“Amúniláradá fún Ìdodo Rẹ”
“Amúniláradá fún Ìdodo Rẹ”
WỌ́N ní ohun tí ń fa ọ̀pọ̀ lára àwọn àìsàn tí ń bá ọmọ aráyé jà ni àwọn nǹkan tí ń kóni láyà sókè, bí ìbẹ̀rù, ìbànújẹ́, ìlara, ìbínú, ìkórìíra, àti ẹ̀bi. Fún ìdí yìí, ẹ wo bí ọ̀rọ̀ Bíbélì náà ti tuni nínú tó, pé ‘ìbẹ̀rù Jèhófà’ jẹ́ “amúniláradá fún ìdodo rẹ àti ìtura fún egungun rẹ”!—Òwe 3:7, 8.
Egungun ni òpó tó mára dúró. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi lo ọ̀rọ̀ náà “egungun” lọ́nà àfiwé, láti dúró fún wíwà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan—ní pàtàkì àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ èrò jíjinlẹ̀ àti ìmí ẹ̀dùn. Àmọ́ báwo ni ìbẹ̀rù Jèhófà ṣe jẹ́ “amúniláradá fún ìdodo rẹ”?
Ẹnu àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ò kò lórí ìtumọ̀ “ìdodo” nínú àyọkà yìí. Ọ̀gbẹ́ni alálàyé kan sọ pé nítorí pé “ìdodo” wà ní “agbedeméjì ara,” ó ṣeé ṣe kó dúró fún àwọn ẹ̀yà ara tó ṣe kókó. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mìíràn dá a lábàá pé ọ̀rọ̀ náà “ìdodo” lè túmọ̀ sí ìwọ́, gẹ́gẹ́ bí a ṣe lò ó nínú Ìsíkíẹ́lì 16:4. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ó lè jẹ́ pé ṣe ni Òwe 3:8 ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì gbígbé gbogbo ara lé Ọlọ́run—gẹ́gẹ́ bí oyún inú, tí kò lè dá ṣe ohunkóhun, ṣe ń gbé gbogbo ara lé ìyá rẹ̀ fún oúnjẹ. Àbá mìíràn tún ni pé ó ṣeé ṣe kí ohun táa pè ní “ìdodo” níhìn-ín túmọ̀ sí àwọn iṣan àti iṣu ẹran ara. Nínú àyíká ọ̀rọ̀ ẹsẹ yìí, bóyá ohun tó ń fi hàn ni bí àwọn iṣan àti iṣu ẹran ṣe yàtọ̀ gan-an sí “egungun”—èyí tó le ju gbogbo àwọn ẹ̀yà ara yòókù lọ.
Ohun yòówù kí ó jẹ́ ìtumọ̀ rẹ̀ pàtó, ohun kan dájú: Níní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà jẹ́ ìwà ọgbọ́n. Mímú ara ẹni bá ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run mu lè fi kún ìlera wa nísinsìnyí. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó lè jẹ́ ká rí ojú rere Jèhófà, tí yóò ṣamọ̀nà sí ìyè àìlópin nínú ìlera pípé—nípa tara àti ní ti ìmí ẹ̀dùn—nínú ayé tuntun rẹ̀ tí ń bọ̀.—Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:4; 22:2.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Dókítà G. Moscoso/SPL/Photo Researchers