Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ojú wo ló yẹ́ káwọn Kristẹni tòótọ́ máa fi wo àṣà wíwọ́pọ̀ ti kí àwọn èèyàn máa fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀dà àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́ (software programs for computers) tí wọ́n ṣe fún títà?
Àwọn kan lè máa wá àwíjàre nípa àṣà yìí kí wọ́n sì fi àṣìṣe tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” Ó dájú pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ fífún àwọn ẹlòmíràn ní àwọn ẹ̀dà ìwé tó ní ẹ̀tọ́ oníǹkan tàbí fífúnni ní ẹ̀dà àwọn àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́ ni Jésù ń tọ́ka sí, àwọn ohun tó jẹ́ pé òfin ló ń darí lílò wọn. Fífúnni tó ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tó ń lọ sí onírúurú ìlú àti ìgbèríko pé kí wọ́n wàásù Ìjọba náà, kí wọ́n mú àwọn aláìsàn lára dá, kí wọ́n Mátíù 10:7, 8.
sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Dípò táwọn àpọ́sítélì náà yóò fi gba owó fún nǹkan yìí, “ọ̀fẹ́ ni” wọ́n ní láti fi “fúnni.”—Pẹ̀lú bí kọ̀ǹpútà aládàáni àti tilé iṣẹ́ ti túbọ̀ ń yamùrá sí i, àwọn tó nílò àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́ ń pọ̀ sí i ni. Títà ni wọ́n sábà máa ń ta àkójọ ìlànà wọ̀nyí. Lóòótọ́, àwọn èèyàn kan wà tó jẹ́ pé fúnra wọn ni wọ́n kọ àkójọ ìlànà wọ̀nyí, tí wọ́n gbà káwọn èèyàn máa lò ó láìsan kọ́bọ̀, tí wọ́n sì sọ pé àwọn èèyàn lè dà wọ́n kọ kí wọ́n sì tún fún àwọn mìíràn. Àmọ́, títà ni wọ́n máa ń ta èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́ ọ̀hún. Ńṣe la sì retí pé káwọn tó ń lo àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́ rà á, kí wọ́n sì sanwó rẹ̀, ì báà jẹ́ ilé ni wọ́n ti fẹ́ lò ó tàbí níbi iṣẹ́. Tẹ́nì kan bá lọ mú tàbí tó da àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́ kan kọ láìsanwó, á jẹ́ pé olúwarẹ̀ ti lùfin, kò sì yàtọ̀ sí kéèyàn lọ ṣe ọ̀pọ̀ yanturu ẹ̀dà àwọn ìwé, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé èèyàn fi wọ́n tọrẹ ni.
Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́ (títí kan àwọn eré orí kọ̀ǹpútà) ló ń béèrè pé kéèyàn ní ìwé àṣẹ kó tó lè lò wọ́n, tí wọn yóò béèrè pé kí ẹni tó rà á tàbí tó fẹ́ lò ó ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà inú rẹ̀ kí wọ́n má sì kọjá àṣẹ tí wọ́n fún wọn. Ọ̀pọ̀ irú àwọn ìwé àṣẹ bẹ́ẹ̀ ló máa ń sọ pé ẹnì kan péré ló lè ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, tó sì lè lò ó—inú kọ̀ǹpútà kan ni wọ́n sábà máa ń fi sí, ì báà jẹ́ kọ̀ǹpútà inú ilé tàbí ọ̀kan tó wà níbi iṣẹ́ tàbí ní iléèwé. Àwọn ìwé àṣẹ kan sọ pé ẹni tó ń lò ó lè ní ẹ̀dà kan nípamọ́ fún ara rẹ̀, àmọ́ kò gbọ́dọ̀ ṣe ẹ̀dà rẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn. Tẹ́ni tó rà á bá fẹ́ fi gbogbo àkójọ ìlànà náà (títí kan ìwé àṣẹ àti ìwé tó bá a wá) tọrẹ, ó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ o, òun kò tún ní ẹ̀tọ́ láti lò ó mọ́ nìyẹn. Onírúurú ìwé àṣẹ ló wà, ìdí nìyẹn tẹ́ni tó fẹ́ ra àkójọ ìlànà kan tàbí tí wọ́n fẹ́ fún ní ọ̀kan ṣe gbọ́dọ̀ mọ nǹkan tí ìwé àṣẹ náà sọ gan-an.
Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló jọ wọnú àdéhùn nípa ẹ̀tọ́ jíjẹ́ oníǹkan, èyí tó ń dáàbò bo “ìmọ̀ ìjìnlẹ̀,” irú bíi àwọn àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́, wọn ò sì fọwọ́ kékeré mú àwọn òfin jíjẹ́ oníǹkan. Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn The New York Times ti January 14, 2000, sọ pé “ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Jámínì àti ti Denmark ba àwọn
mẹ́ńbà ẹgbẹ́ kan tí wọ́n pè ní ẹgbẹ́ kan tó gbówọ́ nídìí ṣíṣe fàyàwọ́ àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́,” tó máa ń ṣàdàkọ àwọn ètò rẹ̀ àti àwọn eré ìdárayá inú rẹ̀, tó sì tún ń pín wọn kiri, kódà wọ́n tún ń tà lára wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì pàápàá.Ìhà wo ni ìjọ Kristẹni kọ sí ọ̀ràn yìí? Tóò, Jésù sọ pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Máàkù 12:17) Ìyẹn ń béèrè pé káwọn Kristẹni pa àwọn òfin orílẹ̀-èdè tí kò bá tako òfin Ọlọ́run mọ́. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìjọba, ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga . . . Ẹni tí ó bá tako ọlá àṣẹ ti mú ìdúró kan lòdì sí ìṣètò Ọlọ́run; àwọn tí wọ́n ti mú ìdúró kan lòdì sí i yóò gba ìdájọ́ fún ara wọn.”—Róòmù 13:1, 2.
Kì í ṣe ẹrù iṣẹ́ àwọn alàgbà nínú ìjọ láti lọ máa yẹ ohun tó wà nínú kọ̀ǹpútà àwọn ẹlòmíràn wò, bí ẹni pé a fún wọn láṣẹ láti ṣàlàyé àti láti máa rí sí i pé àwọn ará kò lu òfin ẹ̀tọ́ jíjẹ́ oníǹkan. Àmọ́ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tí wọ́n sì ń fi kọ́ni ni pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ yẹra fún mímú ohun tí kì í ṣe tiwọn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ tiraka láti jẹ́ ẹni tó ń pa òfin mọ́. Èyí máa ń yọ àwọn Kristẹni nínú dídi ẹni tí a fìyà jẹ gẹ́gẹ́ bí arúfin, ó sì tún ń jẹ́ kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn rere níwájú Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí náà, ìdí tí ń múni lọ́ranyàn wà fún yín láti wà lábẹ́ àṣẹ, kì í ṣe ní tìtorí ìrunú yẹn nìkan, ṣùgbọ́n ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn yín pẹ̀lú.” (Róòmù 13:5) Bákan náà, Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn àwọn Kristẹni tòótọ́ jáde nípa sísọ pé: “Àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn ilé iṣẹ́ kan àtàwọn iléèwé kan máa ń gba ìwé àṣẹ tí ọ̀pọ̀ èèyàn lè lò, èyí tó fòté lé iye àwọn tí wọ́n gbà láyè láti lo àkójọ ìlànà kan. Lọ́dún 1995, àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà jíròrò àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa (ẹ̀dà ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà) tó ní ìmọ̀ràn yìí nínú pé:
“Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n sì ń tà wọ́n, ló jẹ́ pé wọ́n máa ń ní ẹ̀tọ́ oníǹkan lórí wọn, wọ́n sì máa ń fún èèyàn ní ìwé àṣẹ tó ń ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè lo àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ inú rẹ̀ lọ́nà tó bófin mu. Ìwé àṣẹ ọ̀hún sábà máa ń sọ pé ẹni tó rà á kò láṣẹ láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀dà àkójọ ìlànà náà; àní sẹ́, òfin orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè sọ ọ́ di ohun tí kò bófin mu láti ṣe bẹ́ẹ̀. . . . Àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá kan máa ń ta àwọn kọ̀ǹpútà tí àkójọ ìlànà tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ bá wọn wá, tí wọ́n sì ti fàṣẹ sí wọn. Àmọ́ ṣá o, àwọn ilé iṣẹ́ kan tí ń ta kọ̀ǹpútà kì í pèsè ìwé àṣẹ torí pé ẹ̀dà àwọn àkójọ ìlànà tí wọ́n ṣe sínú kọ̀ǹpútà tí wọ́n tà kò bófin mu, èyí tó túmọ̀ sí pé ẹni tó bá rà á rú òfin nípa lílo àwọn àkójọ ìlànà náà. Níbàámu pẹ̀lú èyí, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ yẹra fún dída àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tó ní ẹ̀tọ́ oníǹkan kọ sínú kọ̀ǹpútà wọn (irú bí àwọn ìtẹ̀jáde Society) tí èyí lè jẹ́ láìsí ìyọ̀ǹda tó bófin mu látọ̀dọ̀ oníǹkan.”