Ewu Nílé, Ewu Lóko
Ewu Nílé, Ewu Lóko
“Kò sí nǹkan náà téèyàn ń gbé ṣe láyé yìí—títí kan oorun téèyàn ń sùn pàápàá—tí kò léwu nínú, ewu ọ̀hún sì lè pọ̀ débi pé kí nǹkan náà di àṣemọ fónítọ̀hún.”—Ìwé ìròyìn Discover.
WỌ́N ní ìgbésí ayé ẹ̀dá kò yàtọ̀ sí rírìn nínú pápá tí wọ́n ri àwọn ohun abúgbàù sí, nítorí pé ọṣẹ́ lè ṣeni, ikú sì lè pani nígbàkigbà, lójijì. Onírúurú sì lohun tó lè fa ewu lórílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lára wọn ni jàǹbá ọkọ̀, ogun abẹ́lé, ìyàn, àrùn éèdì, àrùn jẹjẹrẹ, àrùn ọkàn, àti ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn tó lọ bí ilẹ̀ bí ẹní. Fún àpẹẹrẹ, àrùn éèdì ló ń pa àwọn èèyàn jù ní gúúsù aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà. Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé láìpẹ́ yìí, láàárín ọdún kan ṣoṣo, àrùn yìí “pa iye tó lé ní mílíọ̀nù méjì èèyàn, tó jẹ́ ìlọ́po mẹ́wàá àwọn tí gbogbo ogun abẹ́lé Áfíríkà pa.”
Ní báyìí, ayé ń ná owó rẹpẹtẹ-rẹ̀pẹ̀tẹ̀ lórí kí ẹ̀mí lè gùn sí i, kí wọ́n sì lè dín ewu àìsàn àti òkùnrùn kù. Ọ̀pọ̀ ọgbọ́n tí wọ́n ń dá, bíi ká máa jẹ, ká sì máa mu àwọn ohun aṣaralóore, ká tún máa ṣeré ìmárale, kò ṣàìní àǹfààní tiwọn. Ṣùgbọ́n o, ibì kan wà tóo ti lè rí ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé nípa gbogbo ọ̀ràn pàtàkì nínú ìgbésí ayé, tó lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ láti gbádùn ìgbésí ayé aláàbò. Inú Bíbélì lo ti lè rí irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀. Ó ní àwọn ìlànà táa lè fi yanjú
ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìṣòro ọ̀ràn ìlera àti àlàáfíà ara. Kì í kúkú ṣe pé Bíbélì ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí gbogbo ìṣòro. Àmọ́, ó pèsè àwọn ìlànà tó jíire láti tọ́ wa sọ́nà nínú àwọn ọ̀ràn bíi jíjẹ, kí ara wà ní kanpe, nípa ìṣarasíhùwà ẹni, ọ̀ràn ìbálòpọ̀ takọtabo, ọtí mímu, sìgá mímu, àtàwọn oògùn líle táwọn kan fi ń ṣe fàájì, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn nǹkan míì.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ọ̀ràn ìṣúnná owó ti sọ ìgbésí ayé wọn di báṣubàṣu. Ojútùú eléyìí náà ń bẹ nínú Bíbélì. Kì í ṣe kìkì pé ó rọ̀ wá láti má ṣe sọ owó di nǹkan bàbàrà, kí a sì mọ̀ ọ́n ná nìkan ni, àní ó tún jẹ́ ká mọ báa ṣe lè jẹ́ òṣìṣẹ́ àti agbanisíṣẹ́ tó sunwọ̀n. Láìfọ̀rọ̀ gùn, Bíbélì jẹ́ atọ́nà tó dáńgájíá, kì í ṣe kìkì lórí ọ̀ràn ìnáwó àti àlàáfíà ara nìkan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ atọ́nà fún ìgbésí ayé pàápàá. Ṣé wàá fẹ́ mọ bí Bíbélì ṣe wúlò tó lóde òní? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, dákun bá wa ká lọ sínú ọ̀rọ̀ tó kàn.