Bí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Ṣe Yàtọ̀ Sí Àjọ Táa Fòfin Gbé Kalẹ̀
Bí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Ṣe Y àtọ̀ Sí Àjọ Táa Fòfin Gbé Kalẹ̀
LÁTI January ọdún 1885 ni wọ́n ti ń ṣe ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania bọ̀. Nígbà tí kíkó àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jọ ń lọ lọ́wọ́ ní ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ìrètí ti ọ̀run làwọn tó jẹ́ olùdarí àti aláṣẹ ẹgbẹ́ yìí ní nígbà náà. Àní sẹ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ kìkìdá wọn ló ń di ipò náà mú.
Àmọ́ ìyàtọ̀ kan wà. Ní ọdún 1940, wọ́n yan Hayden C. Covington tó jẹ́ amòfin Society nígbà yẹn, tó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn “àgùntàn mìíràn,” tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdarí Society. (Jòhánù 10:16) Ó sìn gẹ́gẹ́ bí igbákejì ààrẹ Society láàárín ọdún 1942 sí 1945. Lásìkò yẹn, Arákùnrin Covington kọ̀wé fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn olùdarí láti lè mú ara rẹ̀ bá ohun tó dà bí pé ó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà nígbà yẹn mu—ìyẹn ni pé kí gbogbo àwọn tó jẹ́ olùdarí àti aláṣẹ àjọ Pennsylvania jẹ́ Kristẹni táa fòróró yàn. Lyman A. Swingle ló wá rọ́pò Hayden C. Covington nínú ìgbìmọ̀ olùdarí, tí wọ́n sì wá yan Frederick W. Franz gẹ́gẹ́ bí igbákejì ààrẹ.
Kí ló mú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà gbà gbọ́ pé gbogbo àwọn olùdarí àti aláṣẹ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania gbọ́dọ̀ jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró? Ìdí ni pé, nígbà yẹn, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà la mọ ìgbìmọ̀ olùdarí àti aláṣẹ àjọ Pennsylvania sí, tó jẹ́ pé kìkì àwọn ọkùnrin táa fẹ̀mí yàn ni wọ́n.
Ìpàdé Ọdọọdún Kan Tó Jẹ́ Mánigbàgbé
Níbi ìpàdé ọdọọdún tí wọ́n ṣe ní October 2, 1944 ní Pittsburgh, àwọn mẹ́ńbà àjọ Pennsylvania tẹ́wọ́ gba ìpinnu mẹ́fà kan tó ṣàtúnṣe àkọsílẹ̀ táa fi ṣàlàyé ète àjọ náà. Tẹ́lẹ̀ rí àkọsílẹ̀ yẹn fàyè sílẹ̀ pé káwọn tó ń dáwó fún iṣẹ́ Society ní ìpín nínú dídìbò, àmọ́ àtúnṣe kẹta mú àǹfààní yẹn kúrò. Ìròyìn kan tó wáyé nípa ìpàdé ọdọọdún yẹn sọ pé: “Àwọn tó máa jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ Society kò ní ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] lọ . . . Olúkúlùkù ẹni tí wọ́n bá yàn gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ alákòókò kíkún fún Society tàbí kẹ̀ kó jẹ́ ìránṣẹ́ tí kì í ṣe alákòókò kíkún ti ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì gbọ́dọ̀ fi ẹ̀mí Olúwa hàn.”
Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn tó fi gbogbo ara wọn jin Jèhófà, láìka iye owó tí wọ́n ń dá láti mú iṣẹ́ Ìjọba náà tẹ̀ síwájú sí, ni yóò máa dìbò yan àwọn tí yóò jẹ́ olùdarí fún Society. Èyí wá wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyọ́mọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé tí a sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní Aísáyà 60:17, níbi tí a ti kà pé: “Dípò bàbà, èmi yóò mú wúrà wá, àti dípò irin, èmi yóò mú fàdákà wá, àti dípò igi, bàbà, àti dípò àwọn òkúta, irin; dájúdájú, èmi yóò sì yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.” Ní títọ́ka sí “alábòójútó” àti “àwọn tí ń pínṣẹ́,” ńṣe ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń tọ́ka sí ìmúsunwọ̀n sí i tí yóò ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ìlànà ètò àjọ láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà.
Ìgbésẹ̀ ṣíṣekókó yìí, nínú mímú ètò àjọ náà wà ní ìbámu pẹ̀lú ìṣàkóso Ọlọ́run, wáyé ní òpin “ẹ̀ẹ́dégbèjìlá alẹ́ àti òwúrọ̀,” tí a mẹ́nu kàn ní Dáníẹ́lì 8:14. Ní àkókò yẹn, a mú “ibi mímọ́ náà wá sí ipò rẹ̀ tí ó tọ́.”
Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn ìpàdé ọdọọdún mánigbàgbé náà ní 1944, ìbéèrè pàtàkì kan ṣì wà nílẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àjọ Pennsylvania tó jẹ́ ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méje ni a mọ̀ sí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso nígbà yẹn, ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso kò lè ní ju àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró méje lọ ni? Yàtọ̀ síyẹn, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn mẹ́ńbà àjọ náà ló máa ń fìbò yan àwọn olùdarí, ṣé àwọn mẹ́ńbà àjọ yẹn lo ń fìbò yan àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso níbi ìpàdé ọdọọdún ni? Ṣé nǹkan kan náà ni àwọn olùdarí àti
aláṣẹ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania àtàwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, àbí wọ́n yàtọ̀ síra wọn?Ìpàdé Ọdọọdún Mìíràn Tó Tún Jẹ́ Mánigbàgbé
Ibi ìpàdé ọdọọdún tí wọ́n ṣe ní October 1, 1971 ni wọ́n ti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Níbi ìpàdé náà, ọ̀kan lára àwọn olùbánisọ̀rọ̀ là á mọ́lẹ̀ pé, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti fi wà ṣáájú Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. (Mátíù 24:45-47) A dá ẹgbẹ́ olùṣàkóso kan sílẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa, ìyẹn ti lé ní ọ̀rúndún méjìdínlógún ṣáájú kí àjọ ti Pennsylvania tó wáyé. Níbẹ̀rẹ̀, kì í ṣe ọkùnrin méje ni ẹgbẹ́ olùṣàkóso ní, àmọ́ àwọn àpọ́sítélì méjìlá ló ní. Ó hàn gbangba pé iye wọn pọ̀ sí i lẹ́yìn ìgbà náà, nítorí “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù” ló ń mú ipò iwájú.—Ìṣe 15:2.
Ní ọdún 1971, olùbánisọ̀rọ̀ kan náà ṣàlàyé pé àwọn mẹ́ńbà Watch Tower Society kò lè fìbò yan àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tó jẹ́ ẹni àmì òróró. Kí nìdí? O sọ pé: “Nítorí pé kì í ṣe èèyàn kankan ló yan ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti ẹgbẹ́ ‘ẹrú’ náà. Jésù Kristi tó jẹ́ Orí ìjọ Kristẹni tòótọ́, tó jẹ́ Olúwa àti Ọ̀gá ẹgbẹ́ ‘ẹrú olóòótọ́ àti olóye’ náà ló yàn án . . . ” Ó wá ṣe kedere nígbà náà pé, àwọn tó wà nínú àjọ èyíkéyìí táa fòfin gbé kalẹ̀ kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fìbò yan àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sípò.
Bí olùbánisọ̀rọ̀ náà ti ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó sọ ọ̀rọ̀ ṣíṣekókó yìí pé: “Ẹgbẹ́ olùṣàkóso kò ní àwọn aláṣẹ nínú bíi ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Society, ìyẹn ni ààrẹ, igbákejì ààrẹ, akọ̀wé òun akápò àti igbákejì rẹ̀. Kìkì alága ló ní.” Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ààrẹ àjọ Pennsylvania yẹn náà ló tún ń mú ipò iwájú nínú mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Ọ̀ràn ò ní rí bẹ́ẹ̀ mọ́ o. Bó tilẹ̀ jẹ̀ pé ìrírí àti bí kálukú wọn ṣe mọ nǹkan ṣe sí kò dọ́gba, àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso gbọ́dọ̀ jẹ́ ọgbọọgba nínú ẹrù iṣẹ́ wọn. Olùbánisọ̀rọ̀ náà fi kún un pé: “Èyíkéyìí lára àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ olùṣàkóso ló lè ṣe alága láìjẹ́ pé òun kan náà ni ààrẹ . . . Society . . . Gbogbo rẹ̀ sinmi lórí ọ̀nà tí ipò alága náà bá fi ń yí po láàárín ẹgbẹ́ olùṣàkóso.”
Níbi ìpàdé ọdọọdún tí kò ṣeé gbàgbé yẹn ní ọdún 1971, wọ́n fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tí a fẹ̀mí yàn àti àwọn olùdarí àjọ ti Pennsylvania hàn gedegbe. Síbẹ̀, àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ṣì ń bá a lọ láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí olùdarí àti aláṣẹ Society. Àmọ́ ṣá o, lónìí, ìbéèrè tó dìde ni pé: Ṣé ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu kankan wà pé àwọn olùdarí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania gbọ́dọ̀ jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso?
Ìdáhùn ni pé rárá, kò sí. Àjọ ti Pennsylvania nìkan kọ́ ni ẹgbẹ́ táa fòfin gbé kalẹ̀ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò. Àwọn mìíràn tún wà. Ọ̀kan ni Watchtower Bible and Tract Society of New York, Incorporated. Òun ló ń bójú tó iṣẹ́ wa ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ó dájú pé Jèhófà ń bù kún àjọ yẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn “àgùntàn mìíràn” ló pọ̀ jù lára àwọn olùdarí àti aláṣẹ rẹ̀. Orúkọ ẹgbẹ́ tí a ń lò ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni International Bible Students Association. (Ẹgbẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé) Àwọn àjọ mìíràn táa fòfin gbé kalẹ̀ wà tí a ń lò láti fi ti ire Ìjọba náà lẹ́yìn ní àwọn ilẹ̀ mìíràn. Pẹ̀lú ìṣọ̀kan ni gbogbo wọn fi ń ṣèrànwọ́, wọ́n sì ní ipa tí wọ́n ń kó nínú mímú kí ìhìn rere náà di èyí ti a ń wàásù rẹ̀ kárí ayé. Láìka ibi yòówù tí wọ́n fìdí kalẹ̀ sí tàbí àwọn tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí olùdarí àti aláṣẹ wọn, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ló ń tọ́ àwọn ẹgbẹ́ yìí sọ́nà tó sì ń lò wọ́n lọ́nà ti ìṣàkóso Ọlọ́run. Nítorí náà, irú àwọn àjọ bẹ́ẹ̀ ní àwọn iṣẹ́ táa yàn fún wọn láti ṣe nínú mímú ire Ìjọba náà gbòòrò sí i.
Ó ṣàǹfààní pé kí á ní àwọn àjọ táa fòfin gbé kalẹ̀. A ń tipa bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé òfin àdúgbò àti ti ìjọba, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti béèrè pé ká ṣe. (Jeremáyà 32:11; Róòmù 13:1) Àwọn àjọ táa fòfin gbé kalẹ̀ ń mú iṣẹ́ wa ti sísọ ìhìn Ìjọba náà fáwọn èèyàn rọrùn, nípasẹ̀ Bíbélì títẹ̀, ìwé ńlá, ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ àtàwọn ìwé mìíràn. Irú àwọn àjọ bẹ́ẹ̀ tún ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ táa fòfin gbé kalẹ̀ láti máa bójú tó àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ níní àṣẹ lórí dúkìá, ètò ìrànlọ́wọ́, bí a ṣe lè rí àwọn ibi táa lè lò fún àpéjọpọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. A mọrírì iṣẹ́ tí irú àwọn àjọ táa fòfin gbé kalẹ̀ bẹ́ẹ̀ ń ṣe.
Mímú Kí Orúkọ Jèhófà Gbapò Iwájú
Ní ọdún 1944, wọ́n ṣe àtúnṣe sí Abala Kejì nínú ìwé ìdásílẹ̀ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania láti túbọ̀ tẹnu mọ́ àwọn ète àjọ yìí. Níbàámu pẹ̀lú ìwé ìdásílẹ̀ ọ̀hún, àwọn ète tí Society náà wà fún ní ète pàtàkì yìí nínú: “Láti wàásù ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ Kristi Jésù fún gbogbo orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí sí orúkọ, ọ̀rọ̀, àti ipò gíga jù lọ ti JÈHÓFÀ Ọlọ́run Olódùmarè.”
Láti ọdún 1926 ni ‘ẹrú olóòótọ́’ náà ti mú kí orúkọ Jèhófà gbapò iwájú. Àgàgà lọ́dún 1931, nígbà táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́wọ́ gba orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísáyà 43:10-12) Lára àwọn ìtẹ̀jáde Society tó ti gbé orúkọ Jèhófà ga ni Jehovah (1934), “Let Your Name Be Sanctified” (1961), “The Nations Shall Know That I Am Jehovah”—How? (1971).
A ò gbọ́dọ̀ kóyán Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kéré, èyí tí a mú jáde lódindi ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ọdún 1960. Ó ní orúkọ Jèhófà nínú, ní gbogbo ibi tí lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ìtumọ̀ yìí tún ní orúkọ àtọ̀runwá náà nínú, ní òjìlúgba ó dín mẹ́ta [237] ibi nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, níbi tí ìfọ́síwẹ́wẹ́ tí a fara balẹ̀ ṣe ti fi hàn pé èyí pọndandan. A dúpẹ́ a tọ́pẹ́ dá pé, Jèhófà ti jẹ́ kó ṣeé ṣe lóríṣiríṣi ọ̀nà, fún “ẹrú” náà àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀ láti lo àwọn iléeṣẹ́ ìtẹ̀wé wọn àtàwọn àjọ tí wọ́n fòfin gbé kalẹ̀ láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ kárí ayé!
A Gbé Pípín Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Kiri Lárugẹ
Àwọn ènìyàn Jèhófà ti ń fìgbà gbogbo jẹ́rìí sí orúkọ rẹ̀, wọ́n sì ti gbé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lárugẹ nípa títẹ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé karí Bíbélì, títí kan Bíbélì fúnra rẹ̀, tí wọ́n sì tún ń pín wọn kiri. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1900, Watch Tower Society di ẹni tó ní ẹ̀tọ́ oníǹkan lórí The Emphatic Diaglott, ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó jẹ́ àpapọ̀ èdè Gíríìkì àti Gẹ̀ẹ́sì tí Benjamin Wilson ṣe. Society tẹ King James Version, ẹ̀dà ti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde, èyí tó ní àfikún ẹ̀yìn ìwé tó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ojú ìwé. Ní 1942, ó tẹ King James Version tó ní atọ́ka etí ìwé jáde. Lẹ́yìn náà, ní ọdún 1944, Society bẹ̀rẹ̀ sí tẹ American Standard Version ẹ̀dà ti 1901 jáde, èyí tó lo orúkọ Ọlọ́run. Orúkọ Ọlọ́run tún jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ẹ̀dà The Bible in Living English, látọwọ́ Stephen T. Byington, tí Society tẹ̀ jáde ní ọdún 1972.
Àwọn àjọ táa fòfin gbé kalẹ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò ti ṣèrànwọ́ nínú títẹ̀ àti pípín gbogbo àwọn ìtumọ̀ Bíbélì yìí kiri. Àmọ́ ṣá o, èyí tó wá kàmàmà jù ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tímọ́tímọ́ tó wà láàárín Watch Tower Society àti àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà táa fòróró yàn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun. Inú wa dùn pé ní báa ṣe ń wí yìí, ẹ̀dà ìtumọ̀ yìí tí a ti tẹ̀ lódindi tàbí lápá kan ti lé ní mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún kan àti mẹ́fà ó lé ogún ọ̀kẹ́ [106,400,000] ní èdè méjìdínlógójì. Òdodo ọ̀rọ̀, ẹgbẹ́ oní-Bíbélì ni Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania!
‘Ẹrú olóòótọ́’ náà ni a ti ‘yàn sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní ọ̀gá rẹ̀.’ Èyí kan àwọn ilé tó wà ní oríléeṣẹ́ ní Ìpínlẹ̀ New York ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àtàwọn ẹ̀ka tó jẹ́ àádọ́fà tó ń báṣẹ́ lọ báyìí jákèjádò ayé. Àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ ẹrú náà mọ̀ pé a ó pè wọ́n láti wá ṣèṣirò ọ̀nà tí wọ́n Mátíù 25:14-30) Síbẹ̀, eléyìí kò dí ‘ẹrú’ náà lọ́wọ́ láti yọ̀ǹda kí àwọn alábòójútó tó dáńgájíá nínú àwọn “àgùntàn mìíràn” wá mójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ kan tó jẹ mọ́ òfin àtàwọn ètò iṣẹ́ ṣíṣe. Ká sòótọ́, ńṣe lèyí túbọ̀ fún àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso láyè láti ya àkókò púpọ̀ sí i sọ́tọ̀ fún “àdúrà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”—Ìṣe 6:4.
gbà lo ohun táa fi síkàáwọ́ wọn. (Níwọ̀n ìgbà tí ipò ayé yìí bá ṣì fàyè gbà á, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tó ń ṣojú fún “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” yóò máa bá a nìṣó ní lílo àwọn àjọ táa fòfin gbé kalẹ̀. Lílo àjọ wọ̀nyí mú nǹkan rọrùn, àmọ́ wọn kì í ṣe kòṣeémánìí o. Bí òfin ìjọba bá tú àjọ kan táa fòfin gbé kalẹ̀ ká, iṣẹ́ ìwàásù yóò ṣì máa bá a lọ. Kódà, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, láwọn ilẹ̀ kan táa ti ka iṣẹ́ wa léèwọ̀, tí a kò sì ní àjọ kankan táa fòfin gbé kalẹ̀ níbẹ̀, à ń polongo ìhìn Ìjọba náà, a ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, bẹ́ẹ̀ sì ni ìbísí nínú ìṣàkóso Ọlọ́run ń tẹ̀ síwájú. Ìyẹn ń ṣẹlẹ̀ nítorí pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbìn, a sì ń bomi rin, tí ‘Ọlọ́run sì ń mú kí ó dàgbà.’—1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.
Bí a ti ń wo ọjọ́ iwájú, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà yóò bójú tó ohun tí àwọn ènìyàn rẹ̀ nílò nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Òun àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi yóò máa bá a lọ láti pèsè ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá àti ìtìlẹyìn tí a nílò láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà parí. Ó dájú pé, ohun yòówù kí a ṣàṣeparí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ‘kì í ṣe nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ológun, tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí Jèhófà.’ (Sekaráyà 4:6) Nígbà náà, a gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí a mọ̀ pé pẹ̀lú okun tí Jèhófà ń pèsè, á ṣeé ṣe fún wa láti parí iṣẹ́ tó gbé fún wa pé ká ṣe ní àkókò òpin yìí!