Kí ni Òótọ́ Ọ̀rọ̀ Nípa Àkájọ Ìwé Òkun Òkú?
Kí ni Òótọ́ Ọ̀rọ̀ Nípa Àkájọ Ìwé Òkun Òkú?
Òkúta tí darandaran ará Bedouin kan jù sínú hòrò kan ní ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn ló ṣokùnfà ohun tí àwọn kan pè ní àwárí títóbi jù lọ tí a walẹ̀ kàn ní ọ̀rúndún ogún. Ará Bedouin náà gbọ́ tí òkúta náà fọ́ ìṣà kan. Nígbà tó wá wò ó dáadáa, ohun tó rí ló jẹ́ àkọ́kọ́ lára ohun táa wá mọ̀ sí àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú.
ÀWỌN àkájọ ìwé wọ̀nyí ti di ohun tó gba àfiyèsí, tó sì ti fa àríyànjiyàn láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àti láwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn fún gbogbo ènìyàn. Ìdàrúdàpọ̀ àti ìsọfúnni òdì ti gbalẹ̀ kan láàárín àwọn èèyàn lápapọ̀. Ọ̀pọ̀ àhesọ ló ti tàn kálẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe di rìkíṣí ńlá kan. Wọ́n ń tan àhesọ yìí kálẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù pé àwọn àkájọ ìwé náà yóò fi àwọn òkodoro òtítọ́ hàn, tó máa sọ ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni àtàwọn Júù di aláìlágbára. Àmọ́, kí ni ìjẹ́pàtàkì àwọn ìwé àkájọ wọ̀nyí gan-an? Lẹ́yìn ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún, ǹjẹ́ a ṣì lè mọ àwọn òkodoro òtítọ́ náà?
Kí Ni Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú?
Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ni àwọn ìwé tí àwọn Júù ayé ọjọ́un fọwọ́ kọ, èdè Hébérù ni wọ́n fi kọ ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn, wọ́n kọ àwọn kan ní èdè Árámáíkì, wọ́n sì fi èdè Gíríìkì kọ díẹ̀ nínú wọn. Ọjọ́ orí ọ̀pọ̀ lára àwọn àkájọ ìwé àtàwọn àjákù wọ̀nyí ti lé ní ẹgbàá [2,000] ọdún, tó fi hàn pé wọ́n ti wà ṣáájú ìbí Jésù. Lára àwọn àkájọ ìwé táa kọ́kọ́ rí gbà lọ́dọ̀ àwọn Bedouin ni àwọn ìwé àfọwọ́kọ méje tó gùn jàn-ànrànjan-anran, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni bí wọ́n ṣe bà jẹ́ tó. Bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń wá àwọn hòrò kiri ni wọ́n tún rí àwọn àkájọ ìwé mìíràn àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àjákù ìwé àkájọ. Láàárín ọdún 1947 sí 1956, àpapọ̀ àwọn hòrò mọ́kànlá tó ní
àwọn àkájọ ìwé nínú ni wọ́n ṣàwárí nítòsí Qumran, lẹ́bàá Òkun Òkú.Nígbà tí wọ́n yẹ gbogbo àwọn àkájọ ìwé àtàwọn àjákù náà wò, wọ́n ń lọ sí nǹkan bí ẹgbẹ̀rin [800] ìwé àfọwọ́kọ. Nǹkan bí ìdá mẹ́rin wọn, tàbí èyí tó kàn fi díẹ̀ lé ní igba ìwé àfọwọ́kọ, ni wọ́n jẹ́ ẹ̀dà àwọn apá tó jẹ́ ti Bíbélì èdè Hébérù. Àwọn ìwé àfọwọ́kọ yòókù jẹ́ ìwé àwọn Júù ìgbàanì tí kì í ṣe ara Bíbélì, ìyẹn ni Apocrypha àti Pseudepigrapha. a
Àwọn kan lára àwọn àkájọ ìwé tó máa ń wú àwọn ọ̀mọ̀wé lórí jù lọ ni àwọn ìwé tí a kò mọ̀ nípa wọn tẹ́lẹ̀. Lára àwọn wọ̀nyí ni àlàyé nípa àwọn ọ̀ràn lórí òfin àwọn Júù, àwọn àṣẹ pàtó kan tó wà fún àwùjọ àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn tó gbé Qumran, ewì àtàwọn àdúrà tí wọ́n ń lò nínú àwọn ààtò ẹ̀sìn, títí kan àwọn ìwé ìgbàgbọ́ tó fi èrò wọn nípa ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti àwọn ọjọ́ ìkẹyìn hàn. Wọ́n tún ṣe àwọn àlàyé kan tó ṣọ̀wọ́n lórí Bíbélì, ìwọ̀nyí ni àkọ́kọ́ irú àlàyé bẹ́ẹ̀, àwọn ni atọ́kùn àlàyé táwọn èèyàn wá ń ṣe lóde òní lórí ẹsẹ Bíbélì kọ̀ọ̀kan.
Ta Ló Kọ Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú?
Onírúurú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń mọ ọjọ́ orí àwọn ìwé àkọsílẹ̀ ìgbàanì fi hàn pé àwọn àkájọ ìwé náà lè jẹ́ èyí tí wọ́n dà kọ tàbí tí wọ́n tún tò láàárín ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa sí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan lérò pé àwọn Júù tó wá láti Jerúsálẹ́mù ló kó àwọn àkájọ ìwé ọ̀hún pa mọ́ sínú àwọn hòrò náà ṣáájú ìparun tẹ́ńpìlì ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó ń ṣe ìwádìí àkájọ ìwé náà ló rí i pé èrò yìí kò bá ohun tó wà nínú àwọn àkájọ ìwé náà fúnra wọn mu. Ọ̀pọ̀ àkájọ ìwé náà ló fi èrò àtàwọn àṣà tó tako ti àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ní Jerúsálẹ́mù hàn. Àwọn àkájọ ìwé wọ̀nyí sọ nípa àwùjọ kan, tó gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ti kọ àwọn àlùfáà àtàwọn ìsìn tí wọ́n ń ṣe ní tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ àti pé ó wo ìjọsìn tí àwùjọ wọn ń ṣe ní aginjù bí èyí tó rọ́pò ìsìn tí wọ́n ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì. Kò jọ pé àwọn aláṣẹ inú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù á gbé àkójọ kan tó ní irú àwọn àkájọ ìwé bẹ́ẹ̀ nínú pa mọ́.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí àwùjọ àwọn adàwékọ wà ní Qumran, síbẹ̀ ó lè jẹ́ pé ibòmíràn làwọn onígbàgbọ́ yẹn tí kó ọ̀pọ̀ lára àkájọ ìwé náà jọ tí wọ́n sì kó wọn wá sí Qumran. Lọ́nà kan ṣáá, àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú jẹ́ àkójọ ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìwé. Bó ṣe máa ń rí níbi ìkówèésí èyíkéyìí, àkójọ ìwé náà lè ní oríṣiríṣi èrò nínú, kò pọndandan kí gbogbo ìwé tó wà níbẹ̀ bá èrò ẹ̀sìn àwọn tó ń kà á mu. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí àwọn àyọkà tí wọ́n wà nínú àìmọye ẹ̀dà jẹ́ àwọn tó bá ìfẹ́ inú àti ìgbàgbọ́ àwùjọ yẹn mu.
Ṣé Ẹlẹ́sìn Essene Làwọn Tó Ń Gbé Qumran Ni?
Bí àwọn àkájọ ìwé wọ̀nyí bá jẹ́ ti ibi ìkówèésí Qumran, àwọn wo ló ń gbé ibẹ̀? Ọ̀jọ̀gbọ́n Eleazar Sukenik, tó gba àkájọ ìwé mẹ́ta fún Yunifásítì tí wọ́n ti ń ṣèwádìí èdè Hébérù ní Jerúsálẹ́mù ní 1947 ni ẹni tó kọ́kọ́ sọ pé àwọn àkájọ ìwé wọ̀nyí jẹ́ ti àwùjọ àwọn Essene.
Àwọn Essene jẹ́ ẹ̀ya ìsìn àwọn Júù kan tí àwọn òǹkọ̀wé ọ̀rúndún kìíní nì, Josephus, Philo ti Alexandria àti Pliny Àgbà mẹ́nu kàn. Ńṣe làwọn èèyàn kàn ń méfò nípa ibi tó jẹ́ orírun àwọn Essene gan-an, àmọ́ ó dà bíi pé sáà pákáǹleke tó tẹ̀ lé ìdìtẹ̀ àwọn Maccabee ní ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa ni wọ́n wá sójútáyé. b Josephus ròyìn wíwà wọn lákòókò yẹn, nígbà tó ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí èrò ẹ̀sìn wọn ṣe yàtọ̀ sí ti àwọn Farisí àtàwọn Sadusí. Pliny mẹ́nu kan ibi tí àwùjọ àwọn Essene kan wà lẹ́bàá Òkun Òkú láàárín Jẹ́ríkò àti Ẹ́ń-gédì.
Ọ̀jọ̀gbọ́n James VanderKam, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa Àkájọ Ìwé Òkun Òkú dábàá pé “àwọn Essene tó ń gbé ní Qumran wulẹ̀ jẹ́ ìwọ̀nba kéréje lára ògìdìgbó ẹgbẹ́ àwọn Essene ni,” àwọn tí Josephus fojú bù pé wọ́n ń lọ sí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000]. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máà bá gbogbo àpèjúwe náà mu tán pátápátá, síbẹ̀ àpapọ̀ àpèjúwe látinú àwọn ìwé tó wá láti Qumran dà bí èyí tó bá àwọn Essene mu ju àwùjọ àwọn Júù èyíkéyìí mìíràn táa mọ̀ ní àkókò yẹn.
Mátíù 15:1-20; Lúùkù 6:1-11) Bákan náà, àwọn Essene wọ̀nyí kì í bá àwùjọ ṣe, wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú kádàrá àti àìleèkú ọkàn, wọ́n sì máa ń tẹnu mọ́ ẹ̀jẹ́ ìnìkàngbé àti èròǹgbà ìbẹ́mìílò nípa bíbá àwọn áńgẹ́lì ṣàjọpín nínú ìjọsìn wọn. Èyí fi hàn pé wọn ò fohùn ṣọ̀kan rárá pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù àti ti àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀.—Mátíù 5:14-16; Jòhánù 11:23, 24; Kólósè 2:18; 1 Tímótì 4:1-3.
Àwọn kan ti sọ pé Qumran ni ẹ̀sìn Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ ìyàtọ̀ tó hàn kedere ló wà láàárín èrò ẹ̀ya ìsìn Qumran àti ti àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Àwọn ìwé Qumran fi bí wọn ò ṣe gba gbẹ̀rẹ́ rárá lórí òfin Sábáàtì hàn àti bí ìwẹ̀nùmọ́ lọ́nà àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ṣe gbà wọ́n lọ́kàn bí nǹkan míì. (Kò Sí Ọ̀rọ̀ Àṣírí, Kò Sí Àwọn Àkájọ Ìwé Tó Fara Sin
Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé ìgbà tí wọ́n ṣàwárí àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, onírúurú ìwé ni wọ́n ṣe jáde tó mú kí àwọn ohun tí wọ́n kọ́kọ́ rí wọ̀nyẹn wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ káàkiri àgbáyé. Àmọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àjákù tí wọ́n rí nínú ọ̀kan lára àwọn hòrò náà, táa mọ̀ sí Hòrò Kẹrin, ló ṣe wọ́n ní wàhálà jù. Ìwọ̀nyí wà lọ́wọ́ ẹgbẹ́ kékeré kan tí í ṣe àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè mélòó kan, wọ́n wà ní Ìlà Oòrùn Jerúsálẹ́mù (tó jẹ́ ara Jọ́dánì nígbà yẹn) ní Ibi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé àwọn Awalẹ̀pìtàn sí ní Palẹ́sìnì. Kò sí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kankan tó jẹ́ Júù tàbí ọmọ Ísírẹ́lì nínú ẹgbẹ́ yìí.
Ẹgbẹ́ náà gbé ìlànà kan dìde pé àwọn ò ní gbà káwọn èèyàn rí àwọn àkájọ ìwé náà títí tí wọ́n á fi gbé èsì ìwádìí wọn jáde. Wọn kò jẹ́ kí iye àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó wà nínú ẹgbẹ́ náà pọ̀. Nígbà tí ọmọ ẹgbẹ́ kan bá kú, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ṣoṣo ni wọ́n máa fi rọ́pò rẹ̀. Iṣẹ́ tó wà nílẹ̀ ń béèrè ọmọ ẹgbẹ́ púpọ̀ sí i, nígbà mìíràn wọ́n sì nílò àwọn tó gbọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Hébérù àti ti Árámáíkì ìgbàanì. Ọ̀nà tí James VanderKam gbà sọ ọ́ nìyí: “Ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn àjákù tí wọ́n ti rí pọ̀ ju iṣẹ́ tí àwọn ògbógi mẹ́jọ lè ṣe lọ, bó ti wù kí wọ́n jẹ́ ọ̀jáfáfá tó.”
Ogun Ọlọ́jọ́ Mẹ́fà tó jà ní 1967 mú kí Ìlà Oòrùn Jerúsálẹ́mù àti àwọn ìwé àkájọ rẹ̀ bọ́ sábẹ́ ìṣàkóso Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n ìlànà kankan kò yí padà nítorí pé wọ́n ti gbé ẹgbẹ́ tí ń ṣèwádìí àwọn àkájọ ìwé náà kalẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń fi gbígbé àwọn àkájọ ìwé láti inú Hòrò Kẹrin jáde falẹ̀, tí ìfifalẹ̀ náà kì í sì í ṣọ̀ràn ọdún nìkan, àmọ́ tó di ọ̀ràn ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, làwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mélòó kan bá figbe ta. Ní ọdún 1977, Ọ̀jọ̀gbọ́n Geza Vermes ti Yunifásítì Oxford pè é ní wàyó tó burú jù lọ nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní ọ̀rúndún ogún. Ọ̀rọ̀ àhesọ wá bẹ̀rẹ̀ sí tàn kálẹ̀ pé Ìjọ Kátólíìkì mọ̀ọ́mọ̀ fi àwọn ìsọfúnni tí ń bẹ nínú àwọn àkájọ ìwé náà pa mọ́ ni, látàrí pé ó lè ṣàkóbá fún ẹ̀sìn Kristẹni.
Àárín àwọn ọdún 1980 ni ẹgbẹ́ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ̀ sí i, tó di ogún ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ níkẹyìn. Àmọ́, ẹgbẹ́ náà wá gbòòrò débi tó fi ní àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó lé ní àádọ́ta lọ́dún 1990, lábẹ́ ìdarí Emanuel Tov, tó jẹ́ olóòtú tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn láti Yunifásítì tí wọ́n ti ń ṣèwádìí èdè Hébérù ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n wá ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tó fún wọn ní àkókò pàtó tí wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ gbogbo ìwádìí tí wọ́n ti ṣe lórí àwọn àkájọ ìwé tó ṣẹ́ kù jáde.
Ojúlówó àṣeyọrí kan dé lójijì ní 1991. Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n tẹ ìwé A Preliminary Edition of the Unpublished Dead Sea Scrolls jáde. Wọ́n ṣe èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ kọ̀ǹpútà tí wọ́n gbé karí ẹ̀dà ìwé atọ́ka àwọn ẹgbẹ́ náà. Lẹ́yìn náà, Ibi Ìkówèésí Huntington tó wà ní San Marino, California, kéde pé àwọn óò jẹ́ kí gbogbo fọ́tò àwọn àkájọ ìwé náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ èyíkéyìí. Kò pẹ́ kò jìnnà, ìwé A Facsimile Edition of the Dead Sea Scrolls tí wọ́n tẹ̀ jáde mú kí fọ́tò àwọn ìwé àkájọ tí wọn ò tẹ̀ jáde tẹ́lẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó.
Nítorí náà, ní ẹ̀wádún tó kọjá, gbogbo Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ló ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àyẹ̀wò. Ìwádìí náà fi hàn pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ àṣírí; kò sì sí àwọn àkájọ ìwé tó fara sin. Ìsinsìnyí tí wọ́n ti tẹ apá tí ó kẹ́yìn nínú àwọn àkájọ ìwé náà jáde nìkan ni àyẹ̀wò lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lè bẹ̀rẹ̀. Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀mọ̀wé tí ń kẹ́kọ̀ọ́ àkájọ ìwé jinlẹ̀ tuntun kan ti dé. Àmọ́, kí ni ìjẹ́pàtàkì ìwádìí yìí fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Apocrypha (ni ṣangiliti, túmọ̀ sí “fara sin”), Pseudepigrapha (ni ṣangiliti, sì túmọ̀ sí “àwọn ìwé tí wọ́n fi èké pè ní orúkọ ẹlòmíì”) ni àwọn ìwé tí àwọn Júù kọ ní ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa sí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì tẹ́wọ́ gba Apocrypha gẹ́gẹ́ bí ara àwọn ìwé Bíbélì tí a mí sí, àmọ́ àwọn Júù àtàwọn Pùròtẹ́sítáǹtì kò tẹ́wọ́ gba ìwé wọ̀nyí rárá. Pseudepigrapha tí wọ́n fi orúkọ àwọn tó lókìkí nínú ìtàn Bíbélì kọ, sábà máa ń jẹ́ àfikún ìsọfúnni nípa àwọn ìtàn inú Bíbélì.
b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Wo Là Ń Pè Ní Maccabee?” nínú Ilé Ìṣọ́ ti November 15, 1998, ojú ìwé 21 sí 24.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ìwọ̀nyí wà lára àwọn hòrò tó wà nítòsí Òkun Òkú nínú èyí tí wọ́n ti rí àwọn àkájọ ìwé ìgbàanì
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Àjákù àkájọ ìwé: Ojú ìwé 3, 4, àti 6: Lọ́lá àṣẹ Israel Antiquities Authority
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Lọ́lá àṣẹ Shrine of the Book, Israel Museum, Jerusalem