Ǹjẹ́ Ò Ń gbé Níbàámu Pẹ̀lú Ìyàsímímọ́ Rẹ?
Ǹjẹ́ Ò Ń gbé Níbàámu Pẹ̀lú Ìyàsímímọ́ Rẹ?
“Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.”—KÓLÓSÈ 3:23.
1. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìyàsímímọ́” túmọ̀ sí nínú ẹ̀kọ́ ayé?
BÁWO ni àwọn eléré ìdárayá ṣe ń di ọ̀jáfáfá? Nínú gbígbá tẹníìsì, bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá, bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀, baseball, eré àfẹsẹ̀sá, bọ́ọ̀lù àfọ̀págbá, tàbí nínú àwọn eré ìdárayá èyíkéyìí, àwọn òléwájú nínú eré wọ̀nyí máa ń dépò iwájú, kìkì nítorí pé wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn ṣe é láìbojúwẹ̀yìn. Mímú ara àti èrò orí wọn bá ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe mú ló máa ń ṣáájú. Ṣé irú ìfitorí-tọrùn ṣe yìí nìkan ló yẹ kó máa wá sọ́kàn wa nígbà táa bá ń ronú nípa ìyàsímímọ́ tí Bíbélì sọ?
2. Kí ni “ìyàsímímọ́” túmọ̀ sí nínú Bíbélì? Ṣàpèjúwe.
2 Kí ni “ìyàsímímọ́” túmọ̀ sí nínú Bíbélì? “Yà sí mímọ́” túmọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù kan tó túmọ̀ sí “ya ara ẹni sọ́tọ̀; di ẹni táa yà sọ́tọ̀; fà sẹ́yìn.” a Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ohun tí Áárónì Àlùfáà Àgbà ń fi sára láwàní rẹ̀ ni “àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́,” èyí jẹ́ àwo dídán tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe, tí wọ́n fín ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà” sí lára. Ìyẹn jẹ́ ohun tí yóò máa rán àlùfáà àgbà náà létí pé ó gbọ́dọ̀ yẹra fún ṣíṣe ohunkóhun tó lè sọ ibùjọsìn náà di aláìmọ́, “nítorí pé àmì ìyàsímímọ́, òróró àfiyanni Ọlọ́run rẹ̀, wà lórí rẹ̀.”—Ẹ́kísódù 29:6; 39:30; Léfítíkù 21:12.
3. Báwo ló ṣe yẹ kí ìyàsímímọ́ nípa lórí ìwà wa?
3 A lè rí i nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí pé ìyàsímímọ́ kì í ṣe nǹkan táa ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú rárá. Ó túmọ̀ sí kéèyàn fi tinútinú fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ó sì ń béèrè ìwà tó mọ́ tónítóní. Nítorí náà, a lè mọ ìdí tí àpọ́sítélì Pétérù fi ṣàyọlò ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.” (1 Pétérù 1:15, 16) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, ẹrù iṣẹ́ wíwúwo wà lọ́rùn wa láti máa gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa, ká jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin. Àmọ́ kí ni ìyàsímímọ́ Kristẹni ní nínú?—Léfítíkù 19:2; Mátíù 24:13.
4. Báwo la ṣe ń dé orí ìgbésẹ̀ ṣíṣe ìyàsímímọ́, kí la sì lè fi wé?
4 Lẹ́yìn táa ti jèrè ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ àti nípa Jésù Kristi àti ipa tí ó kó nínú àwọn ète wọ̀nyẹn, a fúnra wa pinnu láti sin Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, èrò inú, ọkàn, àti okun wa. (Máàkù 8:34; 12:30; Jòhánù 17:3) A tiẹ̀ lè wo ìyẹn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ tí a fúnra wa jẹ́, ìyẹn ni yíya ara wa sí mímọ́ pátápátá fún Ọlọ́run. Ìyàsímímọ́ wa kì í wulẹ̀ ṣe ohun táa kù gìrì ṣe. Ó jẹ́ ohun táa fara balẹ̀ ronú lé lórí pẹ̀lú àdúrà, táa sì lo agbára ìrònú wa. Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìpinnu tí yóò wà fúngbà díẹ̀. A kò lè dà bí ẹnì kan tó bẹ̀rẹ̀ sí túlẹ̀ oko kan, tó wá báṣẹ́ débì kan tó lóun ò ṣe mọ́ nítorí pé iṣẹ́ náà ti le jù, tàbí nítorí tí ó jọ pé àkókò ìkórè ti jìnnà jù tàbí nítorí pé kò dá a lójú rárá pé àkókò ìkórè máa dé. Gbé àpẹẹrẹ àwọn kan yẹ̀ wò, ìyẹn àwọn tí wọ́n ti ‘fi ọwọ́ wọn lé ohun ìtúlẹ̀’ tó jẹ mọ́ ẹrù iṣẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run láìka gbogbo ìṣòro sí.—Lúùkù 9:62; Róòmù 12:1, 2.
Wọn Ò Sẹ́ Ìyàsímímọ́ Wọn
5. Báwo ni Jeremáyà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tí ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fun Ọlọ́run?
5 Àkókò tí Jeremáyà fi jẹ́ iṣẹ́ alásọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù gùn ju ogójì ọdún lọ (láti 647 sí 607 ṣááju Sànmánì Tiwa), kì í sì í ṣe iṣẹ́ tó rọrùn rárá. Ó mọ ibi tí agbára òun mọ. (Jeremáyà 1:2-6) Ó nílò ìgboyà àti ìfaradà lójoojúmọ́ láti kojú àwọn èèyàn Júdà tí wọ́n jẹ́ olórí kunkun. (Jeremáyà 18:18; 38:4-6) Àmọ́, Jeremáyà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó fún un lókun tó fi lè fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tó dìídì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run.—Jeremáyà 1:18, 19.
6. Àpẹẹrẹ wo ni àpọ́sítélì Jòhánù fi lélẹ̀ fún wa?
6 Àpọ́sítélì Jòhánù olóòótọ́ náà ńkọ́, ẹni tó ti darúgbó nígbà tí wọ́n tìtorí “sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́rìí Jésù” mú un lọ sígbèkùn ní erékùṣù Pátímọ́sì tó ṣòroó gbé? (Ìṣípayá 1:9) Ó fara dà á, ó sì gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni fún nǹkan bí ọgọ́ta ọdún. Ó ṣì wà láàyè lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run. Ó láǹfààní kíkọ ọ̀kan nínú ìwé Ìhìn Rere, ó tún kọ lẹ́tà mẹ́ta táa mí sí, àti ìwé ìṣípayá, nínú èyí tó ti rí ogun Amágẹ́dọ́nì tẹ́lẹ̀. Ǹjẹ́ ó jáwọ́ nígbà tó rí i pé Amágẹ́dọ́nì kò ní dé lójú ayé òun? Ǹjẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí lẹ́mìí ìdágunlá? Rárá o, Jòhánù ṣe olóòótọ́ dójú ikú, ó mọ̀ pé bí ‘àkókò tí a yàn kalẹ̀ tiẹ̀ sún mọ́lé,’ ìmúṣẹ ìran náà yóò wáyé lọ́jọ́ iwájú.—Ìṣípayá 1:3; Dáníẹ́lì 12:4.
Àwọn Àpẹẹrẹ Ìyàsímímọ́ Lóde Òní
7. Báwo ni arákùnrin kan ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún ìyàsímímọ́ Kristẹni?
7 Lóde òní, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni tòótọ́ ló ti fi tìtaratìtara gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé Amágẹ́dọ́nì kò ní jà lójú wọn. Ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Ernest E. Beavor nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ó di Ẹlẹ́rìí ní ọdún 1939, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, ó sì fi iṣẹ́ fọ́tò yíyà fún ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn tó ń mówó wọlé fún un sílẹ̀ kí ó lè tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Nítorí pé ó mú ìdúró rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni tí kò dá sí tọ̀túntòsì, ó lọ sẹ́wọ̀n fún ọdún méjì gbáko. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ dúró tì í gbágbáágbá, nígbà tó sì di ọdún 1950, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lọ sí Watchtower Bible School of Gilead, ní New York, láti gbà ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Arákùnrin Beavor nítara gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ débi pé Ernie Alámágẹ́dọ́nì làwọn ọrẹ́ rẹ̀ máa ń pè é. Ó fi ìdúróṣinṣin gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ rẹ̀, ńṣe ló sì ń kéde pé ogun Ọlọ́run ní Amágẹ́dọ́nì ti sún mọ́lé títí tó fi kú lọ́dún 1986. Kò ka ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí bíbá Ọlọ́run ṣàdéhùn fúngbà díẹ̀! b—1 Kọ́ríńtì 15:58.
8, 9. (a) Àpẹẹrẹ wo ní ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin fi lélẹ̀ ní Sípéènì lákòókò tí Franco ń ṣàkóso? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kí a bi ara wa?
8 Àpẹẹrẹ ìtara mìíràn tí kò yingin wá láti Sípéènì. Láàárín àkókò tí Franco ń ṣàkóso (1939 sí 1975), ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ló mú ìdúró wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tí kò dá sí tọ̀túntòsì. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló lo ọdún mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ológun. Àpapọ̀ iye ọdún tí wọ́n tiẹ̀ ní kí Ẹlẹ́rìí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jesús Martín lọ fi ṣẹ̀wọ̀n pọ̀ tó ọdún méjìlélógún. Wọ́n lù ú bí ẹní máa kú nígbà tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n àwọn ológun ní Àríwá Áfíríkà. Kò sí èyí tó rọrùn rárá nínú gbogbo rẹ̀, àmọ́, ó kọ̀ láti juwọ́ sílẹ̀.
9 Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọ̀dọ́kùnrin wọ̀nyí kò mọ ìgbà tí wọ́n máa tú wọn sílẹ̀, ìyẹn tí wọ́n bá máa tú wọn sílẹ̀ rárá, nítorí pé ìlọ́po-ìlọ́po ni wọ́n sọ iye ọdún tí wọ́n máa lò lẹ́wọ̀n dà. Síbẹ̀, wọ́n pa ìwà títọ́ wọn mọ́, ìtara tí wọ́n ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà kò sì yingin ní gbogbo àkókò tí wọ́n fi wà lẹ́wọ̀n. Nígbà tí ipò nǹkan wá bẹ̀rẹ̀ sí rọlẹ̀ ní 1973, ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí, tí wọ́n ti lé ní ẹni ọgbọ̀n ọdún lákòókò yẹn ni wọ́n tú sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, àwọn kan lára wọn di aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, àwọn kan sì di alábòójútó arìnrìn-àjò. Wọ́n gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wọn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì ń bá ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lọ látìgbà tí wọ́n ti kúrò lẹ́wọ̀n. c Àwa ńkọ́ lónìí? Ṣé àwa náà ń gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa bíi tàwọn adúróṣinṣin wọ̀nyí?—Hébérù 10:32-34; 13:3.
Ojú Tó Yẹ Ká Fi Wo Ìyàsímímọ́ Wa
10. (a) Ojú wo ló yẹ ká fi wo ìyàsímímọ́ wa? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ń wo iṣẹ́ ìsìn táa ń ṣe fún un?
10 Ojú wo la fi ń wo ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀? Ṣé ohun àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa ni? Ipòkípò táa bá wà, yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí arúgbó, yálà a ti ṣègbéyàwó tàbí a ṣì wà lápọ̀n-ọ́n, yálà ara wa le koko tàbí a ń ṣàárẹ̀, a gbọ́dọ̀ tiraka láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa, bí ipò táa wà bá ṣe fún wa láyè tó. Ipò ẹnì kan lè fún un láyè láti sìn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà tàbí ẹni tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society, ó tún lè jẹ́ míṣọ́nnárì tàbí ẹni tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn arìnrìn-àjò. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọwọ́ àwọn òbí kan lè dí, bí wọ́n ṣe ń bójú tó àìní ìdílé wọn nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Ǹjẹ́ a lè sọ pé ìwọ̀nba wákàtí tí wọ́n ń lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣooṣù kò níye lórí lójú Jèhófà tó ọ̀pọ̀ wákàtí tí ẹni tó jẹ́ ìránṣẹ́ alákòókò kíkún ń lò? Ó tì o. Ọlọ́run kò lè retí pé ká fóun ní ohun tí a kò ní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ìlànà yìí pé: “Bí ìmúratán bá kọ́kọ́ wà, ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn kò ní.”—2 Kọ́ríńtì 8:12.
11. Kí ni ìgbàlà wa sinmi lé?
11 Bó ti wù kó rí, ìgbàlà wa kò sinmi lórí ohunkóhun táa lè ṣe, bí kò ṣe lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà nípasẹ̀ Kristi Jésù, Olúwa wa. Pọ́ọ̀lù fi yéni yékéyéké pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run, a sì ń polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà tí Kristi Jésù san.” Àmọ́ o, àwọn iṣẹ́ wa jẹ́ ẹ̀rí bí ìgbàgbọ́ wa nínú ìlérí Ọlọ́run ṣe gbéṣẹ́ tó.—Róòmù 3:23, 24; Jákọ́bù 2:17, 18, 24.
12. Èé ṣe tí kò fi yẹ ká máa ṣe àfiwéra?
12 Kò sídìí fún wa láti máa fi àkókò táa ń lò nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a ń fi sóde, tàbí iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a ń darí wé ti àwọn ẹlòmíràn. (Gálátíà 6:3, 4) Láìfi àṣeyọrí èyíkéyìí táa bá ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Kristẹni pè, gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa rántí ọ̀rọ̀ onírẹ̀lẹ̀ tí Jésù sọ pé: “Bákan náà ni ẹ̀yin, pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a yàn lé e yín lọ́wọ́ tán, ẹ wí pé, ‘Àwa jẹ́ ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun. Ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ṣe.’” (Lúùkù 17:10) Ìgbà mélòó la tiẹ̀ lè sọ pé a ti ṣe “gbogbo ohun tí a yàn” lé wa lọ́wọ́? Ìbéèrè náà ni pé, Báwo ló ṣe yẹ kí iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run dára tó?—2 Kọ́ríńtì 10:17, 18.
Iṣẹ́ Ojoojúmọ́ Ni
13. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní báa ṣe ń mú ìyàsímímọ́ wa ṣẹ?
13 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn aya, ọkọ, òbí, àtàwọn ẹrú nímọ̀ràn tán, ó wá kọ̀wé pé: “Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn, nítorí ẹ mọ̀ pé láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ẹ ó ti gba ẹ̀san yíyẹ ti ogún náà. Ẹ máa sìnrú fún Ọ̀gá náà, Kristi.” (Kólósè 3:23, 24) A ò sìn láti fi ohun táa ń ṣe láṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe fọ́rífọ́rí fáwọn èèyàn. A ń tiraka láti sin Ọlọ́run nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi ni. Ẹ̀mí kánjúkánjú ló fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ níwọ̀nba àkókò kúkúrú tó fi ṣe é.—1 Pétérù 2:21.
14. Ìkìlọ̀ wo ni Pétérù fúnni nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?
14 Àpọ́sítélì Pétérù náà fi ẹ̀mí kánjúkánjú hàn. Nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì, ó kìlọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá—ìyẹn àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn oníyèméjì—àwọn tó jẹ́ pé ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn wọn, wọn óò gbé ìbéèrè dìde nípa wíwàníhìn-ín Kristi. Àmọ́, Pétérù sọ pé: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà. Síbẹ̀ ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ó dájú pé ọjọ́ Jèhófà yóò dé. Nítorí náà, bí ìgbàgbọ́ wa nínú ìlérí Ọlọ́run ṣe dájú àti bó ṣe lágbára tó gbọ́dọ̀ máa wà ní góńgó ẹ̀mí wa lójoojúmọ́.—2 Pétérù 3:3, 4, 9, 10.
15. Báwo ló ṣe yẹ ká máa wo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ìgbésí ayé wa?
15 Táa bá fẹ́ fi tọkàntọkàn gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa, ojoojúmọ́ la óò máa fi ìyìn fún Jèhófà. Ní òpin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ǹjẹ́ a lè wẹ̀yìn wò, ká sì rí àwọn ọ̀nà kan táa fi lọ́wọ́ sí yíya orúkọ Ọlọ́run sí mímọ́ àti kíkéde ìhìn rere Ìjọba náà? Ó lè jẹ́ nípa ìwà mímọ́ wa, àwọn ìjíròrò wa tí ń gbéni ró, tàbí àníyàn onífẹ̀ẹ́ táa ní fún tẹbí tọ̀rẹ́. Ǹjẹ́ a lo àwọn àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tí àwa Kristẹni ní? Ǹjẹ́ a tíì ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run? Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun tó ní láárí nípa tẹ̀mí lójoojúmọ́, kí a máa kó ìṣúra tó jọjú sínú ohun táa lè pè ní báńkì tẹ̀mí wa.—Mátíù 6:20; 1 Pétérù 2:12; 3:15; Jákọ́bù 3:13.
Jẹ́ Kí Ojú Rẹ Mọ́lẹ̀ Kedere
16. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì gbà ń gbìyànjú láti sọ ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọ́run di aláìlágbára?
16 A ń gbé ní àkókò tí nǹkan túbọ̀ ń le fáwọn Kristẹni. Sátánì àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ń gbìyànjú láti máà jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín rere àti búburú, láàárín ohun mímọ́ àti àìmọ́, láàárín ìwà rere àti ìwà pálapàla, láàárín ìwà ọmọlúwàbí àti ti ọmọ ìta. (Róòmù 1:24-28; 16:17-19) Ó ti mú kó rọrùn fún wa láti sọ ọkàn àti èrò inú wa dìbàjẹ́ nípasẹ̀ ohun èlò aláfọwọ́tẹ̀ péńpé táa fi ń darí tẹlifíṣọ̀n wa síbi tó wù wá tàbí nípasẹ̀ lílo íńtánẹ́ẹ̀tì. Ojú tẹ̀mí wa lè di bàìbàì, tàbí kó máà ríran kedere mọ́, kó wá di pé a ò ní lè fòye mọ̀ ìwà àrékérekè rẹ̀ mọ́. Ìpinnu táa ṣe láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa lè di aláìlágbára mọ́, kí a sì wá dẹwọ́ táa fi mú “ohun ìtúlẹ̀” náà, ìyẹn bí a bá fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú àwọn ohun tẹ̀mí wa ṣíṣeyebíye.—Lúùkù 9:62; Fílípì 4:8.
17. Báwo ni ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run nìṣó?
17 Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà ní Tẹsalóníkà wá bá àkókò mu wẹ́kú pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, sísọ yín di mímọ́, pé kí ẹ ta kété sí àgbèrè; pé kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá, kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo irúfẹ́ èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì pẹ̀lú tí kò mọ Ọlọ́run ní.” (1 Tẹsalóníkà 4:3-5) Ìwà pálapàla ti mú kí a yọ àwọn kan kúró nínú ìjọ Kristẹni—ìyẹn àwọn èèyàn tí kò kọbi ara sí ìyàsímímọ́ wọn sí Ọlọ́run. Wọ́n jẹ́ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run di aláìlágbára mọ́, tó fi jẹ́ pé Ọlọ́run ò já mọ́ nǹkan kan mọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run kò pè wá pẹ̀lú ìyọ̀ǹda fún ìwà àìmọ́, bí kò ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìsọdimímọ́. Nítorí bẹ́ẹ̀, ènìyàn tí ó bá fi ìwà àìkanisí hàn, kì í ṣe ènìyàn ni ó ń ṣàìkàsí, bí kò ṣe Ọlọ́run, ẹni tí ó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sínú yín.”—1 Tẹsalóníkà 4:7, 8.
Kí Ni Ìpinnu Rẹ?
18. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
18 Bí a bá mọ bí ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó, kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe? Ohun tó yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa tí kò lè yẹ̀ ni pé ká ní ẹ̀rí ọkàn rere nínú ìwà wa àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Pétérù gbani níyànjú pé: “Ẹ di ẹ̀rí-ọkàn rere mú, pé nínú ohun náà tí a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín, kí ojú lè ti àwọn tí ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà rere yín ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi.” (1 Pétérù 3:16) A lè jìyà tàbí káwọn èèyàn bú wa nítorí ìwà Kristẹni táa ń hù, àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe sí Kristi náà nìyẹn nítorí ìgbàgbọ́ àti ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí Pétérù fi sọ pé: “Nítorí náà, níwọ̀n bí Kristi ti jìyà nínú ẹran ara, ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ fi ìtẹ̀sí èrò orí kan náà di ara yín ní ìhámọ́ra; nítorí pé ẹni tí ó ti jìyà nínú ẹran ara ti yọwọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀.”—1 Pétérù 4:1.
19. Kí la fẹ́ kí wọ́n máa sọ nípa wa?
19 Ní tòótọ́, ìpinnu táa ṣe láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa yóò dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun ṣàgbẹ̀-lójú-yòyò inú ayé Sátánì tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí, nípa tí ìwà rere àti nípa tara yìí. Àmọ́, kò mọ síbẹ̀ yẹn o, ọkàn wa yóò balẹ̀ pé a rí ojú rere Ọlọ́run, èyí tó dára ju ohunkóhun tí Sátánì àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ lè fún wa lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, kí wọ́n má ṣe sọ nípa wa láé pé a fi ìfẹ́ táa ní nígbà táa kọ́kọ́ mọ òtítọ́ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa sọ ohun tí wọ́n sọ nípa ìjọ Tíátírà ọ̀rúndún kìíní nípa àwa náà pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìfaradà rẹ, àti pé àwọn iṣẹ́ rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ju àwọn ti ìṣáájú.” (Ìṣípayá 2:4, 18, 19) Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ má ṣe jẹ́ kí a di kò-gbóná-kò-tutù nínú ìyàsímímọ́ wa, ṣùgbọ́n kí a jẹ́ “kí iná ẹ̀mí máa jó nínú” wa, kí a ní ìtara títí dé òpin—òpin ọ̀hún sì ti sún mọ́lé.—Róòmù 12:11; Ìṣípayá 3:15, 16.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé-Ìṣọ́nà April 15, 1987, ojú ìwé 31.
b Wo Ile-Iṣọ Naa September 15, 1980, ojú ìwé 8 sí 11, fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtàn ìgbésí ayé Ernest Beavor.
c Wo1978 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 156 sí 158, 201 sí 218, èyí tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni ìyàsímímọ́ ní nínú?
• Àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run láyé ọjọ́un àti lóde òní wo ló yẹ ká fara wé?
• Ojú wo ló yẹ ká fi wo iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run?
• Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa nípa ìyàsímímọ́ táa ṣe sí Ọlọ́run?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jeremáyà dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ láìfi ìwà búburú jáì tí wọ́n hù sí i pè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ernest Beavor fi àpẹẹrẹ jíjẹ́ Kristẹni onítara lélẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ló pa ìwà títọ́ wọn mọ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Sípéènì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹ jẹ́ kí a ṣe ohun kan tó dára nípa tẹ̀mí lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan