Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọjọ́ Ìdájọ́ Jèhófà Ti Sún Mọ́lé!

Ọjọ́ Ìdájọ́ Jèhófà Ti Sún Mọ́lé!

Ọjọ́ Ìdájọ́ Jèhófà Ti Sún Mọ́lé!

“Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.”—SEFANÁYÀ 1:14.

1. Ìkìlọ̀ wo ni Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ Sefanáyà?

 JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN máa tó dìde ogun sáwọn èèyàn burúkú. Gbọ́ ná! Ó kìlọ̀ pé: “Èmi yóò pa ará ayé . . . rẹ́. . . . Èmi yóò sì ké aráyé kúrò lórí ilẹ̀.” (Sefanáyà 1:3) Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ, sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀, Sefanáyà, tó jọ pé ó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Hesekáyà Ọba olóòótọ́ nì. Ọ̀rọ̀ yẹn, tí Ọlọ́run sọ nígbà ayé Jòsáyà Ọba rere, kò fọre fáwọn ẹni burúkú tó wà ní ilẹ̀ Júdà.

2. Èé ṣe tí àwọn ìgbésẹ̀ tí Jòsáyà gbé kò dá ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà dúró?

2 Láìsí àní-àní, àsọtẹ́lẹ̀ tí Sefanáyà sọ mú kí ọ̀dọ́mọdé Jòsáyà túbọ̀ jí gìrì, kí ó rí ìjẹ́pàtàkì mímú ìjọsìn àìmọ́ kúrò ní Júdà. Àmọ́ àwọn ìgbésẹ̀ tí Jòsáyà gbé láti mú ẹ̀sìn èké kúrò ní ilẹ̀ náà kò fòpin sí gbogbo ìwà burúkú láàárín àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ bàbá-bàbá rẹ̀, Mánásè Ọba, tó “fi ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kún Jerúsálẹ́mù.” (2 Àwọn Ọba 24:3, 4; 2 Kíróníkà 34:3) Nítorí náà, ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà kò lè ṣe kí ó máà dé.

3. Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé ó ṣeé ṣe láti la “ọjọ́ ìbínú Jèhófà” já?

3 Ṣùgbọ́n, àwọn kan yóò la ọjọ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yẹn já. Ìyẹn ló jẹ́ kí wòlíì Ọlọ́run rọ̀ wá pé: “Kí ìlànà àgbékalẹ̀ náà tó bí ohunkóhun, kí ọjọ́ náà tó kọjá lọ bí ìyàngbò, kí ìbínú jíjófòfò Jèhófà tó wá sórí yín, kí ọjọ́ ìbínú Jèhófà tó wá sórí yín, ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé, tí ń fi ìpinnu ìdájọ́ Tirẹ̀ ṣe ìwà hù. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.” (Sefanáyà 2:2, 3) Níwọ̀n bí a ti ní ìrètí pé a lè la ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà já, ẹ jẹ́ ká wá gbé ìwé Sefanáyà inú Bíbélì yẹ̀ wò lẹ́sẹẹsẹ. Ilẹ̀ Júdà la ti kọ ìwé náà ṣáájú ọdún 648 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó sì wà lára “ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀” Ọlọ́run, tó yẹ kí gbogbo wa fiyè sí gidigidi.—2 Pétérù 1:19.

Jèhófà Na Ọwọ́ Rẹ̀ Jáde

4, 5. Báwo ni Sefanáyà 1:1-3 ṣe nímùúṣẹ sórí àwọn ẹni burúkú ní Júdà?

4 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà” tó sọ fún Sefanáyà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìkìlọ̀ táa mẹ́nu kàn níṣàájú. Ọlọ́run kéde pé: “‘Láìkùnà, èmi yóò pa ohun gbogbo rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Èmi yóò pa ará ayé àti ẹranko rẹ́. Èmi yóò pa ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti àwọn ẹja òkun rẹ́, àti àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú; dájúdájú, èmi yóò sì ké aráyé kúrò lórí ilẹ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà.”—Sefanáyà 1:1-3.

5 Àní sẹ́, Jèhófà yóò fòpin sí ìwà burúkú tó lékenkà ní ilẹ̀ Júdà. Ta ni Ọlọ́run yóò lò láti “pa ohun gbogbo rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀”? Níwọ̀n bó ti ṣe kedere pé Sefanáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Jòsáyà Ọba, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 659 ṣááju Sànmánì Tiwa, ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn nímùúṣẹ nígbà táwọn ará Bábílónì sọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù, olú ìlú rẹ̀, dahoro lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Nígbà yẹn, àwọn ẹni burúkú ‘pa rẹ́ kúrò’ ní Júdà.

6-8. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló wà nínú Sefanáyà 1:4-6, báwo ló sì ṣe nímùúṣẹ ní Júdà ìgbàanì?

6 Sefanáyà 1:4-6 sàsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Ọlọ́run yóò ṣe sí àwọn olùjọsìn èké, pé: “Èmi yóò sì na ọwọ́ mi jáde lòdì sí Júdà àti lòdì sí gbogbo àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù, èmi yóò sì ké àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Báálì kúrò ní ibí yìí, àti orúkọ àwọn àlùfáà ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àlùfáà, àti àwọn tí ń tẹrí ba fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run lórí àwọn òrùlé, àti àwọn tí ń tẹrí ba, tí ń búra fún Jèhófà, tí ó sì ń fi Málíkámù búra; àti àwọn tí ń fà sẹ́yìn kúrò ní títọ Jèhófà lẹ́yìn, tí wọn kò sì wá Jèhófà, tí wọn kò sì ṣe ìwádìí nípa rẹ̀.”

7 Jèhófà na ọwọ́ rẹ̀ jáde lòdì sí àwọn ènìyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù. Ó ti pinnu pé òun yóò fi ikú pa àwọn olùjọ́sìn Báálì, ọlọ́run ìbímọlémọ ti àwọn ará Kénáánì. Wọ́n máa ń pe onírúurú àwọn òrìṣà ìbílẹ̀ ní Báálì nítorí pé àwọn tí ń sìn wọ́n gbà pé wọ́n lágbára lórí àwọn àdúgbò kan pàtó. Fún àpẹẹrẹ, Báálì kan wà táwọn ará Móábù àtàwọn ará Mídíánì jọ́sìn lórí Òkè Péórù. (Númérì 25:1, 3, 6) Jákèjádò ilẹ̀ Júdà, Jèhófà yóò ké àwọn àlùfáà Báálì kúrò, àti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà aláìṣòótọ́, tí wọ́n ń rú òfin Ọlọ́run nípa bíbá wọn kẹ́gbẹ́.—Ẹ́kísódù 20:2, 3.

8 Ọlọ́run yóò tún ké àwọn “tí ń tẹrí ba fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run” kúrò, ìyẹn àwọn tí ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n ń wòràwọ̀, wọ́n sì ń bọ oòrùn. (2 Àwọn Ọba 23:11; Jeremáyà 19:13; 32:29) Bákan náà ni ìrunú Ọlọ́run ń bọ̀ lórí àwọn tí ń gbìyànjú láti ṣàmúlùmálà ẹ̀sìn tòótọ́ àti ẹ̀sìn èké, tí wọ́n ‘ń búra fún Jèhófà, tí wọ́n sì ń fi Málíkámù búra.’ Ó jọ pé Málíkámù lorúkọ míì tí wọ́n ń pe Mólékì, tí í ṣe olórí òrìṣà àwọn ará Ámónì. Fífi ọmọdé rúbọ wà lára ohun tí wọ́n fi ń jọ́sìn Mólékì.—1 Àwọn Ọba 11:5; Jeremáyà 32:35.

Òpin Kirisẹ́ńdọ̀mù Kù sí Dẹ̀dẹ̀!

9. (a) Kí ni Kirisẹ́ńdọ̀mù jẹ̀bi rẹ̀? (b) Láìdàbí àwọn aláìṣòótọ́ ní Júdà, kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

9 Gbogbo èyí rán wa létí Kirisẹ́ńdọ̀mù, tó ti ri ara bọnú ìjọsìn èké àti ìwòràwọ̀ bámúbámú. Ipa tó sì kó nínú fífi ẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn rúbọ nínú àwọn ogun tí àwọn àlùfáà ṣètìlẹyìn fún ń kóni nírìíra burúkú-burúkú! Ẹ má ṣe jẹ́ ká dà bí àwọn aláìṣòótọ́ ní Júdà, tí wọ́n “fà sẹ́yìn kúrò ní títọ Jèhófà lẹ́yìn,” tí wọn kò náání rẹ̀, tí wọn kò wá a, tí wọn kò sì wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká pa ìwà títọ́ wa mọ́ sí Ọlọ́run.

10. Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ inú Sefanáyà 1:7?

10 Ọ̀rọ̀ tí wòlíì náà sọ tẹ̀ lé e bá àwọn oníwàkiwà ní Júdà àtàwọn olubi òde òní wí. Sefanáyà 1:7 sọ pé: “Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ; nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé, nítorí Jèhófà ti pèsè ẹbọ sílẹ̀; ó ti sọ àwọn tí ó ké sí di mímọ́.” Ó ṣe kedere pé “àwọn tí ó ké sí” náà ni àwọn ará Kálídíà tó jẹ́ ọ̀tá Júdà. Júdà fúnra rẹ̀, tòun ti olú ìlú rẹ̀, ni “ẹbọ” náà. Nípa báyìí, ńṣe ni Sefanáyà kéde ète Ọlọ́run láti pa Jerúsálẹ́mù run, àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì tún tọ́ka sí ìparun Kirisẹ́ńdọ̀mù. Àní, pẹ̀lú bí ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run ti sún mọ́lé tó lónìí, gbogbo ayé gbọ́dọ̀ “dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ,” kí wọ́n sì gbọ́ ohun tó ń sọ nípasẹ̀ “agbo kékeré” ti àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù àti “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn. (Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16) Ìparun yán-ányán-án ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí kò bá fetí sílẹ̀, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara wọn di ọ̀tá ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run.—Sáàmù 2:1, 2.

Ọjọ́ Híhu Yóò Dé Láìpẹ́!

11. Kí ni kókó tó wà nínú Sefanáyà 1:8-11?

11 Sefanáyà 1:8-11 tún sọ nípa ọjọ́ Jèhófà pé: “‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ẹbọ Jèhófà pé èmi yóò fún àwọn ọmọ aládé ní àfiyèsí dájúdájú, èmi yóò sì fún àwọn ọmọ ọba, àti gbogbo àwọn tí ń wọ aṣọ ilẹ̀ òkèèrè ní àfiyèsí. Dájúdájú, èmi yóò sì fún olúkúlùkù ẹni tí ń gun pèpéle ní àfiyèsí ní ọjọ́ yẹn, àwọn tí ń fi ìwà ipá àti ẹ̀tàn kún ilé ọ̀gá wọn. Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘ìró igbe ẹkún yóò ti Ẹnubodè Ẹja wá, àti híhu láti ìhà kejì, àti ìfọ́yángá ńláǹlà láti àwọn òkè kéékèèké. Ẹ hu, ẹ̀yin olùgbé Mákítẹ́ṣì, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ oníṣòwò ni a ti pa lẹ́nu mọ́; gbogbo àwọn tí ń wọn fàdákà ni a ti ké kúrò.’”

12. Báwo ló ṣe jẹ́ pé àwọn kan “ń wọ aṣọ ilẹ̀ òkèèrè”?

12 Lẹ́yìn Jòsáyà Ọba, Jèhóáhásì, Jèhóákímù, àti Jèhóákínì ni yóò jọba. Lẹ́yìn náà ni Sedekáyà yóò di alákòóso, ìgbà tirẹ̀ sì ni ìparun Jerúsálẹ́mù yóò dé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé irú àjálù bẹ́ẹ̀ rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí wọn, ó jọ pé àwọn kan nínú wọn, bẹ̀rẹ̀ sí wá ojú rere àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká, nípa ‘wíwọ aṣọ ilẹ̀ òkèèrè.’ Bákan náà ló rí lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fi hàn ní onírúurú ọ̀nà pé àwọn kì í ṣe ara ètò àjọ Jèhófà. Níwọ̀n bí wọ́n ti fi hàn pé àwọn jẹ́ ara ètò Sátánì, wọn ò ní lọ láìjìyà.

13. Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ará Bábílónì bá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù?

13 “Ọjọ́ yẹn” tí Júdà yóò jíhìn bá ọjọ́ tí Jèhófà yóò ṣèdájọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ mu, tí yóò fòpin sí ìwà burúkú, tí yóò sì fi hàn pé òun ló ga lọ́lá jù lọ. Bí àwọn ará Bábílónì bá ṣe gbógun ti Jerúsálẹ́mù ni ìró igbe yóò wá láti Ẹnubodè Ẹja. Bóyá nítorí pé ibẹ̀ sún mọ́ ọjà tí wọ́n ti ń ta ẹja ni wọ́n fi ń pè é bẹ́ẹ̀. (Nehemáyà 13:16) Ogunlọ́gọ̀ àwọn ará Bábílónì yóò rọ́ wọ apá ibi tí wọ́n ń pè ní ìhà kejì, bákan náà, ‘ìfọ́yángá láti àwọn òkè kéékèèké’ lè dúró fún ìró àwọn ará Kálídíà tí ń rọ́ bọ̀. Híhu làwọn olùgbé Mákítẹ́ṣì, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ apá òkè Àfonífojì Tírópóónì, yóò “hu.” Kí ni yóò mú kí wọ́n hu? Nítorí àwọn èèyàn ò ní ṣòwò níbẹ̀ mọ́, “àwọn tí ń wọn fàdákà” níbẹ̀ pàápàá á kógbá sílé.

14. Báwo ni àyẹ̀wò tí Ọlọ́run yóò ṣe nípa àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní olùjọ́sìn rẹ̀ yóò ṣe gbòòrò tó?

14 Báwo ni àyẹ̀wò tí Jèhófà yóò ṣe nípa àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní olùjọ́sìn rẹ̀ yóò ṣe gbòòrò tó? Àsọtẹ́lẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní àkókò yẹn pé èmi yóò fi fìtílà wá inú Jerúsálẹ́mù lẹ́sọ̀lẹsọ̀ dájúdájú, èmi yóò sì fún àwọn ènìyàn tí ń dì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn ní àfiyèsí, tí wọ́n sì ń sọ ní ọkàn-àyà wọn pé, ‘Jèhófà kì yóò ṣe rere, kì yóò sì ṣe búburú.’ Ọlà wọn yóò sì wá jẹ́ fún ìkógun àti ilé wọn fún ahoro. Wọn yóò sì kọ́ ilé, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé inú wọn; wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu wáìnì wọn.”—Sefanáyà 1:12, 13.

15. (a) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn àlùfáà apẹ̀yìndà tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù? (b) Kí ní ń bẹ níwájú fún àwọn tí ń ṣe ẹ̀sìn èké lónìí?

15 Àwọn àlùfáà apẹ̀yìndà ní Jerúsálẹ́mù ń da ìjọsìn Jèhófà pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn èké. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rò pé àwọn ti ríbi forí pa mọ́ sí, Ọlọ́run yóò wá wọn kàn, bíi pé ó fi fìtílà mímọ́lẹ̀ yòò wá wọn, èyí tí yóò fi òkùnkùn tẹ̀mí tí wọ́n fi bojú hàn. Ìkankan nínú wọn kò ní mórí bọ́ nínú ìkéde ìdájọ́ àti ìparun tí Ọlọ́run yóò mú wá. Àwọn apẹ̀yìndà aláìka-nǹkan-sí wọ̀nyẹn ti silẹ̀ bíi gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ nísàlẹ̀ agbada ìfúntí. Wọn ò fẹ́ kí ìpolongo èyíkéyìí pé Ọlọ́run fẹ́ dá sí ọ̀ràn aráyé kó ìyọlẹ́nu bá àwọn, ṣùgbọ́n wọn ò ní mórí bọ́ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run. Àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn èké lónìí pẹ̀lú kò ní mórí bọ́, títí kan àwọn mẹ́ńbà Kirisẹ́ńdọ̀mù àtàwọn kan tí wọ́n ti pẹ̀yìn dà sí ìjọsìn Jèhófà. Wọ́n ní kì í ṣe “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí, wọ́n sì ń sọ lọ́kàn wọn pé, “Jèhófà kì yóò ṣe rere, kì yóò sì ṣe búburú.” Ṣùgbọ́n àṣìṣe gbáà ni wọ́n ṣe!—2 Tímótì 3:1-5; 2 Pétérù 3:3, 4, 10.

16. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìdájọ́ Ọlọ́run bá dé sórí Júdà, ipa wo ló sì yẹ kí mímọ èyí ní lórí wa?

16 A kìlọ̀ fún àwọn apẹ̀yìndà ní Júdà pé àwọn ará Bábílónì yóò kó ohun ìní wọn níkòógun, wọn ó sọ ilé wọn dahoro, wọn ó sì kó èso ọgbà àjàrà wọn. Àwọn ohun ìní kò ní já mọ́ nǹkan kan nígbà tí ìdájọ́ Ọlọ́run bá nímùúṣẹ lórí Júdà. Bákan náà ni yóò rí nígbà tí ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà bá dé sórí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí náà, ǹjẹ́ kí a jẹ́ ẹni tẹ̀mí, ká sì máa ‘to ìṣúra jọ pa mọ́ ní ọ̀run’ nípa fífi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò kìíní nínú ayé wa!—Mátíù 6:19-21, 33.

“Ọjọ́ Ńlá Jèhófà Sún Mọ́lé”

17. Gẹ́gẹ́ bí Sefanáyà 1:14-16 ti wí, báwo ni ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ṣe sún mọ́lé tó?

17 Báwo ni ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ṣe sún mọ́lé tó? Gẹ́gẹ́ bí Sefanáyà 1:14-16 ti sọ, Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi. Ìró ọjọ́ Jèhófà korò. Alágbára ńlá ọkùnrin yóò figbe ta níbẹ̀. Ọjọ́ yẹn jẹ́ ọjọ́ ìbínú kíkan, ọjọ́ wàhálà àti làásìgbò, ọjọ́ ìjì àti ìsọdahoro, ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù, ọjọ́ àwọsánmà àti ìṣúdùdù tí ó nípọn, ọjọ́ ìwo àti ti àmì àfiyèsí oníròó ìdágìrì, lòdì sí àwọn ìlú ńlá olódi àti lòdì sí àwọn ilé gogoro tí ó wà ní igun odi.”

18. Èé ṣe tí kò fi yẹ ká parí èrò sí pé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ṣì máa pẹ́?

18 A kìlọ̀ fáwọn àlùfáà tí wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ ní Júdà, àwọn ọmọ aládé, àtàwọn èèyàn wọn yòókù pé “ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé.” Ní ti Júdà, ‘ìyára kánkán ọjọ́ Jèhófà yóò pọ̀ gidigidi.’ Bákan náà, ní àkókò tiwa yìí, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé ó ṣì máa pẹ́ kí Jèhófà tó mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ lórí àwọn ẹni burúkú. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe yára gbégbèésẹ̀ ní Júdà, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe mú kí ọjọ́ ìdájọ́ rẹ̀ ‘yára kánkán.’ (Ìṣípayá 16:14, 16). Ọjọ́ ọ̀hún yóò mà korò o, fún gbogbo àwọn tó kọ etí dídi sí ìkìlọ̀ Jèhófà látẹnu àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀, tí wọ́n sì kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́!

19, 20. (a) Kí ni díẹ̀ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run tú ìrunú rẹ̀ dà sórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù? (b) Níwọ̀n bí a ó ti dá àwọn kan sí, tí a ó sì pa àwọn kan run nígbà ìparun ètò àwọn nǹkan yìí, àwọn ìbéèrè wo la gbé dìde?

19 “Ọjọ́ wàhálà àti làásìgbò” ni ọjọ́ tí Ọlọ́run tú ìrunú rẹ̀ dà sórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù. Àwọn olùgbé Júdà jẹ palaba ìyà lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì tó wá gbógun tì wọ́n, làásìgbò bá wọn bí wọ́n ṣe dojú kọ ikú àti ìparun. “Ọjọ́ ìjì àti ìsọdahoro” yẹn jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn, ọjọ́ kùrukùru, àti ìṣúdùdù tó nípọn, ó tiẹ̀ lè máà jẹ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nìkan, ṣùgbọ́n kí ó ṣẹlẹ̀ ní gidi nítorí pé èéfín bo ibi gbogbo, òkú sì sùn lọ rẹpẹtẹ. Ó jẹ́ “ọjọ́ ìwo àti ti àmì àfiyèsí oníròó ìdágìrì,” ṣùgbọ́n wọ́n kọ etí dídi sí gbogbo ìkìlọ̀ wọ̀nyẹn.

20 Ńṣe làwọn olùṣọ́ Jerúsálẹ́mù kàn ń wò bọ̀ọ̀ láìrọ́gbọ́n dá sí i, bí ohun èlò tí àwọn ará Bábílónì fi ń fọ́ ògiri ṣe ń fọ́ “àwọn ilé gogoro tí ó wà ní igun odi.” Bẹ́ẹ̀ náà ni odi ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí yóò ṣe já sí òtúbáńtẹ́ láìní lè dènà àwọn ohun ìjà tí ń bẹ níkàáwọ́ Ọlọ́run lókè ọ̀run, àwọn ohun tí yóò lò láìjáfara nígbà tí yóò pa àwọn èèyàn kan run tí yóò sì dá àwọn kan sí. Ṣé o ń retí pé kí ó dá ọ sí? Ṣé o ti dúró gbọn-in níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà, ‘ẹni tí ń ṣọ́ gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n tí yóò pa gbogbo ẹni burúkú rẹ́ ráúráú’?—Sáàmù 145:20.

21, 22. Báwo ni Sefanáyà 1:17, 18 yóò ṣe ní ìmúṣẹ lọ́jọ́ tiwa?

21 Ẹ wo ọjọ́ ìdájọ́ amúnigbọ̀nrìrì tí Sefanáyà 1:17, 18 sọ tẹ́lẹ̀! Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò sì fa wàhálà bá aráyé, wọn yóò sì máa rìn bí afọ́jú; nítorí pé Jèhófà ni wọ́n ti ṣẹ̀ sí. Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí ekuru ní ti tòótọ́, àti ìwọ́rọ́kù wọn bí imí. Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kì yóò lè dá wọn nídè ní ọjọ́ ìbínú kíkan Jèhófà; ṣùgbọ́n nípa iná ìtara rẹ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé ni a ó jẹ run, nítorí tí yóò mú ìparun pátápátá, ọ̀kan tí ń jáni láyà ní tòótọ́, wá bá gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.”

22 Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ṣe lọ́jọ́ Sefanáyà, láìpẹ́ òun yóò kó wàhálà bá “gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé,” èyíinì ni àwọn tó kọ̀ láti ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ rẹ̀. Nítorí pé wọ́n ṣẹ Ọlọ́run, wọn ó máa rìn kiri bí afọ́jú tí kò rẹ́ni fọ̀nà hàn án, wọn kò ní rí ìdáǹdè. Lọ́jọ́ ìdájọ́ Jèhófà, ẹ̀jẹ̀ wọn “ni a ó sì tú jáde bí ekuru ní ti tòótọ́,” bí ohun tí kò wúlò. Ikú ẹ̀sín ni wọn yóò kú, nítorí pé ṣe ni Ọlọ́run yóò fọ́n òkú—àti ìwọ́rọ́kù—àwọn olubi wọ̀nyí ká sórí ilẹ̀, “bí imí.”

23. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní mórí bọ́ “ní ọjọ́ ìbínú kíkan Jèhófà,” ìrètí wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà mẹ́nu kàn?

23 Kò sẹ́ni tó lè gba àwọn tí ń bá Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ jà. Fàdákà tàbí wúrà kò lè gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ará Júdà là, àní gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí Kirisẹ́ńdọ̀mù àti àwọn yòókù tó jẹ́ apá kan ètò búburú yìí kó jọ àti owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kò ti ní dáàbò bò wọ́n, tí kò sì ní dá wọn sí “ní ọjọ́ ìbínú kíkan Jèhófà.” Ní ọjọ́ ìpinnu yẹn, “gbogbo ilẹ̀ ayé” ni iná ìtara Ọlọ́run yóò jẹ run bó ti ń pa àwọn ẹni burúkú run ráúráú. Nítorí pé a ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, ó dá wa lójú pé “àkókò òpin” ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bùṣe báyìí. (Dáníẹ́lì 12:4) Ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé, yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀ láìpẹ́. Ṣùgbọ́n, àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà sọ̀rọ̀ nípa ìrètí ìdáǹdè. Kí wá ni ṣíṣe, bí a óò bá pa wá mọ́ lọ́jọ́ ìbínú Jèhófà?

Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?

• Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà ṣe ní ìmúṣẹ lórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù?

• Kí ní ń bẹ níwájú fún Kirisẹ́ńdọ̀mù àti gbogbo àwọn olubi ọjọ́ wa?

• Èé ṣe tí kò fi yẹ ká ronú pé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ṣì jìnnà réré?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Sefanáyà fi àìṣojo kéde pé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé

[Credit Line]

Látinú ìwé Self-Pronouncing Edition of the Holy Bible, tó ní ẹ̀dà ti King James àti Revised nínú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ọjọ́ Jèhófà dé sórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù nípasẹ̀ àwọn ará Bábílónì ní 607 ṣááju Sànmánì Tiwa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ṣé o nírètí pé wàá mórí bọ́ nígbà tí Jèhófà bá pa àwọn ẹni burúkú run?