Ǹjẹ́ Irú Ìtọ́jú Tóo Yàn Ṣe Pàtàkì?
Ǹjẹ́ Irú Ìtọ́jú Tóo Yàn Ṣe Pàtàkì?
ÀÌSÀN, àrùn, àti èṣe tó ń ṣe aráyé ti pọ̀ jù. Nígbà táwọn ọ̀tá àlàáfíà wọ̀nyí bá sì gbéjà ko ọ̀pọ̀ èèyàn, ọ̀dọ̀ àwọn oníṣègùn ni wọ́n ti lọ ń gba ìtọ́jú. Jésù Kristi mọ àǹfààní téèyàn lè rí nínú títọ àwọn oníṣègùn lọ, ìyẹn ló jẹ́ kó sọ pé “àwọn tí ó lera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.”—Lúùkù 5:31.
Oníṣègùn ni Lúùkù alára tó kọ ọ̀rọ̀ Bíbélì wọ̀nyẹn. (Kólósè 4:14) Ó ṣeé ṣe kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jàǹfààní nínú ìmọ̀ ìṣègùn tí Lúùkù ní, bí wọ́n ti jùmọ̀ ń rìnrìn àjò. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ Ìwé Mímọ́ pèsè ìtọ́sọ́nà nípa irú ìtọ́jú tó yẹ káwọn Kristẹni gbà? Ǹjẹ́ irú ìtọ́jú tóo yàn ṣe pàtàkì?
Ìtọ́sọ́nà Látinú Ìwé Mímọ́
Bíbélì lè tọ́ni sọ́nà nínú ṣíṣe àwọn ìpinnu ọlọgbọ́n nípa ìtọ́jú. Fún àpẹẹrẹ, Diutarónómì 18:10-12 là á mọ́lẹ̀ pé àwọn àṣà bí ìwoṣẹ́ àti ṣíṣiṣẹ́ òkùnkùn jẹ́ “ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí” lójú Jèhófà. “Bíbá ẹ̀mí lò,” tí Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa rẹ̀, wà lára àwọn nǹkan táa kà léèwọ̀ wọ̀nyí. (Gálátíà 5:19-21) Ìdí nìyẹn táwọn Kristẹni tòótọ́ fi ń yàgò fún àyẹ̀wò ìṣègùn tàbí ìtọ́jú èyíkéyìí tó bá hàn gbangba pé ó wé mọ́ ìbẹ́mìílò.
Bíbélì tún fi hàn pé ojú ribiribi ni Ẹlẹ́dàá fi ń wo ìjẹ́mímọ́ ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4) Nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pinnu láti ṣègbọràn sí òfin tó sọ pé ká ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀,’ wọ́n kì í gba ìtọ́jú tó bá rú òfin Bíbélì tó ní kí a ta kété sí ẹ̀jẹ̀. (Ìṣe 15:28, 29) Èyí ò wá túmọ̀ sí pé gbogbo ìtọ́jú ni wọ́n ń kọ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fẹ́ ìtọ́jú tó dára jù lọ fún ara wọn àti fáwọn ọmọ wọn. Àmọ́, wọ́n máa ń rọ àwọn oníṣègùn pé kí wọ́n jọ̀wọ́ fún àwọn ní ìtọ́jú tí kò ní tako ìgbàgbọ́ àwọn.
Ronú Nípa Àwọn Ìṣísẹ̀ Rẹ
Sólómọ́nì Ọba kìlọ̀ pé “ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Kódà nígbà tí ìpinnu wa lórí ọ̀ràn ìṣègùn kò bá tako àwọn ìlànà Bíbélì ní tààràtà, ó ṣì yẹ kéèyàn “ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Kì í ṣe gbogbo ìtọ́jú ló ṣàǹfààní. Nígbà tí Jésù sọ pé ‘àwọn tí ń ṣòjòjò nílò oníṣègùn,’ ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ó fọwọ́ sí gbogbo ìtọ́jú táwọn èèyàn ń gbà nígbà ayé rẹ̀. Ó mọ̀ pé àwọn ìtọ́jú kan gbéṣẹ́, àwọn kan sì jẹ́ arúmọjẹ. a
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lónìí, àwọn ìtọ́jú kan lè máà ṣiṣẹ́ rárá, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ arúmọjẹ. Téèyàn ò bá lo làákàyè, ó lè kóra ẹ̀ sínú ewu tó ṣeé yàgò fún. Ó tún yẹ ká mọ̀ pé ìtọ́jú tó ṣiṣẹ́ fún lágbájá lè má ṣiṣẹ́ fún làkáṣègbè, àní ó tiẹ̀ lè pa á lára. Nígbà téèyàn bá fẹ́ ṣe ìpinnu nípa ọ̀ràn ìṣègùn, ẹni tó gbọ́n á fara balẹ̀ gbé gbogbo yíyàn tó wà nílẹ̀ yẹ̀ wò, kò sì ní “ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀,” kódà nígbà tó bá ń gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ onínúure pàápàá. Á lo “ìyèkooro èrò inú” nípa wíwá ìsọfúnni tó ṣeé fọkàn tán, kí ó bàa lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.—Títù 2:12.
Má Ṣàṣejù, Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì
Kò sóhun tó burú nínú ṣíṣàníyàn nípa ìlera wa. Bíbójútó ìlera wa bó ti tọ́ àti bó ṣe yẹ ń fi hàn pé a mọrírì ẹ̀bùn ìwàláàyè àti Ọlọ́run tí í ṣe Orísun rẹ̀. (Sáàmù 36:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ń wá ìtọ́jú yíyẹ, á dáa kí wọ́n wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa ọ̀ràn ìlera. Fún àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan tára rẹ̀ le bá ń ṣe wàhálà àṣejù nípa ìlera àti wíwà ní kanpe, èyí lè máà jẹ́ kó ráyè bójú tó “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10; 2:3, 4.
Obìnrin kan tí àìsàn ń ṣe nígbà ayé Jésù “ná gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀” sórí bóun ṣe máa rí ìtọ́jú gbà lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nítorí àìsàn bára kú tó ń ṣe é. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà ńkọ́? Kàkà kí ó sàn, ńṣe ló túbọ̀ burú sí i, èyí tó wá jẹ́ kí gbogbo rẹ̀ tojú sú u. (Máàkù 5:25, 26) Ó sa gbogbo ipá rẹ̀ kí ó lè rí ìwòsàn, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Ohun tójú rẹ̀ rí fi hàn kedere pé agbára àwọn onímọ̀ ìṣègùn ìgbà ayé rẹ̀ mọ níwọ̀n. Lóde òní gan-an ńkọ́, ṣebí ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti bára wọn nínú irú ipò yẹn, pẹ̀lú gbogbo ìlọsíwájú nínú ìwádìí àti ìmọ̀ nípa ìṣègùn. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé àwọn onímọ̀ ìṣègùn kò lè ṣe ohun gbogbo. Níní ìlera pípé kò ṣeé ṣe lọ́wọ́ táa wà yìí. Àwọn Kristẹni mọ̀ pé àkókò tí Ọlọ́run yóò ‘wo àwọn orílẹ̀-èdè sàn’ ṣì ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Ìṣípayá 22:1, 2) Fún ìdí yìí, èrò wa nípa ìtọ́jú gbọ́dọ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì.—Fílípì 4:5.
Ó ṣe kedere pé ohun táa bá yàn ṣe pàtàkì. Nítorí náà, nígbà táa bá fẹ́ pinnu ìtọ́jú táa fẹ́ gbà, ó yẹ kí ohun táa bá yàn fi hàn pé a fẹ́ kí ara wa le, àti pé a fẹ́ kí àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run wà láìyingin. Báa ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, a lè máa fi ìgbọ́kànlé wọ̀nà fún ìmúṣẹ ìlérí Jèhófà pé nínú ayé tuntun ológo tí ń bọ̀, kò ní “sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ ìṣègùn tí oníṣègùn kan tí wọ́n ń pè ní Dioscorides kọ ní ọ̀rúndún kìíní, sọ pé kí ẹni tí ibà pọ́njú ń ṣe mu oògùn kan tó jẹ́ àpòpọ̀ wáìnì àti ìgbẹ́ ewúrẹ́! Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, a mọ̀ lóde òní pé ńṣe ni irú oògùn yẹn máa dá kún ìṣòro aláìsàn.