Oníṣègùn Ojú Gbin Irúgbìn Kan
Oníṣègùn Ojú Gbin Irúgbìn Kan
Kí ni akitiyan ọkùnrin kan tó jẹ́ oníṣègùn ojú nílùú Lviv, lórílẹ̀-èdè Ukraine, ní í ṣe pẹ̀lú dídá ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń sọ èdè Rọ́ṣíà sílẹ̀ nílùú Haifa, ní Israel, nígbà tó jẹ́ pé ẹgbàá [2,000] kìlómítà ni ibi méjèèjì yìí fi jìnnà síra, tí àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan sì là wọ́n láàárín? Ìṣẹ̀lẹ̀ táa fẹ́ ròyìn rẹ̀ yìí fi hàn pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ nínú Oníwàásù 11:6 pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere.”
ÌTÀN ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1990 nígbà tí obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ella, tí ìrandíran rẹ̀ jẹ́ Júù, ń gbé ní Lviv. Ella àti ìdílé rẹ̀ ń múra àtiṣí lọ sí Israel. Nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n gbéra, Ella fẹ́ lọ rí oníṣègùn ojú kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn ní Ukraine. Bó tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, oníṣègùn náà lo ìdánúṣe rẹ̀ láti bá Ella sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ táa gbé ka Bíbélì. Ẹnu ya Ella
nígbà tó sọ fún un pé Ọlọ́run ní orúkọ tara rẹ̀. Ella fẹ́ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí ọ̀gbẹ́ni yìí ń sọ, bí ìjíròrò tó gbámúṣé nípa Bíbélì ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.Ìjíròrò náà wọ Ella lọ́kàn débi pé ó lóun fẹ́ káwọn tún máa bá ọ̀rọ̀ náà lọ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e àti èyí tó tún tẹ̀ lé e. Ó fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, àmọ́ ìṣòro kan wà ńbẹ̀. Àkókò tí ìdílé wọn máa ṣí lọ sí Israel ti dé tán. Bẹ́ẹ̀ rèé, Ella ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí gba ìmọ̀ ni! Kí ó lè lo gbogbo àkókò tó ṣẹ́ kù lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, ó ní kí wọ́n máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́ títí òun yóò fi lọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbàrà tí Ella dé Israel ló ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìṣó, síbẹ̀ irúgbìn òtítọ́ ti ta gbòǹgbò nínú ọkàn rẹ̀. Nígbà tí ọdún fi máa yí po, ó tún ti jára mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀.
Ogun bẹ́ ní àgbègbè táa ń pè ní Persian Gulf, orílẹ̀-èdè Iraq sì bẹ̀rẹ̀ sí ju àwọn àfọ̀njá olóró sí Israel. Ọ̀rọ̀ yìí làwọn èèyàn wá ń sọ ṣáá. Lọ́jọ́ kan nínú ọjà, Ella gbọ́ èdè Rọ́ṣíà lẹ́nu ìdílé kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ̀lú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ella alára ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ ni, ó lọ bá ìdílé náà, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìlérí Bíbélì nípa ayé àlàáfíà. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé gbogbo wọn, títí kan Galina ìyá àgbà, Natasha ìyá; Sasha (Ariel) ọmọkùnrin wọn; àti Ilana ọmọbìnrin wọn, ló bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ Ella nígbà tí wọ́n bá ń bá a kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Sasha lẹni tó kọ́kọ́ ṣe batisí nínú ìdílé yẹn—láìfi ọ̀pọ̀ àdánwò pè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé akẹ́kọ̀ọ́ tó dáńgájíá ni, wọ́n lé e kúrò nílé ìwé torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni kò gbà á láyè láti lọ́wọ́ nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ológun, èyí tí wọ́n pè ní apá kan ẹ̀kọ́ iléèwé. (Aísáyà 2:2-4) Ẹjọ́ Sasha dé iwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Israel ní Jerusalem, ó sì dùn mọ́ni pé ilé ẹjọ́ yìí pàṣẹ pé kí wọ́n gba Sasha padà kíá kí ó lè parí iléèwé rẹ̀. Ìròyìn nípa ẹjọ́ yìí tàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Èyí jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israel wá mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. a
Lẹ́yìn tí Sasha jáde ìwé mẹ́wàá, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Ní bí a ti ń wí yìí, ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe àti alàgbà nínú ìjọ. Ilana, àbúrò Sasha obìnrin, pẹ̀lú ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ìyá wọn àti ìyá wọn àgbà ti di Ẹlẹ́rìí tó ti ṣe batisí báyìí. Irúgbìn tí oníṣègùn ojú yẹn gbìn ṣì ń sèso!
Láàárín àkókò náà, Ella ń bá bó ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí nìṣó, kò sì pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láti ilé dé ilé. Lẹ́nu ilẹ̀kùn tí Ella kọ́kọ́ kàn, ó pàdé Faina tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti orílẹ̀-èdè Ukraine dé. Faina sorí kọ́. Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn ni Ella wá mọ̀ pé kété ṣáájú kóun tó kanlẹ̀kùn Faina, obìnrin tí àròdùn ọkàn bá yìí, ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run ni, tó sọ pé: “Mi ò mọ̀ ẹ́ o, àmọ́ bóo bá gbọ́ mi, ràn mí lọ́wọ́.” Ìjíròrò òun àti Ella lárinrin. Faina béèrè oríṣiríṣi ìbéèrè, ó sì fara balẹ̀ gbọ́ àwọn ìdáhùn tí a fún un. Bí àkókò ti ń lọ, ó wá dá a lójú pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ni ní òtítọ́ látinú Bíbélì. Ó ṣe ìyípadà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní yunifásítì kí ó bàa lè ní àkókò púpọ̀ sí i láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ àti nínú iṣẹ́ ìwàásù. A batisí Faina ní May 1994. Ó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, ó sì
ń fi iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ nípa ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà gbọ́ bùkátà ara rẹ̀.Ní November 1994, nígbà tí Ella wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ńṣe ló ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀ ẹ́ látinú wá. Ó lọ sí ọsibítù, àwọn àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe sì fi hàn pé egbò kan wà nínú ìfun rẹ̀ tó ń ṣẹ̀jẹ̀. Nígbà tó fi máa di alẹ́, ìwọ̀n èròjà pupa inú ẹ̀jẹ̀ Ella ti lọ sílẹ̀ gan-an, díẹ̀ ló fi lé ní ìwọ̀n méje. Alàgbà kan tó wà nínú ìjọ Ella, tí í ṣe alága Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) lágbègbè yẹn, pèsè ìsọfúnni fáwọn dókítà nípa oríṣiríṣi ọ̀nà ìṣègùn téèyàn lè lò láìgba ẹ̀jẹ̀. b Iṣẹ́ abẹ náà kẹ́sẹ járí láìlo ẹ̀jẹ̀, ara Ella sì wá le koko.—Ìṣe 15:28, 29.
Ìwúrí ńláǹlà ló jẹ́ fún Karl, oníṣègùn tó ń tọ́jú Ella, tó jẹ́ Júù táa bí sílẹ̀ Jámánì. Oníṣègùn yìí wá rántí pé àwọn òbí òun, tó la Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà já, mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Karl béèrè oríṣiríṣi ìbéèrè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ Karl máa ń dí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìṣègùn rẹ̀, ó ṣètò àkókò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Nígbà tí ọdún fi máa yí po, ó ti ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.
Kí ni ìyọrísí irúgbìn tí oníṣègùn ojú yẹn gbìn? A ti gbọ́ nípa ti Sasha àti ìdílé rẹ̀. Ní ti Ella, ó ti di aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Eina, ọmọbìnrin rẹ̀, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ìwé mẹ́wàá, ti dáwọ́ lé iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Faina pẹ̀lú ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Ní ti Karl, oníṣègùn Ella, ó ti ṣe batisí báyìí gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí, ó sì ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó ń bá àwọn tó wá gbàtọ́jú lọ́dọ̀ rẹ̀ àtàwọn míì sọ̀rọ̀ nípa agbára ìwonisàn tí òtítọ́ Bíbélì ní.
Àwùjọ kéréje àwọn aṣíwọ̀lú tí ń sọ èdè Rọ́ṣíà tó bẹ̀rẹ̀ nígbà yẹn gẹ́gẹ́ bí apá kan Ìjọ Haifa tí ń sọ èdè Hébérù, ti di ìjọ onítara tí ń sọ èdè Rọ́ṣíà báyìí, àwọn akéde Ìjọba náà tó wà nínú ìjọ yẹn sì lé ní ọgọ́fà. Ara ohun tó jẹ́ kí ìbísí yìí ṣeé ṣe ni pé oníṣègùn ojú kan nílùú Lviv lo àǹfààní kan tó ṣí sílẹ̀ láti fi gbin irúgbìn kan!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, lọ wo ìwé ìròyìn Jí!, ìtẹ̀jáde ti November 8, 1994, ojú ìwé 12 sí 15.
b Àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn ń ṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, wọ́n ń ṣèrànlọ́wọ́ kí àjọṣe àárín àwọn aláìsàn àtàwọn òṣìṣẹ́ ọsibítù lè dán mọ́rán. Wọ́n tún ń pèsè ìsọfúnni nípa àwọn ìtọ́jú míì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde lórí ìwádìí ìṣègùn.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 29]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
UKRAINE
ISRAEL
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ella àti Eina ọmọbìnrin rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ara àwùjọ aláyọ̀ ti àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń sọ èdè Rọ́ṣíà ní Haifa lẹ̀ ń wò yìí. Láti apá òsì sí ọ̀tún: Sasha, Ilana, Natasha, Galina, Faina, Ella, Eina, àti Karl