Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Iṣẹ́ Àgbàyanu Kan”

“Iṣẹ́ Àgbàyanu Kan”

Ẹ Dúró Lọ́nà Pípé Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀

“Iṣẹ́ Àgbàyanu Kan”

LÁTI ìgbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ti bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ti ní ìfẹ́ àtọkànwá sí ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jésù Kristi tó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Bí ọdún 1914—tó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”—ti ń sún mọ́lé, ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ inú ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan tí kò láfiwé jákèjádò ayé, èyí tí wọ́n gbé karí Ìwé Mímọ́, tí wọ́n sì ń ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in.—2 Tímótì 3:1.

Kí wọ́n lè mú ète wọn láti kéde ìhìn rere náà kárí ayé ṣẹ, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyí lo ọ̀nà kan tó jẹ́ tuntun, tó fi ìgboyà hàn, tó sì ṣe kedere. Ká lè túbọ̀ mọ̀ nípa rẹ̀, ẹ jẹ́ ká padà sígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.

Ọ̀nà Tuntun Láti Kéde Ìhìn Rere

January ọdún 1914 ni. Fojú inú wo ara rẹ láàárín ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] ènìyàn tó jókòó sínú gbọ̀ngàn àpéjọ ṣíṣókùnkùn kan ní New York City. Ògiri ńlá kan tí o ti ń wo àwòrán tó ń rìn wà níwájú rẹ. Baba arúgbó kan tí gbogbo irun rẹ̀ ti funfun tán, tó wọ aṣọ àwọ̀lékè kan sì fara hàn nínú àwòrán ara ògiri náà. O ti máa ń rí sinimá tí kì í sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀, o sì ń gbọ́ ohun tó ń sọ. Ibi tí wọ́n ti ń fi ohun tuntun kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọjú nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ hàn lo wà yí, ọ̀rọ̀ tóò ń gbọ́ sì jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Charles Taze Russell, tó jẹ́ ààrẹ àkọ́kọ́ fún Watch Tower Society ni olùbánisọ̀rọ̀ náà, ohun tí wọ́n sì ń fi hàn ni “Photo-Drama of Creation” [“Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá”].

C. T. Russell rí i pé lọ́jọ́ iwájú ó ṣeé ṣe kí àwòrán tó ń rìn lára ògiri dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tó di ọdún 1912, ó bẹ̀rẹ̀ sí múra “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá” sílẹ̀. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó wá di àwòrán ara ògiri àti sinimá oníwákàtí mẹ́jọ, tó ń gbé àwọ̀ mèremère àti ohùn jáde.

Abala mẹ́rin ni wọ́n pín “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò” sí. Ó jẹ́ kí àwọn òǹwòran rí àwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìṣẹ̀dá jálẹ̀ ìtàn ìran ènìyàn, títí dé paríparì ète Jèhófà Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé àti ìran ènìyàn ní òpin Ẹgbẹ̀rúndún Ìṣàkóso Kristi. Ọ̀pọ̀ ọdún ló máa kọjá, kí àwọn iléeṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ tó mọ irú èyí ṣe. Síbẹ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló rí “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá” náà lọ́fẹ̀ẹ́!

Àwọn orin àtàtà tó gbádùn mọ́ni àti àwọn àsọyé mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún tí wọ́n gbà sílẹ̀ ni wọ́n ṣètò fún “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò” náà. Àwòrán ara ògiri náà ní iṣẹ́ ọnà oríṣiríṣi nínú tó ń ṣàpèjúwe ìtàn ayé. Ó tún pọndandan láti ṣe ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwòrán tuntun. Àwọn kan lára àwọn àwòrán ara ògiri aláwọ̀ mèremère àtàwọn fíìmù náà ló jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fara balẹ̀ jókòó, tí wọ́n sì fọwọ́ yà wọ́n. Wọ́n sì ṣe èyí léraléra, nítorí pé láìpẹ́ sí àkókò yẹn ogún ẹ̀dà ni wọ́n ṣe, wọ́n sì ní abala mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà nínú. Èyí mú kó ṣeé ṣe láti fi apá kan lára “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò” náà hàn ní ọgọ́rin ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ọjọ́ kan pàtó!

Ohun Tí Ń Lọ Lábẹ́lẹ̀

Kí ni ohun tí ń lọ lábẹ́lẹ̀ lákòókò tí wọ́n ń fi “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò” náà hàn? Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Alice Hoffman sọ pé: “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwòrán Arákùnrin Russell. Bó ṣe fara hàn nínú àwòrán ara ògiri náà ni ẹnu rẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí mì, ohun èlò agbóhùnjáde kan á wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ . . . a ó sì máa gbọ́ ohùn rẹ̀.”

Nígbà tí Zola Hoffman ń tọ́ka sí bí wọ́n ṣe ń gbé fọ́tò onírúurú àkókò jáde, ó sọ pé: “Bí mo ṣe jókòó síbẹ̀, kiní ọ̀hún yà mí lẹ́nu débi pé ṣe ni mo ranjú kankan, báa ṣe ń wò àwòrán tó ń fi àwọn àkókò ìṣẹ̀dá hàn. Àwọn òdòdó lílì wà níbẹ̀ tí wọ́n tojú wa ń ṣí díẹ̀díẹ̀.”

Karl F. Klein, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ orin bí nǹkan míì, tó tún jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, fi kún un pé: “Ní àkókò kan náà tí wọ́n ń fi àwọn àwòrán wọ̀nyí hàn, a tún ń gbọ́ ohùn orin dídùn, àwọn orin bíi Narcissus àti Humoreske.”

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé mìíràn tún wà níbẹ̀. Clayton J. Woodworth Kékeré rántí pé: “Àwọn ìgbà mìíràn wà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń dẹ́rìn-ín-pani máa ń wáyé. Ní àkókò kan, àwo orin náà ń kọrin pé, ‘Fò bí Ẹyẹ lọ sí Orí Òkè Ńlá Rẹ,’ àwòrán táa sì rí lára ògiri ni àwòrán gigantosaurus ńlá kan, ìyẹn ni ẹranko ńlá kan tó jẹ́ pé ṣáájú Ìkún Omi ni irú rẹ̀ ti wà gbẹ̀yìn”!

Yàtọ̀ sí “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá” táa máa ń wò déédéé, kò pẹ́ táa tún fi ní àwọn “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Eureka.” (Wo àpótí.) Àwọn àsọyé àti orin táa gbà sílẹ̀ ló wà nínú ìkan. Èkejì kẹ̀ ní àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbà sílẹ̀ àtàwọn àwòrán ara ògiri nínú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Eureka” kò ní àwọn àwòrán tí ń rìn nínú, síbẹ̀ ó kẹ́sẹ járí gan-an nígbà tí wọ́n gbé e jáde láwọn àgbègbè táwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí.

Irinṣẹ́ Lílágbára fún Ìjẹ́rìí

Nígbà tí 1914 fi máa parí, a ti fi “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò” han àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ní North America, Yúróòpù, àti Ọsirélíà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn kéré níye, síbẹ̀ wọn kò ṣe aláìní ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in, èyí tí wọ́n nílò láti fi kéde ìhìn rere náà nípa lílo ohun èlò tuntun yìí. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi dáwó tí wọ́n nílò láti háyà ibi tó jọjú láti ṣe ìfihàn wọ̀nyí. Nípa bẹ́ẹ̀, “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá” wúlò gan-an, ní ti pé ó jẹ́ kí àwọn òǹwòran lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀.

Nínú ọ̀kan lára lẹ́tà tí wọ́n kọ sí C. T. Russell, ẹnì kan kọ̀wé pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo wá wo Àwòkẹ́kọ̀ọ́ yín ni ìgbésí ayé mi ti yí padà; tàbí, kí n kúkú sọ pé, ìgbà yẹn ni ìmọ̀ tí mo ní nínú Bíbélì yí padà.” Ẹlòmíràn sọ pé: “Ọkọ̀ ìgbàgbọ́ mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ rì, mo sì wá rí i pé ‘Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá’ tí wọ́n fi hàn wá ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tó kọjá ló gbà mí là. . . . Mo ti wá ní àlàáfíà tí ayé kò lè fúnni báyìí, n kò sì ní jẹ́ kí gbogbo ọrọ̀ tó wà nínú ayé gbà á lọ́wọ́ mi.”

Demetrius Papageorge, tó ti jẹ́ mẹ́ńbà òṣìṣẹ́ orílé iṣẹ́ Society fún ìgbà pípẹ́, sọ pé: “Àgbàyanu ni iṣẹ́ ‘Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò’ náà jẹ́ nígbà táa bá ronú lórí iye àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí kò ju kéréje àti ìwọ̀nba owó díẹ̀ tó wà lọ́wọ́ nígbà yẹn. Ní ti tòótọ́, ẹ̀mí Jèhófà ló tì í lẹ́yìn!”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

“Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Eureka”

Oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn táa kọ́kọ́ gbé “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò” jáde pàá ni Society rí i pé ó yẹ káwọn gbé oríṣi rẹ̀ mìíràn tí wọ́n pè ní “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Eureka” jáde. Nígbà tó jẹ́ pé “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò” tí wọ́n ti parí ni wọ́n ń fi hàn àwọn èèyàn láwọn ìlú ńláńlá, “Eureka” ni wọ́n fi ń gbé ìsọfúnni kan náà jáde láwọn abúlé àtàwọn ìgbèríko. A ṣàpèjúwe oríṣi “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Eureka” kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ń fún “àwọn arábìnrin láǹfààní aláìlẹ́gbẹ́” láti wàásù. Èé ṣe tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kìlógíráàmù mẹ́rìnlá péré ni ike tí wọ́n kó àwo Eureka sí máa ń wọ̀n. Àmọ́, táa bá fẹ́ fi hàn àwọn èèyàn, ó di dandan láti gbé ohun èlò agbóhùnjáde lọ́wọ́.