Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ará Latvia Tẹ́wọ́ Gba Ìhìn Rere Náà

Àwọn Ará Latvia Tẹ́wọ́ Gba Ìhìn Rere Náà

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Àwọn Ará Latvia Tẹ́wọ́ Gba Ìhìn Rere Náà

BÍBÉLÌ fi hàn kedere pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Àwọn tí wọn ò láǹfààní àtigbọ́ ìhìn rere náà fún ọ̀pọ̀ ọdún tí wá ń gbọ́ ọ báyìí! Ní Latvia, bíi ti àwọn apá ibòmíràn lágbàáyé, tàgbà tèwe àti onírúurú èèyàn ló ń tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ṣe fi hàn.

• Ní Rēzekne, ìlú kan tó wà ní ìhà ìlà oòrùn Latvia, ìyá kan àti ọmọbìnrin rẹ̀ tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún bẹ obìnrin kan tí wọ́n rí lójú pópó pé kó jọ̀wọ́ júwe àwọn ibì kan fún àwọn. Lẹ́yìn tí obìnrin yìí, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, júwe ibẹ̀ fún wọn tán, ó sọ pé kí wọ́n máa wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí.

Nígbà tó sì jẹ́ pé ìsìn jẹ tìyá tọmọ náà lọ́kàn, wọ́n pinnu àtilọ sípàdé ọ̀hún. Bí wọ́n ṣe ń lọ, àwọn méjèèjì fohùn ṣọ̀kan pé bí àwọn bá rí ohunkóhun tí kò bójú mu níbẹ̀, ojú ẹsẹ̀ làwọ́n máa fibẹ̀ sílẹ̀. Àmọ́, ìpàdé náà dùn débi pé èrò àtifibẹ̀sílẹ̀ kò tiẹ̀ wá sí wọn lọ́kàn rárá ni. Wọ́n gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń wá sípàdé déédéé. Láàárín oṣù mẹ́ta péré, wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ máa nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, wọ́n sì fojú sọ́nà láti ṣe batisí.

• Ní ìlú ńlá kan ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Latvia, Ẹlẹ́rìí kan bá Anna tó jẹ́ ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin pàdé. Ìyá yìí fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn, ó sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọmọ rẹ̀ obìnrin àtàwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ yòókù kò fara mọ́ ọn rárá. Àmọ́ Anna kò jẹ́ kí àtakò yẹn tàbí ọjọ́ ogbó àti àìlera ara dí òun lọ́wọ́ láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì òun nìṣó.

Lọ́jọ́ kan, Anna sọ fún ọmọ rẹ̀ pé òun fẹ́ ṣe batisí. Ohun tí ọmọ Anna fi dá a lóhùn ni pé: “Tóo bá ṣe batisí pẹ́nrẹ́n, màá gbé ẹ lọ sílé àwọn arúgbó.” Ṣùgbọ́n ìhàlẹ̀ yìí kò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Anna rárá. Ilé rẹ̀ ni wọ́n tí ṣe batisí ọ̀hún fún un nítorí àìlera rẹ̀.

Kí ni ọmọ Anna wá ṣe sí èyí? Ìṣarasíhùwà rẹ̀ yí padà, ó se àkànṣe oúnjẹ kan fún ìyá rẹ̀ lẹ́yìn batisí náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá bi ìyá rẹ̀ pé, “Báwo ni ara rẹ ṣe rí nísinsìnyí tóo ti ṣe batisí?” Kí ni Anna fi fèsì? Ó ní: “Àfi bíi pé ọmọ tuntun ni mí!”

• Ní December 1998, àwọn méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí bá ọ̀gágun kan tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ní Soviet Union àtijọ́ pàdé. Nítorí pé ó nígbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá, ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyàwó rẹ̀ náà sì dara pọ̀ mọ́ ọn nígbà tó yá. Wọ́n tẹ̀ síwájú kíákíá, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi di akéde tí kò tíì ṣe batisí. Nígbà tó fi máa dìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tó tẹ̀ lé e, ọ̀gágun tẹ́lẹ̀ rí náà ti ṣe batisí. Ìfẹ́ ńlá tí tọkọtaya yìí ní sí àwọn nǹkan tẹ̀mí ti jẹ́ ìṣírí fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ. Yàtọ̀ síyẹn, gbogbo ara ni wọ́n fi ṣiṣẹ́ nígbà tí wọ́n ń tún ilé kan ládùúgbò wọn kọ́, èyí tí wọ́n sọ di Gbọ̀ngàn Ìjọba rèǹtèrente.