Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí A Ṣe Lè Rí Ayọ̀ Tòótọ́

Bí A Ṣe Lè Rí Ayọ̀ Tòótọ́

Bí A Ṣe Lè Rí Ayọ̀ Tòótọ́

AṢÁÁJÚ ẹ̀sìn Búdà kan tó ń jẹ́ Dalai Lama, sọ pé: “Mo gbà gbọ́ pé ohun tó jẹ́ ète ìgbésí ayé wa gan-an ni pé ká máa wá ayọ̀.” Ó wá ṣàlàyé pé òun gbà gbọ́ pé a lè rí ayọ̀ nípa kíkọ́ èrò inú àti ọ̀kan wa, tàbí nípa bíbá wọn wí. Ó sọ pé: “Èrò inú ni lájorí ohun táa nílò láti ní ayọ̀ kíkún.” Ó gbà pé kò pọndandan láti gba Ọlọ́run gbọ́. a

Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ti ẹni yẹn, ronú nípa Jésù, ẹni tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run, tí ẹ̀kọ́ rẹ̀ sì ti nípa lórí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá. Jésù fẹ́ kí ẹ̀dá ènìyàn láyọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè táa mọ̀ bí ẹní mowó pẹ̀lú àwọn ìbùkún mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀—ìyẹn àwọn gbólóhùn mẹ́sàn-án tó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú: “Aláyọ̀ ni . . . ” (Mátíù 5:1-12) Nínú ìwàásù yẹn kan náà ló ti kọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ láti ṣàyẹ̀wò èrò inú àti ọkàn wọ́n, láti sọ ọ́ di mímọ́, kí wọ́n sì máa darí rẹ̀ síbi tó tọ́—kí wọ́n fi àwọn èrò àlàáfíà, tó mọ́ tónítóní, tó sì jẹ́ ti ìfẹ́ rọ́pò èrò tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà jàgídíjàgan, ìwà pálapàla, àti ìmọtara-ẹni-nìkan. (Mátíù 5:21, 22, 27, 28; 6:19-21) Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá gbani nímọ̀ràn lẹ́yìn náà pé àwọn ohun tó jẹ́ ‘òótọ́, tó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ti òdodo, tó jẹ́ mímọ́ níwà, tó dára ní fífẹ́, èyí tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, tó jẹ́ ìwà funfun àti èyí tí ó yẹ fún ìyìn’ ni ká ‘máa bá a lọ ní gbígbà rò.’—Fílípì 4:8.

Jésù mọ̀ pé ayọ̀ tòótọ́ ní í ṣe pẹ̀lú bíbá àwọn ẹlòmíràn ṣe nǹkan pọ̀. A dá àwa èèyàn ní ìdá pé ká kóni mọ́ra, nípa bẹ́ẹ̀ a kò lè láyọ̀ tòótọ́ bí a bá ń ya ara wa sọ́tọ̀ tàbí bí a bá ń bá àwọn tó yí wa ká jà ní gbogbo ìgbà. Ìgbà táa bá rí i pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wa, táwa náà sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn nìkan la lè láyọ̀. Jésù kọ́ni pé àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù nínú irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. Ibí yìí gan-an ni ẹ̀kọ́ Jésù ti yàtọ̀ pátápátá sí ti Dalai Lama, nítorí pé Jésù kọ́ni pé àwọn èèyàn kò lè ní ayọ̀ tòótọ́ bí wọn ò bá fi ti Ọlọ́run ṣe. Èé ṣe tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀?—Mátíù 4:4; 22:37-39.

Máa Ronú Nípa Àwọn Àìní Rẹ Nípa Tẹ̀mí

Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún náà ni: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Kí ló dé tí Jésù fi sọ bẹ́ẹ̀? Nítorí pé a ní àwọn àìní nípa tẹ̀mí, a ò dà bí àwọn ẹranko. Nítorí pé a dá wa ní àwòrán Ọlọ́run, a lè mú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run dàgbà dé àyè kan, ìyẹn àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, àánú, àti ọgbọ́n. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Míkà 6:8; 1 Jòhánù 4:8) Àwọn àìní wa nípa tẹ̀mí wé mọ́ jíjẹ́ kí ìgbésí ayé wa ní ète nínú.

Báwo la ṣe lè kájú àwọn àìní nípa tẹ̀mí bẹ́ẹ̀? Kì í ṣe nípa ṣíṣàṣàrò bí àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù tàbí ríronú nípa ara ẹni ṣáá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4) Ṣàkíyèsí pé Jésù sọ pé Ọlọ́run ni orísun “gbogbo àsọjáde” tó ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè wa. Àwọn ìbéèrè kan wà tó jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè bá wa dáhùn wọn. Òde òní gan-an ni òye yẹn wúlò jù lọ, nítorí ọ̀pọ̀ yanturu àbá ni àwọn èèyàn ń dá nípa ète ìgbésí ayé àti ọ̀nà táa lè gbà láyọ̀. Àwọn ilé ìtàwé kún fún àwọn ìwé tó ń sọ nípa bí àwọn òǹkàwé ṣe máa ní ìlera, ọrọ̀ àti ayọ̀. Àwọn ibì kan ti wà lórí íńtánẹ́ẹ̀tì báyìí tó jẹ́ pé kìkì ọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ ló wà níbẹ̀.

Síbẹ̀síbẹ̀, èrò ẹ̀dá aláìpé lórí àwọn kókó wọ̀nyí kì í sábàá tọ̀nà. Ó máa ń dà bí ẹni pé ìfẹ́ ìmọtara ẹni nìkan tàbí ìjọra ẹni lójú ló ń gbé lárugẹ. Orí ìmọ̀ àti ìrírí tí kò tó nǹkan ni wọ́n gbé e kà, ọ̀pọ̀ ìgbà sì wà tó jẹ́ pé orí èrò èké ló máa ń dá lé. Fún àpẹẹrẹ, ohun tó wọ́pọ̀ jù lọ láàárín àwọn tó ń kọ àwọn ìwé tó ń fúnni ní ìmọ̀ràn bí-a-tií-ṣe-é ni pé wọ́n máa ń gbé èrò wọn karí àbá èrò orí “ìrònú òun ìhùwà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n,” tó sọ pé ohun tó fa ìmọ̀lára táwa èèyàn ń ní ni pé ọ̀dọ̀ ẹranko la ti ṣẹ̀ wá. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ìsapá èyíkéyìí táa lè ṣe láti rí ayọ̀ táa gbé ka àbá èrò orí tí kò náání ipa tí Ẹlẹ́dàá wa kó, kò lè lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láé, ìjákulẹ̀ ni yóò yọrí sí níkẹyìn. Wòlíì ayé àtijọ́ kan sọ pé: “Ojú ti àwọn ọlọ́gbọ́n. . . . Wò ó! Àní wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ọgbọ́n wo sì ni wọ́n ní?”—Jeremáyà 8:9.

Jèhófà Ọlọ́run mọ irú ẹ̀dá táa jẹ́, ó sì mọ ohun tó lè mú wa láyọ̀ ní tòótọ́. Ó mọ ìdí tó fi fi ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé, àti ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó sì sọ gbogbo rẹ̀ fún wa nínú Bíbélì. Ohun tó ṣí payá nínú ìwé tí a mí sí yẹn ń gún àwọn tó ní ọkàn-àyà títọ́ ní kẹ́ṣẹ́ ó sì ń fúnni láyọ̀. (Lúùkù 10:21; Jòhánù 8:32) Bí ọ̀ràn méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe rí gẹ́ẹ́ nìyí. Ọkàn wọ́n gbọgbẹ́ gan-an lẹ́yìn ikú rẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù tó jíǹde fẹnu ara rẹ̀ sọ fún wọn nípa ipa tí òun kó nínú ète Ọlọ́run fún ìgbàlà aráyé, wọ́n sọ pé: “Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ ní ojú ọ̀nà, bí ó ti ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́?”—Lúùkù 24:32.

Irú ayọ̀ yẹn máa ń pọ̀ sí i nígbà táa bá jẹ́ kí òtítọ́ Bíbélì ṣamọ̀nà ìgbésí ayé wa. Lọ́nà yìí, a lè fi ayọ̀ wé òṣùmàrè. Ó máa ń yọ nígbà tí ipò nǹkan bá rọgbọ, àmọ́ yóò túbọ̀ ṣe kedere sí i—ó tiẹ̀ lè di òṣùmàrè onílọ̀ọ́po méjì pàápàá—nígbà tí ipò nǹkan bá gún régé gan-an. Ẹ jẹ́ ká wá wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ nípa bí fífi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì sílò ṣe lè mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i.

Má Ṣe Walé Ayé Máyà

Lákọ̀ọ́kọ́, wo ìmọ̀ràn Jésù nípa ọrọ̀. Lẹ́yìn tó fúnni nímọ̀ràn lórí bí a kò ṣe ní jẹ́ kí lílépa ọrọ̀ jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé wa, ó wá sọ gbólóhùn kan tó gbàfiyèsí. Ó ní: “Nígbà náà, bí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan, gbogbo ara rẹ yóò mọ́lẹ̀ yòò.” (Mátíù 6:19-22) Ní pàtàkì, ó sọ pé bí a bá ń fi ìháragàgà lépa ọrọ̀, agbára, tàbí àwọn góńgó mìíràn táwọn èèyàn ń gbé ka iwájú ara wọn, a ó pàdánù àwọn ohun tó túbọ̀ ṣe pàtàkì jù. Nítorí, Jésù sọ ní àkókò mìíràn pé, “nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Bí a bá fi àwọn ohun tó ṣe pàtàkì ní ti gidi sí ipò kìíní, ìyẹn àwọn nǹkan bí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run, àníyàn ìdílé, àti àwọn nǹkan mìíràn tó tan mọ́ ọn, nígbà náà ni “ojú” wa yóò “mú ọ̀nà kan,” tí kò ní ṣe bàìbàì.

Ṣàkíyèsí pé, Jésù kò sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ tàbí fífi gbogbo nǹkan du ara ẹni. Ó ṣe tán, Jésù fúnra rẹ̀ kò ṣẹ́ ara rẹ̀ níṣẹ̀ẹ́. (Mátíù 11:19; Jòhánù 2:1-11) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kọ́ni pé àwọn tí wọ́n wo ìgbésí ayé bí ohun tó wà fún kìkì kíkó ọrọ̀ jọ ń pàdánù ní ti gidi.

Nígbà tí olùtọ́jú àrùn ọpọlọ kan ní San Francisco, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tó ti kékeré lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ní owó ni “gbòǹgbò másùnmáwo àti àìbalẹ̀ ọkàn” fún wọn. Ó fi kún un pé àwọn èèyàn wọ̀nyí “máa ń ra ilé méjì tàbí mẹ́ta, wọ́n a ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, wọ́n a sì náwó wọn sórí àwọn nǹkan mìíràn. Ìgbà tíyẹn ò bá sì ṣe ohun tí wọ́n ń wá fún wọn [ìyẹn ni pé, kó fún wọn láyọ̀], wọ́n a sorí kọ́, ayé wọn ò ní lójú, wọn ò sì ní mọ ohun tí wọ́n máa fi ìgbésí ayé wọn ṣe mọ́.” Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, àwọn tí wọ́n kọbi ara sí ìmọ̀ràn Jésù pé kí wọn má ṣe walé ayé máyà, kí wọ́n sì fàyè sílẹ̀ fún àwọn nǹkan tẹ̀mí ni àwọn tó rọrùn fún jù lọ láti rí ayọ̀ tòótọ́.

Tom, tó ń ṣe iṣẹ́ ilé kíkọ́ ní Hawaii, yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti bá wọn kọ́ àwọn ibi ìjọsìn ní àwọn erékùṣù Pàsífíìkì, níbi táwọn èèyàn kò ti rí jájẹ. Tom kíyè sí ohun kan nípa àwọn ẹni rírẹlẹ̀ wọ̀nyí. Ó ní: “Àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin mi tó wà ní àwọn erékùṣù wọ̀nyí ní ayọ̀ tòótọ́. Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti rí i kedere pé owó àti ohun ìní kọ́ ni ohun tó lè múni láyọ̀.” Ó tún kíyè sí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn, tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ láwọn erékùṣù náà, ó sì rí i bí wọ́n ṣe ní ìtẹ́lọ́rùn tó. Tom sọ pé: “Wọn ì bá ti di olówó rẹpẹtẹ. Àmọ́ wọ́n yàn láti fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò kìíní, kí wọ́n má sì walé ayé máyà.” Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí ni kò jẹ́ kí Tom náà walé ayé máyà, kí ó lè lo àkókò púpọ̀ sí i fún ìdílé rẹ̀ àti fún àwọn nǹkan tẹ̀mí—ìgbésẹ̀ tí kò kábàámọ̀ rẹ̀ rí.

Ayọ̀ àti Iyì Ara Ẹni

Kéèyàn tó lè láyọ̀, ó gbọ́dọ̀ níyì lọ́wọ́ ara ẹ̀, tàbí kó fi ọ̀wọ̀ wọ ara ẹ̀. Nítorí àìpé ẹ̀dá àti àìlera tó tibẹ̀ jáde, àwọn kan máa ń wo ara wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, ọ̀pọ̀ ló sì jẹ́ pé àtikékeré ni wọ́n ti ń fi irú ojú bẹ́ẹ̀ wo ara wọn. Ó lè má rọrùn láti borí irú èrò tó ti fẹsẹ̀ rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó ṣeé ṣe. Fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò ni ojútùú rẹ̀.

Bíbélì ṣàlàyé ojú tí Ẹlẹ́dàá fi ń wò wá. Ǹjẹ́ ojú tó fi ń wò wá kò ṣe pàtàkì ju ti ènìyàn èyíkéyìí lọ—kódà táwa fúnra wa? Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ àpẹẹrẹ ìfẹ́ gan-an ń wò wá láìsí ẹ̀tanú tàbí inú burúkú. Ó mọ ohun táa jẹ́ lónìí, ó sì mọ ohun táa lè dà lọ́la. (1 Sámúẹ́lì 16:7; 1 Jòhánù 4:8) Àní, ojú ohun tó ṣeyebíye, àní, ti ohun tó fani mọ́ra ló fi ń wo àwọn tó ń sapá láti ṣe ohun tó wù ú, láìka àìpé wọn sí.— Dáníẹ́lì 9:23; Hágáì 2:7.

Àmọ́, kì í ṣe pé Ọlọ́run kò ka àwọn àìlera wa àti ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí táa bá dá sí o. Ó retí pé ká sa gbogbo ipá wa láti ṣe ohun tó tọ́, ó sì máa ń tì wá lẹ́yìn nígbà táa bá ṣe bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 13:24) Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró? Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.”—Sáàmù 103:13; 130:3, 4.

Nítorí náà, kọ́ bí o ṣe máa wo ara rẹ bí Ọlọ́run ṣe ń wò ọ́. Mímọ̀ pé ó ń wo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ohun iyebíye àti pé ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú wọn—bí wọ́n tilẹ̀ ń wo ara wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan—lè fi kún ayọ̀ ẹni.—1 Jòhánù 3:19, 20.

Ìrètí Ṣe Pàtàkì fún Ayọ̀

Èròǹgbà kan tí wọ́n ń gbé lárugẹ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, tí wọ́n ń pè ní ìrònú òun ìhùwà gbígbéṣẹ́, sọ pé ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára, tí èèyàn máa ń ní nítorí níní èrò rere àti gbígbájúmọ́ àwọn ànímọ́ rere téèyàn ní, lè yọrí sí ayọ̀. Ṣàṣà lẹni tó lè sẹ́ òtítọ́ náà pé níní èrò nǹkan-yóò-dára nípa ìgbésí ayé àti nípa ọjọ́ iwájú ń fi kún ayọ̀ wa. Àmọ́ ṣá o, irú ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ dá lórí òkodoro òtítọ́, kì í ṣe lórí àlá tí kò lè ṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, kò sí bí ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára tàbí èrò rere náà ṣe lè pọ̀ tó tí yóò wá mú ogun, àìrí oúnjẹ jẹ, àrùn, ìbàyíkájẹ́, ọjọ́ ogbó, àìsàn, tàbí ikú kúrò—ìyẹn àwọn nǹkan tí kì í jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn láyọ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ó níṣẹ́ tí ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára ń ṣe.

Ó yẹ fún àfiyèsí pé Bíbélì kò lo ọ̀rọ̀ náà ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára; ó lo ọ̀rọ̀ kan tó lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ—ìyẹn ni ìrètí. Ìwé atúmọ̀ èdè Vine’s Complete Expository Dictionary túmọ̀ “ìrètí” bí wọ́n ṣe lò ó nínú Bíbélì pé ó jẹ́ “ìfojúsọ́nà tó dára tó sì fini lọ́kàn balẹ̀, . . . fífi ayọ̀ hára gàgà fún ohun tó dára.” Bí Bíbélì ṣe lo ìrètí ju kéèyàn kàn ní ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára nípa ipò kan lọ. Ó tún ń tọ́ka sí nǹkan tí ẹnì kan gbé ìrètí rẹ̀ kà. (Éfésù 4:4; 1 Pétérù 1:3) Fún àpẹẹrẹ, ìrètí Kristẹni ni pé gbogbo àwọn nǹkan búburú táa mẹ́nu kan ní ìpínrọ̀ tó ṣáájú la óò mú kúrò láìpẹ́. (Sáàmù 37:9-11, 29) Àmọ́, ó wé mọ́ ohun tó ju ìyẹn lọ.

Àwọn Kristẹni ń wọ̀nà fún àkókò tí àwọn olóòótọ́ èèyàn yóò ní ìwàláàyè pípé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:42, 43) Láti mú kí ìrètí yẹn ṣe kedere sí i, Ìṣípayá 21:3, 4 sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. . . . Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”

Ẹnikẹ́ni tó bá ń retí àtiní irú ọjọ́ ọ̀la bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ aláyọ̀, kódà bí ipò tó wà báyìí kò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ bára dé. (Jákọ́bù 1:12) Nítorí náà, o ò ṣe yẹ Bíbélì wò, kóo lè rídìí tó fi yẹ kóo gbà á gbọ́. Fún ìrètí rẹ lókun nípa lílo àkókò lórí Bíbélì kíkà lójoojúmọ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí ipò tẹ̀mí rẹ túbọ̀ dára sí i, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fáwọn nǹkan tí kì í jẹ́ káwọn èèyàn láyọ̀, yóò sì jẹ́ kóo túbọ̀ nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Bẹ́ẹ̀ ni o, olórí àṣírí ayọ̀ tòótọ́ ni pé kéèyàn máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Oníwàásù 12:13) Ìgbésí ayé táa gbé ka ṣíṣègbọràn sí àwọn ìlànà Bíbélì jẹ́ ìgbésí ayé aláyọ̀, torí Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—Lúùkù 11:28.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kò pọndandan fáwọn ẹlẹ́sìn Búdà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

A ò lè rí ayọ̀ nípa kíkó ọrọ̀ jọ, yíya ara ẹni sọ́tọ̀, tàbí gbígbẹ́kẹ̀lé ìmọ̀ táṣẹ́rẹ́ téèyàn ní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìgbésí ayé táa gbé ka ṣíṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ìgbésí ayé aláyọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìrètí Kristẹni ń mú kéèyàn láyọ̀