Sísìn Níbikíbi Tí A Bá Ti Nílò Mi
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Sísìn Níbikíbi Tí A Bá Ti Nílò Mi
GẸ́GẸ́ BÍ JAMES B. BERRY ṢE SỌ Ọ́
Ọdún 1939 ni. Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé ń han àwọn èèyàn léèmọ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Dùgbẹ̀dùgbẹ̀ ogun sì ń fì jákèjádò Yúróòpù. Èmi àti Bennett àbúrò mi ọkùnrin rìnrìn àjò láti ilé wa ní Ìpínlẹ̀ Mississippi lọ́ sílùú Houston, ní Ìpínlẹ̀ Texas, a ń wáṣẹ́ kiri.
LỌ́JỌ́ kan, bí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti ń kógbá sílé, a gbọ́ ìkéde amúnijígìrì kan tó dún kọ̀rọ̀kọ̀rọ̀ jáde lórí rédíò, pé: Ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hitler ti gbógun wọ Poland. Ni àbúrò mi bá figbe ta pé: “Ogun Amágẹ́dónì ti dé!” Kíá, a fiṣẹ́ sílẹ̀. A lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ń bẹ nítòsí láti lọ ṣe ìpàdé fún ìgbà àkọ́kọ́. Ó ṣe jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba la lọ? Ẹ jẹ́ kí n kúkú bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ náà látìbẹ̀rẹ̀.
Ìlú Hebron, ní Mississippi ni wọ́n ti bí mi lọ́dún 1915. Àrọko là ń gbé. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ nígbà yẹn, máa ń wá ságbègbè wa ní nǹkan bí ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, wọ́n á sì sọ àsọyé nílé ẹnì kan. Ìyẹn làwọn òbí mi fi ní ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde Bíbélì nílé. Èmi àti Bennett wá gba ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé wọ̀nyí gbọ́, a gbà pé: Hẹ́ẹ̀lì kò gbóná, ọkàn ń kú, àwọn olódodo yóò máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Ṣùgbọ́n nǹkan púpọ̀ ṣì wà tí a kò tíì mọ̀. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí mo jáde iléèwé lèmi àti àbúrò mi wáṣẹ́ lọ sí Texas.
Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, táa wá kàn sáwọn Ẹlẹ́rìí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ńṣe ni wọ́n béèrè bóyá aṣáájú ọ̀nà ni wá. Àwa ò kúkú mọ̀ pé òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ń pè ní aṣáájú ọ̀nà. Wọ́n bi wá léèrè bóyá a fẹ́ máa wàásù. A dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni o!” Èrò wa ni pé wọ́n á sọ pé kí àwa àti ẹnì kan jọ lọ, kí ó lè fi bí wọ́n ṣe ń ṣe é hàn wá. Dípò ìyẹn, àwòrán ìpínlẹ̀ kan ni wọ́n fi
lé wa lọ́wọ́, tí wọ́n sọ fún wa pé, “Ẹ lọ ṣiṣẹ́ ńbẹ̀!” Hà, èmi àti Bennett ò mọ nǹkan kan nípa iṣẹ́ ìwàásù, a ò sì fẹ́ nǹkan kan tó máa sọ wá dẹni yẹ̀yẹ́. Ńṣe la kàn sọ àwòrán ìpínlẹ̀ ọ̀hún sínú àpótí ìfìwéránṣẹ́, kí wọ́n bá wa fi ránṣẹ́ padà sí ìjọ, báa ṣe padà sí Mississippi nìyẹn!Sísọ Òtítọ́ Bíbélì Di Tiwa
Lẹ́yìn táa padà sílé, ojoojúmọ́ la ń ka ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí fún nǹkan bí ọdún kan. Kò sí iná mànàmáná nílé wa, nítorí náà iná ààrò la fi ń kàwé lóru. Láyé ọjọ́un, àwọn ìránṣẹ́ àyíká, ìyẹn àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, máa ń bẹ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní àdádó wò, láti fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ náà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ted Klein, wá bẹ ìjọ wa wò, ó sì bá èmi àti Bennett jáde nínú iṣẹ́ ìwàásù àtilé-délé, ó máa ń mú àwa méjèèjì jáde lẹ́ẹ̀kan náà. Ó ṣàlàyé ohun tí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà jẹ́ fún wa.
Bí a ṣe jọ rìn yẹn jẹ́ ká ronú gan-an nípa ṣíṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Nítorí náà, ní April 18, 1940, Arákùnrin Klein batisí èmi àti Bennett àti Velva àbúrò wa obìnrin. Àwọn òbí wa wà níbẹ̀ nígbà táa ṣe batisí, ìpinnu wa sì múnú wọn dùn. Àwọn pẹ̀lú ṣe batisí ní nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn náà. Àwọn méjèèjì ṣe olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí dọjọ́ ikú wọn—bàbá mi kú ní 1956, màmá mi sì kú ní 1975.
Nígbà tí Arákùnrin Klein bi mí bóyá màá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà, mo sọ fún un pé ó wù mí, ṣùgbọ́n mi ò lówó lọ́wọ́, mi ò láṣọ, mi ò ní nǹkan kan. Ó wá dáhùn pé: “Kékeré nìyẹn, màá wá nǹkan ṣe sí i.” Ó sì wá nǹkan ṣe sí i lóòótọ́. Ó kọ́kọ́ fi fọ́ọ̀mù iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi ránṣẹ́ ná. Ó wá ní ká jọ lọ sílùú New Orleans, tó jẹ́ nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà sí wa, ó sì fi àwọn yàrá kan tó dáa hàn mí lókè Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Àwọn aṣáájú ọ̀nà ni wọ́n kọ́ wọn fún. Kò pẹ́ rárá tí mo fi kó lọ síbẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi. Àwọn Ẹlẹ́rìí ní New Orleans ṣèrànwọ́ nípa fífún àwa aṣáájú ọ̀nà láṣọ, owó, àti oúnjẹ. Lọ́sàn-án, àwọn ará á kó oúnjẹ wá sẹ́nu ọ̀nà wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ bá wa kó o sínú fìríìjì. Arákùnrin kan tó ní ilé àrójẹ nítòsí sọ pé tó bá ti ń di àkókò àtiṣíwọ́ ká máa wá kó oúnjẹ òòjọ́—bí ẹran, búrẹ́dì, ọbẹ̀ ẹran lílọ̀, àtàwọn ìpápánu eléròjà nínú—tí wọ́n bá tà kù lọ́jọ́ yẹn.
Àwọn Jàǹdùkú Gbéjà Kò Wá
Lẹ́yìn sáà kan, wọ́n ní kí n lọ máa ṣe aṣáájú ọ̀nà nílùú Jackson, Mississippi. Àwọn jàǹdùkú gbéjà ko èmi àti ọ̀dọ́kùnrin táa jọ ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó sì jọ pé ẹ̀yìn àwọn jàǹdùkú wọ̀nyẹn làwọn agbófinró àdúgbò yẹn wà! Bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn tún rí níbi tí wọ́n yàn fún wa tẹ̀ lé e—ìyẹn ìlú Columbus, Mississippi. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè là ń wàásù fún, àwọn aláwọ̀ funfun kan ò fẹ́ rí wa sójú. Ojú ọlọ̀tẹ̀ síjọba làwọn kan tiẹ̀ fi ń wò wá. Lára wọn ni ọ̀gá Ẹgbẹ́ Àwọn Ajagunfẹ̀yìntì Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, èyí jẹ́ ẹgbẹ́ kan tó gba ìfẹ́ orílẹ̀-èdè kanrí. Kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀mejì ni ọ̀gá ẹgbẹ́ yìí dẹ àwọn ẹhànnà jàǹdùkú sí wa.
Ìgbà àkọ́kọ́ táa rí pupa ojú àwọn agánnigàn ẹ̀dá wọ̀nyí ní Columbus ni ìgbà kan tí wọ́n gbá tẹ̀ lé wa, báa ṣe ń fi ìwé ìròyìn lọni lójú pópó. Wọ́n tì wá lọ sídìí fèrèsé onígíláàsì ní ilé ìtajà kan. Èrò sì pé jọ síbẹ̀ láti wá wòran. Kò pẹ́ ni ọlọ́pàá dé, tí wọ́n sì kó wa lọ sílé ẹjọ́. Àwọn jàǹdùkú yìí bá wa dé ilé ẹjọ́ kẹlẹlẹ, wọ́n sì kéde
níṣojú gbogbo àwọn agbófinró tó wà níbẹ̀ pé táa bá jáde nílùú lọ́jọ́ báyìí-báyìí, a lè faraare lọ. Àmọ́ tó bá jẹ́ lẹ́yìn ọjọ́ yẹn la ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ lọ, a ò ní faraare lọ o! A rí i pé ohun tó máa dára jù ni pé ká ṣì fi ìlú sílẹ̀ fún sáà kan. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, a padà dé, a sì ń bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ.Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn làwọn jàǹdùkú mẹ́jọ tún dà bò wá, wọ́n sì fipá mú wa wọ ọkọ̀ méjèèjì tí wọ́n gbé wá. Wọ́n wà wá lọ sínú igbó kan, wọ́n bọ́ṣọ lára wa, wọ́n sì fi bẹ́líìtì mi na ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ní ọgbọ̀n ẹgba! Ìbọn àti okùn pàápàá ń bẹ lọ́wọ́ wọn. Kí n sòótọ́, ẹ̀rù bà wá. Mo rò pé ńṣe ni wọ́n máa dì wá tọwọ́tẹsẹ̀, tí wọ́n á sọ wá sínú odò. Wọ́n ya àwọn ìwé wa wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, wọ́n sì fọ́n wọn ká, wọ́n tiẹ̀ wó ẹ̀rọ giramafóònù wa mọ́gi, ńṣe ló fọ́ yángá.
Ìgbà tí wọ́n nà wá tán, wọ́n ní ká gbé ẹ̀wù wa wọ̀, ká sì máa tọ ọ̀nà kan nínú igbó lọ láìwẹ̀yìn. Báa ti ń lọ, ẹ̀rù ń bà wá pé táa bá ṣèèṣì wẹ̀yìn, ńṣe ni wọ́n máa yìnbọn pa wá—kò sì sóhun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ jáde! Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, a gbọ́ tí wọ́n wa mọ́tò wọn lọ.
Ìgbà kan tún wà táwọn ẹhànnà jàǹdùkú kan lé wa bàràbàrà, nígbà tí a kò mọ ohun táa lè ṣe, la bá so aṣọ wa mọ́rùn, a sì wẹ odò kan já kí ọwọ́ wọn má bàa tẹ̀ wá. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn ìyẹn làwọn ọlọ́pàá mú wa lórí ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ mọ́ ìjọba. Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta la fi wà látìmọ́lé kí wọ́n tó ṣẹjọ́ wa. Wọ́n kéde ọ̀ràn yìí ní gbogbo ìlú Columbus. Wọ́n tiẹ̀ yọ̀ǹda kí àwọn ọmọ yunifásítì tó wà nítòsí tètè ṣíwọ́ níléèwé kí wọ́n lè wá wòran. Nígbà tọ́jọ́ kò, ńṣe ni ilé ẹjọ́ kún fọ́fọ́—ibi tí ìjókòó ò sí nìkan làwọn èrò ò kún! Oníwàásù méjì àti olórí ìlú àti ọlọ́pàá wà lára àwọn tí Ìjọba pè láti wá jẹ́rìí.
Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ lọ́yà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ G. C. Clarke àti alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ ni wọ́n rán wá pé kí wọ́n wá ṣojú wa. Wọ́n rọ ilé ẹjọ́ pé kí ó fagi lé ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ mọ́ ìjọba, torí pé kò sí ẹ̀rí kankan. Lọ́yà tó ń bá Arákùnrin Clarke ṣiṣẹ́ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n ó ṣe bẹbẹ lọ́jọ́ náà, ẹjọ́ tó rò fakíki. Nígbà tó rojọ́ débì kan, ó sọ fún adájọ́ pé, “Àwọn èèyàn ń sọ pé ayírí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ayírí ni wọ́n, àbí? Ṣebí bí wọ́n ṣe pe Thomas Edison ní ayírí nìyẹn!” Ó wá nàka sí iná tó wà ní títàn, ó ní, “Ṣùgbọ́n gílóòbù iná rèé!” Àwọn kan lè sọ pé ayírí ni Edison, tó hùmọ̀ gílóòbù iná mànàmáná, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè sẹ́ àwọn ohun tó ṣe.
Lẹ́yìn tí adájọ́ tó jẹ́ alága ilé ẹjọ́ náà gbọ́ ẹjọ́ tán, ó yíjú sí olùpẹ̀jọ́, ó ní: “O ò ní ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé wọ́n jẹ̀bi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ mọ́ ìjọba. Wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ yìí. Láìjẹ́ pé o ní ẹ̀rí, o ò gbọ́dọ̀ kó wọn wá sílé ẹjọ́ yìí mọ́ o. Kì í ṣe kóo wá máa fi ọ̀ràn wọn fàkókò Ìjọba àti owó Ìjọba àti àkókò tèmi náà ṣòfò!” Bí wọ́n ṣe dá wa láre nìyẹn o!
Àmọ́ lẹ́yìn náà, adájọ́ pè wá sí ìyẹ̀wù rẹ̀. Ó mọ̀ pé inú gbogbo ìlú ò dùn sí ẹjọ́ tóun dá. Nítorí náà, ó kìlọ̀ fún wa pé: “Ohun tí òfin wí ni mo sọ yẹn, ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn tí màá gba ẹ̀yin méjèèjì ni pé: Ẹ kúrò níbí, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ wọ́n á pa yín o!” A mọ̀ pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ló sọ, nítorí náà a jáde nílùú.
Ìgbà tí mo kúrò níbẹ̀ ni mo wá sọ́dọ̀ Bennett àti Velva, níbi tí wọ́n ti ń sìn nílùú Clarksville, Tennessee, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, wọ́n yàn wá sílùú Paris, ní Ìpínlẹ̀ Kentucky.
Ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn náà, báa ṣe ń múra àtidá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀, lèmi àti Bennett rí ìkésíni àrà ọ̀tọ̀ kan gbà.Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Yá
Nígbà táa rí ìkésíni láti wá sí kíláàsì kejì ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, ohun táa rò ni pé, ‘Wọ́n ṣàṣìṣe ni! Èé ṣe tí wọ́n á fi ké sí àwọn ọmọdékùnrin méjì tí ò dákan mọ̀ láti Mississippi sílé ẹ̀kọ́ yẹn?’ Èrò wa tẹ́lẹ̀ ni pé ọ̀mọ̀wé ni wọ́n fẹ́, ṣùgbọ́n a sáà lọ ṣá. Ọgọ́rùn-ún làwa akẹ́kọ̀ọ́ táa wà ní kíláàsì náà, ẹ̀kọ́ náà sì gba oṣù márùn-ún gbáko. January 31, 1944, lọjọ́ ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege, a sì ń hára gàgà láti lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè. Àmọ́ láyé ọjọ́un, àtirí ìwé àṣẹ ìrìn àjò àti ìwé àṣẹ wíwọ orílẹ̀-èdè mìí gbà kì í yá, fún ìdí yìí wọ́n ṣètò káwọn akẹ́kọ̀ọ́ sìn fúngbà díẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn táa ṣe aṣáájú ọ̀nà fún sáà kan ní Alabama àti Georgia ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yanṣẹ́ fún èmi àti Bennett—wọ́n rán wa lọ sórílẹ̀-èdè Barbados, ní West Indies.
Ogun Àgbáyé Kejì ṣì ń jà lọ́wọ́, wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ àti ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ibi púpọ̀, títí kan Barbados. Nígbà táa dé ibodè wọn, àwọn aláṣẹ tú ẹrù wa wò, wọ́n sì rí àwọn ìwé táa kó pa mọ́ sínú rẹ̀. A sọ lọ́kàn ara wa pé, ‘Ọwọ́ ti bà wá.’ Ṣùgbọ́n ṣe ni ọ̀kan lára wọn kàn sọ fún wa pé: “Ẹ máà bínú pé a tú ẹrù yín; ẹrù òfin làwọn kan lára ìwé wọ̀nyí jẹ́ ní Barbados.” Síbẹ̀, ó jẹ́ ká kó gbogbo ìwé táa dì sínú ẹrù wa wọlé! Nígbà tó yá, táa wá ń jẹ́rìí fáwọn aláṣẹ ìjọba, wọ́n sọ pé àwọn ò mọ̀dí tí wọ́n fi fòfin de ìwé wọ̀nyí. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, wọ́n mú ìfòfindè náà kúrò.
Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kẹ́sẹ járí gan-an ní Barbados. Ó kéré tán ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ló sì tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. A láyọ̀ láti rí àwọn kan nínú wọn tí ń wá sí ìpàdé ìjọ. Àmọ́ o, nítorí pé wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìwé wa fún sáà kan, àwọn ará níbẹ̀ kò ní òye ti lọ́wọ́lọ́wọ́ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa darí ìpàdé. Kò pẹ́ ṣá, táa fi fún àwọn arákùnrin mélòó kan tó tóótun ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Ó jẹ́ ayọ̀ wa láti ran ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, inú wa sì dùn bí a ti rí i tí ìjọ ń gbèrú.
Mo Di Onídìílé
Lẹ́yìn táa ti lo nǹkan bí ọdún kan ààbọ̀ ní Barbados, ó di dandan fún mi láti ṣe iṣẹ́ abẹ, mo wá padà sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tí mo wà níbẹ̀ ni mo gbé Ẹlẹ́rìí kan táa ti jọ ń kọ̀wé síra, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dorothy níyàwó. Èmi àtìyàwó mi wá ń ṣe aṣáájú ọ̀nà nílùú Tallahassee, ní Florida. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn oṣù mẹ́fà a ṣí lọ sílùú Louisville, Kentucky, níbi tí Ẹlẹ́rìí kan ti ríṣẹ́ fún mi. Bennett àbúrò mi ń bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nìṣó ní Barbados fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Nígbà tó ṣe, ó fẹ́ míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan, ó sì ń ṣe iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ní àwọn erékùṣù wọ̀nyẹn. Nígbà tó tún yá, ó di dandan fún wọn láti padà sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nítorí ọ̀ràn ìlera.
Wọ́n ń bá iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò nìṣó, wọ́n sì ń bẹ àwọn ìjọ tí ń sọ èdè Spanish wò títí di ọjọ́ ikú Bennett ní 1990, lẹ́ni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin.Ọdún 1950 ni Dorothy bí àkọ́bí wa, obìnrin ni, a sì sọ ọ́ ní Daryl. Márùn-ún ni gbogbo ọmọ táa wá bí. Derrick, ọmọ wa kejì, kú lọ́mọ ọdún méjì ààbọ̀ péré nígbà tí àrùn lọ́rùnlọ́rùn kọlù ú. Ṣùgbọ́n a bí Leslie ní 1956, Everett sì tẹ̀ lé e ní 1958. Èmi àti Dorothy sapá láti tọ́ àwọn ọmọ wa ní ọ̀nà òtítọ́ Bíbélì. A máa ń gbìyànjú láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a sì máa ń ṣe é lọ́nà tí gbogbo àwọn ọmọ wa yóò fi gbádùn rẹ̀. Nígbà tí Darly, Leslie, àti Everett ṣì kéré, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la máa ń fún wọn ní àwọn ìbéèrè tí wọ́n máa ṣèwádìí lé lórí, tí wọ́n á sì dáhùn lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Wọ́n tún ń fi ìwàásù láti ilé dé ilé dánra wò. Ọ̀kan lára wọn á lọ sínú yàrá kékeré táa ń kó aṣọ sí, á sì ṣe bí onílé. Èkejì á dúró síta, á máa kanlẹ̀kùn. Wọ́n á máa fi ọ̀rọ̀ tí ń dẹ́rìn-ín pani gbé àtakò dìde síra wọn, èyí sì jẹ́ kí wọ́n fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù. Àwa pẹ̀lú wọn tún máa ń jáde lọ wàásù déédéé.
Nígbà táa bí Elton, ọmọkùnrin wa àbígbẹ̀yìn ní 1973, Dorothy ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni àádọ́ta ọdún nígbà yẹn, èmi náà sì ti ń sún mọ́ ẹni ọgọ́ta ọdún. Ìyẹn ni wọ́n fi ń pè wá ní Ábúráhámù àti Sárà nínú ìjọ! (Jẹ́nẹ́sísì 17:15-17) Àwọn ẹ̀gbọ́n Elton máa ń gbé e dání nígbà tí wọ́n bá ń jáde òde ẹ̀rí. A ronú pé yóò jẹ́ ẹ̀rí ńláǹlà fún àwọn èèyàn tí wọ́n bá rí odindi ìdílé—tẹ̀gbọ́n tàbúrò, tòbí tọ́mọ—tí wọ́n jùmọ̀ ń sọ òtítọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn. Àgbégbà làwọn ẹ̀gbọ́n Elton ọkùnrin máa ń gbé e léjìká, wọ́n sì máa ń fi ìwé àṣàrò kúkúrú Bíbélì lé e lọ́wọ́. Ṣàṣà làwọn tí kì í fẹ́ gbọ́ nígbà tí wọ́n bá ṣílẹ̀kùn, tí wọ́n rí ọmọ kékeré tí ojú rẹ̀ gún régé léjìká ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin wa kọ́ Elton bí yóò ṣe fi ìwé àṣàrò kúkúrú lé onílé lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá parí ọ̀rọ̀, kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ díẹ̀. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí wàásù nìyẹn.
Ó ti ṣeé ṣe fún wa láti ọdún wọ̀nyí wá láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà. Nǹkan bí ọdún 1976 sí 1979 la ṣí kúrò nílùú Lousville lọ sí Shelbyville, ní Ìpínlẹ̀ Kentucky, láti lọ sìn nínú ìjọ kan tí àìní wà. Nígbà táa wà níbẹ̀, kì í ṣe kìkì pé ìjọ náà ní ìbísí nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún rí ilẹ̀, wọ́n sì kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Lẹ́yìn náà ni wọ́n ní ká lọ sìn nínú ìjọ kan tí kò jìnnà síbẹ̀.
Àìdánilójú Ipò Ìdílé
Ohun tí ì bá wù mí láti sọ ni pé gbogbo ọmọ wa ló ń tọ ọ̀nà Jèhófà, àmọ́ ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí wọ́n dàgbà tán, tí wọ́n fi ilé sílẹ̀, mẹ́ta lára àwọn ọmọ wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó ṣẹ́ kù fi ọ̀nà òtítọ́ sílẹ̀. Àmọ́ Everett ọmọ wa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ mi, ó sì di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Nígbà tó yá, ó sìn ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New York, nígbà tó sì di ọdún 1984, wọ́n ké sí i wá sí kíláàsì kẹtàdínlọ́gọ́rin ti Gilead. Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege, ó lọ síbi táa yàn án sí ní Sierra Leone, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Ní 1988, ó fẹ́ Marianne, tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà láti Belgium. Látìgbà yẹn ni wọ́n ti ń sìn pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì.
Gẹ́gẹ́ bí yóò ti rí lára òbí èyíkéyìí, ọkàn wa gbọgbẹ́ nígbà tí mẹ́ta lára àwọn ọmọ wa fi ọ̀nà ìyè sílẹ̀, ọ̀nà tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ nísinsìnyí, tó sì ń fúnni ní àgbàyanu ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Mo máa ń dẹ́bi fún ara mi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n ohun tí mo fi ń tu ara mi nínú ni pé àwọn kan lára ẹ̀dá ẹ̀mí ọmọ Jèhófà, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì, sáà fi ìjọsìn rẹ̀ sílẹ̀—bó tiẹ̀ jẹ́ pé pẹ̀lú ìfẹ́ àti inú rere ni Jèhófà fi ń tọ́ni sọ́nà, láìṣe àṣìṣe kankan. (Diutarónómì 32:4; Jòhánù 8:44; Ìṣípayá 12:4, 9) Èyí tẹ̀ ẹ́ mọ́ mi lọ́kàn pé bó ti wù káwọn òbí gbìyànjú tó láti tọ́ àwọn ọmọ wọn ní ọ̀nà Jèhófà, pẹ̀lú ìyẹn náà, àwọn kan ṣì lè kọ̀ láti gba òtítọ́.
Gẹ́gẹ́ bí igi tí ẹ̀fúùfù ń fì sọ́tùn-ún sósì, ó ti di dandan fún wa láti máa bá onírúurú ìṣòro àti ìnira yí. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, mo ti rí i pé kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé àti lílọ sípàdé déédéé ló fún mi lókun láti máa bá ìṣòro wọ̀nyí yí, kí n sì là á já nípa tẹ̀mí. Bí mo ti ń dàgbà sí i, tí mo ń rántí àwọn àṣìṣe tí mo ṣe sẹ́yìn, mo tún máa Jákọ́bù 1:2, 3.
ń gbìyànjú láti rántí pé Ọlọ́run kò ṣàìfi àyè ọpẹ́ sílẹ̀. Ṣebí táa bá ń bá ìṣòtítọ́ wa nìṣó, irú ìrírí bẹ́ẹ̀ á tún fi kún ìdàgbàsókè wa nípa tẹ̀mí ni. Báa bá fi nǹkan wọ̀nyí ṣe àríkọ́gbọ́n, àwọn ìrírí tí kò bára dé nínú ìgbésí ayé lè wá ṣàǹfààní lọ́nà kan ṣá.—Lọ́wọ́ tí èmi àti Dorothy wà báyìí, ara ò fi bẹ́ẹ̀ le mọ́, agbára wa ò sì gbé gbogbo ohun tí ì bá wù wá láti máa ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà mọ́. Ṣùgbọ́n a mọrírì ìtìlẹyìn àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìpàdé làwọn ará ti ń sọ fún wa pé inú àwọn dùn gan-an láti rí wa. Wọ́n sì ń sa gbogbo ipá wọn láti ràn wá lọ́wọ́—títí kan títún ilé àti ọkọ̀ wa ṣe.
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń tiraka láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, a sì ń bá àwọn olùfìfẹ́hàn ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Ńṣe ni ìdùnnú sì máa ń ṣubú lu ayọ̀ nígbàkigbà táa bá gbúròó ọmọ wa tí ń sìn ní Áfíríkà. A ò sì tíì dẹ́kun ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa méjì nìkan ló kù sẹ́nu ẹ̀. Inú wa dùn pé a ti lo gbogbo ọdún wọ̀nyí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó kúkú ti fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé òun ò ní ‘gbàgbé iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ tí a fi hàn fún orúkọ òun.’—Hébérù 6:10.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi, Velva, àti Bennett, nígbà tí Ted Klein ń batisí wa ní April 18, 1940
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti Dorothy aya mi ní apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940 àti ní 1997
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Pípolongo àsọyé náà, “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” fún àwọn èèyàn láti ara ọkọ̀ akérò ní Barbados
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Bennett àbúrò mi nìyí níwájú ilé àwọn míṣọ́nnárì