Ogun Tí À Ń Bá Ipò Òṣì Jà—Ṣé Àjàpòfo Ni?
Ogun Tí À Ń Bá Ipò Òṣì Jà—Ṣé Àjàpòfo Ni?
ÀWỌN arìnrìn-àjò afẹ́ tó ṣèbẹ̀wò sí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní New York City rí ibi Àpérò Ìgbìmọ̀ Tí Ń Mójú Tó Ọ̀ràn Ìṣúnná Owó àti Ti Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà, wọ́n sì rí àwọn páìpù téèyàn ń wò kedere lára òrùlé tó wà lókè ìloro tí gbogbo gbòò ń gbà kọjá. Ẹni tí ń fi wọ́n mọ̀nà ṣàlàyé pé: “Òrùlé tí wọn ‘kò tíì parí’ yẹn ni wọ́n máa ń rí gẹ́gẹ́ bí àmì tó ń rán wọn létí pé iṣẹ́ tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń ṣe lórí ọ̀ràn ìṣúnná owó àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà kò lè parí; gbogbo ìgbà ni wọ́n á máa rí ohun kan tí wọ́n lè ṣe láti mú kí ipò àwọn ènìyàn inú ayé túbọ̀ sunwọ̀n sí i.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìgbìmọ̀ náà ti fi ara wọn jin jíjẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé, ó dà bí ẹni pé iṣẹ́ náà kò lè parí. Ó yẹ fún àfiyèsí pé, nígbà tí Jésù Kristi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ó sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì.” (Lúùkù 4:18) Kí ni “ìhìn rere” tó polongo? Ó jẹ́ ìhìn tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba tí Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó di “odi agbára fún òtòṣì nínú wàhálà,” yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú èyí tí Jésù Kristi yóò ti jẹ́ Ọba. Kí ni Ìjọba yẹn yóò ṣe? Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sì se àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn fún gbogbo àwọn ènìyàn . . . . àkànṣe àsè wáìnì tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti àwọn oúnjẹ tí a fi òróró dùn, èyí tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ti wáìnì sísẹ́, èyí tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀. Ní ti tòótọ́, òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:4-6, 8.
Ṣé o fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe “mú kí ipò àwọn ènìyàn inú ayé túbọ̀ sunwọ̀n sí i,” kí ó má bàa sí àìní mọ́? Wo ìsàlẹ̀ láti mọ bí o ṣe lè rí olùkọ́ kan tó dáńgájíá, tí yóò wá bẹ̀ ọ́ wò láti túbọ̀ fi ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ hàn ọ́.