Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn ní Kẹ́ńyà

Wíwá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn ní Kẹ́ńyà

Wíwá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn ní Kẹ́ńyà

KẸ́ŃYÀ jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ẹwà rẹ̀ gadabú. Àwọn igbó kìjikìji, àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó lọ salalu, àwọn aṣálẹ̀ tó gbóná bí ajere, àti àwọn òkè ńlá tí yìnyín bò túbọ̀ fi kún ẹwà ilẹ̀ ẹlẹ́tùlójú yìí. Ó jẹ́ ibi tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ẹtu àtàwọn rhino tí a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa tán ń gbé. Èèyàn tún lè rí agbo àwọn àgùnfọn tí ń gba orí pápá kọjá.

Àwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run tún pọ̀ yanturu níbẹ̀, látorí àwọn idì lílágbára, tí ń fò lọ sókè lálá, títí dé orí ẹgbàágbèje àwọn ẹyẹ kọrinkọrin aláwọ̀ mèremère tí ìró orin atunilára wọn máa ń dáni lára yá gágá. Ta ló sì lè gbójú fo àwọn erin àtàwọn kìnnìún ibẹ̀ dá? Mánigbàgbé làwọn ohun téèyàn ń rí, àtàwọn ìró téèyàn ń gbọ́ ní Kẹ́ńyà.

Síbẹ̀, ìró mìíràn tún wà táa ń gbọ́ jákèjádò orílẹ̀-èdè rírẹwà yìí. Ìyẹn ni ìró ẹgbẹẹgbẹ̀rún ohùn tí ń sọ ìhìn tí ń fúnni ní ìrètí jáde. (Aísáyà 52:7) Ohùn yìí ń dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tó wá láti ẹ̀yà àti ahọ́n tó lé ní ogójì. Lọ́nà yìí, Kẹ́ńyà tún jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tó lẹ́wà nípa tẹ̀mí.

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn tó wà ní Kẹ́ńyà ló lẹ́mìí ìsìn, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí. Bo tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àtirí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá nítorí pé Kẹ́ńyà ti ń yí padà bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

Ipò ìṣúnná owó tó le koko ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn yí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn padà. Àwọn obìnrin tó jẹ́ pé iṣẹ́ ilé ni wọ́n máa ń ṣe látọjọ́ táláyé ti dáyé ti bára wọn ní ọ́fíìsì báyìí tàbí kí wọ́n wà lójú pópó níbí tí wọ́n ti ń ta èso, ẹ̀fọ́, ẹja, àti agbọ̀n. Àwọn ọkùnrin máa ń ṣiṣẹ́ àṣeṣúlẹ̀ àti àṣekúdórógbó, níbi tí wọ́n ti ń gbìyànjú àtigbọ́ bùkátà ìdílé wọn. Ọ̀rọ̀ náà kan àwọn ọmọdé pàápàá, ńṣe ni ọwọ́ wọn kéékèèké ń kún fún ẹ̀pà yíyan tí wọ́n dì àti ẹyin sísè, tí wọ́n ń lọ sókè lọ sódò bí wọ́n ṣe ń kiri ọjà wọn lójú pópó. Àbájáde rẹ̀ ni pé ìwọ̀nba èèyàn ló máa ń wà nílé lọ́sàn-án. Ipò yìí ti mú kó pọndandan kí àwọn olùpòkìkí ìhìn rere Ìjọba náà ṣe àwọn ìyípadà kan.

A wá gba àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà níyànjú láti túbọ̀ darí àfiyèsí sí àwọn tí kò sí nínú ilé wọn, tí wọ́n ń wá àtijẹ àtimu káàkiri, títí kan àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí, àwọn oníṣòwò àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀. Àwọn ará fi ohun tí wọ́n gbọ́ yìí sílò, wọ́n ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ níbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí wọn. (Mátíù 10:11) Ǹjẹ́ ìsapá yìí láti lo onírúurú àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ tilẹ̀ ní àṣeyọrí kankan? Bẹ́ẹ̀ ni o! Gbé àwọn àpẹẹrẹ bíi mélòó kan yẹ̀ wò.

Àwọn Ẹbí Ni Ọmọnìkejì Tó Sún Mọ́ Wa Jù Lọ

Nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn ló ń gbé Nairobi tó jẹ́ olú ìlú Kẹ́ńyà. Ìhà ìlà oòrùn ìlú ńlá náà ni ọ̀gá sójà kan tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ń gbé. Ọkùnrin yìí kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ó wá yà á lẹ́nu pé Ẹlẹ́rìí ni ọmọ òun gan-an alára. Ní oṣù February kan báyìí, ọ̀gá tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ yìí rin ìrìn àjò ọgọ́jọ [160] kìlómítà lọ sí ilé ọmọ rẹ̀ ní ìlú Nakuru tó wà ní Àfonífojì Ńlá. Ní àkókò ìbẹ̀wò rẹ̀ yìí, ọmọ rẹ̀ fún un ní ẹ̀bùn kan—ìyẹn ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. a Baba yìí gbà á, ó sì lọ.

Nígbà tó délé, ọ̀gá sójà tẹ́lẹ̀ rí yìí mú ìwé náà fún ìyàwó rẹ̀, tó bẹ̀rẹ̀ sí kà á, láìmọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ̀ ẹ́ jáde. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, òtítọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ohun tó ń kà fún ọkọ rẹ̀. Nítorí pé òun náà fẹ́ rí fìn-ín ìdí kókò, ó bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé náà. Nígbà tí wọ́n wá mọ àwọn tó tẹ ìwé náà jáde, wọ́n rí i pé ohun táwọn ń gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀ kì í ṣe òótọ́ rárá. Wọ́n kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì bẹ̀rẹ̀. Ohun tí wọn kà nínú ìwé náà jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kò tọ́ kí Kristẹni máa mu tábà tàbí kó máa tà á. (Mátíù 22:39; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Láìbojúwẹ̀yìn rárá, wọ́n kó gbogbo sìgá tó wà nínú ṣọ́ọ̀bù wọn dànù. Lẹ́yìn oṣù bíi mélòó kan, wọ́n tóótun láti di akéde tí kò tíì ṣe batisí, kó sì pẹ́ tí wọ́n fi ṣe batisí ní àpéjọpọ̀ àgbègbè kan.

Ìṣúra Kan Jáde Láti Orí Ààtàn

Ní àwọn apá ibì kan ní àgbègbè olú ìlú náà, àwọn abúlé onílé gátagàta kan wà níbẹ̀ tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn ń gbé. Ibí yìí lèèyàn ti ń rí ọ̀pọ̀ ilé tí wọ́n fi amọ̀, igi, àwọn àgékù irin, tàbí páànù kọ́. Nígbà táwọn èèyàn ò bá ríṣẹ́ láwọn ilé iṣẹ́ ńlá àti kéékèèké, àwọn èèyàn á wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣe àdá. Àwọn òṣìṣẹ́ inú Jua kali (èdè Swahili fún “oòrùn gbígbóná janjan”) máa ń ṣe iṣẹ́ àṣekára nínú oòrùn, tí wọ́n a máa fi àwọn ògbólógbòó táyà mọ́tò ṣe sálúbàtà tàbí kí wọ́n máa fi àwọn àlòkù agolo ṣe àtùpà elépo. Àwọn mìíràn a lọ máa ṣa bébà, agolo, àti ìgò tó ṣeé tún lò lórí ààtàn àti nínú àwọn garawa táwọn èèyàn ń da ìdọ̀tí sí.

Ǹjẹ́ a lè rí ìṣúra kankan lórí ààtàn? Bẹ́ẹ̀ ni o! Arákùnrin kan rántí pé: “Ọkùnrin kan tó taagun, tí kò túnra ṣe, tó rí jákujàku gbé àpò ńlá kan tó kún fún àwọn ìwé ìròyìn táwọn èèyàn dànù lérí wá sí ilẹ̀ Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa. Lẹ́yìn tó sọ fún mi pé William lorúkọ òun, ó wá béèrè pé: ‘Ǹjẹ́ o ní àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́?’ Ẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí, nítorí mi ò mọ ohun tí ọkùnrin yìí fẹ́ dán wò. Nígbà tí mo fún un ní ẹ̀dà ìwé ìròyìn márùn-ún, ó wò wọ́n níkọ̀ọ̀kan, ó sì sọ pé: ‘Màá gbà gbogbo wọn.’ Pẹ̀lú ìyàlẹ́nu yẹn, mo padà sínú yàrá mi mo sì mú ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye jáde. b Mo fi àwòrán Párádísè hàn án, mo sì sọ fún un pé a máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Mo wá dábàá pé: ‘William, o ò ṣe kúkú wá lọ́la ká lè bẹ̀rẹ̀ sí bá ọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́?’ Ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn!

“Ó wá sí ìpàdé tó máa kọ́kọ́ wá pàá ní ọjọ́ Sunday kan. Èmi ni mò ń sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn lọ́jọ́ yẹn. Nígbà tí William wọlé, ó wo gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ gààràgà, ó rí mi lórí pèpéle, ó sì sá jáde nínú gbọ̀ngàn náà. Lẹ́yìn náà, mo béèrè ohun tó mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó rọra fìtìjú dáhùn pé: ‘Àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ mọ́ tónítóní gan-an. Ojú wá tì mí.’

“Bí William ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ tó ń kọ́, ni òtítọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà. Ó wẹ̀, ó gẹ irun ẹ̀, ó wọ aṣọ tó mọ́ tónítóní, kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí wá sí àwọn ìpàdé déédéé. Nígbà tí ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun jáde, a bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Láàárín àkókò náà, ó ti níṣẹ́ nígbà méjì ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ó sì ti di akéde tí kò tíì ṣe batisí. Inú mi dùn gan-an láti kí i káàbọ̀ gẹ́gẹ́ bí arákùnrin mi nípa tẹ̀mí nígbà tó ṣe batisí ní àpéjọ àkànṣe.”

Ibo ni William ti kọ́kọ́ rí ìníyelórí Ilé Ìṣọ́? “Mo rí àwọn ìtẹ̀jáde kan láàárín àwọn bébà tí wọ́n dà sórí ààtàn.” Bẹ́ẹ̀ ni, ó rí ìṣúra ní ọ̀nà tó ṣàjèjì yẹn!

Jíjẹ́rìí Ní Ibi Iṣẹ́

Ǹjẹ́ a máa ń lo àwọn àǹfààní táa ní láti jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà níbi iṣẹ́ wa? Ọ̀nà yẹn ni wọ́n gbà fi òtítọ́ Bíbélì han James, tó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ kan ní Nairobi. Lẹ́yìn ìyẹn, òun náà ti wá di ọ̀jáfáfá nínú lílo irú ọ̀nà yẹn láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní àkókò kan, James rí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tó lẹ káàdì tí wọ́n kọ “Jesus Saves” sí máyà wá sí ọ́fíìsì. James fara wé Fílípì ajíhìnrere, ó bi ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ náà pé: “Ǹjẹ́ o lóye àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ní ti gidi?” (Ìṣe 8:30) Ìbéèrè yẹn ni wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kan tó lárinrin. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, ọkùnrin náà sì ṣe batisí níkẹyìn. Ǹjẹ́ James tún ṣàṣeyọrí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Ẹ jẹ́ kó ṣàlàyé:

“Ilé iṣẹ́ kan náà lèmi àti Tom ti ń ṣiṣẹ́. A sábà jọ máa ń wọ bọ́ọ̀sì tí wọ́n fi ń kó àwa òṣìṣẹ́ ni. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé a jọ jókòó pọ̀ ní àárọ̀ ọjọ́ kan. Mo ń ka ọ̀kan nínú àwọn ìwé wa, mo gbé ìwé náà dání lọ́nà tí mo mọ̀ pé Tom fi lè rí i dáadáa. Bí mo ṣe retí gẹ́ẹ́ lọ̀ràn náà rí, kíá ni ìwé náà gba àfiyèsí rẹ̀, mo sì fi tayọ̀tayọ̀ yá a ní ìwé mi. Ohun tó kà níbẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an ni, ó sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òun àti aya rẹ̀ ti di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣe batisí báyìí.”

James ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ: “Léraléra la máa ń ní àwọn ìjíròrò alárinrin láàárín àkókò táa fi ń jáde fún oúnjẹ ọ̀sán níbi iṣẹ́ wa. Àkókò yẹn ni mo fi bá Ephraim àti Walter sọ̀rọ̀ láwọn ìgbà tó yàtọ̀ síra wọn. Àwọn méjèèjì ló mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni mí. Ephraim fẹ́ mọ ìdí táwọn èèyàn fi kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyẹn. Walter ní tiẹ̀ láwọn ìbéèrè nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí àtàwọn ẹ̀sìn mìíràn. Inú àwọn méjèèjì ló dùn gan-an sí bí mo ṣe fi Ìwé Mímọ́ dáhùn àwọn ìbéèrè wọn, wọ́n sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́. Ephraim tẹ̀ síwájú kíákíá. Kò sì pẹ́ tí òun àti aya rẹ̀ fi ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà báyìí, ìyàwó rẹ̀ náà sì ti di aṣáájú ọ̀nà déédéé. Àmọ́, Walter dojú kọ àtakò líle koko débi pé ó ju ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sígbó. Ṣùgbọ́n nítorí pé mi ò juwọ́ sílẹ̀, ó tún padà sórí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Òun náà ti ń gbádùn àǹfààní sísìn bí alàgbà báyìí.” Lápapọ̀, ẹni mọ́kànlá ló ti di Kristẹni tòótọ́ báyìí, nítorí pé James lo àǹfààní tó ní láti jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà níbi iṣẹ́ rẹ̀.

Àbájáde Tó Jẹ́ Àgbàyanu Jù Lọ

Àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ẹbí kóra jọ síbi ètò ìsìnkú kan ní abúlé kékeré kan tó wà ní etídò Adágún Victoria. Arákùnrin àgbàlagbà kan wà lára àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ náà. Ó rìn sún mọ́ olùkọ́ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dolly, ó sì ṣàlàyé fún un nípa ipò táwọn òkú wà àti ète Jèhófà láti mú ikú kúró títí láé. Nígbà tó rí i pé ó fèsì lọ́nà tó dára, ó mú un dá a lójú pé: “Nígbà tóo bá padà sí ìlú rẹ, ọ̀kan lára àwọn míṣọ́nnárì wa yóò wá bá ọ, yóò sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Ìlú Dolly ni ìlú ńlá tó tóbi ṣe ìkẹta ní Kẹ́ńyà. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ míṣọ́nnárì mẹ́rin péré ló ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ lásìkò yẹn. Arákùnrin àgbàlagbà náà kò sọ fún èyíkéyìí nínú àwọn míṣọ́nnárì ọ̀hún pé kí wọ́n lọ bẹ Dolly wò. Ó kàn sáà dá a lójú pé bó ṣe máa rí nìyẹn. Ó sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́! Kò pẹ́ kò jìnnà, arábìnrin míṣọ́nnárì kan bá Dolly pàdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Dolly ti ṣe ìrìbọmi báyìí, ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ti forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì sì ti ṣe batisí. Òun pàápàá ti láǹfààní àtilọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà.

Bíbójútó Ìbísí Náà

Bí a ṣe ń tẹnu mọ́ ìjẹ́rìí àìjẹ́ bí àṣà ti mú kó ṣeé ṣe fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn láti gbọ́ ìhìn rere náà ní Kẹ́ńyà. Àwọn akéde tó lé ní ẹgbàá méje (14,000) ni ọwọ́ wọ́n dí fún iṣẹ́ pàtàkì yìí báyìí, àwọn tó sì lé ní ẹgbàá mẹ́tàdínlógún [34,000] ló wá sí Ìṣe Ìrántí ikú Kristi lọ́dún tó kọjá. Jákèjádò Kẹ́ńyà ni àwọn tó ń wá sípàdé ti sábà máa ń jẹ́ ìlọ́po méjì iye àwọn akéde Ìjọba náà. Èyí sì ti mú kí wọ́n nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i.

Wọ́n ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sáwọn ìlú ńláńlá àtàwọn àgbègbè àdádó. Ọ̀kan lára irú ìlú bẹ́ẹ̀ ni ìlú àdádó kan tó wà ní Àgbègbè Samburu, tó jẹ́ nǹkan bí okòó lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún [320] kìlómítà sí ìhà àríwá ìlà oòrùn Nairobi. Ọdún 1934 ni wọ́n kọ́kọ́ kọ́ ilé tí wọ́n fi páànù kàn síbẹ̀. Ńṣe ló máa ń tàn yinrin nínú oòrùn, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ìlú náà ní “Maralal,” tó túmọ̀ sí “dán yinrin” ní èdè àwọn Samburu. Ọdún méjìlélọ́gọ́ta lẹ́yìn náà ni wọ́n tún kọ́ ilé mìíràn tí wọ́n fi páànù ṣe òrùlé rẹ̀ ní Maralal. Ńṣe lòun náà “ń tàn yinrin,” tó sì “ń kọ mọ̀nà” nítorí pé ó jẹ́ ibi táa kọ́ fún ìjọsìn tòótọ́ ládùúgbò náà.

Àwọn akéde mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó wà níbẹ̀ sapá kárakára láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní apá ibi tó jẹ́ àdádó ní Kẹ́ńyà yìí. Owó tí wọ́n ní lọ́wọ́ kò tó nǹkan, ìdí nìyẹn tí àwọn ará fi ní láti lo àwọn ohun èlò tó wà lágbègbè wọn. Amọ̀ ni wọ́n fi mọ ògiri, wọ́n fi omi po amọ̀ náà, wọ́n sì mọ ọ́n sáàárín àwọn òpó tí wọ́n gbé dúró. Ìgbẹ́ màlúù àti eérú ni wọ́n fi rẹ́ ògiri náà, èyí tó mú kó lágbára tó fi lè wà fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Kí wọ́n lè rí òpó tí wọ́n máa fi kọ́lé náà, àwọn ará gbàṣẹ láti gé igi. Àmọ́ igbó tó sún mọ́ wọn jù lọ jìnnà tó nǹkan bí kìlómítà mẹ́wàá sí ọ̀dọ̀ wọn. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ní láti rìn lọ sínú igbó náà, kí wọ́n gé igi náà lulẹ̀, kí wọ́n gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, kí wọ́n sì gbé àwọn òpó náà padà wá síbi iṣẹ́ ìkọ́lé ọ̀hún. Nígbà kan, bí wọ́n ṣe ń bọ̀ láti inú igbó, àwọn ọlọ́pàá dá àwọn ará dúró, wọ́n sọ pé àṣẹ tí wọ́n gbà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá náà wá sọ fún aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan pé àwọn ti mú un nítorí àwọn igi tí wọ́n gé. Arábìnrin kan tí wọ́n mọ̀ bí ẹni mowó ládùúgbò náà, tí àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún pàápàá mọ̀ dáadáa, sọ pé: “Tí ẹ bá mú arákùnrin wa, ẹ ní láti mú gbogbo wa, nítorí pé gbogbo wa la gé àwọn igi náà!” Bí ọ̀gá ọlọ́pàá náà ṣe fi gbogbo wọn sílẹ̀ nìyẹn.

Àwọn ẹranko búburú wà nínú igbó náà, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé inú ewu la ń rìn. Ní ọjọ́ kan, arábìnrin kan gé igi kan. Bí igi náà ṣe délẹ̀ báyìí ni arábìnrin náà rí ẹranko kan tó bẹ́ gìjà, tó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Nígbà tó rí àwọ̀ rẹ̀ pípọ́n fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fìrí, ó rò pé ẹtu lásán ni, àmọ́ nígbà tó wá wo ipa ẹsẹ̀ rẹ̀ ló wá rí i pé kìnnìún ni! Láìfi irú àwọn ewu bẹ́ẹ̀ pè, àwọn ará parí gbọ̀ngàn náà, ó sì dúró gẹ́gẹ́ bí ibi “dídán yinrin” tí ń fi ìyìn fún Jèhófà.

February 1, 1963 jẹ́ ọjọ́ pàtàkì kan nínú ìtàn ìṣàkóso Ọlọ́run ní Kẹ́ńyà. Ọjọ́ yẹn ni wọ́n ṣí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àkọ́kọ́, tó jẹ́ yàrá kan ṣoṣo tó fẹ̀ ní mítà méje ààbọ̀ níbùú lóròó. October 25, 1997, tún jẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé mìíràn nínú ìtàn ìṣàkóso àtọ̀runwá ní Kẹ́ńyà—ìyẹn ni ọjọ́ tí wọ́n ya Bẹ́tẹ́lì tuntun tó fẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún méje mítà ó lé ẹgbẹ̀rin [7,800] níbùú lóròó sí mímọ́. Iṣẹ́ tí wọ́n parí yìí jẹ́ àṣekágbá kíkọyọyọ fún iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n fi tọkàntọkàn ṣe fún odindi ọdún mẹ́ta. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ti sọ hẹ́kítà mẹ́ta ilẹ̀ ẹlẹ́rẹ̀, tí igbó kún bò, di ọgbà rírẹwà kan tí í ṣe ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa tuntun, tó gba ọgọ́rin àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì.

A ní ìdí tó pọ̀ láti máa yọ̀ nínú ohun tí Jèhófà ti ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ríru tí ó ń ru ọkàn-àyà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sókè kí wọ́n lè lo onírúurú àǹfààní tó ṣí sílẹ̀, kí wọ́n sì tẹra mọ́ wíwá tí wọ́n ń wá àwọn ẹni yíyẹ kàn ní Kẹ́ńyà, tí wọ́n sì sọ ibẹ̀ di orílẹ̀-èdè rírẹwà nípa tẹ̀mí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ̀ ẹ́ jáde.

b Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ̀ ẹ́ jáde.