Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú—Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Fẹ́ Láti Mọ̀ Nípa Wọn?

Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú—Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Fẹ́ Láti Mọ̀ Nípa Wọn?

Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú—Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Fẹ́ Láti Mọ̀ Nípa Wọn?

Kó tó di pé wọ́n ṣàwárí àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, ìwé àfọwọ́kọ tó lọ́jọ́ lórí jù lọ lára Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni àwọn táa kọ ní nǹkan bí ọ̀rúndún kẹsàn-án sí ìkẹwàá Sànmánì Tiwa. Ǹjẹ́ ní ti tòótọ́ ni àwọn ìwé àfọwọ́kọ wọ̀nyí ṣeé fọkàn tán pé wọ́n jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a ta ní àtaré sí wa láìlábùlà, nígbà tó jẹ́ pé wọ́n ti kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tán ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú àkókò yẹn? Ọ̀jọ̀gbọ́n Julio Trebolle Barrera, tó jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ àwọn olóòtú tó ń bójú tó àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, sọ pé: “Àkájọ Ìwé Aísáyà [láti Qumran] fúnni ní ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí àwọn adàwékọ Júù fi ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún dà kọ, bá ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu wẹ́kú, ó sì jẹ́ ohun tí wọ́n fi tìṣọ́ratìṣọ́ra ṣe.”

ODINDI ìwé Aísáyà ló wà nínú àkájọ ìwé tí Barrera ń tọ́ka sí. Ní báyìí, lára iye tó lé ní igba [200] àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ tí wọ́n rí ní Qumran, wọ́n ti rí àwọn apá kan nínú gbogbo ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ìwé Ẹ́sítérì nìkan ni wọn ò rí. Ó yàtọ̀ sí Àkájọ Ìwé Aísáyà, ní ti pé ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló jẹ́ kìkì àjákù, ohun tí wọ́n rí ṣà jọ kò sì tó ìdámẹ́wàá ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwé wọ̀nyí. Àwọn ìwé inú Bíbélì tó wọ́pọ̀ jù lọ ní Qumran ni Sáàmù (ẹ̀dà mẹ́rìndínlógójì), Diutarónómì (ẹ̀dà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n), àti Aísáyà (ẹ̀dà mọ́kànlélógún). Àwọn ìwé wọ̀nyí la sì sábà máa ń ṣàyọlò wọn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àkájọ ìwé wọ̀nyí fi hàn pé Bíbélì kò tíì yí padà ní ti gidi, wọ́n tún fi hàn pé dé àyè kan, onírúurú ìtumọ̀ Bíbélì Lédè Hébérù làwọn Júù lò ní àkókò Tẹ́ńpìlì Kejì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan sì yàtọ̀ sí èkejì. Kì í ṣe gbogbo àkájọ ìwé náà ni ọ̀nà ìkọ̀wé tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ̀ bá ti ìwé àwọn Masorete mu. Àwọn kan bá ìtumọ̀ ti Septuagint lédè Gíríìkì mu. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ rò pé àwọn ìyàtọ̀ ẹ̀dà ti Septuagint ló ní láti fa àṣìṣe tàbí ohun tí àwọn olùtumọ̀ mọ̀ọ́mọ̀ hùmọ̀ rẹ̀ pàápàá. Nísinsìnyí, àwọn àkájọ ìwé náà wá fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ìyàtọ̀ wọ̀nyí ló jẹ́ pé bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣe ń yí padà ló fà wọ́n ní ti gidi. Èyí lè jẹ́ ká lóye ìdí tó fi jẹ́ pé nínú àwọn ibì kan tí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ti ṣàyọlò àwọn ọ̀rọ̀ kan látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ tó yàtọ̀ sí ẹ̀dà ti àwọn Masorete.— Ẹ́kísódù 1:5; Ìṣe 7:14.

Nípa bẹ́ẹ̀, ohun ìṣúra inú àwọn àkájọ ìwé Bíbélì àti àwọn àjákù yìí pèsè ìpìlẹ̀ títayọ lọ́lá fún kíkẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe ta àtaré ọ̀rọ̀ inú Bíbélì Lédè Hébérù. Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ti jẹ́ ká mọ bí Septuagint àti ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ti àwọn ará Samáríà, ṣe níye lórí tó fún fífi ọ̀rọ̀ wéra. Wọ́n jẹ́ orísun àfikún ìsọfúnni fún àwọn olùtumọ̀ Bíbélì láti ronú nípa àtúnṣe èyíkéyìí tí wọ́n bá lè ṣe sí ẹ̀dà ti àwọn Masorete. Nínú àwọn ọ̀ràn bíi mélòó kan, wọ́n fìdí àwọn ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun ṣe múlẹ̀ pé kí wọ́n dá orúkọ Jèhófà padà sí àwọn ibi tí wọ́n ti yọ ọ́ kúrò nínú ẹ̀dà ti àwọn Masorete.

Bí àwọn àkájọ ìwé náà ṣe ṣàpèjúwe àwọn ìlànà àti ìgbàgbọ́ àwọn ẹ̀ya ìsìn Qumran fi hàn kedere pé kì í ṣe oríṣi ìsìn àwọn Júù kan ṣoṣo ló wà ní àkókò Jésù. Àwọn ẹ̀ya ìsìn Qumran ní àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tó yàtọ̀ sí ti àwọn Farisí àtàwọn Sadusí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ìyàtọ̀ wọ̀nyí ló fà á tí ẹ̀ya ìsìn yìí fi kóra wọn lọ sínú aginjù. Wọ́n fi àṣìṣe gbà pé àwọn ni ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 40:3 ṣẹ sí lára, èyí tó sọ nípa ohùn kan tó ń ké ní aginjù, tí ń mú kí ọ̀nà Jèhófà di títọ́. Àwọn bíi mélòó kan lára àwọn àjákù yẹn ló tọ́ka sí Mèsáyà náà, ẹni tí àwọn òǹṣèwé náà rí i pe dídé rẹ̀ ti sún mọ́lé. A nífẹ̀ẹ́ gidigidi láti mọ̀ nípa èyí nítorí pé Lúùkù sọ pé “àwọn ènìyàn náà ti ń fojú sọ́nà” fún dídé Mèsáyà.—Lúùkù 3:15.

Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú náà ràn wá lọ́wọ́ dé àyè kan láti lóye bí ìgbésí ayé àwọn Júù ṣe rí ní ayé ìgbà tí Jésù wàásù. Wọ́n fúnni ní àwọn ìsọfúnni tó ṣeé fi wéra nígbà táa bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Hébérù ìgbàanì àti ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú náà ṣì ń fẹ́ àyẹ̀wò síwájú sí i. Nítorí náà, a ṣì lè jèrè ìjìnlẹ̀ òye tuntun sí i. Dájúdájú, ohun gíga lọ́lá jù lọ tí àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí ní ọ̀rúndún ogún ṣì ń bá a lọ láti ru àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́kàn sókè bí a ti ń tẹ̀ síwájú nínú ọ̀rúndún kọkànlélógún.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn ohun tí wọ́n hú jáde ní Qumran: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.; ìwé àfọwọ́kọ: Lọ́lá àṣẹ Shrine of the Book, Israel Museum, Jerusalem