Ǹjẹ́ o Ti Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ?
Ǹjẹ́ o Ti Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ?
“Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—RÓÒMÙ 12:2.
1, 2. Èé ṣe tí kò fi rọrùn láti jẹ́ Kristẹni tòótọ́ lóde òní?
LÁTI jẹ́ Kristẹni tòótọ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí—ìyẹn ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” wọ̀nyí—kò rọrùn rárá. (2 Tímótì 3:1) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, èèyàn gbọ́dọ̀ ṣẹ́gun ayé kó tó lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. (1 Jòhánù 5:4) Rántí ohun tí Jésù sọ nípa ọ̀nà Kristẹni pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” Ó tún sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.”—Mátíù 7:13, 14; Lúùkù 9:23.
2 Lẹ́yìn tí Kristẹni kan bá ti rí ojú ọ̀nà híhá tó lọ sí ìyè, ìpèníjà tó tẹ̀ lé e ni pé kó dúró síbẹ̀. Èé ṣe tíyẹn fi jẹ́ ìpèníjà? Ìdí ni pé ìyàsímímọ́ àti ìbatisí táa ṣe ti sọ wá di ẹni tí ìwà àrékérekè tàbí ètekéte Sátánì yóò máa dọdẹ rẹ̀ kiri. (Éfésù 6:11; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Ó ń kíyè sí àwọn àìlera wa, ó sì ń wá bí òun ṣe máa lò wọ́n láti fi dojú ipò tẹ̀mí wa dé. Ó ṣe tán, ó gbìyànjú láti bi Jésù ṣubú, ṣé a wá rò pé ó máa fi wá lọ́rùn sílẹ̀ ni?—Mátíù 4:1-11.
Àwọn Ọgbọ́n Àrékérekè Sátánì
3. Báwo ni Sátánì ṣe gbin iyèméjì sọ́kàn Éfà?
3 Ọgbọ́n kan tí Sátánì ń lò ni pé ó máa ń gbin iyèméjì sí wa lọ́kàn. Àìlera tó wà nínú ìhámọ́ra tẹ̀mí wa ló máa ń wá kiri. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pàá, ó fi àrékérekè yẹn mú Éfà, ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” (Jẹ́nẹ́sísì 3:1) Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé, ‘Ṣé pé Ọlọ́run lè ṣe irú òfin yẹn fún yín lóòótọ́? Ṣé pé ó lè fi irú nǹkan tó dára tó báyìí dù yín? Hà, ṣebí Ọlọ́run mọ̀ pé ní ọjọ́ náà gan-an tí ẹ bá jẹ nínú igi náà ni ojú yín yóò là, pé ẹ ó sì dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú!’ Bí Sátánì ṣe gbin iyèméjì sí i lọ́kàn nìyẹn o, tó sì retí pé kí ó hù.—Jẹ́nẹ́sísì 3:5.
4. Kí làwọn iyèméjì tó lè nípa lórí àwọn kan lónìí?
4 Báwo ni Sátánì ṣe ń lo ọgbọ́n yìí lónìí? Bí a bá fọwọ́ yẹpẹrẹ mú Bíbélì kíkà wa, ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa, àdúrà wa, àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni àti àwọn ìpàdé wa, a lè sọ ara wa di ìjẹ fún iyèméjì táwọn ẹlòmíràn ń gbé dìde. Fún àpẹẹrẹ: “Báwo la ṣe mọ̀ pé òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ni nìyí?” “Ṣé ọjọ́ ìkẹyìn nìwọ̀nyí lóòótọ́? Ó ṣe tán, a ti wà ní ọ̀rúndún kọkànlélógún báyìí.” “Ṣé a ti ń sún mọ́ Amágẹ́dọ́nì ni, àbí ọ̀nà rẹ̀ ṣì jìn?” Bí irú iyèméjì bẹ́ẹ̀ bá dìde, kí la lè ṣe láti mú un kúrò?
5, 6. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe bí iyèméjì bá dìde?
5 Jákọ́bù fúnni ní ìmọ̀ràn tó ṣeé mú lò nígbà tó kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un. Ṣùgbọ́n kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá, nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dà bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì, tí a sì ń fẹ́ káàkiri. Ní ti tòótọ́, kí ẹni yẹn má rò pé òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà; ó jẹ́ aláìnípinnu, aláìdúrósójúkan ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.”—Jákọ́bù 1:5-8.
6 Kí la wá lè ṣe nígbà náà? A gbọ́dọ̀ “máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run” nínú àdúrà, pé kó fún wa ní ìgbàgbọ́ àti òye, kí ó sì bù kún ìsapá wa láti dá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìbéèrè tàbí iyèméjì èyíkéyìí. A tún lè béèrè fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tó dúró dáadáa nínú ìgbàgbọ́, ká má ṣe mikàn láé pé Jèhófà yóò fún wa ní ìtìlẹ́yìn táa nílò. Jákọ́bù tún sọ pé: “Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” Dájúdájú iyèméjì táa bá ní yóò pòórá báa ṣe ń sún mọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àdúrà.—Jákọ́bù 4:7, 8.
7, 8. Kí ni díẹ̀ lára àwọn kókó táa lè fi mọ irú ìjọsìn tí Jésù fi kọ́ni, àwọn wo ló sì kúnjú ìwọ̀n ohun táa là sílẹ̀ wọ̀nyí?
7 Ẹ wo ìbéèrè yìí fún àpẹẹrẹ: Báwo la ṣe mọ̀ pé irú ìjọsìn tí Jésù fi kọ́ni là ń ṣe? Táa bá fẹ́ dáhùn èyí, kí làwọn kókó táa gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò? Bíbélì là á mọ́lẹ̀ pé àwọn ojúlówó Kristẹni gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ tòótọ́ láàárín ara wọn. (Jòhánù 13:34, 35) Wọ́n gbọ́dọ̀ ya orúkọ Ọlọ́run, tí ń jẹ́ Jèhófà sí mímọ́. (Aísáyà 12:4, 5; Mátíù 6:9) Wọ́n sì gbọ́dọ̀ sọ orúkọ yẹn di mímọ̀.—Ẹ́kísódù 3:15; Jòhánù 17:26.
8 Nǹkan mìíràn táa fi ń dá ìjọsìn tòótọ́ mọ̀ ni ọ̀wọ̀ tó ní fún Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Òun ni ìwé aláìlẹ́gbẹ́ tó fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ hàn. (Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:16, 17) Ní àfikún sí i, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń kéde Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo tí ènìyàn ní láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Máàkù 13:10; Ìṣípayá 21:1-4) Wọ́n ń ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ìṣèlú ayé yìí tó ti dómùkẹ̀ àti ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ tó jẹ́ ẹlẹ́gbin. (Jòhánù 15:19; Jákọ́bù 1:27; 4:4) Láìsí àní-àní, àwọn wo ló kúnjú ìwọ̀n ohun tí a là sílẹ̀ wọ̀nyí lónìí? Àwọn òkodoro òtítọ́ náà fi hàn pé ọ̀kan ṣoṣo ni ìdáhùn náà—àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni.
Bí Iyèméjì Ò Bá Lọ Ńkọ́?
9, 10. Kí la lè ṣe láti borí iyèméjì tó kọ̀ tí ò lọ?
9 Báa bá rí i pé iyèméjì ti gbà wá lọ́kàn ńkọ́? Kí ló yẹ ká ṣe nígbà náà? Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba dáhùn ìbéèrè yìí, ó sọ pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ, láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀; jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá ké pe òye, tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”—Òwe 2:1-5.
10 Ǹjẹ́ èrò yẹn ò fakíki? Bí a bá múra tán láti fi tọkàntọkàn fiyè sí ọgbọ́n Ọlọ́run, a óò “rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ìmọ̀ Olúwa Ọba Aláṣẹ àgbáyé lè tẹ̀ wá lọ́wọ́ bí a bá múra tán láti gba àwọn àsọjáde rẹ̀, tí a sì fi wọ́n ṣúra. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ká máa yíjú sí Jèhófà nínú àdúrà àti nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́. Ìṣúra tí ó fara sin nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè mú iyèméjì èyíkéyìí kúrò, kí ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́.
11. Báwo ni iyèméjì ṣe nípa lórí ẹmẹ̀wà Èlíṣà?
11 Àpẹẹrẹ kan tó ṣe kedere nípa bí àdúrà ṣe ṣèrànwọ́ fún ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tó ń bẹ̀rù tó sì ń ṣiyèméjì wà nínú 2 Àwọn Ọba 6:11-18. Ẹmẹ̀wà Èlíṣà kò lè fojú tẹ̀mí wo nǹkan. Kò lè fojú inú rí i pé àwọn ogun ọ̀run wà níbẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún wòlíì Ọlọ́run, tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà sàga tì. Pẹ̀lú ìbẹ̀rù ni ìránṣẹ́ náà fi kígbe pé: “Págà, ọ̀gá mi! Kí ni àwa yóò ṣe?” Báwo ni Èlíṣà ṣe fèsì? Ó ní: “Má fòyà, nítorí àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” Àmọ́, báwo ni ìránṣẹ́ náà ṣe lè gbà pé òótọ́ ni? Kò kúkú lè rí àwọn ogun ọ̀run náà.
12. (a) Báwo la ṣe mú iyèméjì ẹmẹ̀wà náà kúrò? (b) Báwo la ṣe lè mú iyèméjì èyíkéyìí táa bá ní kúrò?
12 “Èlíṣà bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà, ó sì wí pé: ‘Jèhófà, jọ̀wọ́, là á ní ojú, kí ó lè ríran.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà la ojú ẹmẹ̀wà náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ríran; sì wò ó! ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà kún fún àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná yí Èlíṣà ká.” Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà mú kí ó ṣeé ṣe fún ẹmẹ̀wà náà láti rí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run tó ń dáàbò bo Èlíṣà. Àmọ́ o, a ò gbọ́dọ̀ retí irú ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá kan náà lóde òní. Rántí pé ẹmẹ̀wà wòlíì náà kò ní odindi Bíbélì tó lè kà láti fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun. Àwa ní Bíbélì ní tiwa. Bí a bá lò ó dáadáa, ìgbàgbọ́ wa lè di èyí táa fún lókun bákan náà. Fún àpẹẹrẹ, a lè ronú lórí àwọn àkọsílẹ̀ mélòó kan tó ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe wà nínú àgbàlá rẹ̀ ti ọ̀run. Èyí kò ní jẹ́ ká ṣiyèméjì rárá pé Jèhófà ní ètò àjọ kan ní ọ̀run, tó ń ṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe jákèjádò ayé lónìí.—Aísáyà 6:1-4; Ìsíkíẹ́lì 1:4-28; Dáníẹ́lì 7:9, 10; Ìṣípayá 4:1-11; 14:6, 7.
Ṣọ́ra fún Àwọn Ètekéte Sátánì!
13. Ọ̀nà wo ni Sátánì fi ń gbìyànjú láti sọ ọwọ́ táa fi di òtítọ́ mú di aláìlágbára?
13 Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà mìíràn tí Sátánì ń lò láti sọ ipò tẹ̀mí wa àti ọwọ́ tí a fi mú òtítọ́ di aláìlágbára? Ọ̀kan lára wọn ni ìwà pálapàla, ní gbogbo ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣe é. Nínú ayé tí ìbálòpọ̀ ń sín níwín lóde òní, ohun tí wọ́n ń pè ní ìlójúlóde (ìyẹn àdàpè ọ̀rọ̀ fún àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó) tàbí ìgbádùn ìbálòpọ̀ fún òru ọjọ́ kan péré (ìyẹn àgbèrè tí wọn ò kà sí nǹkan kan) ti wá di ohun tí ìran ènìyàn yìí, tí kò mọ nǹkan mìíràn ju fàájì ṣíṣe ti sọ di ohun tí wọ́n ń fi ojoojúmọ́ ṣe. Ọ̀nà ìgbésí ayé yìí ni sinimá, tẹlifíṣọ̀n, àti fídíò ń gbé lárugẹ. Àwọn ohun tí ń rùfẹ́ ìṣekúṣe sókè ló kún inú àwọn ohun tí iléeṣẹ́ ìròyìn ń gbé jáde, àgàgà lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Kò sí bí àwọn tó fẹ́ mọ fìn-ín ìdí kókò kò ṣe ní kó sínú ìdẹwò.—1 Tẹsalóníkà 4:3-5; Jákọ́bù 1:13-15.
14. Èé ṣe táwọn Kristẹni kan fi di ẹni ti Sátánì fi ètekéte rẹ̀ mú?
14 Àwọn Kristẹni kan ti jẹ́ kí ìfẹ́ ìtọpinpin tí wọ́n ní kó bá wọn, wọ́n sì ti sọ èrò inú àti ọkàn-àyà wọn dìbàjẹ́ nípa wíwo àwọn àwòrán arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè, ì báà jẹ́ èyí tó ń ṣàpèjúwe rẹ̀ tàbí èyí tó tiẹ̀ ń fi bí wọ́n ṣe ń ṣe é gan-an hàn pàápàá. Wọ́n ti jẹ́ kí pańpẹ́ tí Sátánì fi ń dẹni lọ mú wọn. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sábà máa ń yọrí sí ọkọ̀ rírì nípa tẹ̀mí. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti kùnà láti máa “jẹ́ ìkókó ní ti ìwà búburú.” Wọn kò tíì “dàgbà di géńdé nínú agbára òye.” (1 Kọ́ríńtì 14:20) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn lọ́dọọdún nítorí pé wọn ò pa àwọn ìlànà àti ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́. Wọ́n ti kùnà láti gbé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” wọ̀, kí wọ́n má sì bọ́ ọ kúrò.—Éfésù 6:10-13; Kólósè 3:5-10; 1 Tímótì 1:18, 19.
Ẹ Jẹ́ Kí A Mọyì Ohun Táa Ní
15. Kí ló lè mú kó ṣòro fáwọn kan láti mọyì ogún tẹ̀mí tí wọn ní?
15 Jésù sọ pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Ẹlẹ́rìí ló di dandan fún láti jáwọ́ nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì tún fi ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ sílẹ̀. Ìyẹn lè jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọyì òmìnira tí òtítọ́ ń jẹ́ kéèyàn ní. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ kan táwọn òbí tó wà nínú òtítọ́ tọ́ dàgbà lè rí i pé ó ṣòro fáwọn láti mọrírì ogún tẹ̀mí wọn. Wọn ò tíì fìgbà kan jẹ́ apá kan ìsìn èké tàbí apá kan ayé yìí tí kò mọ̀ ju fàájì ṣíṣe, ìjoògùnyó, àti ìwà pálapàla. Èyí lè wá jẹ́ kí wọ́n kùnà láti rí ìyàtọ̀ ńláǹlà tó wà láàárín párádísè tẹ̀mí wa àti ayé Sátánì tó ti dómùkẹ̀. Àwọn kan tiẹ̀ lè juwọ́ sílẹ̀ fún ìdẹwò láti tọ́ májèlé inú ayé wò kí wọ́n lè ṣe ohun tí wọn ò ráyè ṣe tẹ́lẹ̀!—1 Jòhánù 2:15-17; Ìṣípayá 18:1-5.
16. (a) Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa? (b) Kí la kọ́ wa, táa sì rọ̀ wá láti ṣe?
16 Ṣé ó dìgbà táa bá fọwọ́ jóná ká tó mọ ohun tó ń jẹ́ ìyà àti ìrora? Ṣé a ò lè fi ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹlòmíràn ṣàríkọ́gbọ́n ni? Ǹjẹ́ ó yẹ kí a kó sínú “ẹrẹ̀” ayé yìí ká tó lè mọ̀ bóyá ó ní nǹkan kan táa ti pàdánù? (2 Pétérù 2:20-22) Pétérù rán àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, tí wọ́n ti fìgbà kan jẹ́ apá kan ayé Sátánì, létí pé: “Àkókò tí ó ti kọjá lọ ti tó fún yín láti fi ṣe ìfẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè, nígbà tí ẹ ń tẹ̀ síwájú nínú àwọn ìwà àìníjàánu, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àṣejù nídìí wáìnì, àwọn àríyá aláriwo, ìfagagbága ọtí mímu, àti àwọn ìbọ̀rìṣà tí ó lòdì sí òfin.” Ní kedere, kò dìgbà táa bá kó sínú “kòtò ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀” ayé yìí ká tó mọ nǹkan tí wọ́n ń pè ní káyé èèyàn dìdàkudà. (1 Pétérù 4:3, 4) Dípò ìyẹn, a ń kọ́ wa ní àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere gíga ti Jèhófà láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, tó jẹ́ ibùdó ẹ̀kọ́ Bíbélì. A sì ń rọ̀ wá láti máa lo agbára ìmọnúúrò wa ká lè mú un dá ara wa lójú pé ọ̀dọ̀ wa ni òtítọ́ wà, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ òtítọ́ di tiwa.—Jóṣúà 1:8; Róòmù 12:1, 2; 2 Tímótì 3:14-17.
Orúkọ Wa Kì Í Ṣe Àfẹnujẹ́ Lásán
17. Báwo la ṣe lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó múná dóko?
17 Bí a bá sọ òtítọ́ di tiwa, a óò máa gbìyànjú láti sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíràn ní gbogbo ìgbà tí àyè rẹ̀ bá yọ. Èyí kò wá túmọ̀ sí pé a óò máa fagbára mú àwọn tí kò bá fìfẹ́ hàn. (Mátíù 7:6) Bẹ́ẹ̀ náà la ò sì tún ní tijú àtifi ara wa hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí a bá rí àmì pé ẹnì kan fìfẹ́ hàn nípa bíbéèrè ìbéèrè àtọkànwá tàbí nípa gbígba ìtẹ̀jáde Bíbélì kan, a óò múra tán láti bá a sọ̀rọ̀ nípa ìrètí wa. Àmọ́ o, èyí yóò túmọ̀ sí pé kí a máa ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà níbikíbi tí a bá wà—ì báà jẹ́ nínú ilé, níbi iṣẹ́, nílé ìwé, nílé ìtajà, tàbí láwọn ibí táa ti ń najú.—1 Pétérù 3:15.
18. Báwo ni fífi ara wa hàn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ṣe lè nípa tó dára nínú ìgbésí ayé wa?
18 Nígbà tí a bá fi ara wa hàn kedere gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a óò túbọ̀ lókun láti kojú àwọn ọṣẹ́ tí Sátánì ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣe. Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ọjọ́ ìbí tàbí Kérésìmesì tàbí tí wọ́n bá fẹ́ ta tẹ́tẹ́ ní ọ́fíìsì, ohun táwọn táa jọ ń ṣiṣẹ́ sábà máa ń sọ ni pé, “Ẹ fi sílẹ̀ jẹ́jẹ́ o. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni o.” Nítorí ìdí kan náà yìí, àwọn èèyàn lè máà fẹ́ dá àwọn àpárá oníwà pálapàla níbi táa bá wà. Nípa bẹ́ẹ̀, sísọ ìdúró wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni di mímọ̀ ń ní ipa tó dára nínú ìgbésí ayé wa, àní bọ́ràn náà ṣe rí gẹ́lẹ́ ni àpọ́sítélì Pétérù sọ, nígbà tó sọ pé: “Ní tòótọ́, ta ni ẹni tí yóò pa yín lára bí ẹ bá di onítara fún ohun rere? Ṣùgbọ́n àní bí ẹ bá ní láti jìyà nítorí òdodo pàápàá, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀.”—1 Pétérù 3:13, 14.
19. Báwo la ṣe mọ̀ pé a ti rìn jìnnà wọnú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?
19 Àǹfààní mìíràn tó tún wà nínú sísọ òtítọ́ di tiwa ni pé a óò ní ìdánilójú pé ní ti tòótọ́, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí nìwọ̀nyí. A ó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ń sún mọ́ òtéńté wọn lásìkò tiwa. a Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amúnigbọ̀nrìrì tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún tó kọjá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù pé, “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.” (2 Tímótì 3:1-5; Máàkù 13:3-37) Àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn kan tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa ọ̀rúndún ogún ni wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “A Óò Máa Rántí Rẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Sáà Ìwà Ẹhànnà.” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ọdún 1999 jẹ́ ọdún tí ìpànìyàn pọ̀ jù lọ ní apá kejì ọ̀rúndún tí ìpànìyàn pọ̀ jù lọ.”
20. Ìsinsìnyí ni àkókò láti gbé irú ìgbésẹ̀ wo?
20 Ìsinsìnyí kọ́ ló yẹ ká máa ṣiyèméjì. Ìbùkún Jèhófà ti fara hàn kedere nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gíga jù lọ tí a ti ń ṣe ní gbogbo àgbáyé láti ṣe ẹ̀rí fún àwọn orílẹ̀-èdè. (Mátíù 24:14) Sọ òtítọ́ di tìrẹ, kí o sì ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ìyè àìnípẹ̀kun rẹ ọjọ́ iwájú sinmi lórí ohun tóo bá ṣe nísinsìnyí. Dídẹwọ́ kò ní jẹ́ kí o rí ìbùkún Jèhófà. (Lúùkù 9:62) Dípò ìyẹn, àkókò yìí ló yẹ kí ‘o fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, kí o di aláìṣeéṣínípò, kí o máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò rẹ kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.’—1 Kọ́ríńtì 15:58.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé Ìṣọ́, January 15, 2000, ojú ìwé 12 sí 14. Ìpínrọ̀ 13 sí 18 fún wa ní àwọn ẹ̀rí mẹ́fà tí kò ṣeé já ní koro, tó ń fi hàn pé láti ọdún 1914 la ti ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo la ṣe lè mú iyèméjì kúrò?
• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ ẹmẹ̀wà Èlíṣà?
• Kí ni àwọn ìdẹwò nípa ìwà rere táa gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra fún ní gbogbo ìgbà?
• Èé ṣe táa fi gbọ́dọ̀ fara wa hàn kedere gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà gbígbà déédéé lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú iyèméjì kúrò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ìran kan ló ran ẹmẹ̀wà Èlíṣà lọ́wọ́ láti mú iyèméjì rẹ̀ kúrò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
A ń kọ́ wa ní àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere gíga ti Jèhófà ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba bí irú èyí tó wà ní Benin yìí.