Àwọn Alábòójútó Àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Táa Yàn Sípò Lọ́nà Ìṣàkóso Ọlọ́run
Àwọn Alábòójútó Àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Táa Yàn Sípò Lọ́nà Ìṣàkóso Ọlọ́run
“Ẹ kíyè sí ara yín àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín ṣe alábòójútó.”—ÌṢE 20:28.
1, 2. Báwo ni Aísáyà 60:22 ṣe ń nímùúṣẹ?
TIPẸ́TIPẸ́ ni Jèhófà ti sọ pé ohun àrà ọ̀tọ̀ kan yóò ṣẹlẹ̀ ní àkókò òpin. Ó gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.”—Aísáyà 60:22.
2 Ǹjẹ́ ẹ̀rí wà pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń nímùúṣẹ lónìí? Ẹ̀rí wà mọ̀nà! Ní àwọn ọdún 1870, a dá ìjọ kan tó jẹ́ ti àwọn èèyàn Jèhófà sílẹ̀ ní Allegheny, Pennsylvania, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Látorí ìbẹ̀rẹ̀ kékeré yẹn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá-mẹ́wàá ìjọ la ti dá sílẹ̀ kárí ayé, tí wọ́n sì ń gbèrú. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà—àní tí wọ́n ti di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè—ló ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ tó ti lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rin lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáfà [91,000], ní igba ó lé márùnlélọ́gbọ̀n [235] ilẹ̀ yí ká ayé báyìí. Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, èyí fi hàn dájú pé Jèhófà ń mú kí kíkó àwọn olùjọsìn tòótọ́ wọlé yára kánkán, kí “ìpọ́njú ńlá,” tó ti kù sí dẹ̀dẹ̀ báyìí, tó wọlé dé.—Mátíù 24:21; Ìṣípayá 7:9-14.
3. Kí ni ṣíṣe ìbatisí “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́” túmọ̀ sí?
3 Lẹ́yìn tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọ̀nyí ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, a batisí wọ́n “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́,” ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni Jésù. (Mátíù 28:19) Ìbatisí “ní orúkọ Baba” túmọ̀ sí pé àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ yìí gbà pé Jèhófà ni Baba wọn ọ̀run, Òun ló sì fún wọn ní ìyè, wọ́n sì ń tẹrí ba fún ipò ọba aláṣẹ rẹ̀. Ìbatisí ‘lórúkọ Ọmọ’ túmọ̀ sí pé wọ́n gbà pé Jésù Kristi ni Olùràpadà, Aṣáájú, àti Ọba wọn. Wọ́n tún mọ ipa tí ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn, ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ń kó nínú dídarí ìgbésí ayé wọn. Èyí ló fi hàn pé a ti batisí wọn ‘lórúkọ ẹ̀mí mímọ́.’
4. Báwo la ṣe ń yan àwọn òjíṣẹ́ Kristẹni?
4 Ìgbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun bá ṣe batisí la yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. Ta ló yàn wọ́n? Títí dé àyè kan, a lè lo ọ̀rọ̀ tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 3:5 fún wọn, pé: “Títóótun wa tẹ́rùntẹ́rùn [bí òjíṣẹ́] ń jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Ní tiwọn, kò sí ọlá tí ó tó jíjẹ́ ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yàn! Lẹ́yìn ìbatisí wọn, wọn yóò máa tẹ̀ síwájú nìṣó nípa tẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ “ìhìn rere,” bí wọ́n bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò.—Mátíù 24:14; Ìṣe 9:31.
Ìyannisípò Jẹ́ Lọ́nà Ìṣàkóso Ọlọ́run, Kì Í Ṣe Lọ́nà Ìjọba Tiwa-N-Tiwa
5. Ǹjẹ́ lọ́nà ìjọba tiwa-n-tiwa la fi ń yan àwọn Kristẹni alábòójútó àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sípò? Ṣàlàyé.
5 Àbójútó tó múná dóko nípasẹ̀ àwọn alábòójútó tó tóótun àti ìtìlẹyìn tó mọ́yán lórí látọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ pọndandan láti lè bójú tó nǹkan tẹ̀mí tí àwọn òjíṣẹ́ aláápọn tí ń pọ̀ sí i ń fẹ́. (Fílípì 1:1) Báwo la ṣe ń yan irú àwọn ọkùnrin tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ sípò? Kì í ṣe ọ̀nà tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ń lò làwa ń lò. Fún àpẹẹrẹ, a kì í dìbò yan àwọn Kristẹni alábòójútó lọ́nà ìjọba tiwa-n-tiwa, èyíinì ni, nípa yíyan ẹni tí àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú ìjọ bá dìbò fún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la ń yan àwọn èèyàn wọ̀nyí lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run. Kí nìyẹn túmọ̀ sí?
6. (a) Kí ni ìṣàkóso Ọlọ́run ní tòótọ́? (b) Èé ṣe tí ọ̀nà táa gbà ń yan àwọn alábòójútó àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ fi bá ìṣàkóso Ọlọ́run mu?
6 Láìfọ̀rọ̀gùn, Ọlọ́run ló ni ọ̀pá àṣẹ nínú ìjọba táa bá pè ní ìṣàkóso Ọlọ́run ní tòótọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fínnú-fíndọ̀ tẹrí ba fún ìṣàkóso rẹ̀, wọ́n sì máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Sáàmù 143:10; Mátíù 6:9, 10) Báa ṣe ń yan àwọn Kristẹni alábòójútó, ìyẹn, àwọn alàgbà, àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá ìṣàkóso Ọlọ́run mu, nítorí pé báa ṣe ń dámọ̀ràn àti báa ṣe ń yan àwọn ọkùnrin tó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ wọ̀nyí wà ní ìbámu rẹ́gí pẹ̀lú ìṣètò tí Ọlọ́run là sílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Níwọ̀n bí ó sì ti jẹ́ pé Jèhófà ni ‘olórí ohun gbogbo,’ ó lẹ́tọ̀ọ́ dáadáa láti pinnu bí nǹkan yóò ṣe máa lọ sí nínú ètò àjọ rẹ̀ tí a lè fojú rí.—1 Kíróníkà 29:11; Sáàmù 97:9.
7. Báwo la ṣe ń ṣàkóso àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
7 Láìdàbí ọ̀pọ̀ ètò ẹ̀sìn ní Kirisẹ́ńdọ̀mù, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbé ètò tara wọn kalẹ̀ nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn. Ńṣe làwọn Kristẹni olóòótọ́ inú wọ̀nyí ń tiraka láti rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà. Kì í ṣe ètò àkóso ṣọ́ọ̀ṣì, bóyá ti inú ìjọ, tàbí ti àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì, tàbí ti àwọn bàbá ìjọ ló ń yan àwọn alábòójútó láàárín wọn. Bí ẹ̀mí ayé bá fẹ́ wọnú ọ̀ràn bí wọ́n ṣe ń yanni sípò yìí, àwọn èèyàn Jèhófà kò ní fàyè gbà á. Pẹ̀lú ìdúróṣinṣin, wọ́n rọ̀ mọ́ ìpinnu àìyẹhùn ti àwọn àpọ́sítélì ọ̀rúndún kìíní, nígbà tí wọ́n sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí ń fi ara wọn sábẹ́ Ọlọ́run nínú ohun gbogbo. (Hébérù 12:9; Jákọ́bù 4:7) Títẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run ń jẹ́ ká rí ojú rere Ọlọ́run.
8. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ètò ìjọba tiwa-n-tiwa àti ìṣàkóso Ọlọ́run?
8 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá tí ń ṣàkóso, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìlànà ìjọba tiwa-n-tiwa àti ti ìṣàkóso Ọlọ́run. Ìjọba tiwa-n-tiwa gbà pé àǹfààní ọgbọọgba gbọ́dọ̀ wà fún kálukú, ìpolongo ìbò àti ètò ìdìbò sì máa ń wáyé nígbà tí wọ́n bá ń wá káwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ dìbò fáwọn, kí wọ́n lè wọlé. Kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀ nínú báa ṣe ń yan àwọn èèyàn sípò nínú ìṣàkóso Ọlọ́run. Àwọn èèyàn tàbí àjọ kan lábẹ́ òfin kọ́ ló ń yanni sípò nínú ìṣàkóso Ọlọ́run. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa yíyàn tí Jésù àti Jèhófà yan òun ṣe “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” ó sọ fáwọn ará Gálátíà pé a kò yan òun “láti ọwọ́ àwọn ènìyàn tàbí nípasẹ̀ ènìyàn kan, bí kò ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó gbé e dìde kúrò nínú òkú.”—Róòmù 11:13; Gálátíà 1:1.
Ẹ̀mí Mímọ́ Ló Yàn Wọ́n
9. Kí ni Ìṣe 20:28 sọ nípa yíyan àwọn Kristẹni alábòójútó sípò?
9 Pọ́ọ̀lù rán àwọn alábòójútó tí ń gbé ní Éfésù létí pé Ọlọ́run ló yàn wọ́n nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Ó sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristẹni alábòójútó wọ̀nyẹn jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wọn bí wọ́n ti ń ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run. Bí ẹnì kan táa yàn sípò, kò bá kúnjú ìwọ̀n mọ́ lójú Ọlọ́run, nígbà tó bá yá, ẹ̀mí mímọ́ yóò rí sí i pé a gba ipò náà lọ́wọ́ onítọ̀hún.
10. Èé ṣe tí ẹ̀mí mímọ́ fi ń kó ipa tó ṣe pàtàkì nínú yíyannisípò lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run?
10 Èé ṣe tí ẹ̀mí mímọ́ fi ń kó ipa tó ṣe pàtàkì? Èkíní, ẹ̀mí mímọ́ ló mí sí àkọsílẹ̀ tó ṣàlàyé àwọn ohun téèyàn gbọ́dọ̀ dé ojú ìlà rẹ̀ kó tó lè di alábòójútó nípa tẹ̀mí. Nínú àwọn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì àti Títù, ó to ohun tí àwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbọ́dọ̀ dójú ìlà rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. Àpapọ̀ àwọn nǹkan bíi mẹ́rìndínlógún ló sọ pé a ń béèrè. Fún àpẹẹrẹ, alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìlẹ́gàn, oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà, ẹni tó yè kooro ní èrò inú, tó wà létòlétò, tó ní ẹ̀mí aájò àlejò, ẹni tó tóótun láti kọ́ni, àti olórí ìdílé tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Kò ní jẹ́ ọ̀mùtí, kò ní jẹ́ olùfẹ́ owó, yóò sì jẹ́ ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga la gbé kalẹ̀ fáwọn ọkùnrin tó bá ń nàgà láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.—1 Tímótì 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9.
11. Kí ni díẹ̀ lára ohun tí àwọn ọkùnrin tí ń nàgà fún ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ gbọ́dọ̀ dójú ìlà rẹ̀?
11 Bí a bá tún àwọn ohun tí a ń béèrè wọ̀nyí wò dáadáa, a óò rí i pé àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọsìn Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ Kristẹni tí ìwà wọn jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Àwọn ọkùnrin tó bá ń nàgà fún ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ gbọ́dọ̀ fẹ̀rí hàn pé ẹ̀mí mímọ́ ń bá àwọn ṣiṣẹ́. (2 Tímótì 1:14) Ó gbọ́dọ̀ hàn gbangba pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń so èso tẹ̀mí nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, àwọn èso bí “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gálátíà 5:22, 23) Irú èso bẹ́ẹ̀ yóò hàn nínú bí wọ́n ṣe ń bá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àtàwọn ẹlòmíì lò. Àmọ́ àwọn kan lè ta yọ nínú fífi àwọn èso tẹ̀mí kan hàn, nígbà tí àwọn mìíràn ní àrà ọ̀tọ̀ máa ń dójú ìlà àwọn nǹkan míì tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn alábòójútó. Bó ti wù kó rí, nínú ìgbésí ayé wọn látòkèdélẹ̀, gbogbo àwọn tó bá fẹ́ ká yan àwọn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbọ́dọ̀ fi hàn gbangba pé àwọn jẹ́ ẹni tẹ̀mí, tó kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń béèrè.
12. Àwọn wo la lè sọ pé a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn?
12 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n máa fara wé òun, ẹnu rẹ̀ gbà á láti sọ ọ́, nítorí pé òun alára ń fara wé Jésù Kristi, ẹni tí ‘ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún wa kí a lè máa tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ òun pẹ́kípẹ́kí.’ (1 Pétérù 2:21; 1 Kọ́ríńtì 11:1) Fún ìdí yìí, a lè sọ pé ẹ̀mí mímọ́ ló yan àwọn tó bá dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè ní àkókò táa yàn wọ́n ṣe alábòójútó tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.
13. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí ń dámọ̀ràn àwọn ọkùnrin tí yóò sìn nínú ìjọ?
13 Kókó míì tún wà tó ń fi hàn bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú dídámọ̀ràn àti yíyan àwọn alábòójútó. Jésù sọ pé ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run ń fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.’ (Lúùkù 11:13) Fún ìdí yìí, nígbà táwọn alàgbà nínú ìjọ bá pàdé pọ̀ láti dámọ̀ràn àwọn ọkùnrin fún ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ, wọ́n máa ń gbàdúrà pé kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí àwọn. Ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run táa mí sí ni wọ́n máa ń gbé ìdámọ̀ràn wọn kà, ẹ̀mí mímọ́ sì máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá ẹni tí wọ́n ń gbé yẹ̀ wò láti yàn sípò dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè. Àwọn tí ń ṣe ìdámọ̀ràn kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìrísí ẹni tí wọ́n ń gbé yẹ̀ wò, tàbí bó ṣe kàwé sí, tàbí àwọn ẹ̀bùn àbínibí rẹ̀, nípa lórí wọn ju bó ṣe yẹ lọ. Ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ darí àfiyèsí sí ní pàtàkì ni bóyá onítọ̀hún jẹ́ ẹni tẹ̀mí, ẹni tí kò ní ṣòro fáwọn mẹ́ńbà ìjọ láti lọ gba ìmọ̀ràn tẹ̀mí lọ́dọ̀ rẹ̀.
14. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú Ìṣe 6:1-3?
14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ń bá àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lọ́wọ́ nínú dídámọ̀ràn àwọn arákùnrin láti sìn bí alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tó bá wá di ọ̀ràn yíyàn wọ́n gan-an, àpẹẹrẹ bí wọ́n ṣe ń ṣe é ní ọ̀rúndún kìíní là ń tẹ̀ lé. Ní àkókò kan, ó ṣẹlẹ̀ pé wọ́n nílò àwọn ọkùnrin tó tóótun nípa tẹ̀mí láti bójú tó iṣẹ́ pàtàkì kan. Ẹgbẹ́ olùṣàkóso pèsè ìtọ́ni tó tẹ̀ lé e yìí: “Ẹ ṣàwárí fún ara yín, ọkùnrin méje tí a jẹ́rìí gbè láàárín yín, tí wọ́n kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n, kí a lè yàn wọ́n sípò lórí iṣẹ́ àmójútó tí ó pọndandan yìí.” (Ìṣe 6:1-3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin tó wà nídìí ọ̀ràn náà gan-an ló ṣe ìdámọ̀ràn, àwọn ọkùnrin táa fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ ní Jerúsálẹ́mù lọ́hùn-ún ló yàn wọ́n. Àpẹẹrẹ yẹn làwa náà ń tẹ̀ lé lónìí.
15. Báwo ni Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ṣe ń lọ́wọ́ sí yíyan àwọn ọkùnrin sípò?
15 Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń fúnra wọn yan gbogbo àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Nígbà tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso bá ń pinnu àwọn tó lè gbé irú ẹrù iṣẹ́ bàǹtà-banta yìí, wọ́n máa ń fi gbólóhùn Jésù sọ́kàn, pé: “Olúkúlùkù ẹni tí a bá fi púpọ̀ fún, púpọ̀ ni a ó fi dandan béèrè lọ́wọ́ rẹ̀; àti ẹni tí àwọn ènìyàn fi sí àbójútó púpọ̀, wọn yóò fi dandan béèrè fún púpọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 12:48) Ní àfikún sí yíyan àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ló tún ń yan àwọn alàgbà Bẹ́tẹ́lì àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò. Àmọ́, wọ́n ti fún àwọn arákùnrin tó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ láṣẹ láti máa bá àwọn yan àwọn kan sípò. Àpẹẹrẹ eléyìí náà wà nínú Ìwé Mímọ́.
‘Yanni Sípò, Bí Mo Ti fún Ọ Láṣẹ’
16. Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi fi Títù sílẹ̀ ní Kírétè, kí sì ni èyí fi hàn nípa báa ṣe ń yanni sípò lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run lónìí?
16 Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ pé: “Fún ìdí yìí ni mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè, kí o lè ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó ní àbùkù, kí o sì lè yan àwọn àgbà ọkùnrin sípò láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá, gẹ́gẹ́ bí mo ti fún ọ ní àwọn àṣẹ ìtọ́ni.” (Títù 1:5) Ẹ̀yìn ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù wá ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ohun tí Títù yóò máa wá lára àwọn ọkùnrin tí yóò tóótun fún yíyàn sípò. Nítorí náà, lóde òní Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti yan àwọn arákùnrin tó tóótun ní àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ láti máa ṣojú fún wọn nínú yíyan àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Wọ́n ń rí sí i pé àwọn tó ń ṣojú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa àwọn ìtọ́ni tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ nípa yíyannisípò, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìtọ́ni wọ̀nyẹn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé lábẹ́ ìdarí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso la fi ń yan àwọn ọkùnrin tó tóótun láti sìn nínú àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé.
17. Báwo ni ẹ̀ka iléeṣẹ́ ṣe ń bójú tó yíyan àwọn tí a dámọ̀ràn pé kí wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?
17 Nígbà tí wọ́n bá fi orúkọ àwọn tí wọ́n dámọ̀ràn pé kí a yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society, àwọn ọkùnrin onírìírí gbára lé ìdarí ẹ̀mí Ọlọ́run kí wọ́n tó yàn wọ́n sípò. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí mọ̀ pé àwọn máa jíhìn, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn ò gbọ́dọ̀ fi ìkánjú gbé ọwọ́ lé ọkùnrin èyíkéyìí, kí wọ́n má bàa pín nínú ẹ̀ṣẹ̀ onítọ̀hún.—1 Tímótì 5:22.
18, 19. (a) Báwo la ṣe ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ nípa àwọn kan táa yàn sípò? (b) Báwo la ṣe ń ṣe gbogbo ètò dídámọ̀ràn àti yíyannisípò?
18 Ó lè jẹ́ lẹ́tà kan tó ní òǹtẹ̀ àṣẹ, tó wá látọ̀dọ̀ àjọ kan táa fòfin gbé kalẹ̀, la fi ránṣẹ́ láti fi hàn pé wọ́n ti yan àwọn kan sípò. Ó lè jẹ́ irú lẹ́tà yẹn la lò láti yan àwọn arákùnrin mélòó kan sípò nínú ìjọ.
19 Ìyannisípò lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ àti nípasẹ̀ ipa ọ̀nà táa lè fojú rí tí Ọlọ́run ń lò lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀. (Mátíù 24:45-47) Ẹ̀mí mímọ́ ló ń darí gbogbo ètò dídámọ̀ràn àti yíyannisípò. Ìdí táa fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé a ti fi àwọn ohun tí a ń béèrè lélẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ẹ̀mí mímọ́ mí sí, ẹni táa sì yàn sípò ti fi ẹ̀rí hàn pé òun ń so èso ẹ̀mí yẹn. Nítorí náà, ojú tó yẹ ká máa fi wo àwọn táa yàn sípò ni pé ẹ̀mí mímọ́ ló yàn wọ́n. Gan-an gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé ọ̀nà ìṣàkóso Ọlọ́run la gbà yan àwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ọ̀rúndún kìíní, bẹ́ẹ̀ náà ló rí lónìí.
A Dúpẹ́ fún Ìtọ́sọ́nà Jèhófà
20. Èé ṣe táa fi ní irú ìmọ̀lára tí Dáfídì ní nínú Sáàmù 133:1?
20 Ní àkókò aásìkí tẹ̀mí yìí àti ìbísí ìṣàkóso Ọlọ́run nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà, a dúpẹ́ pé Jèhófà gan-an ló wà nídìí yíyan àwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ìṣètò tó bá Ìwé Mímọ́ mu yìí ń jẹ́ kó ṣeé ṣe láti pa ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo gíga ti Ọlọ́run mọ́ láàárín ara wa gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ẹ̀mí Kristẹni àti iṣẹ́ àṣekára àwọn ọkùnrin wọ̀nyí fi ń fi kún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan gíga lọ́lá tó wà láàárín wa gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà Dáfídì ti wí, ọkàn àwa náà sún wa láti kókìkí pé: “Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!”—Sáàmù 133:1.
21. Báwo ni Aísáyà 60:17 ṣe ń nímùúṣẹ lónìí?
21 A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ń tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀! Ọ̀rọ̀ gidi, tó nítumọ̀ sì lọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 60:17, pé: “Dípò bàbà, èmi yóò mú wúrà wá, àti dípò irin, èmi yóò mú fàdákà wá, àti dípò igi, bàbà, àti dípò àwọn òkúta, irin; dájúdájú, èmi yóò sì yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.” Bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú nínú títẹ̀lé àwọn ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run, ni ayọ̀ túbọ̀ ń jẹ́ tiwa jákèjádò ètò àjọ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.
22. Kí ni à ń dúpẹ́ fún, kí ló sì yẹ ká pinnu láti ṣe?
22 A dúpẹ́ dúpẹ́ fún ètò ìṣàkóso Ọlọ́run tó wà ní àyè rẹ̀ yíyẹ láàárín wa. A dúpẹ́, a sì tún ọpẹ́ dá fún iṣẹ́ takuntakun tí ń fúnni láyọ̀ táwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ táa yàn sípò lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run ń ṣe. A ń fi tọkàntọkàn kókìkí Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, tó mú wa láásìkí nípa tẹ̀mí, tó sì ti bù kún wa ní jìngbìnnì. (Òwe 10:22) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò máa bá ètò àjọ Jèhófà rìn. Lékè gbogbo rẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó ní sísìn pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan, sí ọlá, ìyìn, àti ògo orúkọ ńlá àti orúkọ mímọ́ Jèhófà.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Èé ṣe táa fi lè sọ pé kì í ṣe lọ́nà ìjọba tiwa-n-tiwa, bí kò ṣe lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run la fi ń yan àwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?
• Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń yan àwọn ọkùnrin Kristẹni tó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́?
• Báwo ni Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ṣe ń lọ́wọ́ sí yíyan àwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?
• Nípa àwọn táa yàn sípò lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, èé ṣe tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Nípasẹ̀ ìṣàkóso Ọlọ́run la fi yan àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó láǹfààní láti sìn