Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ń Tẹ̀ Síwájú Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀!

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ń Tẹ̀ Síwájú Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀!

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ń Tẹ̀ Síwájú Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀!

Ìròyìn Ìpàdé Ọdọọdún

LÁYÉ táa wà yìí, àwọn èèyàn kì í sábàá gba nǹkan gbọ́, wọ́n sì máa ń ṣiyè méjì. Àmọ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé wọ́n jẹ́ àwọn Kristẹni tó ní ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀. A mú èyí ṣe kedere nígbà ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, èyí táa ṣe lọ́jọ́ Sátidé, October 7, 2000, ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Jersey City, Ìpínlẹ̀ New Jersey. a

Nínú ọ̀rọ̀ tí John E. Barr, alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kọ́kọ́ sọ, ó ní: “Nínú gbogbo ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èèyàn tí ń gbé ayé, àwa mọ̀, a sì gbà gbọ́ pé Kristi Jésù, Ọmọ ọ̀wọ́n fún Jèhófà, ti wà lórí ìtẹ́ báyìí ní ọ̀run, ó sì ń jọba láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀.” Ẹ̀rí tó ti irú ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ni èyí táa rí nínú àwọn ìròyìn mẹ́fà tí ń wúni lórí tó wá láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé.

Fífi Òtítọ́ Bíbélì Ṣẹ́gun Ìbẹ́mìílò ní Haiti

Ìbẹ́mìílò wọ́pọ̀ gan-an ní orílẹ̀-èdè Haiti. John Norman, tó jẹ́ olùṣekòkárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka náà, ròyìn pé: “Àwọn èèyàn sábà máa ń lọ́wọ́ sí voodoo, tí í ṣe bíbọ àwọn baba ńlá, kí wọ́n lè rí ààbò.” Oníṣègùn ìbílẹ̀ kan bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyè méjì nígbà tó kán lẹ́sẹ̀ nínú jàǹbá kan. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì pé: ‘Báwo ni èyí ṣe lè ṣẹlẹ̀ sí mi bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ làwọn ẹ̀mí ń dáàbò bò mí?’ Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ọkùnrin yìí lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ láti já ara rẹ̀ gbà lọ́wọ́ ìbẹ́mìílò. A ń retí ìbísí púpọ̀ sí i ní Haiti, nítorí pé ní April 19, 2000, ìlọ́po mẹ́rin iye àwọn akéde Ìjọba náà ní orílẹ̀-èdè yẹn ló wá síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi.

Ìtara ní Ìpínlẹ̀ Kòríà Tó Lọ Salalu

Ní Kòríà, ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ ló wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Milton Hamilton, tó jẹ́ olùṣekòkárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka náà, sọ pé: “Pẹ̀lú àwọn ògìdìgbó yìí, nǹkan bí ẹ̀ẹ̀kan lóṣù là ń kárí ìpínlẹ̀ wa táwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàdínláàádọ́ta.” Ìbísí ọ̀hún tún gọntíọ nínú iye ìjọ tí wọ́n ti ń lo èdè àwọn adití. Nínú àyíká kan tí wọ́n ti ń lo èdè àwọn adití, ẹgbẹ̀rin [800] ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé ni a ń darí. Èyí jẹ́ ìpíndọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ kan fún akéde kọ̀ọ̀kan. Ó kàn jẹ́ pé àwọn arákùnrin wa tó jẹ́ ọ̀dọ́ ṣì ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ìdúró àìdásí tọ̀túntòsì wọn ni. Àmọ́ o, wọn kì í fìtínà àwọn Kristẹni olóòótọ́ wọ̀nyí, àwọn ni wọ́n sì sábà máa ń fún láwọn iṣẹ́ tó ṣeé gbé fún kìkì àwọn tí wọ́n bá fọkàn tán.

Kíkájú Ohun Tí Ìbísí Béèrè ní Mẹ́síkò

Góńgó 533,665 àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà ló ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ní Mẹ́síkò ní August 2000. Àwọn tó wá síbi Ìṣe Ìrántí lé ní ìlọ́po mẹ́ta iye yẹn. Robert Tracy, tó jẹ́ olùṣekòkárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka náà, sọ pé: “Góńgó táa ń lé lọ́dún yìí ni láti kọ́ òjìlélúgba [240] Gbọ̀ngàn Ìjọba sí i.” Ó wá fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n, a ṣì nílò púpọ̀ sí i.”

Àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mẹ́síkò jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Àlùfáà Kátólíìkì kan sọ nípa ọ̀dọ́ kan pé: “Ì bá wù mí kí n tiẹ̀ rí ọ̀kan ṣoṣo bíi tirẹ̀ láàárín àwọn ọmọ ìjọ mi. Mo máa ń kan sáárá sáwọn èèyàn yìí nítorí ìdúró àìyẹsẹ̀ wọn àti bí wọ́n ṣe ń fọgbọ́n lo Bíbélì. Wọ́n ti gbèjà Ọlọ́run, kódà nígbà tí ẹ̀mí wọ́n wà nínú ewu.”

Ìwà Títọ́ Láàárín Rúkèrúdò ní Sierra Leone

Láti April 1991, tí ogun abẹ́lé ti bẹ́ sílẹ̀ ní Sierra Leone, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ni wọ́n ti pa, tí wọ́n ti ṣe léṣe, tàbí tí wọ́n ti sọ di aláàbọ̀ ara. Bill Cowan, tó jẹ́ olùṣekòkárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka náà, ròyìn pé: “Ogun àti ìpọ́njú ti gbo àwọn èèyàn gan-an. Ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò fẹ́ gbọ́rọ̀ wa tẹ́lẹ̀ ló ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí wa báyìí. Àní nígbà míì, àwọn kan á kàn fẹsẹ̀ ara wọn rìn wá sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba láti wá bá wa ṣèpàdé fúngbà àkọ́kọ́, láìjẹ́ pé ẹnì kan ké sí wọ́n wá. Àìmọye ìgbà ni wọ́n máa ń dá àwọn ará dúró lójú pópó, tí wọ́n á sì sọ pé àwọn fẹ́ kí wọ́n máa wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sierra Leone kò tòrò, síbẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ń so èso ní orílẹ̀-èdè yẹn.

Ọ̀pọ̀ Rẹpẹtẹ Iṣẹ́ Ilé Kíkọ́ ní Gúúsù Áfíríkà

Ní báa ti ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó tó ẹgbẹ̀rún mélòó kan la nílò ní ìpínlẹ̀ tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Gúúsù Áfíríkà ń bójú tó. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún gbọ̀ngàn la ti kọ́. John Kikot, tí í ṣe mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka níbẹ̀ sọ pé: “Dípò ká máa ṣèpàdé lábẹ́ àtíbàbà tàbí lábẹ́ igi, báa ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀, àwọn ará wa ti ń ṣèpàdé níbi tó yẹ, wọ́n sì ń jókòó sórí àwọn ìjókòó tó bójú mu. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọ̀nyí kì í ṣe ilé ràgàjì, síbẹ̀ àwọn ló máa ń jẹ́ ilé tó gbayì jù lọ ládùúgbò tí wọ́n bá wà. Ní àwọn àgbègbè kan, a ti rí i pé lẹ́yìn kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ìjọ náà yóò ti ju ìlọ́po méjì lọ́dún tó tẹ̀ lé e.”

Àwọn Èwe Ìwòyí Túbọ̀ Ń Di Ẹlẹ́rìí ní Ukraine

Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000, orílẹ̀-èdè yìí ní 112,720 góńgó tuntun iye àwọn akéde. Iye tó pọ̀ ju ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000] lára wọn ló kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì láàárín ọdún márùn-ún sẹ́yìn. John Didur, tó jẹ́ olùṣekòkárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka náà, sọ pé: “Lóòótọ́, Jèhófà ti gbé àwọn ọ̀dọ́ ẹlẹ́jẹ̀ tútù dìde gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí rẹ̀ láti máa polongo orúkọ rẹ̀!” Ó wá fi kún un pé: “Láàárín ọdún méjì tó ti kọjá, a ti fi ìwé ìròyìn tó lé ní àádọ́ta mílíọ̀nù síta, tó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú iye ènìyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè yìí. Ní ìpíndọ́gba, a ń gba ẹgbẹ̀rún lẹ́tà lóṣooṣù látọ̀dọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn tó fẹ́ mọ̀ sí i.”

Àwọn Nǹkan Míì Tó Gbádùn Mọ́ni Nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Náà

Daniel Sydlik, tí í ṣe mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, sọ àsọyé kan tó wọni lọ́kàn. Àpilẹ̀kọ náà, “Bí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Ṣe Yàtọ̀ sí Àjọ Táa Fòfin Gbé Kalẹ̀,” èyí tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí, dá lé àsọyé náà lórí.

Theodore Jaracz tí í ṣe mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ àsọyé tí ń múni ronú jinlẹ̀ náà, “Àwọn Alábòójútó àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Táa Yàn Sípò Lọ́nà Ìṣàkóso Ọlọ́run.” Ọ̀kan lára àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí dá lórí kókó ọ̀rọ̀ yẹn.

David Splane, ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tún sọ ọ̀rọ̀ tí ń tani jí nípa ẹsẹ ọdọọdún fún ọdún 2001 nínú ìpàdé ọdọọdún náà. A gbé e ka ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó sọ pé: ‘Ẹ dúró lọ́nà tí ó pé pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.’ (Kólósè 4:12) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọ́n ti ń fi ìṣòtítọ́ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ilẹ̀ ayé.—Mátíù 24:14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn èèyàn ń gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà nípasẹ̀ ẹ̀rọ alátagbà ní àwọn ibi mélòó kan, èyí sì mú kí gbogbo àwọn tó gbọ́ pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá, ó lé méjìlélọ́gọ́rin [13,082].