ́mìí ìsìn ni, níwọ̀n bí ó sì ti ka àwọn apá ibì kan nínú Bíbélì, ó mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ìjọ Abraham sọ pé àwọn ó ran Robert lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye Bíbélì sí i, kíá ló gbà láìjanpata.
Robert ṣàlàyé pé: “Láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá ni inú mi ti dùn sí bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ń lo orúkọ Jèhófà àti ti Jésù, tí wọ́n gbà pé wọn kì í ṣe ẹnì kan náà. Ìyẹn bá ohun tí mo ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì mu wẹ́kú. Àwọn Ẹlẹ́rìí tún máa ń múra dáadáa, wọ́n sì nínúure sí àwọn ẹlòmíràn láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí. Àwọn nǹkan wọ̀nyẹn nípa tó lágbára lórí mi.”
Àwọn Ọ̀tá Di Ọ̀rẹ́
Robert àti Abraham, àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá ara wọn tẹ́lẹ̀, ti wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ báyìí. Wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí oníwàásù alákòókò kíkún nínú ìjọ kan náà tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Abraham ṣàlàyé pé: “Lákòókò ogun yẹn, mo sábà máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè tó múlé gbe ara wọn—tí ọ̀pọ̀ lára wọn wà nínú ẹ̀sìn kan náà—fi ní láti kórìíra ara wọn. Inú ẹ̀sìn kan náà ni èmi àti Robert wà, síbẹ̀ a lọ ń bára wa jà lójú ogun. Àwa méjèèjì ti wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí, ẹ̀sìn wa sì ti so wá pọ̀ ṣọ̀kan.”
Robert fi kún un pé: “Ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ nìyẹn. A ti wá wà nínú ẹ̀sìn kan tó sọ àwa méjèèjì di ara ojúlówó ẹgbẹ́ àwọn ará báyìí. A ò ní lọ jagun mọ́ láé.” Bíbélì ti ní ipa tó lágbára lórí ọkàn àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá ara wọn tẹ́lẹ̀ yìí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìfọkàntánni àti ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ wá rọ́pò ìkórìíra àti ẹ̀tanú.
Lákòókò kan náà tí Abraham àti Robert wà lójú ogun, àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì mìíràn dojú kọ ara wọn nínú ogun kan tí àwọn orílẹ̀-èdè méjì mìíràn tí wọ́n múlé gbe ara wọn ń jà. Láìpẹ́ Bíbélì ṣiṣẹ́ bí oògùn tí kì í bà á tì láti wo ọkàn tiwọn náà sàn. Lọ́nà wo?
Kí N Pa Wọ́n—Lẹ́yìn Náà Kí N Fi Ẹ̀mí Mi Rúbọ
Gabriel, tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú ìdílé kan tí kò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá ni wọ́n kọ́ pé ogun mímọ́ ni orílẹ̀-èdè rẹ̀ ń jà. Nítorí náà, nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún, ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ológun, ó sì ní kí wọ́n jẹ́ kí òun lọ sójú ogun. Fún oṣù mẹ́tàlá gbáko ló fi wà níbi tí ogun ti le gan-an, ìgbà mìíràn sì wà tó máa ń wà níbi tí kò ju kìlómítà kan ààbọ̀ péré síbi táwọn ọ̀tá wà. Ó sọ pé: “Mo rántí àkókò kan pàtó. Olùdarí wa sọ fún wa pé àwọn ọ̀tá máa bá wa jà lóru ọjọ́ yẹn. Ẹ̀rù bà wá tó jẹ́ pé ṣe la yìnbọn ní gbogbo òru náà.” Ó ka àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè tó múlé gbè wọ́n sí ọ̀tá rẹ̀, tí ikú tọ́ sí. “Gbogbo èrò mi ni pé kí n pa iye ẹni tí mo bá lè pa. Lẹ́yìn náà, mo fẹ́ fi ẹ̀mí mi rúbọ, bíi ti ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi.”
Mátíù 24:3-14; 2 Tímótì 3:1-5.
Àmọ́ ṣá, bí àkókò ti ń lọ, gbogbo nǹkan tojú sú Gabriel. Ó sá lọ sórí àwọn òkè ńlá, ó rọra yọ́ kẹ́lẹ́ kọjá ẹnu ibodè bọ́ sí orílẹ̀-èdè kan tí kò dá sí tọ̀túntòsì, ó sì tibẹ̀ forí lé Yúróòpù. Ó sáà ń bi Ọlọ́run ní ohun tó fà á tí ìgbésí ayé fi nira tó bẹ́ẹ̀, bóyá àwọn ìṣòro jẹ́ ìyà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Wọ́n sì fi ohun tó fà á tí ìgbésí ayé fi kún fún ìṣòro lóde òní hàn án nínú Bíbélì.—Bí ẹ̀kọ́ tí Gabriel ń kọ́ látinú Bíbélì ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń mọ̀ pé òtítọ́ ni. “Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé a lè wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Kẹ́ẹ sì wá wò ó, ohun tó ti ń wù mí láti kékeré nìyẹn.” Bíbélì tu Gabriel nínú, ó sì tu ọkàn rẹ̀ tí wàhálà ti bá títí di àkókò yẹn lára. Àwọn ọgbẹ́ tí ń bẹ nínú ọkàn rẹ̀ lọ́hùn-ún bẹ̀rẹ̀ sí san. Nítorí bẹ́ẹ̀, kò sí ìkórìíra kankan lọ́kàn Gabriel mọ́ nígbà tó fi máa bá Daniel, tó jẹ́ ọ̀tá rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pàdé. Àmọ́, kí ló gbé Daniel wá sí Yúróòpù?
“Tó Bá Jẹ́ Pé Lóòótọ́ Lo Wà, Jọ̀wọ́ Ràn Mí Lọ́wọ́!”
Inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ Daniel dàgbà, ìgbà tó sì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún ni wọ́n pè é síṣẹ́ ológun. Wọ́n rán an kó lọ ja ogun kan náà tí Gabriel jà, àmọ́ ọ̀tá ni wọ́n jẹ́ síra. Nítòsí ojú ìjà náà, Daniel wà nínú ọkọ̀ ológun kan tí wọ́n sọ ohun abúgbàù lù. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú, òun náà fara pa yánnayànna, wọ́n sì mú un lẹ́rú. Ó lo ọ̀pọ̀ oṣù nílé ìwòsàn àti ní àgọ́ kan, kó tó di pé wọ́n fi í ránṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè kan tí kò dá sí tọ̀túntòsì. Ó dá nìkan wà, kò sì ní dúkìá kankan, ló bá ronú àtipa ara rẹ̀. Daniel wá gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo wà, jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́!” Ọjọ́ tó tẹ̀ le gan-an ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé rẹ̀, wọ́n sì dáhùn ọ̀pọ̀ lára àwọn ìbéèrè rẹ̀. Níkẹyìn, ó lọ sí Yúróòpù bí olùwá-ibi-ìsádi. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Daniel dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tó kọ́ dín hílàhílo àti ìbìnújẹ́ kíkorò rẹ̀ kù.
Gabriel àti Daniel ti wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ báyìí, wọ́n tí wá wà ní ìṣọ̀kan nínú ẹgbẹ́ àwọn ará nípa tẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣe batisí. Gabriel sọ pé: “Ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà àti ìmọ̀ Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́ láti rí àwọn nǹkan bó ṣe ń rí wọn. Daniel kì í ṣe ọ̀tá mi mọ́. Ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, kíá ni ǹ bá ti pa á. Bíbélì ti kọ́ mi ní ohun tó jẹ́ òdìkejì rẹ̀ gan-an—ìyẹn ni pé kí n múra tán láti kú fún un.”
Daniel sọ pé: “Mo rí àwọn èèyàn tí wọ́n wá láti inú onírúurú ẹ̀sìn àti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń pa ara wọn. Mo tún rí àwọn tó wá látinú ẹ̀sìn kan náà tí wọ́n dojú kọra lójú ogun tí wọ́n sì ń para wọn. Nígbà tí mo rí èyí, mo ronú pé Ọlọ́run ló yẹ ká dá lẹ́bi. Nísinsìnyí, mo ti wá mọ̀ pé Sátánì ló wà nídìí gbogbo ogun. Èmi àti Gabriel ti wá di onígbàgbọ́ alájùmọ̀ṣiṣẹ́pọ̀ báyìí. A kò ní jà mọ́ láé!”
“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yè, Ó sì Ń Sa Agbára”
Kí ló mú kí Abraham, Robert, Gabriel, àti Daniel yí padà pátápátá? Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún wọn láti mú ìkórìíra àti ẹ̀dùn ọkàn tó ti jinlẹ̀ nínú ọkàn wọn kúrò?
Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ka Bíbélì, wọ́n ṣàṣàrò lórí ohun tó wí, wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì, tó ‘yè, tó sì ń sa agbára.’ (Hébérù 4:12) Ẹlẹ́dàá aráyé ni Orísun Bíbélì, ẹni tó mọ bí a ṣe ń yí ọkàn ẹni tó fẹ́ gbọ́ kó sì kẹ́kọ̀ọ́ padà sí rere. “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” Gbàrà tí ẹni tó ń ka Bíbélì bá ti gbà kí Bíbélì darí òun, ó ti tẹ́wọ́ gba àwọn ìlànà àti ọ̀pá ìdiwọ̀n tuntun nìyẹn. Yóò bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ bí Jèhófà ṣe ń wo nǹkan. Ìgbésẹ̀ yìí ń mú ọ̀pọ̀ àǹfààní wá, títí kan wíwo àwọn ọgbẹ́ ogun sàn.—2 Tímótì 3:16.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàlàyé pé kò sí orílẹ̀-èdè kankan, tàbí ẹ̀yà tàbí ìran tó dára tàbí tó burú ju òmíràn lọ. “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” Òǹkàwé tó bá tẹ́wọ́ gba èyí la máa ń ràn lọ́wọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ láti ṣẹ́pá kíkórìíra ẹ̀yà tàbí orílẹ̀ èdè èyíkéyìí.—Ìṣe 10:34, 35.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé kò ní pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi Ìjọba Mèsáyà rọ́pò ètò ìṣàkóso ènìyàn tó wà báyìí. Ìjọba yìí ni Ọlọ́run yóò lò láti “mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” Àwọn àjọ tó máa ń gbé ogun lárugẹ, tí wọ́n sì máa ń rọ àwọn èèyàn láti jagun la óò mú kúrò. Àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tó kú sógun yóò jíǹde, wọn ó sì láǹfààní àtigbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Kò sí ẹni táá tún máa sá fún òfínràn tàbí aninilára kankan mọ́.—Sáàmù 46:9; Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣe 24:15.
Ní ti àwọn èèyàn tó máa wà lákòókò yẹn, Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé . . . Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò bímọ fún ìyọlẹ́nu.” Kò sí àbùkù tàbí ìfarapa èyíkéyìí tí a kò ní wò sàn. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ìgbàgbọ́ nínú irú ìrètí bẹ́ẹ̀ máa ń mú ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn ẹni.—Aísáyà 65:21-23.
Láìsí àní-àní, Bíbélì jẹ́ oògùn tó ń wo ọkàn sàn. Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí wo àwọn ọgbẹ́ ogun sàn. Àwọn tó jẹ́ ọ̀tá ara wọn tẹ́lẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí wà ní ìṣọ̀kan nínú ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé. Ìwòsàn yìí yóò máa bá a lọ nínú ètò tuntun Ọlọ́run, títí kò fi ní sí ìkórìíra àti ìbìnújẹ́ kíkorò, ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn lọ́kàn àwọn ènìyàn mọ́. Ẹlẹ́dàá ṣèlérí pé “àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.”—Aísáyà 65:17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
“Inú Bíbélì ni mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ńṣe ni mo kàn fi gbogbo àwọn ọdún tí mo fi jagun wọ̀nyẹn ṣòfò”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Bíbélì lè ní ipa tó lágbára lórí ọkàn-àyà àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá ara wọn tẹ́lẹ̀
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìfọkàntánni àti ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ wá rọ́pò ìkórìíra àti ẹ̀tanú
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Gbàrà tí ẹni tó ń ka Bíbélì bá ti gbà kí Bíbélì darí òun, ó ti tẹ́wọ́ gba àwọn ìlànà àti ọ̀pá ìdiwọ̀n tuntun nìyẹn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá ara wọn tẹ́lẹ̀ ti wá wà ní ìṣọ̀kan nínú ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé báyìí
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi: FỌ́TÒ ÀJỌ UN 186811/J. Isaac