Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Bá Ètò Àjọ Jèhófà Rìn

Máa Bá Ètò Àjọ Jèhófà Rìn

Máa Bá Ètò Àjọ Jèhófà Rìn

“Kí Ọlọ́run àlàáfíà . . . fi ohun rere gbogbo mú yín gbára dì láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.”—HÉBÉRÙ 13:20, 21.

1. Èèyàn mélòó ló wà láyé, èèyàn mélòó la sì ṣírò pé ó ń ṣe àwọn ẹ̀sìn kan?

 LỌ́DÚN 1999, iye àwọn olùgbé ayé di bílíọ̀nù mẹ́fà! Ìwé náà, The World Almanac, sọ fún wa pé nínú iye yìí, bílíọ̀nù kan àti àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́jọ ó lé márùn-ún [1,165,000,000] làwọn tó jẹ́ Mùsùlùmí; bílíọ̀nù kan àti àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgbọ̀n [1,030,000,000] jẹ́ Roman Kátólíìkì; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé méjìlélọ́gọ́ta mílíọ̀nù [762,000,000] jẹ́ ẹlẹ́sìn Híńdù; àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́rìnléláàádọ́ta [354,000,000] jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà; àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́rìndínlógún [316,000,000 ] jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì; nígbà tí àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà igba ó lé mẹ́rìnlá [214,000,000] sì jẹ́ ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì.

2. Kí la lè sọ nípa ipò tí ẹ̀sìn wà lónìí?

2 Lójú ìyapa àti ìdàrúdàpọ̀ tó kún inú ẹ̀sìn lónìí, ǹjẹ́ a lè sọ pé gbogbo àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọ̀nyí ló ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ bí? Rárá o, “nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.” (1 Kọ́ríńtì 14:33) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé ńkọ́? (1 Pétérù 2:17) Ìwádìí àfẹ̀sọ̀ṣe fi hàn pé ‘Ọlọ́run àlàáfíà fi ohun rere gbogbo mú wọn gbára dì láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.’—Hébérù 13:20, 21.

3. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, èé sì ti ṣe?

3 Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ọ́, kì í ṣe iye àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà la fi ń mọ̀ bóyá Ọlọ́run yọ́nú sí wọn; kì í sì í ṣe bí wọ́n ṣe pọ̀ rẹpẹtẹ tó ló ń pinnu ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. Kì í ṣe nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló “pọ̀ jù lọ” láyé ló ṣe yàn wọ́n. Àní, àwọn ló “kéré jù lọ.” (Diutarónómì 7:7) Àmọ́, nítorí pé Ísírẹ́lì di aláìṣòótọ́, nígbà tó di Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jèhófà yí ojú rere rẹ̀ sí àwọn mẹ́ńbà ìjọ tuntun tí í ṣe àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. A fi ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà yàn wọ́n, wọ́n sì fi ìtara jáde lọ láti polongo òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Kristi fáwọn ẹlòmíràn.—Ìṣe 2:41, 42.

Ó Ń Tẹ̀ Síwájú Láìsọsẹ̀

4. Èé ṣe tí wàá fi sọ pé ìjọ Kristẹni ìjímìjí tẹ̀ síwájú láìsọsẹ̀?

4 Ní ọ̀rúndún kìíní, ńṣe ni ìjọ Kristẹni ń tẹ̀ síwájú láìsọsẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà láwọn ìpínlẹ̀ tuntun, wọ́n ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n sì ń gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ nípa ète Ọlọ́run. Àwọn lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí ń la àwọn Kristẹni ìjímìjí lóye nípa tẹ̀mí, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlàlóye náà. Wọ́n ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láṣepé, bí ìbẹ̀wò tí àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì ṣe sọ́dọ̀ wọn ti ń gún wọn ní kẹ́ṣẹ́. Gbogbo èyí wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.—Ìṣe 10:21, 22; 13:46, 47; 2 Tímótì 1:13; 4:5; Hébérù 6:1-3; 2 Pétérù 3:17, 18.

5. Èé ṣe tí ètò àjọ Ọlọ́run fi ń tẹ̀ síwájú lónìí, èé sì ti ṣe tó fi yẹ ká máa bá a rìn?

5 Gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn Kristẹni ìjímìjí, ìwọ̀nba kéréje làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀. (Sekaráyà 4:8-10) Láti apá ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ẹ̀rí kedere ti wà pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà pẹ̀lú ètò àjọ rẹ̀. Ìdí tí òye wa nípa Ìwé Mímọ́ fi ń jinlẹ̀ sí i, táa sì túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú nínú ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ni pé a kò gbẹ́kẹ̀ lé agbára ènìyàn, bí kò ṣe ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́. (Sekaráyà 4:6) Nísinsìnyí táa ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ó ṣe pàtàkì pé ká máa bá ètò àjọ Jèhófà tí ń tẹ̀ síwájú rìn. (2 Tímótì 3:1-5) Bíbá a rìn yóò jẹ́ kí ìrètí wa wà lọ́kàn wa digbí, a ó sì máa kópa nínú jíjẹ́rìí nípa Ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀, kí òpin pátápátá tó dé bá ètò àwọn nǹkan yìí.—Mátíù 24:3-14.

6, 7. Kí ni àwọn ọ̀nà mẹ́ta tí ètò àjọ Jèhófà ti gbà tẹ̀ síwájú táa fẹ́ jíròrò?

6 Láàárín wa, àwọn kan wà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ ètò àjọ Jèhófà láti àwọn ọdún 1920, àwọn ọdún 1930, àtàwọn ọdún 1940. Ní àwọn ọdún tó ti pẹ́ wọ̀nyẹn, ǹjẹ́ ẹnì kankan nínú wa lè mọ̀ pé ìbísí gígọntíọ àti ìdàgbàsókè ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ètò àjọ yìí títí di òní yìí lè pọ̀ tó báyìí? Sáà ronú nípa àwọn nǹkan mánigbàgbé tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn wa òde òní! Ká sòótọ́, ó ṣàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ nípa tẹ̀mí láti máa ronú nípa ohun tí Jèhófà ti ṣe nípasẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ tó ṣètò lọ́nà ti ìṣàkóso Ọlọ́run.

7 Orí Dáfídì ìgbàanì wú nígbà tó ronú nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà. Ó sọ pé: “Ká ní mo fẹ́ máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn ni, wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.” (Sáàmù 40:5) Àwa náà mọ̀ pé iṣẹ́ wọ̀nyẹn ò lóǹkà, nítorí pé mélòó la fẹ́ kà lára ọ̀pọ̀ jaburata iṣẹ́ Jèhófà, àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tó yẹ fún ìyìn lọ́jọ́ tiwa. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà mẹ́ta tí ètò àjọ Jèhófà ti gbà tẹ̀ síwájú: (1) ìlàlóye tẹ̀mí tí ń pọ̀ sí i, (2) iṣẹ́ òjíṣẹ́ táa ti mú sunwọ̀n sí i, táa sì ti mú gbòòrò sí i, àti (3) àwọn àtúnṣe tó bágbà mu táa ń ṣe sí àwọn ìlànà ètò àjọ náà.

A Dúpẹ́ fún Ìlàlóye Tẹ̀mí

8. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé Òwe orí kẹrin, ẹsẹ ìkejìdínlógún, kí ni ìlàlóye tẹ̀mí ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ̀ nípa Ìjọba náà?

8 Ní ti ìlàlóye tẹ̀mí tí ń pọ̀ sí i, a ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú ìwé Òwe orí kẹrin, ẹsẹ ìkejìdínlógún. Ó wí pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” A mà dúpẹ́ o, fún ìlàlóye tẹ̀mí táa ń rí gbà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé! Ní àpéjọpọ̀ tó wáyé nílùú Cedar Point, Ohio, lọ́dún 1919, wọ́n tẹnu mọ́ ọ̀ràn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba yìí ni Jèhófà ń lò láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, kí ó sì fi dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre. Ní ti gidi, ìlàlóye tẹ̀mí ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ̀ pé láti Jẹ́nẹ́sísì títí dé Ìṣípayá, Bíbélì jẹ́rìí sí i pé ète Jèhófà jẹ́ láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ nípasẹ̀ Ìjọba náà tí Ọmọ rẹ̀ ń ṣàkóso. Ìyẹn gan-an ni ìrètí ológo tí gbogbo àwọn olùfẹ́ òdodo ní.—Mátíù 12:18, 21.

9, 10. Ní àwọn ọdún 1920, kí la kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba náà àti nípa àwọn ètò àjọ méjì tí ń figagbága, kí sì ni àǹfààní ẹ̀kọ́ yìí?

9 Ní àpéjọpọ̀ Cedar Point, lọ́dún 1922, J. F. Rutherford, tó jẹ́ olùbánisọ̀rọ̀ pàtàkì nígbà àpéjọpọ̀ yẹn, rọ àwọn èèyàn Ọlọ́run pé, “ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Nínú àpilẹ̀kọ náà, “Birth of the Nation” [Ìbí Orílẹ̀-Èdè Náà], nínú Ilé Ìṣọ́ March 1, 1925 [lédè Gẹ̀ẹ́sì], a pe àfiyèsí sí ìjìnlẹ̀ òye tẹ̀mí nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé ọdún 1914 la óò gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀. A tún fòye mọ̀ láwọn ọdún 1920 pé ètò àjọ méjì ló wà tó ń figagbága—ti Jèhófà àti ti Sátánì. Ìjà ń lọ lọ́wọ́ láàárín àwọn méjèèjì, àfi bí a bá ń bá ètò àjọ Jèhófà rìn nìkan la fi lè wà ní ìhà tí yóò ṣẹ́gun.

10 Báwo ni irú òye tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ṣe ràn wá lọ́wọ́? Níwọ̀n bí Ìjọba Ọlọ́run àti Jésù Kristi Ọba kò ti jẹ́ apá kan ayé, àwa pẹ̀lú kò gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan rẹ̀. Nípa yíya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, a ń fi hàn pé ìhà ti òtítọ́ la wà. (Jòhánù 17:16; 18:37) Bí àwa náà ti ń fojú ara wa rí àwọn òkè ìṣòro tí ń bá ètò burúkú yìí fínra, a mà dúpẹ́ o pé a kì í ṣe apá kan ètò àjọ Sátánì! Ojú rere ńláǹlà ló mà sì jẹ́ fún wa o, pé a ní ààbò nípa tẹ̀mí nínú ètò àjọ Jèhófà!

11. Kí ni orúkọ tó bá Ìwé Mímọ́ mu táwọn èèyàn Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà lọ́dún 1931?

11 Ní àpéjọpọ̀ tó wáyé ní Columbus, Ohio, lọ́dún 1931, a ṣàlàyé Aísáyà orí kẹtàlélógójì, ẹsẹ ìkẹwàá sí ìkejìlá lọ́nà tó ṣe wẹ́kú. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́wọ́ gba orúkọ tí kò láṣìmọ̀ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àǹfààní ńláǹlà mà ló jẹ́ o, pé a lè máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀ kí àwọn ẹlòmíràn lè máa ké pè é kí wọ́n lè rí ìgbàlà!—Sáàmù 83:18; Róòmù 10:13.

12. Ìlàlóye tẹ̀mí wo la pèsè nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá náà lọ́dún 1935?

12 Ṣáájú àwọn ọdún 1930, ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn Ọlọ́run ni kò mọ ìrètí wọn fún ìyè ọjọ́ ọ̀la dájú. Àwọn kan ń ronú pé ọ̀run làwọn ń lọ, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa Párádísè ilẹ̀ ayé tún wù wọ́n. Ìròyìn amọ́kànyọ̀ táa gbọ́ ní àpéjọpọ̀ Washington, D.C., lọ́dún 1935 ni pé, ògìdìgbó ńlá, tàbí ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí Ìṣípayá orí keje sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ tó ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé. Látìgbà yẹn ni kíkó ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jọ ti ń tẹ̀ síwájú kánmọ́kánmọ́ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa dúpẹ́ pé ọ̀ràn nípa àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá kì í ṣe àdììtú fún wa mọ́? Rírí tí a ń rí i lóòótọ́ pé a ń kó ogunlọ́gọ̀ jọ látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, àti ahọ́n ń sún wa láti túbọ̀ máa gbésẹ̀ kánmọ́kánmọ́ báa ti ń bá ètò àjọ Jèhófà rìn.

13. Ọ̀ràn ńlá wo ni wọ́n ṣàlàyé nígbà àpéjọpọ̀ St. Louis lọ́dún 1941?

13 Ọ̀ràn ńlá tó yẹ kó jẹ aráyé lógún ni wọ́n ṣàlàyé lọ́dún 1941, ní àpéjọpọ̀ tó wáyé ní St. Louis, Missouri. Ọ̀ràn ìṣàkóso tàbí ipò ọba aláṣẹ àgbáyé mà ni o. Ọ̀ràn yìí la gbọ́dọ̀ yanjú láìpẹ́, ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù tí a ó yanjú ọ̀ràn yìí sì ń bọ̀ kánkán! Ohun mìíràn tó tún tan mọ́ ọ̀ràn táa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, tí wọ́n tún fún láfiyèsí lọ́dún 1941, ni ọ̀ràn ìwà títọ́, tó ń jẹ́ ká lè fi ìhà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa wà hàn nínú ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run.

14. Nígbà àpéjọpọ̀ àgbáyé tó wáyé lọ́dún 1950, ẹ̀kọ́ wo la kọ́ nípa àwọn ọmọ aládé táa mẹ́nu kàn nínú Aísáyà orí kejìlélọ́gbọ̀n, ẹsẹ kìíní àti ìkejì?

14 Nígbà àpéjọpọ̀ àgbáyé tó wáyé ní New York City, lọ́dún 1950, wọ́n ṣàlàyé ẹni tí àwọn ọmọ aládé tí Aísáyà orí kejìlélọ́gbọ̀n, ẹsẹ kìíní àti ìkejì jẹ́ gan-an. Ó jẹ́ àkókò tí ń tani jí gan-an nígbà tí Arákùnrin Frederick Franz sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, tó sì ṣàlàyé pé àwọn ọmọ aládé nínú ayé tuntun ń bẹ láàárín wa. Nínú àpéjọpọ̀ yẹn àtàwọn tó tẹ̀ lé e, ọ̀pọ̀ ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ló ti tàn. (Sáàmù 97:11) A mà dúpẹ́ o, pé ipa ọ̀nà wa “dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i”!

Títẹ̀síwájú Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa

15, 16. (a) Báwo la ṣe tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní àwọn ọdún 1920 àti àwọn ọdún 1930? (b) Àwọn ìtẹ̀jáde wo ló ti fúnni ní ìṣírí láti jára mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí?

15 Ọ̀nà kejì tí ètò àjọ Jèhófà ti gbà tẹ̀ síwájú ní í ṣe pẹ̀lú olórí iṣẹ́ wa—èyíinì ni iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 28:19, 20; Máàkù 13:10) Láti ṣàṣeparí iṣẹ́ yìí, ìgbà gbogbo ni ètò àjọ yìí ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì mímú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i. Lọ́dún 1922, a rọ gbogbo àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ló kù sí láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ máa tàn, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ máa kópa nínú jíjẹ́rìí sí òtítọ́. (Mátíù 5:14-16) Lọ́dún 1927, a gbégbèésẹ̀ láti ya àwọn ọjọ́ Sunday sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Bẹ̀rẹ̀ láti February 1940, àwọn èèyàn sábà máa ń rí àwọn Ẹlẹ́rìí ní òpópónà ibi tí àwọn èèyàn ti ń ṣòwò, tí wọ́n á máa fi Ilé Ìṣọ́ àti Consolation (táa ń pè ní Jí! nísinsìnyí) lọni.

16 A mú ìwé kékeré náà, Model Study, jáde lọ́dún 1937, láti tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò láti lè máa fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, a tẹnu mọ́ iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gidigidi. A fúnni ní ìṣírí láti jára mọ́ ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí nípa mímú ìwé “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” jáde lọ́dún 1946, àti ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye lọ́dún 1968. Lọ́wọ́lọ́wọ́, a ń lo ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Kíkẹ́kọ̀ọ́ irú ìwé bẹ́ẹ̀ máa ń fi ìpìlẹ̀ tó dáa lélẹ̀ fún sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.

Títẹ̀síwájú Pẹ̀lú Àwọn Àtúnṣe Nínú Ètò Àjọ Náà

17. Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà orí ọgọ́ta, ẹsẹ ìkẹtàdínlógún ti wí, báwo ni ètò àjọ Jèhófà ti ṣe tẹ̀ síwájú?

17 Ọ̀nà kẹta tí ètò àjọ Jèhófà ti gbà tẹ̀ síwájú jẹ́ nínú àwọn àtúnṣe tí ń wáyé nínú ètò àjọ náà. Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà orí ọgọ́ta, ẹsẹ ìkẹtàdínlógún ti wí, Jèhófà ṣèlérí pé: “Dípò bàbà, èmi yóò mú wúrà wá, àti dípò irin, èmi yóò mú fàdákà wá, àti dípò igi, bàbà, àti dípò àwọn òkúta, irin; dájúdájú, èmi yóò sì yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.” Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, a ti gbégbèésẹ̀ láti bójú tó iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn agbo lọ́nà tó sunwọ̀n sí i.

18, 19. Àwọn àtúnṣe wo la ti ṣe nínú ètò àjọ yìí bí ọdún ti ń gorí ọdún?

18 Lọ́dún 1919, a yan olùdarí iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ń fẹ́ pé ká ṣètò àwọn fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Èyí jẹ́ ìwúrí fún wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Dídìbò yan àwọn alàgbà àti díákónì dópin lọ́dún 1932, tó fi hàn pé a ti ṣíwọ́ lílo ọ̀nà ìjọba tiwa-n-tiwa. Ohun pàtàkì mìíràn tún ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1938, nígbà táa bẹ̀rẹ̀ sí yan gbogbo ìránṣẹ́ nínú ìjọ lọ́nà tó túbọ̀ bá ètò ìyannisípò lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run mu, gẹ́gẹ́ bó ti rí nínú ìjọ Kristẹni ìjímìjí. (Ìṣe 14:23; 1 Tímótì 4:14) Ọdún 1972 la bẹ̀rẹ̀ sí yan àwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti máa sìn, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe ń sìn láàárín àwọn Kristẹni ìjímìjí. Dípò kí ọkùnrin kan ṣoṣo máa sìn bí alábòójútó nínú ìjọ, Fílípì orí kìíní, ẹsẹ kìíní, àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn fi hàn pé àwọn tó dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè fáwọn alábòójútó ni ó para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn alàgbà.—Ìṣe 20:28; Éfésù 4:11, 12.

19 Ní 1975 la ṣètò pé kí àwọn ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí bójú tó ìgbòkègbodò ètò àjọ Ọlọ́run jákèjádò ayé. A wá ń yan àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka láti máa bójú tó iṣẹ́ náà ní àwọn ìpínlẹ̀ tiwọn. Láti ìgbà yẹn wá, a ti pe àfiyèsí sí mímú kí iṣẹ́ tí a ń ṣe ní orílé-iṣẹ́ àti ní àwọn ẹ̀ka Watch Tower Society rọrùn sí i, kí a lè “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:9, 10) Ẹrù iṣẹ́ tó já lé èjìká àwọn olùṣọ́ àgùntàn ọmọ abẹ́ Kristi ju wíwulẹ̀ mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere, kíkọ́ni nínú ìjọ, àti ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run lọ́nà yíyẹ.—1 Tímótì 4:16; Hébérù 13:7, 17; 1 Pétérù 5:2, 3.

Jésù Ló Ń Darí Iṣẹ́ Náà

20. Bíbá ètò àjọ Jèhófà rìn ń béèrè pé ká mọ kí ni nípa ipò Jésù?

20 Bíbá ètò àjọ Jèhófà tó ń tẹ̀ síwájú rìn ń béèrè pé ká mọ iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí “orí ìjọ.” (Éfésù 5:22, 23) Ìwé Aísáyà orí karùndínlọ́gọ́ta, ẹsẹ ìkẹrin tún yẹ fún àfiyèsí, ibẹ̀ kà pé: “Wò ó! Mo [Jèhófà] ti fi í fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àti aláṣẹ fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” Ó dájú pé Jésù mọ iṣẹ́ aṣíwájú ṣe. Ó mọ àwọn àgùntàn rẹ̀, ó sì mọ iṣẹ́ wọn. Àní, nígbà tó bẹ ìjọ méje tí ń bẹ ní Éṣíà Kékeré wò, ẹ̀ẹ̀marùn-ún ló sọ pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ.” (Ìṣípayá 2:2, 19; 3:1, 8, 15) Jésù tún mọ àwọn àìní wa, bí Baba rẹ̀, Jèhófà, ṣe mọ̀ wọ́n. Kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ Àdúrà àwòfiṣàpẹẹrẹ náà, ó wí pé: “Ọlọ́run tí í ṣe Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.”—Mátíù 6:8-13.

21. Báwo la ṣe ń rí i kedere pé Jésù ló ń darí ìjọ Kristẹni?

21 Báwo ló ṣe hàn kedere pé Jésù ni aṣáájú? Ọ̀kan lára ọ̀nà náà ni nípasẹ̀ àwọn Kristẹni alábòójútó, èyíinì ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.” (Éfésù 4:8) Ìṣípayá orí kìíní, ẹsẹ ìkẹrìndínlógún fi hàn pé àwọn alábòójútó wà lọ́wọ́ ọ̀tún Kristi, èyíinì ni lábẹ́ àkóso rẹ̀. Lónìí, Jésù ló ń darí ìṣètò fún àwọn alàgbà, yálà àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ìrètí ti ọ̀run tàbí ti orí ilẹ̀ ayé. Gẹ́gẹ́ báa ti sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ẹ̀mí mímọ́ ló ń yàn wọ́n ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun táa là sílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. (1 Tímótì 3:1-7; Títù 1:5-9) Ní ọ̀rúndún kìíní, àwùjọ àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù ló para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ olùṣàkóso tí ń bójú tó àwọn ìjọ àti iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní gbogbo gbòò. Ètò kan náà là ń tẹ̀ lé lónìí nínú ètò àjọ Jèhófà.

Máa Bá A Rìn Nìṣó!

22. Ìrànlọ́wọ́ wo ni Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ń pèsè?

22 Àwọn ire Ìjọba náà lórí ilẹ̀ ayé ń bẹ níkàáwọ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” èyí tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣojú fún. (Mátíù 24:45-47) Iṣẹ́ pàtàkì tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso gbájú mọ́ ni pípèsè ìtọ́ni àti ìdarí tẹ̀mí fún ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 6:1-6) Ṣùgbọ́n, nígbà tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso máa ń sọ pé kí àjọ kan tàbí àwọn àjọ mélòó kan táa fòfin gbé kalẹ̀ ṣètò ìrànwọ́ fún wọn, wọ́n sì máa ń ṣètò bí a ó ṣe tún ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bàjẹ́ ṣe. Bí wọ́n bá ń han àwọn Kristẹni kan léèmọ̀ tàbí tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wọn, wọ́n máa ń gbégbèésẹ̀ láti gbé wọn ró nípa tẹ̀mí. Pẹ̀lúpẹ̀lù, “ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú,” wọ́n máa ń rí i dájú pé iṣẹ́ ìwàásù náà kò dúró.—2 Tímótì 4:1, 2.

23, 24. Kí ni Jèhófà máa ń pèsè déédéé láìka ìṣòro yòówù kó dé bá àwọn èèyàn rẹ̀ sí, kí ló sì yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?

23 Ìṣòro yòówù kí ó dé bá àwọn èèyàn Jèhófà, ó máa ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí déédéé, ó sì ń pèsè ìtọ́sọ́nà tí wọ́n nílò. Ọlọ́run tún ń fún àwọn arákùnrin tó ní ẹrù iṣẹ́ ní ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ òye láti múra sílẹ̀ fún ìtẹ̀síwájú àtàwọn àtúnṣe púpọ̀ sí i nínú ètò àjọ tí Ọlọ́run ń ṣàkóso yìí. (Diutarónómì 34:9; Éfésù 1:16, 17) Láìkùnà, Jèhófà ń pèsè ohun táa nílò láti lè ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn láṣepé, ká sì ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeparí kárí ayé.—2 Tímótì 4:5.

24 Ó dá wa lójú hán-ún pé Jèhófà kò ní pa àwọn èèyàn rẹ̀ olùṣòtítọ́ tì láé; òun yóò mú wọn la “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ wá já. (Ìṣípayá 7:9-14; Sáàmù 94:14; 2 Pétérù 2:9) Kò sídìí fún mímikàn rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ jẹ́ ká di ìgbọ́kànlé táa ní ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mú ṣinṣin títí dé òpin. (Hébérù 3:14) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò máa bá ètò àjọ Jèhófà rìn nìṣó.

Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?

• Èé ṣe táa fi lè sọ pé ètò àjọ Jèhófà ń tẹ̀ síwájú láìsọsẹ̀?

• Ẹ̀rí wo ló wà pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn ìlàlóye tẹ̀mí tí ń tẹ̀ síwájú?

• Báwo làwọn àtúnṣe ṣe wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni?

• Kí làwọn àtúnṣe tó bákòókò mu táa ti ṣe sí àwọn ìlànà ètò àjọ yìí láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Bíi ti Dáfídì, a kò lè ka gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà lẹ́sẹẹsẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Agbo Ọlọ́run ti jàǹfààní nínú àwọn àtúnṣe tó bákòókò mu táa ti ṣe sí àwọn ìlànà ètò àjọ yìí