Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí a Ṣe Lè ní Ìwà Funfun

Bí a Ṣe Lè ní Ìwà Funfun

Bí a Ṣe Lè ní Ìwà Funfun

ÀWỌN ìwé atúmọ̀ èdè òde òní túmọ̀ “ìwà funfun” gẹ́gẹ́ bí “ìwà títayọ lọ́lá; ìwà rere.” Ó jẹ́ “ìgbésẹ̀ àti èrò títọ̀nà; ìwà tó dára.” Olùtumọ̀ èdè Marvin R. Vincent sọ pé èrò ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìgbàanì tí a túmọ̀ sí “ìwà funfun” dúró fún ni “ìtayọlọ́lá èyíkéyìí.” Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé àwọn ànímọ́ bí òye, ìgboyà, ìsẹ́ra ẹni, àìṣègbè, ìyọ́nú, ìforítì, àìlábòsí, ìrẹ̀lẹ̀, àti ìdúróṣinṣin làwọn èèyàn ti kan sáárá sí pé ó jẹ́ ìwà funfun láwọn ìgbà kan tàbí òmíràn. Ìwà funfun la tún ti túmọ̀ sí “bíbá ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà títọ́ mu.”

Ọ̀pá ìdiwọ̀n títayọ lọ́lá, ti ìwà rere, àti ti ìwà títọ́ ta ló yẹ ká fara mọ́? Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú èrò àwọn òléwájú nínú ẹ̀kọ́ nípa ìwà híhù, iyèméjì tí èròǹgbà Ayé Ọ̀làjú dá sílẹ̀ ti sọ gbogbo èrò tí a ní nípa rere àti búburú di ọ̀ràn èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́, bí ọ̀ràn bá ṣe rí lára kálukú ni tàbí bí ọ̀ràn àṣà ìbílẹ̀ bá ṣe rí ni.” Àmọ́, ṣé bí ẹnì kan bá ṣe fẹ́ lásán ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti pinnu rere àti búburú? Rárá o. Ká tó lè níwà funfun, a nílò ọ̀pá ìdiwọ̀n tó ṣeé fọkàn tán nípa rere àti búburú—ọ̀pá ìdíwọ̀n kan táa fi lè mọ̀ bóyá ìgbésẹ̀ kan, ìṣarasíhùwà kan tàbí ànímọ́ kan dára tàbí ó burú.

Orísun Tòótọ́ Kan Ṣoṣo fún Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Ìwà Rere

Orísun tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà fún ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere—òun ni Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá aráyé. Kété tí Jèhófà Ọlọ́run dá Ádámù, ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, ó pàṣẹ yìí fún ọkùnrin náà pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Jèhófà Ọlọ́run fún igi náà ni orúkọ àrà ọ̀tọ̀ yẹn láti fi hàn pé òun nìkan ṣoṣo ló ní ẹ̀tọ́ láti pinnu ohun tó dára àti èyí tí kò dára fún àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀. Bí ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run fún rere àti búburú ṣe di ìpìlẹ̀ fún ṣíṣe ìdájọ́, tàbí ṣíṣàgbéyẹ̀wò, àwọn ìṣe ẹnì kan, ojú ìwòye ẹni, àti ìwà àbímọ́ni nìyẹn. Láìsí irú ọ̀pá ìdiwọ̀n bẹ́ẹ̀, a ò lè fi ìyàtọ̀ tí ó tọ́ sáàárín rere àti búburú.

Àṣẹ tó ní í ṣe pẹ̀lú igi ìmọ̀ rere àti búburú yẹn gbé yíyàn kan síwájú Ádámù àti Éfà—yálà kí wọ́n ṣègbọràn tàbí kí wọ́n ṣàìgbọràn. Ní tiwọn, ìwà funfun túmọ̀ sí ṣíṣègbọràn sí àṣẹ yẹn. Bí àkókò ti ń lọ, Jèhófà túbọ̀ ṣí ohun tó fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́ payá, ó sì mú kí a kọ èyí sílẹ̀ fún wa nínú Bíbélì. Nítorí náà, níní ìwà funfun túmọ̀ sí pé ká rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Jèhófà tí a là lẹ́sẹẹsẹ sínú Ìwé Mímọ́.

Mọ Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Ọlọ́run Dáadáa

Níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run ti gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n táa fi lè mọ rere àti búburú kalẹ̀, tó sì ti ṣí i payá nínú Bíbélì, ǹjẹ́ kò yẹ ká mọ̀ wọ́n dáadáa? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.

Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa èdè àìyedè tí Kunihito, táa mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, dojú kọ nígbà tó ń fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn lọ́nà tó bá àṣà ìbílẹ̀ rẹ̀ mu. Gbígbé tó wá túbọ̀ gbé ọ̀pá ìdíwọ̀n Ìwé Mímọ́ yẹ̀ wò níkẹyìn ló ràn án lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní ojú ìwòye tó wà déédéé. Ó dájú pé Bíbélì gbà wá níyànjú láti jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà, ó sì kìlọ̀ pé kí a má ṣe jọ ara wa lójú, kí a má sì ní ẹ̀mí ìkùgbù. (Òwe 11:2; Míkà 6:8) Síbẹ̀, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń to àwọn ohun tó lè mú kéèyàn tóótun fún “ipò iṣẹ́ alábòójútó” lẹ́sẹẹsẹ, ó sọ̀rọ̀ nípa ‘nínàgà’ fún àǹfààní yẹn. (1 Tímótì 3:1) A ò wá ní tìtorí pé a ń “nàgà” ká wá máa fọ́nnu kiri tàbí ká máa fi ìkùgbù ṣe nǹkan, bẹ́ẹ̀ sì ni a ò ní tìtorí èyí máa fi ara wa wọ́lẹ̀.

Kí ni Bíbélì sọ nípa ìwà rere tó tayọ lọ́lá nínú iṣẹ́ okòwò? Ṣíṣe àwọn ohun tí ń kọni lóminú tàbí gbígba ọ̀nà ẹ̀bùrú láti lè yẹra fún àwọn àṣẹ ìjọba àti àwọn òfin lórí owó orí jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ lágbo àwọn oníṣòwò òde òní. Àmọ́ ṣá o, láìka ohun yòówù táwọn míì lè máa ṣe sí, ìlànà Bíbélì ni pé kí a “máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Nípa bẹ́ẹ̀, a ń mú ìwà funfun dàgbà nípa jíjẹ́ aláìṣàbòsí àti ẹni tí ń ṣẹ̀tọ́ fún agbanisíṣẹ́, ẹni tí a gbà síṣẹ́, oníbàárà, àti àwọn ìjọba ayé. (Diutarónómì 25:13-16; Róòmù 13:1; Títù 2:9, 10) Dájúdájú, àìlábòsí máa ń fi kún ìfọkàntánni àti ojú rere. Kíkọ àwọn àdéhùn sílẹ̀ sì sábà máa ń dènà èdè àìyedè àti àwọn ọ̀ràn dídíjú tó lè dìde nítorí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.”—Oníwàásù 9:11; Jákọ́bù 4:13, 14.

Ọ̀ràn nípa ìwọṣọ àti ìmúra tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn táa ti gbọ́dọ̀ níwà funfun. Aṣọ tó máa ń wu èèyàn wọ̀ máa ń yàtọ̀ síra, ó sì sinmi lórí àṣà ìbílẹ̀ oníkálùkù, a sì lè dojú kọ ìpèníjà lọ́tùn-ún lósì láti máa lo àwọn aṣọ tó dé kẹ́yìn àti èyí táwọn èèyàn ń gba tiẹ̀. Àmọ́, kí ló dé táa fi ní láti máa tẹ̀ lé gbogbo àṣà tuntun tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde? Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.” (Róòmù 12:2) Dípò gbígbé onírúurú òfin kalẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé lábẹ́ ìmísí pé: “Mo ní ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòlétò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.” (1 Tímótì 2:9, 10) Tọkùnrin tobìnrin ni ọ̀pá ìdíwọ̀n pàtàkì yìí kàn. Àmọ́ ṣá o, àǹfààní wà láti yan onírúurú àṣà ìwọṣọ tó bá wuni nítorí àṣà ìbílẹ̀ ẹni tàbí ohun tó wu olúkúlùkù.

Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣekúṣe tí Ọlọ́run kà léèwọ̀. Nínú 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10, a ka ìkìlọ̀ náà níbẹ̀ pé: “Kínla! Ẹ kò ha mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ran Maria, tí a mẹ́nu kàn níṣàájú lọ́wọ́, láti rí i pé àjọṣe òun àti Juan kò bá ọ̀pá ìdíwọ̀n ìwà títayọ lọ́lá tí Ẹlẹ́dàá gbé kalẹ̀ mu rárá, àti pé òun gbọ́dọ̀ fòpin sí i, bí òun bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run. Ní kedere, ká tó lè ní ìwà funfun, a ní láti mọ ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà dáadáa.

Jẹ́ Kí Ẹ̀kọ́ Nípa Ìwà Funfun Dé Ọkàn-Àyà Rẹ

Ìwà funfun kì í wulẹ̀ ṣe ká kàn máa sá fún ohun búburú. Ó ní agbára ìwà rere nínú. Ẹni tó níwà funfun níwà rere pẹ̀lú. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé: “Ẹ̀kọ́ nípa ìwà funfun kì í ṣe àkọ́sórí nìkan, ó tún gbọ́dọ̀ dé ọkàn-àyà wa.” Nítorí náà, níní ìwà funfun kọjá ká kàn mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Ó ń béèrè pé kí á ṣàṣàrò lórí ohun táa kọ sínú rẹ̀, kí ọkàn-àyà wa lè kún fún ìmoore sí Jèhófà, kí ó sì sún wa láti máa fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò nínú ìgbésí ayé wa.

Onísáàmù náà polongo pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sáàmù 119:97) Dáfídì Ọba náà kọ̀wé pé: “Mo ti rántí àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn; mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ [Ọlọ́run]; tinútinú ni mo ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ṣe ìdàníyàn mi.” (Sáàmù 143:5) Àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ṣíṣe àṣàrò tàdúràtàdúrà jẹ́ apá pàtàkì nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa àti ti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé ka Bíbélì.

Lóòótọ́, àtirí àkókò láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tó múná dóko, ká sì tún ṣàṣàrò lè jẹ́ ìṣòro. Àmọ́ lílépa àtiní ìwà funfun ń béèrè pé kí a ra àkókò padà láti inú àwọn ìgbòkègbodò mìíràn. (Éfésù 5:15, 16) Aaron, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún, ń ra irú àkókò bẹ́ẹ̀ padà lójoojúmọ́. Ó ń jí ní ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ṣáájú àkókò tó máa ń jí tẹ́lẹ̀. Ó ròyìn pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀, mo kàn máa ń fi gbogbo ọgbọ̀n ìṣẹ́jú yẹn ka Bíbélì ni. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe àṣàrò. Nípa bẹ́ẹ̀, ṣe ni mo wá ń fi ìdajì àkókò yẹn ṣàṣàrò lórí ohun tí mo ṣẹ̀sẹ̀ kà tán. Èyí sì ti ṣàǹfààní gan-an.” A tún lè ṣàṣàrò láwọn àkókò mìíràn. Nínú orin ìyìn kan tí Dáfídì kọ sí Jèhófà, ó kọ ọ́ lórin pé: “Mo ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní àwọn ìṣọ́ òru.” (Sáàmù 63:6) Bíbélì sì ròyìn pé: “Ísákì sì ń rìn níta kí ó lè ṣe àṣàrò nínú pápá nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ ní ìrọ̀lẹ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:63.

Ṣíṣe àṣàrò ṣe pàtàkì gan-an nínú mímú ìwà funfun dàgbà, nítorí pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní irú ìmọ̀lára tí Jèhófà ní àti láti ní irú ojú ìwòye tó ní. Fún àpẹẹrẹ, Maria mọ̀ pé Ọlọ́run ka àgbèrè léèwọ̀. Àmọ́ kó tó lè ‘fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú, kó sì rọ̀ mọ́ ohun rere,’ ó ní láti ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣe kókó. (Róòmù 12:9) A ràn án lọ́wọ́ láti rí i pé ó pọndandan fún òun láti ṣàtúnṣe lẹ́yìn tó ka Kólósè 3:5, tó rọ̀ wá láti ‘sọ àwọn ẹ̀yà ara wa tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò.’ Maria ní láti bi ara rẹ̀ pé: ‘Irú ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo wo ni kí n sọ di òkú? Kí ló lè ru ìfẹ́ ọkàn àìmọ́ sókè tí mo gbọ́dọ̀ yẹra fun? Ṣé àwọn ìyípadà kan wà tí mo gbọ́dọ̀ ṣe lórí ọ̀nà tí mo gbà ń bá àwọn ọkùnrin ṣe nǹkan pọ̀ ni?’

Gbígbé ohun tó máa jẹ́ àbájáde ìgbésẹ̀ kan yẹ̀ wò wà lára àṣàrò ṣíṣe. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni láti ta kété sí àgbèrè, kí wọ́n sì ní ìkóra-ẹni-níjàánu kí “ẹnì kankan má ṣe lọ títí dé àyè ṣíṣe ìpalára fún àti rírakakalé àwọn ẹ̀tọ́ arákùnrin rẹ̀.” (1 Tẹsalóníkà 4:3-7) Àwọn ìbéèrè tó yẹ láti ronú lé lórí nìwọ̀nyí: ‘Ìpalára wo ni mo máa ṣe fún ara mi, ìdílé mi, tàbí àwọn mìíràn bí mo bá ṣe nǹkan yìí? Ipa wo ló máa ní lórí ipò tẹ̀mí mi, ìmọ̀lára mi, àti ara mi pàápàá? Báwo ni nǹkan ṣe rí fún àwọn tó rú òfin Ọlọ́run láyé ọjọ́un?’ Irú ìrònú bẹ́ẹ̀ ló fún Maria lágbára, ó sì lè fún àwa náà lágbára pẹ̀lú.

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àwọn Àpẹẹrẹ

Ǹjẹ́ a lè kọ́ni níwà funfun nínú kíláàsì? Ìbéèrè yìí jẹ́ ọ̀kan tó ti ń da àwọn amòye láàmú láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì nì, Plato, gbà pé ó ṣeé ṣe. Àmọ́ o, Aristotle gbà pé àfi téèyàn bá ń fi ìwà funfun ṣèwà hù ló fi lè ní ànímọ́ yìí. Oníròyìn kan ṣe àkópọ̀ àríyànjiyàn lórí ọ̀ràn náà báyìí pé: “Ní kúkúrú, ìlànà ìwà funfun kì í ṣe ohun táa lè dá nìkan kọ́. Bẹ́ẹ̀ la ò sì lè kọ́ ọ látinú ìwé. Ìwà rere máa ń wá látinú gbígbé láwọn àwùjọ . . . tí wọ́n ti gbé híhùwà funfun lárugẹ, tí wọ́n sì ti ń yẹ́ àwọn tó níwà funfun sí.” Àmọ́, ibo la ti lè rí àwọn èèyàn tó dìídì níwà funfun? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àṣà ìbílẹ̀ ló ń fúnni lápẹẹrẹ ìwà funfun, ó kéré tán wọ́n máa ń tọ́ka sí àwọn akọni inú ìtàn àròsọ wọn àti àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu, Bíbélì ní ọ̀pọ̀ jaburata àwọn àpẹẹrẹ tòótọ́ nínú.

Àpẹẹrẹ ìwà funfun tí ó tayọ jù lọ ni Jèhófà. Ó máa ń hùwà funfun, ó sì máa ń ṣe ohun tó jẹ́ òdodo tó sì dára. A lè ní ìwà funfun nípa dídi “aláfarawé Ọlọ́run.” (Éfésù 5:1) Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, náà ‘fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún wa kí a lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.’ (1 Pétérù 2:21) Láfikún sí i, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ olóòótọ́ èèyàn, àwọn bí Ábúráhámù, Sárà, Jósẹ́fù, Rúùtù, Jóòbù, àti Dáníẹ́lì àti àwọn Hébérù ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Èyí tí a ò tún ní gbójú fò dá ni àwọn àpẹẹrẹ ìwà funfun táa rí láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní.

A Lè Ṣàṣeyọrí

Ǹjẹ́ a lè ṣàṣeyọrí ní tòótọ́ nínú níní ìwà funfun lójú Ọlọ́run? Níwọ̀n bí a ti jogún àìpé, àwọn àkókò kan wà tí ogun gbígbóná máa ń dìde nínú wa, láàárín èrò inú àti ẹran ara wa—láàárín fífẹ́ láti hùwà funfun àti títẹ̀lé àwọn ohun tí ń sún wa dẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 5:12; 7:13-23) Àmọ́, a lè borí ogun náà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. (Róòmù 7:24, 25) Jèhófà ti pèsè Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì. Nípa fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ àti ṣíṣe àṣàrò lé wọn lórí tàdúràtàdúrà, a lè di ẹni tí ó mọ́ ní ọkàn-àyà. Látinú irú ọkàn-àyà mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni èrò, ọ̀rọ̀, àti àwọn ìṣe oníwà funfun ti máa ń wá. (Lúùkù 6:45) Tí a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi, a lè mú àkópọ̀ ìwà bíi ti Ọlọ́run dàgbà. Ó sì dájú pé a lè kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ lára àwọn tí ń fi òtítọ́ sin Ọlọ́run lóde òní.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn òǹkàwé rẹ̀ láti “máa bá a lọ ní gbígba” ìwà funfun àti àwọn nǹkan mìíràn tí ó yẹ fún ìyìn “rò.” Ó dájú pé ṣíṣe èyí yóò mú ìbùkún Ọlọ́run wá. (Fílípì 4:8, 9) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè ṣàṣeyọrí ní mímú ìwà funfun dàgbà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Mú kí ṣíṣe àṣàrò jẹ́ apá kan ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Mú àkópọ̀ ìwà bíi ti Ọlọ́run dàgbà nípa fífarawé Kristi Jésù